diff --git "a/diacritics/validation/yor.tsv" "b/diacritics/validation/yor.tsv" new file mode 100644--- /dev/null +++ "b/diacritics/validation/yor.tsv" @@ -0,0 +1,1545 @@ +text target +--- Aare Buhari lo le yohun pada lori eto konilegbele – Minisita --- Ààrẹ Buhari ló lè yóhùn padà lórí ètò kónílégbélé – Mínísítà +Minisita fun eto ilera lorileede Naijiria, Osagie Ehanire ti soro lojo Aiku pe, aare Mohammadu Buhari nikan lo lee so igba teto konile-gbele taarun Corona (COVID-19) dasile lorileede Naijiria yoo pari. Mínísítà fún ètò ìlera lórílèèdè Nàìjíríà, Osagie Ehanire ti sọ̣̣̀rọ̀ lọ̣̣́jọ́ Àìkú pé, ààrẹ̣̣ Mohammadu Buhari nìkan ló leè sọ̣̣ ìgbà tétò kónílé-gbélé táárùn Corona (COVID-19) dásílẹ̀ lórílèèdè Nàìjíríà yóò parí. +Minisita tun tesiwaju peto konile-gbele to n lo lowo yii wa nipa beto ilana ti gbogbo orile agbaye lasile. Mínísítà tún tẹ̀síwájú pétò kónílé-gbélé tó ń lọ̣ lọ̣̣́wọ́ yìí wà nípa bétò ìlànà tí gbogbo orílẹ̀ àgbáyé làsílẹ̀. +"O ni, ""Aare yoo logbon re lati so beto konile-gbele yoo se dopin lorileede yii." "Ó ní, ""Ààrẹ̣̣ yóò lọ̣̣gbọ̣̣́n rẹ̀ láti sọ̣̣ bétò kónílé-gbélé yóò se dópin lórílèèdè yìí." +--- COVID-19: Awon eniyan metadinlaadorun un (87) miran tun jeyo lorile ede Naijiria --- COVID-19: Àwọ̣̣n ènìyàn mẹ̣́tàdínláàdọ̣̣́rùn ún (87) míràn tún jẹ̣̣yọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Awon eniyan metadinlaadorun un (87) miran tun ti jeyo ti won ni aarun Corona (COVID 19 ) lorile ede Naijiria ni eyi ti o je ki iye awon to ni aarun Corona je mejilelogosananlelegberun (1182), nigba ti awon eniyan bi okanlenigba ati meji (222 ) ti gba iwosan , ti awon eniyan marundinlogoji (35) si ti je Olorun nipe. Àwọ̣̣n ènìyàn mẹ̣̣́tàdínláàdọ́rùn ún (87) míràn tún ti jẹyọ tí wọ̣̣́n ní ààrùn Corona (COVID 19 ) lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní èyí tí ó jẹ́ kí iye àwọ̣̣n tó ní ààrùn Corona jẹ́ méjìlélọ̣̣́gọ̣̣́sànánlélẹ́gbẹ̣̣̀rún (1182), nígbà tí àwọ̣̣n ènìyàn bi ọ̣̀kànlénígba àti méjí (222 ) ti gba ìwòsàn , tí àwọ̣̣n ènìyàn márùndínlógójì (35) sì ti jẹ́ Ọlọ́run nípè. +Ajo to n gbogun ti ajakale aarun lorile ede Naijiria (NCDC) lo kede yii lori ero Twitter won, @NCDC. gov. Ninu eniyan metadinlaadorun un (87) ti won sese jeyo ohun , metalelogbon ( 33) ni ipinle Eko , mejidinlogun (22) ni ipinle Borno , mejila ( 12) ipinle Osun, mesan an (9) ni ipinle Katsina, eyo merin (4) ni ipinle Kano ati Ekiti , eyo meta (3) ni ipinle Edo ati Bauchi , eyo kan (1) ni ipinle Imo. Àjọ̣ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̣̀ ààrùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NCDC) ló kéde yìí lórí ẹ̀rọ Twitter wọ̣̣n, @NCDC. gov. Nínú ènìyàn mẹ́tàdínláàdọ̣̣́rùn ún (87) tí wọ̣́n ṣ̣ẹ̣̣̀ṣ̣ẹ̀ jẹ̣̣yọ̣̣ ọ̣̣̀hún , mẹ̣̣́tàlélọ̣̣́gbọ̣̣̀n ( 33) ní ìpínlẹ̀ Eko , méjìdínlógún (22) ní ìpínlẹ̀ Borno , méjìlá ( 12) ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, mẹ́sàn án (9) ní ìpínlẹ̀ Katsina, ẹ̣yọ̣ mẹ́rin (4) ní ìpínlẹ̀ Kánò àti Èkìtì , ẹ̣̣yọ̣̣ mẹ́ta (3) ní ìpínlẹ̀ Edo ati Bauchi , ẹ̣̣yọ̣ kan (1) ní ìpínlẹ̀ Imo. +--- Ajo WHO yan Okonjo-Iweala lati je asoju iko to n gbogun ti aarun COVID-19 --- Àjọ̣̣ WHO yan Okonjo-Iweala láti jẹ́ aṣ̣ojú ikọ̀ tó ń gbógun ti ààrùn COVID-19 +Ajo agbaye fun eto ilera , (World Health Organisation, WHO) ti yan minisita fun eto inawo teleri lorile ede Naijiria, Ngozi Okonjo-Iweala gege bi asoju iko tuntun ti yoo maa mojuto irinse ati ohun elo fun itoju aarun COVID-19. Àjọ àgbáyé fún ètò ìlera , (World Health Organisation, WHO) ti yan mínísítà fún ètò ìnáwó tẹ̣́lẹ̣̀rí lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ngozi Okonjo-Iweala gẹ̣̣́gẹ́ bí aṣ̣ojú ikọ̀ tuntun tí yóò máa mójútó irinsẹ́ àti ohun èlò fún ìtọ́jú ààrùn COVID-19. +Omowe Okonjo-Iweala ni yoo maa sise po pelu onisowo ara ile Britain, Andrew Witty, lati maa dari awon ise akanse lati fi gbogun ti aarun COVID-19 fun ajo agbaye. Ọ̣̣̀mọ̣̣̀wé Okonjo-Iweala ni yóò máa ṣ̣iṣ̣ẹ́ pọ̀ pẹ̣̀lú onísòwò ará ilẹ̀ Britain, Andrew Witty, láti máa darí àwọ̣̣n iṣ̣ẹ́ àkànṣ̣e láti fi gbógun ti ààrùn COVID-19 fún àjọ̣̣ àgbáyé. +Oludari ajo naa,Tedros Ghebreyesus, lo soro yii lori ero ayelujara lasiko ti won se idasile iko ohun ni Geneva. Olùdarí àjọ̣̣ náà,Tedros Ghebreyesus, ló sọ̣̣̀rọ̀ yìí lórí ẹ̣̀rọ̣ ayélujára lásìkò tí wọ̣̣́n ṣe ìdásílẹ̀ ikọ̀ ọ̀hún ní Geneva. +Ghebreyesus so pe “Mo fe dupe pupo lowo Andrew Witty ati Ngozi Okonjo-Iweala lati je adari iko ti yoo maa mojuto awon irinse ati ohun elo fun gbigbogun ti aarun COIVD-19. Ghebreyesus sọ pé “Mo fẹ́ dúpẹ́ púpọ̀ lọ̣̣́wọ̣̣́ Andrew Witty àti Ngozi Okonjo-Iweala láti jẹ́ adarí ikọ̀ tí yóò máa mójútó àwọ̣��n irinsẹ̣̣́ àti ohun èlò fún gbígbógun ti ààrun COIVD-19. +"O tun ni , ""Ise akanse yii je ifowosowopo ajo agbaye lati pese awon irinse, oogun , abere ajesara , ohun itoju fun gbigbogun ti aarun COVID-19 ati lati maa pin kaakiri gbogbo orile ede agbaye. """ "Ó tún ní , ""Iṣ̣ẹ́ àkànṣ̣e yìí jẹ́ ìfọ̣̣wọ̣̣́sowọ̣̣́pọ̣̣̀ àjọ̣̣ àgbáyé láti pèsè àwọ̣̣n irinsẹ́, òògùn , abẹ́ṛ̣ẹ́ àjẹsára , ohun ìtọ́jú fún gbígbógun ti ààrùn COVID-19 àti láti máa pín káàkiri gbogbo orílẹ̀ èdè àgbáyé. """ +Lose to koja ni adari ajo eto agbaye lori oro owo yiya, Kristalina Georgieva, tun yan Ngozi Okonjo Iweala gege bi okan lara iko ti yoo maa samojuto eto inawo fun ajo naa. Lọ̣́sẹ̀ tó kọ̣̣já ni adarí àjọ ètò àgbáyé lórí ọ̀rọ̀ owó yíyá, Kristalina Georgieva, tún yan Ngozi Okonjo Iweala gẹ̣̣́gẹ̣́ bí ọ̀kan lára ikọ̀ tí yóò máa ṣ̣àmójútó ètò ìnáwó fún àjọ̣̣ náà. +Iko naa yoo maa sepade loore-koore lodun lati maa salaye nipa idagbasoke ati eto ilana ti won ti se. Ikọ̀ náà yóò máa ṣ̣èpàdé lóòrè-kóòrè ḷ̣ọ̣̣́dún láti máa sàlàyé nípa ìdàgbàsókè àti ètò ìlànà tí wọ́n ti sẹ. +--- COVID-19: Iyawo aare Buhari pin awon ohun ile-iwosan --- COVID-19: Ìyàwó ààrẹ Buhari pín àwọn ohun ilé-ìwòsàn +Iyawo aare orile ede Naijiria, iyaafin Aisha Buhari ti pin awon ohun elo ile-iwosan fun iranwo lati gbogun ti itankale aarun Corona iyen COVID-19. Ìyàwó ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìyáàfin Aisha Buhari ti pín àwọn ohun èlò ilé-ìwòsàn fún ìrànwọ́ láti gbógun ti ìtànkálẹ̀ ààrùn Corona ìyẹn COVID-19. +Iyaafin Buari fi aidunu re han si bi aarun asekupani COVID 19 se n tan kale kaakiri tibu tooro orile ede Naijiria eyi si ti mu ki o dide si a ti ko awon ohun iranwo jo lati koju aarun naa. Ìyáàfin Bùárí fi àìdùnú rẹ̀ hàn sí bí ààrùn aṣekúpani COVID 19 ṣe ń tàn kálẹ̀ káàkiri tìbú tòòró orílẹ̀ èdè Nàìjíríà èyí sì ti mú kí ó dìde sí à ti kó àwọn ohun ìrànwó jọ láti kojú ààrùn náà. +Iyaafin Buhari wa fi idunnu re han si gbogbo awon to pese iranwo fun gbigbogun ti itankale aarun ohun naa, O ni, “orile ede Naijiria yoo jegbadun awon eto iranwo ti e pese. Ìyáàfin Buhari wá fi ìdùnnú rẹ̀ hàn sí gbogbo àwọn tó pèsè ìrànwọ̣̣́ fún gbígbógun ti ìtànkálẹ̀ ààrùn ọ̣̣̀hún náà, Ó ní, “orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yóò jẹ̣̣̀gbádùn àwọ̣̣n ètò ìrànwọ̣̣̣́ tí ẹ pèṣ̣̣è. +Iyaafin Buari wa pe awon omo Naijiria lati wa lailewu ki won si maa fi aaye sile laarin ara won lati lee bori ajakale arun yii. Ìyáàfin Bùárí wá pe àwọn ọmọ Nàìjíríà láti wà láìléwu kí wọn sì máa fi ààyè sílẹ̀ láàrín ara wọn láti leè borí àjàkálẹ̀ àrùn yìí. +O tun ro “awon ipinle ti won je anfaani ohun iranwo wonyi lati lo won daradara” Ó tún rọ “àwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n jẹ àǹfààní ohun ìrànwọ́ wọ̀nyí láti lò wọ́n dáradára” +Oluranlowo pataki fun iyaafin aare Buhari lori eto ilana ise ati igbaye-gbadun awon obinrin, Hajo Sani lo soju iyawo aare Buhari lasiko ayeye lati pin awon ohun elo ohun niluu Abuja. Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ìyáàfin ààrẹ Buhari lórí ètò ìlànà iṣẹ́ ati ìgbáyé-gbádùn àwọn obìnrin, Hajo Sani ló ṣojú ìyàwó ààrẹ Buhari lásìkò ayẹyẹ láti pín àwọn ohun èlò ọ̀hún nílùú Àbújá. +Lara awon ohun elo ti won pin ohun ni; awon ose ifowo a-pa kokoro, awon oogun oyinbo, ohun elo idaabo bo ara, irinse, ibowo ati aso idaabo bo. Lára àwọn ohun èlò tí wọ́n pín ọ̀hún ni; àwọn ọṣẹ ìfọwọ́ á-pa kòkòrò, àwọn òògùn òyìnbó, ohun èlò ìdáàbò bo ara, irinsẹ́, ìbọ̀wọ́ àti aṣọ ìdáàbò bò. +Awon ohun miran tun ni aso ibowo, gilaasi iboju, awon ohun ibusun abbl. Àwọn ohun míràn tún ni aṣọ ìbọ̀wọ́, gíláásì ìbòjú, àwọn ohun ìbùsùn abbl. +Awon ipinle meta ni won fun ni awon ohun elo wonyi, awon ipinle naa ni Bauchi, Gombe ati ilu Abuja, Federal Capital Territory (FCT). Àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́ta ni wọ́n fún ní àwọn ohun èlò wọ̀nyí, àwọn ìpínlẹ̀ náá ní Bauchi, Gombe àti ìlú Àbújá, Federal Capital Territory (FCT). +Adari eka to n mojuto ise akanse fun eto ilera ati igbaye –gbadun awon eniyan, niluu Abuja ,Mathew Ashikeni, lo tewogba awon ohun elo ohun fun minisita ilu Abuja. Adarí ẹ̀ka tó ń mójútó isẹ́ àkànse fún ètò ìlera àti ìgbáyé –gbádùn àwọn ènìyàn, nílùú Àbújá ,Mathew Ashikeni, ló tẹ́wọ́gba àwọn ohun èlò ọ̀hún fún mínísítà ìlú Àbújá. +Dokita Ashikeni ni; “Awon ohun elo iranwo naa yoo wulo lati gbogun ti aarun COVID-19 ni olu-ilu orile ede Naijiria, to wa niluu Abuja. Dókítà Ashikeni ní; “Àwọ̣n ohun èlò ìrànwọ́ náà yóò wúlò láti gbógun ti ààrun COVID-19 ní olú-ìlú orílẹ̣̀ èdè Nàìjíríà, tó wà nílùú Àbújá. +O wa fi awon asoju ohun loju pe awon yoo lo ohun elo naa bo se to ati bo se ye. Ó wá fi àwọn aṣojú ọ̀hún lójú pé àwọn yóò lo ohun èlò náà bó se tọ́ àti bó se yẹ. +--- COVID-19: Awon eniyan merinlelaadofa (114) miran tun jeyo lorile ede Naijiria, iye awon to ni aarun Corona je marundinlogorunlelegberun (1095) --- COVID-19: Àwọn ènìyàn mẹ́rìnléláàdọ́fà (114) míràn tún jẹyọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, iye àwọn tó ní ààrun Corona jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùńlélẹ́gbẹ̀rún (1095) +Awon eniyan merinlelaadofa (114) miran tun ti jeyo ti won ni aarun Corona (COVID 19 ) lorile ede Naijiria ni eyi ti o je ki iye awon to ni aarun Corona je marundinlogorunlelegberun (1095), nigba ti awon eniyan bi mejidinlaadofa (208 ) ti gba iwosan , ti awon eniyan mejilelogbon (32) si ti je Olorun nipe. Àwọn ènìyàn mẹ́rìnléláàdọ́fà (114) míràn tún ti jẹyọ tí wọ́n ní ààrun Corona (COVID 19 ) lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní èyí tí ó jẹ́ kí iye àwọn tó ní ààrun Corona jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùńlélẹ́gbẹ̀rún (1095), nígbà tí àwọn ènìyàn bí méjídínláàdọ́fà (208 ) ti gba ìwòsàn , tí àwọn ènìyàn méjìlélọ́gbọ̀n (32) sì ti jẹ́ Ọlọ́run nípè. +Ajo to n gbogun ti ajakale aarun lorile ede Naijiria (NCDC) lo kede yii loriero Twitter won, @NCDC. gov ni deede aago mejila koja iseju marundinlogbon,lojo Eti ,ojo kerinlelogun, Osu kerin,odun, 2020. Àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ ààrùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NCDC) ló kéde yìí lóríẹ̀rọ Twitter wọn, @NCDC. gov ní déédé aago méjìlá kọjá ìsẹ́jú márùndínlọ́gbọ̀n,lọ́jọ́ Ẹtì ,ọjọ́ kẹrìnlélógún, Osù kẹrin,ọdún, 2020. +Ninu eniyan merinlelaadofa (114) ti won sese jeyo ohun , ogorin ( 80) ni ipinle Eko , mokanlelogun (21) ni ipinle Gombe , marun un ( 5) ni ilu Abuja, Federal Capital Territory (FCT), meji (2) ni ipinle Zamfara ati Edo, eyo kan (1) ni ipinle Ogun, Oyo, Kaduna ati ipinle Sokoto. Nínú ènìyàn mẹ́rìnléláàdọ́fà (114) tí wọn sẹ̀sẹ̀ jẹyọ ọ̀hún , ọgọ́rin ( 80) ní ìpínlẹ̀ Èkó , mọ́kànlélógún (21) ní ìpínlẹ̀ Gombe , márùn ún ( 5) ní ilu Àbújá, Federal Capital Territory (FCT), méjì (2) ní ìpínlẹ̀ Zamfara àti Edó, ẹyọ kan (1) ní ìpínlẹ̀ Ògùn, Ọ̀yọ́, Kàdúná àti ìpínlẹ̀ Sókótó. +--- Abba Kyari je oloooto fun aare Buhari ati agbenuso rere fun Amerika: Ijoba Amerika --- Abba Kyari jẹ́ olóòótọ́ fún ààrẹ Buhari àti agbẹnusọ rere fún Amẹ́ríkà: Ìjọba Amẹ́ríkà +Ijoba orile ede Amerika ti sapejuwe oloogbe Abba Kyari gege bi o se je oloooto adari osise ijoba fun aare Buhari ati agbenuso rere fun ijoba orile ede Amerika. Ìjọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti ṣàpéjúwe olóògbé Abba Kyari gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ̣̣́ olóòótọ́ adarí òṣìṣẹ́ ìjọba fún ààrẹ Buhari àti agbẹnuṣọ rere fún ìjọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. +Ninu oro ibanikedun re si aare Muhammadu Buhari, igbakeji akowe agba ipinle to n mojuto eto ile Afirika, Tibor Nagy, lo gbosuba fun iwa akinkanju ti oloogbe Kyari,wu paapaa julo, nipa bi orile ede Amerika se da owo ti iye re je oodunrun milionu dola ($300 million) ti oloogbe Sani Abacha jigbe lo si orile Amerika pada fun orile Naijiria. Nínú ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn rẹ̣̀ sí ààrẹ Muhammadu Buhari, igbákejì akọ̀wé àgbà ìpínlẹ̀ tó ń mójútó ètò ilẹ̀ Áfíríkà, Tibor Nagy, ló gbósùbà fún ìwà akínkanjú tí olóògbé Kyari,wù pàápàá jùlọ, nípa bí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ṣe dá owó tí iye rẹ̀ jẹ́ ọ́ọ̀dúnrún mílíọ̀nù dọ́là ($300 million) tí olóògbé Sani Abacha jígbé lọ sí orílẹ̀ Amẹ́ríkà padà fún orílẹ̀ Nàìjíríà. +Nagy so pe Kyari je oloooto adari osise ijoba fun aare Buhari ati agbenuso rere fun ijoba orile ede Amerika paapaa julo adari rere fun iko wa to wa niluu Abuja. Nagy sọ pé Kyari jẹ́ olóòótọ́ adarí òṣìṣẹ́ ìjọba fún ààrẹ Buhari àti agbẹnuṣọ rere fún ìjọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà pàápàá jùlọ adarí rere fún ikọ̀ wa tó wà nílùú Àbújá. +Inu wa dun lati ba oloogbe Kyari se awon ise gidi-gidi papo paapaa julo, nipa bi won se da oodunrun milionu dola ($300 million) ti oloogbe Sani Abacha jigbe lo si orile ede Amerika pada fun orile ede Naijiria. Inú wa dùn láti bá olóògbé Kyari ṣe àwọn iṣ̣ẹ́ gidi-gidi papọ̀ pàápàá jùlọ, nípa bí wọ́n ṣe dá ọ́ọ̀dúnrún mílíọ́nù dọ́là ($300 million) tí olóògbé Sani Abacha jígbé lọ sí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà padà fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +O dabaa pe ki won pin owo ohun si ona meta lati fi se awon ise akanse ohun amayederun, ni eyi lati lee je ki isokan ati eto oro aje tubo fese mule lorile ede Naijiria. Ó dábàá pé kí wọ́n pín owó ọ̀hún sí ọ̀nà mẹ́ta láti fi ṣe àwọn iṣẹ́ àkànṣe ohun amáyédẹrùn, ní èyí láti lèè jẹ́ kí ìsọ̀kan àti ètò ọrọ̀ ajé túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Nagy soro yii lasiko to n kedun pelu ijoba ati awon omo orile ede Naijiria ati ebi Kyari , o ni ijoba orile ede Amerika ti seleri lati duro ti orile ede Naijiria lati gbogun ti itankale aarun Corona. Nagy sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń kẹ́dùn pẹ̀lú ìjọba àti àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti ẹbí Kyari , ó ní ìjọba ̀orílẹ̀ èdè Améríkà ti ṣèlérí láti dúró ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti gbógun ti ìtànkálẹ̀ ààrun Corona. +Aare tun ri iwe ikedun gba lati owo minisita fun Niger Delta, Usani Uguru Usani, olokoowo lati ilu Kano, Alhaji Sabiu Bako ati adari awon osise, Ààrẹ tún rí ìwé ìkẹ́dùn gbà láti ọwọ́ mínísítà fún Niger Delta, Usani Uguru Usani, olókoòwò láti ìlú Kánò, Alhaji Sabiu Bàkó àti adarí àwọn òṣìṣẹ́, +--- COVID-19: Awon eniyan mejidinlaadofa (108) miran tun jeyo lorile ede Naijiria --- COVID-19: Àwọn ènìyàn méjìdínláàdọ́fà (108) míràn tún jẹyọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Awon eniyan mejidinlaadofa (108) miran tun ti jeyo ti won ni aarun Corona (COVID 19) lorile ede Naijiria. Àwọn ènìyàn méjìdínláàdọ́fà (108) míràn tún ti jẹyọ tí wọ́n ní ààrun Corona (COVID 19) lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Ni eyi ti o je ki iye awon to ni aarun Corona je mokandilogundinlegberun (981) Ní èyí tí ó jẹ́ kí iye àwọn tó ní ààrùn Corona jẹ́ mọ́kàndílógúndínlẹ́gbẹ̀rún (981) +Ajo to n gbogun ti ajakale aarun lorile ede Naijiria (NCDC) lo kede yii lori ero Twitter won, @NCDC. gov. Àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ ààrùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NCDC) ló kéde yìí lórí ẹ̀rọ Twitter wọn, @NCDC. gov. +Ninu eniyan mokandilogundinlegberun (981) ti won sese jeyo ohun , mejidinlogorin (78) ni ipinle Eko , marun un (5) ni ipinle Katsina , merinla ( 14) ni ilu Abuja, Federal Capital Territory (FCT), marun un (5) ni ipinle Ogun, merin (4) ni ipinle Gombe, meta (3) ni ipinle Borno, meji (2) ni ipinle Akwa Ibom, eyo kan (1 )ni ipinle Kwara ati eyo kan (1 ) ni ipinle Plateau. Nínú ènìyàn mọ́kàndílógúndínlẹ́gbẹ̀rún (981) tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹyọ ọ̀hún , méjìdínlọ́gọ́rin (78) ní ìpínlẹ̀ Èkó , márùn ún (5) ní ìpínlẹ̀ Katsina , mẹ́rìnlá ( 14) ní ìlú Àbújá, Federal Capital Territory (FCT), márùn ún (5) ní ìpínlẹ̀ Ògùn, mẹ́rin (4) ní ìpínlẹ̀ Gombe, mẹ́ta (3) ní ìpínlẹ̀ Borno, méjì (2) ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom, ẹyọ kan (1 )ní ìpínlẹ̀ Kwara ati ẹyọ kan (1 ) ní ìpínlẹ̀ Plateau. +--- Ile-ise ologun ofurufu se idanilekoo fun awon noosi re nipa sise itoju awon to ba farapa --- Ilé-iṣẹ́ ológun òfúrufú ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn nọ́ọ̀sì rẹ̀ nípa ṣíṣe ìtọ́jú àwọn tó bá farapa +Ile-ise ologun ofurufu orile ede Naijiria (NAF) ti se idanilekoo fun awon noosi oko ofurufu ati awon awako ofurufu. Ilé-iṣẹ́ ológun òfúrufú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NAF) ti ṣ̣e ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn nọ́ọ̀sì ọkọ̀ òfúrufú àti àwọn awakọ̀ òfúrufú. +idanilekoo yii wa lara awon eto ilana ti ile-ise ologun ofurufu la sile fun awon iko omo ogun won nipa bi won yoo se maa ko ati se itoju awon omo ogun to ba farapa loju ogun. ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí wà lára àwọn ètò ìlànà tí ilé-iṣẹ́ ológun òfúrufú là sílẹ̀ fún àwọn ikọ̀ ọmọ ogun wọn nípa bí wọn yóò ṣe máa kó àti ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ ogun tó bá farapa lójú ogun. +Adari eka iroyin ati ibasepo ti iko omo ogun ofurufu ohun (NAF) Air Commodore Ibikunle Daramola so pe idanilekoo olose- kan pari nipa lilo oko ofurufu C-130H to wa ni papa oko ofurufu Nnamdi Azikwe to n mojuto irinajo ile okeere to wa niluu Abuja, ni eyi lati je ki awon iko omo ogun ohun ni imo to gbohunje-fegbe, gbawobo nipa sise itoju ninu oko ofurufu fun awon omo ogun to ba farapa loju ogun lati du emi won titi ti won yoo fi gbe won de ile-iwosan. Adarí ẹ̀ka ìròyìn àti ìbáṣepọ̀ tí ikọ̀ ọmọ ogun òfúrufú ọ̀hún (NAF) Air Commodore Ìbíkúnlé Dáramólá sọ pé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́sẹ̀- kan parí nípa lílo ọkọ òfúrufú C-130H tó wà ní pápá ọkọ̀ òfúrufú Nnamdi Azikwe tó ń mójútó írínájó ilẹ̀ òkèèrè tó wà nílùú Àbújá, ní èyí láti jẹ́ kí àwọn ikọ̀ ọmọ ogun ọ̀hún ní ìmọ̀ tó gbóhúnjẹ-fẹ́gbẹ́, gbàwobọ̀ nípa ṣíṣe ìtọ́jú nínú ọkọ̀ òfúrufú fún àwọn ọmọ ogun tó bá farapa lójú ogun láti du ẹ̀mí wọn títí tí wọn yóò fi gbé wọn dé ilé-ìwòsàn. +Daramola ni won ti se oko ofurufu NAF C-130H lona ti awon ohun elo ti awon to ba farapa tabi alaisan lee lo lati gba itoju pajawiri. Dáramólá ní wọn ti se ọkọ̀ òfúrufú NAF C-130H lọ́nà tí àwọn ohun èlò tí àwọn tó bá farapa tàbí aláìsàn leè lò láti gba ìtọ́jú pàjáwìrì. +Adari ile-ise ologun oko ofurufu lorile ede Naijiria, ogagun Sadique Abubakar, wa fi idunnu re han nipa idanilekoo ohun bi awon noosi ti yoo maa wa ninu oko ofurufu naa se fakoyo. Adarí ilé-iṣẹ́ ológun ọkọ̀ òfúrufú lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ọ̀gágun Sadique Abubakar, wá fi ìdùnnú rẹ̀ hàn nípa ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún bí àwọn nọ́ọ̀ṣì tí yóò máa wà nínú ọkọ̀ òfúrufú náà ṣe fakọyọ. +O tesiwaju pe won tun lee lo awon irinse ati ohun elo ohun fun gbigbe awon alaisan aarun COVID-19 to ba nilo itoju ni kiakia. Ó tẹ̀síwájú pé wọ́n tún leè lo àwọn irinṣẹ́ àti ohun èlò ọ̀hún fún gbígbé àwọn aláìsàn ààrun COVID-19 tó bá nílò ìtọ́jú ní kíákíá. +Adari ohun tun ni lati bi odun merin ati aabo seyin ni ile-ise iko omo ogun ofurufu ti n gbiyanju lati seto idalekoo fun iko osise eleto ilera to je omo ogun oko ofurufu nipa pipese itoju eto ilera fun awon iko omo ogun, ebi won ati awon to ba farapa loju ogun. Adarí ọ̀hún tún ní láti bí ọdún mẹ́rin àti ààbọ̀ sẹ́yìn ní ilé-iṣẹ́ ikọ̀ ọmọ ogun òfúrufú ti ń gbìyànjú láti ṣètò ìdálẹ́kọ́ọ̀ fún ikọ̀ òṣìṣẹ́ elétò ìlera tó jẹ́ ọmọ ogun ọkọ̀ òfúrufú nípa pípèsè ìtọ́jú ètò ìlera fún àwọn ikọ̀ omọ ogun, ẹbí wọn àti àwọn tó bá farapa lójú ogun. +--- Ile-ise ologun run agbegbe ti iko omo ogun olote fi n se ibugbe ni ipinle Borno --- Ilé-iṣẹ́ ológun run agbègbè ti ikọ̀ ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ fi ń ṣe ibùgbé ní ìpínlẹ̀ Borno +Ile-ise ologun ori afefe, iyen Air Task Force of Operation LAFIYA DOLE, ti run gbogbo awon agbegbe ti adari iko omo ogun olote Boko Haram fi n se ibugbe ni Bulawa ninu igbo Sambisa to wa ni ipinle Borno patapata. Ilé-isẹ́ ológun orí afẹ́fẹ́, ìyẹn Air Task Force of Operation LAFIYA DOLE, ti run gbogbo àwọn agbègbè tí adarí ikọ̀ ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ Boko Haram fi ń ṣe ibùgbé ní Bulawa nínú igbó Sambisa tó wà ní ìpínlẹ̀ Borno pátápátá. +Agbenuso fun eka iroyin ile-ise ohun, ogagun John Enenche so pe“ oko ogun ofurufu bere si ni maa ju ado oloro si awon agbegbe ti adari iko olote Boko Haram wa nipase iroyin ti awon gbo pe agbegbe naa ni o farapamo si. Agbẹnusọ fún ẹ̀ka ìròyìn ilé-iṣẹ́ ọ̀hún, ọ̀gágun John Enenche sọ pé“ ọkọ̀ ogun òfúrufú bẹ̀rẹ̀ sí ní máa ju àdó olóró sí àwọn agbègbè tí adarí ikọ̀ ọlọ́tẹ̀ Boko Haram wà nípaṣẹ̀ ìròyìn tí àwọn gbọ́ pé agbègbè náà ni ó farapamọ́ sí. +Ogagun John Enenche tun ni ki o to di pe iko olote Boko Haram to maa gbaradi lati koju ija pelu iko omo -ogun ofurufu to n ju ado oloro ni kikan-kikan si agbegbe, ni awon ti fi ado oloro se won bi ose se n soju. Ọ̀gágun John Enenche tún ní kí ó tó di pé ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀ Boko Haram tó máa gbáradì láti kojú ìjà pẹ̀lú ikọ̀ ọmọ -ogun òfúrufú tó ń ju àdó olóró ní kíkan-kíkan sí agbègbè, ni àwọn ti fi àdó olóró ṣe wọ́n bí ọṣẹ́ ṣe ń ṣojú. +--- Aare Buhari fi ikini ranse si awon Musulumi bi Ramandan se bere --- Ààrẹ Bùhárí fi ìkíni ránṣẹ́ sí àwọn Mùsùlùmí bí Ramandan ṣe bẹ̀rẹ̀ +Aare orile ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti fi ikini re ranse si gbogbo awon musulumi to wa lorile ede yii ati ni gbogbo agbaye latari bi won se ri osupa lati bere aawe ogbonjo. Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti fi ìkíni rẹ̀ ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn mùsùlùmí tó wà lórílẹ̀ èdè yìí àti ni gbogbo àgbáyé látàrí bí wọ́n ṣe rí òṣùpá láti bẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ ọgbọ̀njọ́. +Aare Buhari ni o seni laaanu pe aawe odun yii waye lasiko ti gbogbo agbaye n koju Ààrẹ Buhari ní ó ṣeni láàànù pé ààwẹ̀ ọdún yìí wáyé lásìkò tí gbogbo àgbáyé ń kojú +ipenija ajakale aarun COIVD-19, ni eyi ti o ti tan ka igba (200) orile ede to wa lagbaaye, ti gbogbo orile ede si n pariwo pe ki awon eniyan yago fun ipejopo, ki won si maa da gbadura ati isirun won tabi pelu ebi won. ìpèníjà àjàkálẹ̀ ààrùn COIVD-19, ní èyí tí ó ti tàn ká igba (200) orílẹ̀ èdè tó wà lágbàáyé, tí gbogbo orílẹ̀ èdè sì ń pariwo pé kí àwọn ènìyàn yàgò fún ìpéjọpọ̀, kí wọ́n sì máa dá gbàdúrà àti ìsírun wọn tàbí pẹ̀lú ẹbí wọn. +"Aare tun tesiwaju pe ""Lasiko Ramadan yii, ibasepo ti e maa n se tele ti di ohun ti aarun Corona so di ewu bayii,"" aare wa ro gbogbo awon musulumi lati sora , ki won si yago fun awon ipejopo nipa ounje ati gbigbadura papo, ni eyi ti awon adari elesin ti fopin si bayii ni gbogbo agbaye." "Ààrẹ tún tẹ̀síwájú pé ""Lásìkò Ramadan yìí, ìbásepọ̀ tí ẹ máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ ti di ohun tí ààrun Corona ṣọ di ewu báyìí,"" ààrẹ wá rọ gbogbo àwọn mùsùlùmí láti sọ́ra , kí wọ́n sì yàgò fún àwọn ìpéjọpọ̀ nípa oúnjẹ àti gbígbàdúrà papọ̀, ní èyí tí àwọn adarí ẹlẹ́sìn ti fòpin si báyìí ní gbogbo àgbáyé." +Aare Buhari tun wa ro gbogbo awon musulumi lati farada isele aarun Corona to n ja lorile ede yii sugbon ki won maa se lo isele ohun lati fi yera nipa kikopa ninu aawe Ramadan ayafi ti won ba ni idi kan pataki to ni se pelu eto ilera tabi eyi ti adari esin ba la sile lati maa kopa ninu aawe ohun. Ààrẹ Buhari tún wá rọ gbogbo àwọn mùsùlùmí láti farada ìṣẹ̀lẹ̀ ààrun Corona tó ń jà lórílẹ̀ èdè yíí sùgbọ́n kí wọn máa ṣe lo ìsẹ̀lẹ̀ ọ̀hún láti fi yẹra nípa kíkópa nínú ààwẹ̀ Ramadan àyàfi tí wọ́n bá ní ìdí kan pàtàkì tó ní ṣe pẹ̀lú ètò ìlera tàbí èyí tí adarí ẹ̀sìn bá là sílẹ̀ láti máa kópa nínú ààwẹ̀ ọ̀hún. +O wa ki gbogbo awon musulumi lorile ede yii ati ni gbogbo agbaye pe gbogbo ibukun inu aawe mimo yii yoo je ti won. Ó wá kí gbogbo àwọ̣n mùsùlùmí lórílẹ̀ èdè yìí àti ní gbogbo àgbáyé pé gbogbo ìbùkún inú ààwẹ̀ mímọ́ yìí yóò jẹ́ ti wọn. +--- COVID-19: Awon eniyan mokanlelaadorun un (91) miran tun jeyo lorile ede Naijiria --- COVID-19: Àwọn ènìyàn mọ́kànléláàdọ́rùn ún (91) míràn tún jẹyọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Awon eniyan mokanlelaadorun un (91) miran tun ti jeyo ti won ni aarun Corona (COVID 19 ) lorile ede Naijiria. Àwọn ènìyàn mọ́kànléláàdọ́rùn ún (91) míràn tún ti jẹyọ tí wọ́n ní ààrùn Corona (COVID 19 ) lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Ni eyi ti o je ki iye awon to ni aarun Corona je metalelaadorinleniegberin(873), nigba ti awon eniyan bi metadinnigba (197 ) ti gba iwosan , ti awon eniyan marundinlogbon (25) si ti je Olorun nipe. Ní èyí tí ó jẹ́ kí iye àwọn tó ní ààrùn Corona jẹ́ mẹ́tàléláàdọ́rinléníẹgbẹ̀rin(873), nígbà tí àwọn ènìyàn bí mẹ́tàdínnígba (197 ) ti gba ìwòsàn , tí àwọn ènìyàn márùndínlọ́gbọ̀n (25) ṣì ti jẹ́ Ọlọ́run nípè. +Ninu eniyan mokanlelaadorun un (91) ti won sese jeyo ohun , merinlelaadorin ( 74) ni ipinle Eko , marun un (5) ni ipinle Katsina ,eyo kan ( 1) ni ilu Abuja, Federal Capital Territory (FCT), merin (4) ni ipinle Ogun, meji (2) ni ipinle Delta ati Edo ,eyo kan (1) ni ipinle Oyo, Kwara ati Adamawa. Nínú ènìyàn mọ́kànléláàdọ́rùn ún (91) tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹyọ ọ̀hún , mẹ́rìnléláàdọ́rin ( 74) ní ìpínlẹ̀ Èkó , márùn ún (5) ní ìpínlẹ̀ Katsina ,ẹyọ kan ( 1) ní ìlú Àbújá, Federal Capital Territory (FCT), mẹ́rin (4) ní ìpínlẹ̀ Ògùn, méjì (2) ní ìpínlẹ̀ Delta ati Edo ,ẹyọ kan (1) ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Kwara àti Adámáwá. +--- Ile igbimo Asofin ti ipinle Eko bebe fun ifarada ipenija sisemole latari aarun Korona. --- Ilé igbimo Aṣ̣òfin ti ìpínlè̩ Èkó bẹ̀bẹ̀ fún ìfaradà ìpèníjà sísémó̩lé látàrí ààrùn Kòrónà. +Ile Igbimo Asofin ti ipinle Eko ti ro awon olugbe ipinle Eko lati jowo farada ipenija ti o waye latari igbele to waye lati fi opin si itankale aarun Korona. Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣ̣òfin ti ìpínlẹ̀ Èkó ti rọ̣ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Èkó láti jọ̀wọ́ farada ìpèníjà tí ó wáyé látàri ìgbélé tó wáyé láti fi òpin sí ìtànkálè̩ ààrùn Kòrónà. +Igbimo to n mojuto eto ilera ati Igbimo to n mojuto eto iroyin ninu ile igbimo asofin rawo ebe nigbati won n ba awon oniroyin soro lori akiyesi won nibi ayewo awon ohun eelo ti won pese fun itoju arun ‘COVID-19’ ni Ipinle Eko. Ìgbìmọ̀ tó ń mójútó ètò ìlera àti Ìgbìmọ̀ tó ń mójútó ètò ìròyìn nínú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nígbàtí wọ́n ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí àkíyèsí wọ̣n níbi àyẹ̀wò àwọn ohun èelò tí wọn pèsè fún ìtọ́jú àrùn ‘COVID-19’ ní Ìpínlẹ̀ Èkó. +Alaga Igbimo to n mojuto eto ilera ninu ile igbimo asofin ti ipinle Eko, asofin Hakeem, ti o saaju iko naa so pe o se pataki ki awon ara ilu tele ofin konile-gbele ti ijoba se yii lati lee dekun itankale arun korona yii. Alága Ìgbìmọ̀ tó ń mójútó ètò ìlera nínú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti ìpínlẹ̀ Èkó, aṣòfin Hakeem, tí ó ṣáájú ikọ̀ náà sọ pé ó ṣe pàtàkì kí àwọn ará ìlú tẹ̀lé òfin kónílé-gbélé tí ìjọba ṣe yìí láti leè dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àrùn kòrónà yìí. +Awon omo ile igbimo Asofin to wa nibe ni Alaga igbimo to n mojuto eto iroyin ati eto oselu ninu Ile Igbimo Asofin naa, asofin Tunde Braimoh; asofin Desmond Elliot, asofin Temitope Adewale. Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin tó wà níbẹ̀ ni Alága ìgbìmọ̀ tó ń mójútó ètò ìròyìn àti ètò òṣ̣èlú nínú Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà, aṣòfin Túndé Braimoh; aṣòfin Desmond Elliot, aṣòfin Tèmítọ́pẹ́ Adéwálé. +Awon igbimo naa se abewo si Ile-iwosan ajakale arun ni agbegbe Yaba; gbongan idaniduro fun ayewo ni agbegbe Mobolaji Johnson ni Onikan; gbongan idaniduro fun ayewo ni agbegbe Victoria Island ni Ijoba Ibile Eti-Osa ati Ile-Iwosan gbogboogbo ni Gbagada. Àwọn ìgbìmọ̀ náà ṣe àbẹ̀wò sí Ilé-ìwòsàn àjàkálẹ̀ àrùn ní agbègbè Yaba; gbọ̀ngàn ìdánidúró fún àyẹ̀wò ní àgbègbè Mobọ́lájí Johnson ní Oníkàn; gbọ̀ngàn ìdánidúró fún àyẹ̀wò ní àgbègbè Victoria Island ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Etí-Ọ̀sà àti Ilé-Ìwòsàn gbogboògbò ní Gbàgádà. +Igbimo naa woye pe awon ohun eelo fun itoju arun naa ati ise won nibe duro daradara lati koju itankale arun korona ni Ipinle Eko, ti ijoba apapo se atileyin fun. Ìgbìmọ̀ náà wòye pé àwọn ohun èèlò fún ìtọ́jú àrùn náà àti iṣẹ́ wọn níbẹ̀ dúró dáradára láti kojú ìtànkálẹ̀ àrùn kòrónà ní Ìpínlẹ̀ Èkó, tí ìjọba àpapọ̀ ṣe àtìlẹyìn fún. +Won se ileri pe awon ipenija diedie ti won n koju ni awon ile-iwosan yii to nii se pelu aito awon ohun eelo ti awon osise naa fi n daabo bo ara won. Wọ́n ṣe ìlérí pé àwọn ìpèníjà díẹ̀díẹ̀ tí wọ́n ń kojú ní àwọn ilé-ìwòsàn yìí tó níi ṣ̣e pẹ̀lú àìtó àwọn ohun èèlò tí àwọn òṣìṣẹ́ náà fi ń dáàbò bo ara wọn. +Ati pe gbogbo ipa ni ijoba n sa lati gbogun ti aarun yii, sugbon awon ara ilu ni lati satileyin fun aseyori eyi. Àti pé gbogbo ipá ni ìjọba ń sà láti gbógun ti ààrùn yìí, ṣùgbọ́n àwọn ará ìlú ní láti ṣàtìlẹyìn fún àṣeyọrí èyí. +Ninu oro ti Asofin Shokunle so, ona kan pataki ti o ro lati dena itankale aarun yii ni ikede konile-gbele. Nínú ọ̀rọ̀ tí Aṣòfin Shókúnlè so̩, ò̩nà kan pàtàkì tí ó rò láti dènà ìtànkálẹ̀ ààrùn yìí ni ìkéde kónílé-gbélé. +"Mo mo pe eleyii ko rorun, sugbon nigba miiran, ti a ba ni ki a wo ipalara iru aarun ""Coronavirus"", a o rii pe o se pataki lati se eyi." "Mo mọ̀ pé eléyìí kò rọrùn, sùgbọ́n nígbà miíràn, tí a bá ní kí á wo ìpalára irú ààrùn ""Coronavirus"", a ó rii pé ó ṣe pàtàkì làti ṣe èyí." +Asofin Tunde Bramoh naa ro awon ara ilu lati tunbo ni suuru die, niwon to je pe airotele ni gbgbo oro yii sele, o si nilo owo kunkun lati fi mu u. O ni: Aṣòfin Túndé Bramoh náà rọ àwọn ará ìlú láti túnbọ̀ ní sùúrù díẹ̀, níwọ̀n tó jẹ́ pé àìròtẹ́lẹ̀ ní gbgbo ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, ó sì nílò ọwọ́ kunkun láti fi mú u. Ó ní: +A ro awon eniyan wa, nitori oro aarun COVID-19, oro irorun awon ara ilu naa wa loto. A rọ àwọn ènìyàn wa, nítorí ọ̀rọ̀ ààrùn COVID-19, ọ̀rọ̀ ìrọ̀rùn àwọn ará ìlú náà wà lọ́tọ̀. +O ye ki a mo pe oro aarun korona yii nii se pelu emi eda, ni o fi se pataki ki a koko yanju oro aarun yii na. Ó yẹ kí á mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ààrùn kòrónà yìí níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí ẹ̀dá, ni ó fi ṣe pàtàkì kí á kọ́kọ́ yanjú ọ̀rọ̀ ààrùn yìí ná. +Igbimo Asofin naa se abewo si awon gbogan itoju Korona mereerin nipininle Eko, won si pese awon eelo pelu awon osise to ye, ti aaye ibusun sii fe daadaa. Ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà s̩e àbẹ̀wò sí àwọn gbọ̀gàn ìtọ́jú Kòrónà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nípìnínlẹ̀ Èkó, wọ́n sì pèsè àwọn èèlò pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ tó yẹ, tí ààyè ìbùsùn síì fè̩ dáadáa. +--- Gomina ipinle Oyo daroo onidajo agba teleri– Makinde --- Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ dáròo onídàjọ́ àgbà tẹ́lẹ̀rí– Mákindé +Gomina ipinle Oyo, Seyi Makinde ti fi iku oloogbe onidaajo agba, Richard Akinjide to ti figba kan je Minisita fun eto idajo ni orile ede Naiiria we adanu nla fun ipinle Oyo, orile ede Naijiria ati agbaye lapapo. Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Sèyí Mákindé ti fi ikú olóògbé onídàájọ́ àgbà, Richard Akínjídé tó ti fìgbà kan jẹ́ Mínísítà fún ètò ìdájọ́ ní orílẹ̀ èdè Nàí̀íríà wé àdánù ńlá fún ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti àgbáyé lápapọ̀. +Gomina Seyi Makinde, eni ti o tun fi aidunnu re han si iku onidaajo agba Akinjide han ninu oro ibanikedun re, eleyii ti o fi sowo si ebi oloogbe ohun lati owo amugbalegbe re lori oro iroyin, Taiwo Adisa, lo soo di mimo pe oloogbe Akinjide ti fi igba aye re sin orile ede Naijiria tokan -tokan. Gómìnà Sèyí Mákindé, ẹni tí ó tún fi àìdùnnú rẹ̀ hàn sí ikú onídàájọ́ àgbà Akínjídé hàn nínú ọ̀r��̀ ìbánikẹ́dùn rẹ̀, eléyìí tí ó fi sọwọ́ sí ẹbí olóògbé ọ̀hún láti ọwọ́ amúgbálẹ́gbẹ́ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Táíwò Àdìsá, ló sọọ́ di mímọ̀ pé olóògbé Akínjídé ti fi ìgbà ayé rẹ̀ sin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tọkàn -tọkàn. +Makinde tun tesiwaju pe, iku oloogbe naa wa lasiko ti omo orile ede Naijiria nilo lati mu ninu omi ogbon re eleyii to ti fihan ninu oniruuru ona bi i , isejoba ati eka ofin eleyii to le tan imole fun won lati je adari to see mu yangan lagbaaye. Mákindé tún tẹ̀síwájú pé, ikú olóògbé náà wá lásìkò tí ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nílò láti mu nínú omi ọgbọ́n rẹ̀ eléyìí tó ti fihàn nínú onírúurú ọ̀nà bí i , ìṣèjọba àti ẹ̀ka òfin eléyìí tó le tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn láti jẹ́ adarí tó ṣeé mú yangàn lágbàáyé. +"Makinde tun salaye pe: ""Iroyin iku baba wa, adari ati enikansoso to tayo lara awon oloselu orile ede Naijiria, Oloye Richard Akinjide je iyalenu nla nitori pe, baba ko fe ki enikeni lara mo pe olojo ti de, titi o fi mi eemi ikeyin, baba si n soro lori awon isele to n lo, to si n gba ijoba nimoran ni orisirisi ona, baba duro gege bi opomulero ninu oselu ati oro ofin. """ "Mákindé tún sàlàyé pé: ""Ìròyìn ikú bàbá wa, adarí ati ẹnìkanṣoṣo tó tayọ lara àwọn olóṣèlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Olóyè Richard Akínjídé jẹ́ ìyàlẹ́nu ńlá nítorí pé, bàbá kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni lára mọ̀ pé ọlọ́jọ́ ti dé, títí ó fi mí èémì ìkẹyìn, bàbá sì ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tó ń lọ, tó sì ń gba ìjọba nímọ̀ràn ní oríṣiríṣi ọ̀nà, bàbá dúró gẹ́gẹ́ bí òpómúléró nínú òṣèlú àti ọ̀rọ̀ òfin. """ +"""Iku re je adanu nla fun ipinle Oyo, orile ede Naijiria ati agbaye lapapo, nitori o je asiwaju rere ti se omo bibi ile Ibadan ni ipinle Oyo, ti ko fi eleyameya se, to fi ojo aye re sin orile ede Naijiria pelu agbara re """ """Ikú rẹ̀ jẹ́ àdánù ńlá fún ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti àgbáyé lápapọ̀, nítorí ó jẹ́ asíwájú rere tí se ọmọ bíbí ilẹ̀ Ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí kò fi ẹlẹ́yàmẹ̀yà ṣe, tó fi ọjọ́ ayé rẹ̀ sin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pẹ̀lú agbára rẹ̀ """ +Gomina wa fi asiko ohun ba awon omo oloogbe naa to tun je ogbontarigi ninu egbe oselu Peoples Democratic Party (PDP), oloye Jumoke Akinjide ati gbogbo omo bibi inu baba yooku laiyo enikankan sile ati ninu oselu kedun. Gómìnà wá fi àsìkò ọ̀hún bá àwọn ọmọ olóògbé náà tó tún jẹ́ ògbóǹtarìgì nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP), olóyè Jùmọ̀ké Akínjídé àti gbogbo ọmọ bíbí inú bàbá yòókù láìyọ ẹnìkankan sílẹ̀ àti nínú òṣèlú kẹ́dùn. +O wa tun fi asiko naa ba gbogbo omo bibi ipinle Oyo ati omo orile ede Naijiria kedun lori iku eni rere to dagbere faye. oloogbe Richard Akinjide je eni odun Mejidinlaadorun ki o to jade laye. Ó wá tún fi àsìkò náà bá gbogbo ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kẹ́dùn lórí ikú ẹ̣ni rere tó dágbére fáyé. olóògbé Richard Akínjídé jẹ́ ẹni ọdún Méjìdínláàdọ́rùń kí ó tó jáde láyé. +--- Ile-ise ologun gbemi awon omo-ogun olote mokanlelogun ni ipinle Zamfara --- Ilé-isẹ́ ológun gbẹ̀mí àwọn ọmọ-ogun ọlọ̀tẹ̀ mọ́kànlélógún ní ìpínlẹ̀ Zamfara +Ile-ise omo ogun orile ede Naijiria, Operation Hadarin Daji ti gbemi awon omo ogun olote ti ko din ni mokanlelogun ti won ba woya ija ni Zurmi ni ijoba ibile Zurmi ni ipinle Zamfara. Ilé-isẹ́ ọmọ ogun orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Operation Hadarin Daji ti gbẹ̀mi àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ tí kò dín ní mọ́kànlélógún tí wọ́n bá wọ̀yá ìjà ní Zurmi ní ìjọba ìbílẹ̀ Zurmi ní ìpínlẹ̀ Zamfara. +Agbenuso fun ile-ise iroyin ,ogagun John Enenche, lo soro yii lojoru niluu Abuja,pe omo ogun orile ede Naijiria merin lo ku nibi isele ohun. Agbẹnusọ fún ilé-isẹ́ ìròyìn ,ọ̀gágun John Enenche, ló sọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́rú nílùú Àbújá,pé ọmọ ogun orílẹ̀ èdè Nàìjíríà mẹ́rin ló kú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún. +Enenche tesiwaju pe awon yoo tun maa so bi igbese ti o kan nipa isele ohun ni agbegbe naa se n lo si. Enenche tẹ̣̀síwájú pé àwọn yóò tún máa sọ bí ìgbésẹ̀ tí ó kàn nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̣̀hún ní àgbègbè náà ṣ̣e ń lọ sí. +O tun ni iko omo ogun naa yoo tun tesiwaju lati maa gbogun ti iko olote to wa ni agbegbe naa. Ó tún ní ikọ̣̀ ọmọ ogun náà yóò tún tẹ̀síwájú láti máa gbogún ti ikọ̀ ọḷọ̀tẹ̀ tó wà ní àgbègbè náà. +--- COVID-19: ipinle Kano bere ounje pinpin fun awon ara ilu --- COVID-19: ìpínlẹ̀ Kán�� bẹ̀rẹ̀ oúnjẹ pínpín fụ́n àwọn ará ìlú +Ijoba ipinle Kano yoo bere si ni maa pin ounje lati fi se eto iranwo fun awon omo ipinle naa, ki o le din wahala ti won n koju lasiko eto konile-gbele ku nipase aarun COVID-19 Ìjọba ìpínlẹ̀ Kánò yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní máa pín oúnjẹ láti fi ṣe ètò ìrànwọ́ fún àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ náà, kí ó le dín wàhálà tí wọ́n ń kojú lásìkò ètò kónílé-gbélé kù nípasẹ̀ ààrùn COVID-19 +Oluranlowo ijoba ipinle naa lori iroyin, Salihu Tanko Yakasai lo kede lori ero twitter re laasale ojo Aiku. Olùrànlọ́wọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ náà lórí ìròyìn, Salihu Tanko Yakasai ló kéde lórí ẹ̀rọ twitter rẹ̀ láásálẹ́ ọjọ́ Àìkú. +O tesiwaju pe awon yoo maa pin ounje naa kaakiri gbogbo ijoba ibile mejilelogoji to wa ni ipinle ohun. Ó tẹ̀síwájú pé àwọn yóò máa pín ouńjẹ náà káàkiri gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ méjìlélógójì tó wà ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún. +Gomina ipinle Kano, Abdullahi Ganduje lo ti koko kede eto konile-gbele fun ose kan gbako lojobo ni deede aago meewa asale pe eto konile-gbele yoo bere ni Ojoru. Gómìnà ìpínlẹ̀ Kánò, Abdullahi Gàndújè ló ti kọ́kọ́ kéde ètò kónílé-gbélé fún ọ̀sẹ̀ kan gbáko lọ́jọ́bọ̀ ní déédé aago mẹ́ẹ́wá àsálẹ́ pé ètò kónílé-gbélé yóò bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́rú. +Amosa Ganduje ni o se e se ki atunse ba eto ohun. Àmọ́ṣá Gàndújè ní ó se é se kí àtúnṣe bá ètò ọ̀hún. +Igbimo ijoba ipinle Kano to n seto owo iranwo fun aarun COVID-19, ni eyi ti ojogbon Muhammad Yahuza Bello je alakooso re so pe igbimo naa ti ri owo to le ni irinwo milionu gba ati orisi ounje meedogun. Ìgbìmọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ Kánò tó ń sètò owó ìrànwọ́ fún ààrùn COVID-19, ní èyí tí ọ̀jọ̀gbọ́n Muhammad Yahuza Bello jẹ́ alákòóso rẹ̀ sọ pé ìgbìmọ̀ náà ti rí owó tó lé ní irinwó mílíọ́nù gbà àti orísi oúnjẹ mẹ́ẹ̀dógún. +--- COVID-19: Awon eniyan merindinlaadorun un (86) miran tun jeyo lorile ede Naijiria --- COVID-19: Àwọn ènìyàn mẹ́rìndínláàdọ́rùn ún (86) míràn tún jẹyọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Awon eniyan merindinlaadorun un (86) miran tun ti jeyo ti won ni aarun Corona (COVID 19 ) lorile ede Naijiria Àwọn ènìyàn mẹ́rìndínláàdọ́rùn ún (86) míràn tún ti jẹyọ tí wọ́n ní ààrùn Corona (COVID 19 ) lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Ni eyi ti o je ki iye awon to ni aarun Corona je metadinlogbonleniegbeta(627), nigba ti awon eniyan bi aadosan an (170 ) ti gba iwosan , ti awon eniyan mokanlelogun (17) si ti je Olorun nipe. Ajo to n gbogun ti ajakale aarun lorile ede Naijiria (NCDC) lo kede yii lori ero Twitter won, @NCDCgov ni deede aago mejila ku iseju mewaa asale ojo kokandinlogun , osu kerin , odun 2020. Ní èyí tí ó jẹ́ kí iye àwọn tó ní ààrùn Corona jẹ́ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀nléníẹgbẹ̀ta(627), nígbà tí àwọn ènìyàn bí àádọ́sàn án (170 ) ti gba ìwòsàn , tí àwọn ènìyàn mọ́kànlélógún (17) ṣì ti jẹ́ Ọlọ́run nípè. Àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ ààrùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NCDC) ló kéde yìí lórí ẹ̀rọ Twitter wọn, @NCDCgov ní déédé aago méjìlá ku ìsẹ́jú mẹ́wàá àṣálẹ́ ọjọ́ kọkàndínlógún , osù kẹrin , ọdún 2020. +Ninu eniyan merindinlaadorun un (86) ti won sese jeyo ohun , aadorin ( 70) ni ipinle Eko ,meta (3) ni ipinle Katsina ,meje ( 7) ni ilu Abuja, Federal Capital Territory (FCT) eyo meta (3) ni ipinle Akwa Ibom, eyo kan (1) ni ipinle Bauchi, Jigawa ati Borno. Nínú ènìyàn mẹ́rìndínláàdọ́rùn ún (86) tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ jẹyọ ọ̀hún , àádọ́rin ( 70) ní ìpínlẹ̀ Èkó ,mẹ́ta (3) ní ìpínlẹ̀ Katsina ,méje ( 7) ní ìlú Àbújá, Federal Capital Territory (FCT) ẹyọ mẹ́ta (3) ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom, ẹyọ kàn (1) ní ìpínlẹ̀ Bauchi, Jigawa àti Borno. +--- Abba Kyari: Aare Buhari ba ipinle Borno kedun --- Abba Kyari: Ààrẹ Buhari bá ìpínlẹ̀ Borno kẹ́dùn +Aare Muhammadu Buhari ti ba ipinle Borno kedun , nigba ti aare pe gomina ipinle ohun, ojogbon Babagana Zulum, olori agbegbe Banki, awon oba ipinle ohun ati egbon oloogbe Mallam Abba Kyari, Zanna Baba Shehu Arjinoma, lojo Aiku. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti bá ìpínlẹ̀ Borno kẹ́dùn , nígbà tí ààrẹ pe gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀hún, ọ̀jọ̀gbọ́n Babagana Zulum, olórí agbègbè Banki, àwọn ọba ìpínlẹ̀ ọ̀hún àti ẹ̀gbọ́n olóògbé Mallam Abba Kyari, Zanna Baba Shehu Arjinoma, lọ́jọ́ Àìkú. +Ninu oro ti aare n ba awon so lori ero ibanisoro, aare ba olori ebi ati awon ebi re ; Shehu ti Borno, Shehu Abubakar Ibn Umar Garbai El-Kanemi; Shehu ti Bama, Shehu Kyari ibn Umar ibn Ibrahim Elkenemi kedun iku oloogbe ohun. Nínú ọ̀rọ̀ tí ààrẹ ń bá àwọn sọ lórí ẹ̀rọ̀ ìbánisọ̀r��̀, ààrẹ bá olórí ẹbí àti àwọn ẹbí rẹ̀ ; Shehu ti Borno, Shehu Abubakar Ibn Umar Garbai El-Kanemi; Shehu ti Bama, Shehu Kyari ibn Umar ibn Ibrahim Elkenemi kẹ́dùn ikú olóògbé ọ̀hún. +Aare Buhari sapejuwe oloogbe ohun gege bi adanu nla fun orile ede Naijiria, o wa ro ijoba ,awon omo ipinle Borno ati ebi oloogbe naa lati maa se bokanje nitori oloogbe Mallam Kyari lo igbe aye to dara. Ààrẹ Buhari ṣàpèjúwe olóògbé ọ̀hún gẹ́gẹ́ bí àdánù ńlá fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ó wá rọ ìjọba ,àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Borno àti ẹbí olóògbé náà láti máa ṣe bọkànjẹ́ nítorí olóògbé Mallam Kyari lo ìgbé ayé tó dára. +O ni, Abba je eni ti a feran julo. Ó ní, Abba jẹ́ ẹni tí a fẹ́ràn jùlọ. +O se nkan ti o je ki orile ede Naijiria di nla. Ó ṣe ǹkan tí ó jẹ́ kí orílẹ̣̀ èdè Nàìjíríà di ńlá. +Awon eniyan lati orile ede Naijiria ati nile okeere si n pe aare lati baa kedun lori iku adari osise re. Àwọ̣n ènìyàn láti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti nílẹ̣̀ òkèèrè sì ń pe ààrẹ láti báa kẹ́dùn lórí ikú adarí òsìsẹ́ rẹ̀. +Lara awon ti o fiwe ikini ranse si aare ni: aare orile ede Naijiria teleri , ogagun Ibrahim Babangida; Gomina ipinle Rivers, Nyesom Wike, Enugu, Ifeanyi Ugwuanyi, Yobe, Mai Mala Buni, Taraba, Darius Dickson Ishaku ati awon akeegbe re ti won jo lo si ile eko lodun 1953. Lára àwọn tí ó fìwé ìkíni ránsẹ́ sí ààrẹ ni: ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí , ọ̀gágun Ibrahim Bàbáńgídá; Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike, Enugu, Ifeanyi Ugwuanyi, Yobe, Mai Mala Buni, Taraba, Darius Dickson Ishaku àti àwọn akẹẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ lọ́dún 1953. +Aare tun ri iwe gba lati odo aare igbimo ajo agbaye, Ambassador (Prof. ) Tijjani Muhammad-Bande, egbe awon akoroyin agbaye (the global network of Editors, the International Press Institute, IPI, aare awon egbe Nigerian Guild of Editors, Mustapha Isa, Emir ti ipinle Kano, Aminu Ado Bayero, olori ebi awon Dantata ni ipinle Kano, Alhaji Aminu Dantata, adari egbe Izala religious movement lorile ede Naijiria, Alhaji Bala Lau ati igbakeji adari ile igbimo asofin agba, Bala Ibn Na’Allah. Ààrẹ tún rí ìwé gbà láti ọ̀dọ̀ ààrẹ ìgbìmọ̀ àjọ àgbáyé, Ambassador (Prof. ) Tijjani Muhammad-Bande, ẹgbẹ́ àwọn akọ̀ròyìn àgbáyé (the global network of Editors, the International Press Institute, IPI, ààrẹ àwọn ẹgbẹ́ Nigerian Guild of Editors, Mustapha Isa, Emir ti ìpínlẹ̀ Kánò, Àmínù Ado Bayero, olórí ẹbí àwọn Dantata ní ìpínlẹ̀ Kánò, Alhaji Àmínù Dantata, adarí ẹgbẹ́ Izala religious movement lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Alhaji Bala Lau àti igbákejì adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Bala Ibn Na’Allah. +Awon miiran tun ni : Asoju orile ede Naijiria fun orile ede Amerika (USA), adajo Sylvanus Adiewere Nsofor, Emir ti Zamfara, oba Alhaji Attahiru Muhammad Ahmad, asofin Umaru Kurfi, Burhan Karabult, Nigeria’s Turkish partner in the Defence Industries Corporation, DICON, ojogbon James Momoh, igbakeji alaga fun ile-ise to n mojuto ina mona-mona( Nigerian Electricity Regulatory Commission) ati ajihinrere lati ipinle Kano, Ustashi Tijjani Bala Kalarawi. Àwọn mííràn tún ni : Aṣojú orílẹ̀ èdè Nàíjíríà fún orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà (USA), adájọ́ Sylvanus Adiewere Nsofor, Emir ti Zamfara, ọba Alhaji Attahiru Muhammad Ahmad, aṣòfin Umaru Kurfi, Burhan Karabult, Nigeria’s Turkish partner in the Defence Industries Corporation, DICON, ọ̀jọ̀gbọ́n James Momoh, igbákejì alága fún ilé-isẹ́ tó ń mójútó iná mọ̀nà-mọ́ná( Nigerian Electricity Regulatory Commission) àti ajíhìnrere láti ìpínlẹ̀ Kánò, Ustashi Tijjani Bala Kalarawi. +--- Awon eniyan metadinlaadota padanu emi won lori ikolu to sele ni ipinle katsina --- Àwọn ènìyàn mẹ́tàdínláàdọ́ta pàdánù ẹ̀mí wọn lórí ìkọlù tó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ katsina +Aare Muhammadu Buhari ti fi aidunnu re han lori ikolu to sele ni ijoba ibile meta kan ni ipinle katsina nibi ti awon eniyan metadinlaadota ti padanu emi won. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti fi àìdùnnú rẹ̀ hàn lórí ìkọlù tó ṣẹlẹ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ta kan ní ìpínlẹ̀ katsina níbi tí àwọn ènìyàn mẹ́tàdínláàdọ́ta ti pàdánù ẹ̀mí wọn. +Aare Buhari soro yii lasiko to n dahun ibeere nipa isele buruku to waye lojo Aiku. Aare ni inu oun baje nipa ikolu ohun. Ààrẹ Buhari ṣọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń dáhùn ìbéèrè nípa ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tó wáyé lọ́jọ́ Àìkú. Ààrẹ ní inú òun bàjẹ́ nípa ìkọlù ọ̀hún. +"O wa ro gbogbo omo orile ede Naijiria lati fokanbale pe ""ijoba yii ti pinnu lati gbogun ati fiya je gbogbo awon odaran ti won ba n lo asiko konile-gbele lati fi hu iwa ibaje si awon alaise ""." "Ó wá rọ gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti fọkànbalẹ̀ pé ""ị̀jọba yìí ti pinnu láti gbógun àti fìyà jẹ gbogbo àwọn ọ̀daràn tí wọ́n bá ń lo àsìkò kónílé-gbélé láti fi hu ìwà ìbàjẹ́ sí àwọn aláìsẹ̀ ""." +Aare Buhari ni oun ko ni faramo bi awon odaran se n pa awon alaise ati pe “gege bi ipinnu mi lati mojuto eto aabo awon ara ilu,awon ikolu yii ni a oo ri pe a gbogun tii. ” Ààrẹ Buhari ní òun kò ní faramọ́ bí àwọn ọ̀daràn ṣe ń pa àwọn aláìsẹ̀ àti pé “gẹ́gẹ́ bí ìpinnu mi láti mójútó ètò ààbò àwọn ará ìlú,àwọn ìkọlù yìí ni a óò ri pé a gbógun tìì. ” +Aare wa pase fun gbogbo awon agbofinro lati maa se kaare nipa gbigbogun ti awon odaran ki won si fi won jofin. Ààrẹ wa pàsẹ fún gbogbo àwọn agbófinró láti máa ṣe káárẹ̀ nípa gbígbógun ti àwọn ọ̀daràn kí wọ́n sì fi wọ́n jófin. +Aare wa ba awon ebi to padanu eniyan won kedun , o wa ro gbogbo awon eniyan lati je oju ni alakan fi n sori , ki won si maa fi to gbogbo awon agbofinro leti, ti won ba fura si awon odaran ni agbegbe won. Ààrẹ wa bá àwọn ẹbí tó pàdánù ènìyàn wọn kẹ́dùn , ó wá rọ gbogbo àwọn ènìyàn láti jẹ́ ojú ni alákàn fi ń ṣọ́rí , kí wọ́n sì máa fi tó gbogbo àwọn agbófinró létí, tí wọ́n bá fura sí àwọn ọ̀daràn ní àgbègbè wọn. +--- Ile igbimo asoju kedun iku Abba Kyari --- Ilé ìgbìmọ̀ aṣojú kẹ́dùn ikú Abba Kyari +Abenugan ile igbimo asoju lorile ede Naijiria, ogbeni Femi Gbajabiamila ti sapejuwe iku adari osise aare, Malam Abba Kyari gege bi eyi to bani lokanje. Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojú lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ọ̀gbẹ́ni Fémi Gbàjàbíàmílà ti sàpèjúwe ikú adarí òṣìṣẹ́ ààrẹ̣, Malam Abba Kyari gẹ́gẹ́ bi èyí tó bani lọ́kànjẹ́. +Ninu oro ikini ti oluranlowo re, Lanre Lasisi fowosi, abenugan ile igbimo asoju, Gbajabiamila so pe, o se ni laaanu pe aarun COVID-19 ti o n ja kaakiri gbogbo agbaye ni o pa Abba Kyari Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni tí olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, Láńre Làsísì fọwọ́sí, abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojú, Gbàjàbíàmílà sọ pé, ó se ni láàánú pé ààrùn COVID-19 tí ó ń jà káàkiri gbogbo àgbáyé ni ó pa Abba Kyari +O tesiwaju pe oruko Abba Kyari yoo wa ninu iwe iranti orile ede Naijiria gege bi akinkanju ati olufokansi eniyan si aare Buhari ati orile ede Naijiria. Ó tẹ̀síwájú pé orúkọ̣ Abba Kyari yóò wà nínú ìwé ìrántí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí akínkanjú àti olùfọkànsì ènìyàn sí ààrẹ Buhari àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Ninu oro ikini tire, igbakeji abenugan ile igbimo asoju, Alhaji Idris Ahmed Wase wa kedun pelu aare Muhammadu Buhari lori iku adari osise re, Mallam Abba Kyari. Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni tirẹ̀, igbákejì abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojú, Alhaji Idris Ahmed Wase wá kẹ́dùn pẹ̀lú àarẹ Muhammadu Buhari lórí ikú adarí òṣìṣẹ́ rẹ̀, Mallam Abba Kyari. +O wa fi oro ikedun re ranse si awon ebi oloogbe ohun ati ijoba ipinle Borno. Ó wá fi ọ̀rọ̀ ìkẹ́dùn rẹ̀ ránsẹ́ sí àwọn ẹbí olóògbé ọ̀hún àti ìjọba ìpínlẹ̀ Borno. +Adari omo egbe to kere julo nile igbimo asoju, Ndudi Elumelu, naa wa sapejuwe iku Abba Kyari gege bi adanu nla fun orile Naijiria paapaa julo ni iru asiko ti a wa yii. Adarí ọmọ ẹgbẹ́ tó kéré jùlọ nílé ìgbìmọ̀ aṣojú, Ndudi Elumelu, náà wá sàpèjúwe ikú Abba Kyari gẹ́gẹ́ bí àdánù ńlá fún orílẹ̀ Nàìjíríà pàápàá jùlọ ní irú àsìkò tí a wà yìí. +--- Erin wo! Aarun Corona(COVID-19) pa adari osise aare Buhari --- Erín wó! Ààrùn Corona(COVID-19) pa adarí òṣìṣẹ́ ààrẹ Buhari +Adari osise fun aare orile ede Naijiria, Abba Kyari ni aarun (COVID-19) ti pa bayii. Adarí òṣìṣẹ́ fún ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Abba Kyari ni ààrùn (COVID-19) ti pa báyìí. +Oluranlowo aare Buhari lori iroyin ati ikede, Femi Adesina lo kede yii ni owuro ojo Abameta pe Mallam Kyari dagbere faye lojo Eti (Friday) ojo ketadinlogbon ,osu kerin, odun, 2020. Olùrànlọ́wọ́ ààrẹ Buhari lórí ìròyìn àti ìkéde, Fémi Adésínà ló kéde yìí ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta pé Mallam Kyari dágbére fáyé lọ́jọ́ Ẹtì (Friday) ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n ,oṣù kẹrin, ọdún, 2020. +Ti a o ba gbagbe pe Mallam Kyari ni won ri aarun COVID-19 lara re, ti o si n gba iwosan , ki o to di pe o dagbere fun aye pe o digboose. Tí a ò bá gbàgbé pé Mallam Kyari ni wọ́n rí ààrùn COVID-19 lára rẹ̀, tí ó sì ń gba ìwòsàn , kí ó tó di pé ó dágbére fún ayé pé ò dìgbòóse. +Adesina ni awon yoo kede eto isinku laipe, O wa gbadura pe ki Olorun te oloogbe naa si afefe ire. Adésínà ni àwọn yóò kéde ètò ìsìnkú láìpẹ́, Ó wá gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tẹ̣́ olóògbé náà sí afẹ́fẹ́ ire. +--- COVID-19: Awon eniyan mokanlelaadota (51) miran tun jeyo lorile ede Naijiria --- COVID-19: Àwọn ènìyàn mọ́kànléláàdọ́ta (51) míràn tún jẹyọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Awon eniyan mokanlelaadota (51) miran tun ti jeyo ti won ni aarun Corona (COVID 19 ) lorile ede Naijiria Àwọn ènìyàn mọ́kànléláàdọ́ta (51) míràn tún ti jẹyọ tí wọ́n ní ààrùn Corona (COVID 19 ) lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Awon ipinle mokandinlogun ni aarun COIVD-19 ti jeyo bayii. Àwọn ìpínlẹ̀ mọ́kàndínlógún ní ààrùn COIVD-19 tí jẹyọ báyìí. +--- COVID-19: Minisita romo Naijiria lati safihan awon a-lo-ona-aito wo enubode. --- COVID-19: Mínísítà ro̩mo̩ Nàìjíríà láti s̩àfihàn àwo̩n a-lo-ò̩nà-àìtó̩ wo̩ e̩nubodè. +Minisita fun eto oro abele, ogbeni Rauf Aregbesola, ti ro omo Naijiria lati tu asiri awon a-lo-ona-aito wo enubode si Naijiria fun ajo amojuto eto enu ibode ni orileede Naijiria. Mínísítà fún ètò ọ̀rọ̀ abẹlé, ọ̀gbé̩ni Rauf Aré̩gbé̩ṣolá, ti rọ ọmọ Nàìjíríà láti tú àṣírí àwo̩n a-lo-ò̩nà-àìtó̩ wo̩ ẹnubodè sí Nàìjíríà fún àjọ amójútó ètò ẹnu ibodè ní orílèèdè Nàìjíríà. +Aregbesola soyi lasiko tawon iko ijoba apapo amojuto aarun COIVD-19 n dahun ibeere lowo awon akoroyin niluu Abuja lojobo. Arégbésolá sọ̀yí lásìkò táwọn ikò̩ ìjọba àpapọ̀ amójútó ààrùn COIVD-19 ń dáhùn ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn akọròyìn nílùú Àbújá lọ́jọ́bọ̀. +O ni o lodi si ofin pe ki enikeni ko aarun COVID-19 wo orile ede kan, lasiko ti awon omo orile ede ohun si n koju ipenija ofin konile-gbele ti ijoba apapo se. Ó ní ó lòdì sí òfin pé kí ẹnikẹ́ni kó ààrùn COVID-19 wọ orílẹ̀ èdè kan, lásìkò tí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè ọ̀hún sì ń kojú ìpèníjà òfin kónílé-gbélé tí ìjọba àpapọ̀ ṣe. +“Naijiria ti se laalaa pupo lati kapa COVID-19 a si gbodo kiyesara iwole-aito, ere yii wa pelu idojuko nla o si ti ni ipa lori eto oro aje, ibasepo pelu Olorun ati ibasepo lawujo wa. “Nàìjíríà ti s̩e làálàá púpò̩ láti kápa COVID-19 a sì gbo̩dò̩ kíyèsára ìwo̩lé-àìtó̩, èrè yìí wá pè̩lú ìdojúko̩ ńlá ó sì ti ní ipá lórí ètò o̩rò̩ ajé, ìbás̩epò̩ pè̩lú O̩ló̩run àti ìbás̩epò̩ láwùjo̩ wa. +“A gbodo kin orileede wa leyin lati daabobo ilu wa, ikonimora ati ifeni wa eyi ti o je orile ede Naijiria logun julo ko gbodo di ohun atemole,” O so. “A gbó̩dò̩ kín orílèèdè wa lé̩yìn láti dáàbòbò ìlú wa, ìkónimó̩ra àti ìfé̩ni wa èyí tí ó je̩ orílè̩ èdè Nàìjíríà lógún jùlo̩ kò gbo̩dò̩ dí ohun àtè̩mó̩lè̩,” Ó so̩. +Sisoro lori idariji ijoba apapo si awon elewon ti won tu u le, Aregbesola ni aadorin elewon ijoba apapo lo janfaani iyonda yii, ti egbetala si je tipinle. Sísò̩rò̩ lórí ìdárìjì ìjo̩ba àpapò̩ sí àwo̩n e̩lé̩wò̩n tí wó̩n tú ú lè̩, Aré̩gbé̩s̩o̩lá ni àádó̩rin e̩lé̩wò̩n ìjo̩ba àpapò̩ ló jàǹfààní ìyò̩nda yìí, tí e̩gbè̩tàlá sì jé̩ tìpínlè̩. +Aregbesola ni Aare Muhammadu Buhari tin i ki adajo to n risi eyi sowopo pelu awon ipinle lati yonda awon elewon egbetala. Aré̩gbé̩s̩o̩lá ní Ààre̩ Muhammadu Buhari tin í kí adájó̩ tó ń rísí èyí sowó̩pò̩ pè̩lú àwo̩n ìpínlè̩ láti yò̩nda àwo̩n e̩lé̩wò̩n e̩gbè̩tàlá. +O ni pe ijoba apapo n wa ona lati se adinku ogba ewon. Ó ní pé ìjo̩ba àpapò̩ ń wá ò̩nà láti s̩e àdínkù o̩gbà è̩wò̩n. +Minisita wa gbosuba fun awon omo Naijiria, paapaa julo awon ajo eleto ilera fun igbiyanju won lati dekun aarun COVID-19. Mínísítà wá gbós̩ùbà fún àwo̩n o̩mo̩ Nàìjíríà, pàápàá jùlo̩ àwo̩n àjo̩ elétò ìlera fún ìgbìyànjú wo̩n láti dé̩kun ààrùn COVID-19. +O ke si awon ipinle bii Eko, Sokoto, Cross Rivers ati Niger to ni aala pelu awon orile ede miiran lati ri pe won n so enu ibode daadaa ki ajeji ma baa wo orile ede Naijiria ni akoko yii. Ó ké sí àwọn ìpínlẹ̀ bíi Èkó, Sókótó, Cross Rivers áti Niger tó ní ààlà pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè mííràn láti ri pé wó̩n ń s̩o̩ e̩nu ibodè dáadáa kí àjèjì má baà wo̩ orílè̩ èdè Nàìjíríà ní àkókò yìí. +--- COVID-19: FCTA gbe ilana tuntun jade lasiko ofin konile-gbele --- COVID-19: FCTA gbé ìlànà tuntun jáde lásìkò òfin kónílé-gbélé +Ijoba ilu Abuja (The Federal Capital Territory Administration, FCTA) ti gbe eto ilana tuntun jade lasiko ofin konile-gbele yii lati dekun itankale aarun COVID-19 niluu Abuja. Ìjọba ìlú Àbújá (The Federal Capital Territory Administration, FCTA) ti gbé ètò ìlànà tuntun jáde lásìkò òfin kónílé-gbéle yìí láti dẹ̣́kun ìtànkálẹ̀ ààrùn COVID-19 nílùú Àbújá. +Gege bi atejade kan ti ile-ise ti o n mojuto ilu Abuja gbe jade lori ero twitter won pe awon ti seto ilana tuntun lori eto konile-gbele ohun. Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde kan tí ilé-isẹ́ tí ó ń mójútó ìlú Àbújá gbé jáde lórí ẹ̀rọ twitter wọn pé àwọn ti ṣètò ìlànà tuntun lórí ètò kónílé-gbélé ọ̀hún. +Lara awon eto ilana tuntun tigbimo eleto aabo ilu Abuja alamoojuto aarun COVID-19, ti minisita FCT, Malam Muhammad Musa Bello joludari ni: Lára àwọn ètò ìlànà tuntun tígbìmọ̀ elétò ààbò ìlú Àbújá alámòójútó ààrùn COVID-19, tí mínísítà FCT, Malam Muhammad Musa Bello jólùdarí ní: +Awon ojo oja ni ojoru ati abameta nikan. Ra nnkan loja to sunmo re. Àwo̩n o̩jó̩ o̩jà ni o̩jó̩rú àti àbámé̩ta nìkan. Ra nǹkan ló̩jà tó súnmó̩ re̩. +Idaduro okada ni Kubwa ati Dutse. Ìdádúró ò̩kadà ní Kubwa àti Dutse. +Idasile ile-ejo alagbeeka lati dajo awon arufin. Ìdásílè̩ ilé-e̩jó̩ alágbèéká láti dájó̩ àwo̩n arúfin. +--- Aare Buhari badari ijoba Geesi, Johnson yo fun bibori Corona --- Ààrẹ Buhari bádarí ìjọba Gè̩é̩sì, Johnson yọ̀ fún bíborí Corona +Aare Naijiria Muhammadu Buhari ki adari ijoba Geesi, Boris Johnson kooriire leyin ti won yonda re nileewosan nitori korona. Ààrẹ Nàìjíríà Muhammadu Buhari kí adarí ìjọba Gè̩é̩sì, Boris Johnson kóorííre lé̩yìn tí wó̩n yò̩nda rè̩ níléèwòsàn nítorí kòrónà. +Ninu leta ikini re to fi ranse ni April 14, 2020, si ogbeni Johnson, aare Buhari ni, “Inu mi dun lasiko ti mo gboroyin ayo pe o kuro nile-iwosan ailarun korona mo.” Nínú lé̩tà ìkíni rẹ̀ tó fi ránsẹ́ ní April 14, 2020, sí ọ̀gbẹ́ni Johnson, ààrẹ̀ Buhari ní, “Inú mi dùn lásìkò tí mo gbọ́ròyìn ayọ̀ pé ó kúrò nílé-ìwòsàn àìlárùn kòrónà mó̩.” +Aare Buhari gbadura fun adari ohun, pe kOlorun fun lalaafia pipe ni gbogbo ojo aye re. Ààrẹ Buhari gbàdúrà fún adarí ọ̣̀hún, pé kỌlọ́run fun lálàáfíà pípé ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. +--- COVID-19: China lo baaarun korona ja ki i se omo Naijiria tabi alawodudu ni China – Minisita --- COVID-19: China ló báààrùn kòrónà jà kì í s̩e o̩mo̩ Nàìjíríà tàbí aláwò̩dúdú ní China – Mínísítà +Ijoba orileede Naijiria ni ijoba China lo n koju aarun korona kii se pe won koriira tabi saida si omo Naijiria tabi alawodudu to n gbe Guangzhou ni China. Ìjọba orílèèdè Nàìjíríà ní ìjo̩ba China ló ń kojú ààrùn kòrónà kìí s̩e pé wó̩n kórìíra tàbí s̩àìda sí o̩mo̩ Nàìjíríà tàbí aláwò̩dúdú tó ń gbe Guangzhou ní China. +Minisita fun eto oro ile okeere, ogbeni Geoffrey Onyeama, ati asoju orile ede China ni Naijiria, Zhou Pingjian,ni won soro yii fun awon akoroyin niluu Abuja. Mínísítà fún ètò ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè, ọ̀gbẹ́ni Geoffrey Onyeama, àti aṣojú orílẹ̀ èdè China ní Nàìjíríà, Zhou Pingjian,ní wọn sọ̀rọ̀ yìí fún àwọn akọ̀ròyìn nílùú Àbújá. +Okunfa ni fidio kan ti awon omo Naijiria fihan kaakiri, to n safihan ohun buburu ti awon omo China foju wa ri lohun-un. Okùnfà ni fídíò kan tí àwo̩n o̩mo̩ Nàìjíríà fihàn káàkiri, tó ń s̩àfihàn ohun búburú tí àwo̩n o̩mo̩ China fojú wa rí ló̩hùn-ún. +Minisita tesiwaju pe arabinrin kan to n ta ounje niluu Guangzhou, ni China, alarun COVID-19 lodun 2019 pelu awon omo Naijiria ti won ra ounje lodo re fara kaasa aarun korona, won fe fi won si igbele sugbon ti oro gbabomiran nipase aigbonran. Mínísítà tẹ̀síwájú pé arábìnrin kan tó ń ta oúnjẹ nílùú Guangzhou, ní China, alárùn COVID-19 lọ́dún 2019 pẹ̀lú àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ra oúnjẹ ló̩dò̩ rè̩ fara káása ààrùn kòrónà, wó̩n fé̩ fi wó̩n sí ìgbélé s̩ùgbó̩n tí ò̩rò̩ gbabòmíràn nípasè̩ àìgbó̩nràn. +Minisita tun ni ibasepo to monyan lori wa laarin orile ede China ati orile ede Naijiria, orile ede mejeeji yii si ti n fowosowopo lati yanju wahala ohun. Mínísítà tún ní ìbásepọ̀ tó mọ́nyán lórí wà láàrín orílẹ̀ èdè China àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, orílẹ̀ èdè méjèèjì yìí sí ti ń fọwọ́sowọ́pọ̀ láti yanjú wàhálà ọ̀hún. +--- COVID-19: Aare Buhari gbosuba fun akoroyin, ajo eleto aabo ati ilera --- COVID-19: Ààrẹ Buhari gbósùbà fún akọ̀ròyìn, àjọ elétò ààbò àti ì̀lera +Aare Muhammadu Buhari ti dupe lowo awon akoroyin, ajo to n mojuto eto ilera, awon ile-ise eto aabo fun gudu gudu meje yaya mefa ti won n se lorile ede yii lati dekun itankale aarun COVID-19. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn akọ̀ròyìn, àjọ tó ń mójútó ètò ìlera, àwọn ilé-isẹ́ ètò ààbò fún gudu gudu méje yàyà mẹ́fà tí wọ́n ń ṣe lórílẹ̀ èdè yìí láti dẹ́kun ìtànkalẹ̀ ààrùn COVID-19. +Lakooko igbohunsafefe si awon omo orile-ede Naijiria lojo aje, Aare ni: Lákòókò ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ sí àwo̩n ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló̩jó̩ ajé, Ààre̩ ní: +Mo gbodo mo riri awon osise eto ilera ati awon ti o fara won jin ni jakejado orile ede Naijiria, paapaa julo ni ipinle Eko, Ogun ati ni olu ilu Naijiria, iyen Abuja. Mo gbó̩dò̩ mo̩ rírì àwọn òṣìsẹ́ ètò ìlera àti àwọn tí ó fara wọn jìn ní jákèjádò orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, pàápàá jùlọ ní ìpínlẹ̀ Èkó, Ògùn àti ní olú ìlú Nàìjíríà, ìye̩n Abuja. +“Eyin ni akoni wa gege bi orile-ede, fun ojo aye wa gbogbo la maa dupe lowo yin fun ifarajin yin lasiko ipenija yii. “Ẹ̀yin ni akọni wa gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè, fún o̩jó̩ ayé wa gbogbo lá máa dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìfarajìn yin lásìkò ìpèníjà yìí. +A maa pese ohun amoriwu fun awon osise eto ilera, leyii taa kede lose to n bo. A máa pèsè ohun amóríwú fún àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera, léyìí táa kéde lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀. +Mo tun dupe lowo gbogbo ile-ise iroyin , awon gbaju-gbaja osere ati awon eniyan pataki lawujo fun ise ribi-ribi won lati maa la awon eniyan loye nipa imototo, yiyera ati ohun to ni se pelu ipejo. Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo ilé-isẹ́ ìròyìn , àwọn gbajú-gbajà òṣ̣èré àti àwọn ènìyàn pàtàkì láwùjọ fún iṣẹ́ ribi-ribi wọn láti máa la àwọn ènìyàn lọ́yẹ̀ nípa ìmọ́tótó, yìyẹra àti ohun tó ní ṣe pẹ̀lú ìpéjọ. +Latari awon atileyin ati ifowosowopo yii, opolopo awon aseyori ni a ti se lasiko eto konile-gbele ojo merinla ti a se. Látàrí àwọn àtìlẹyìn àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àseyọrí ni a ti ṣe lásìkò ètò kónílé-gbélé ọjọ́ mẹ́rìnlá tí a ṣe. +Awon eso eto aabo ati agbofinro naa ko gbeyin lati koju ipenija yii, mo kan saara si won. Àwọn ẹ̀ṣọ́ ètò ààbò àti agbófinró náà kò gbẹ́yìn láti kojú ìpèníjà yìí, mo kan sáárá sí wọn. +Mo ro won lati tubo maa se ojuse won bii ise lasiko eto konile-gbele yii, ki won si tun maa gbagbe ojuse won. Mo rọ̀ wọ́n láti túbọ̀ máa ṣ̣e ojúṣe wọn bíi iṣẹ́ lásìkò ètò kónílé-gbélé yìí, kí wọ̣́n sì tún máá gbàgbé ojúṣe wọn. +Awon adari orile ede yii nigbagbo pe igbese ti won n gbe yii ni lati dekun itankale aarun COVID-19. Àwọn adarí orílẹ̀ èdè yìí nígbàgbọ́ pé ìgbésẹ̀ tí wọ́n ń gbé yìí ní láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ ààrùn COVID-19. +--- Owo olopaa te odaran to pa ajihinrere Grace Ajibola niluu Ibadan --- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọ̀daràn tó pa ajíhìnrere Grace Ajíbọ́lá nílùú Ìbàdàn +Ile- ise olopaa ni ipinle Oyo ti se afihan afurasi odaran kan, Abegunde Olaniyi to lowo ninu iku Abileko Grace Ajibola ti se ajihinrere ni ile ijosin omoleyin Kristi kan ni agbegbe Oluyole ni ilu Ibadan to wa ni ekun Gusu iwo oorun orile ede Naijiria ni ojo ketadinlogun osu keta odun 2020 yii. Ilé- iṣẹ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti se àfihàn afurasí ọ̀daràn kan, Abégúndé Oláníyì tó lọ́wọ́ nínú ikú Abilékọ Grace Ajíbọ́lá tí ṣe ajíhìnrere ní ilé ìjọsìn ọmọlẹ́yìn Kristi kan ní agbègbè Olúyọ̀lé ní ìlú Ìbàdàn tó wà ní ẹkùn Gúsù ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjiríà ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹta ọdún 2020 yìí. +Ninu alaye re, komisona olopaa, Shina Olukolu je ki o di mimo pe afurasi odaran yii pa abileko Grace Ajibola leyin ti o gba owo to le ni milionu meji naira ninu apo ifowopamo re. Nínú àlàyé rẹ̀, kọmísọ́nà ọlọ́pàá, Shínà Olúkólù jẹ́ kí ó di mímọ́ pé afurasí ọ̀daràn yìí pa abilékọ Grace Ajíbọ́lá lẹ́yìn tí ó gba owó tó lé ní mílíọ́nù méjì náírà nínú àpò ìfowópamọ́ rẹ̀. +Sugbon owo palaba afurasi yii segi nigba ti owo ile-ise olopaa ipinle Oyo gbaa mu, ti won si fi kele ofin gbe e. Sùgbọ́n ọwọ́ pálábá afurasí yìí ségi nígbà tí ọ̣wọ́ ilé-isẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̣̀ Ọ̀yọ́ gbáa mú, tí wọ̣́n sì fi kélé òfin gbé e. +Ile- ise olopaa tun ri awon nnkan bii orisi kaadi ile –ifowopamo meta ti won fi n gba owo lenu ero powo-powo (ATM) gba, ero ilewo ibaraeni soro Techno, orisiirisii aso ati igi ti o fi pa arabinrin naa gba. Ilé- iṣẹ ọlọ́pàá tún rí àwọn nǹkan bíi oríṣi káádì ilé –ìfowópamọ́ mẹ́ta tí wọ́n fi ń gba owó lẹ́nu ẹ̀rọ pọwó-pọwó (ATM) gbà, ẹ̀rọ ìléwọ́ ìbáraẹni sọ̀rọ̀ Techno, orísiirísii aṣọ àti igi tí ó fi pa arábìnrin náà gbà. +Bakan naa, ni Ile- ise olopaa ipinle Oyo tun se afihan awon afurasi mokandinlogun miran ti won lowo ninu oniruuru iwa odaran bii ijinigbe, ijinipa ati idigunjale ni awon agbegbe kan ni ipinle Oyo. Bákan náà, ní Ilé- isẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tún ṣe àfihàn àwọn afurasí mọ́kàndínlógún míràn tí wọ́n lọ́wọ́ nínú onírúurú ìwà ọ̀daràn bíi ìjínigbé, ìjínipa àti ìdigunjalè ní àwọn àgbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. +Lara awon ohun ti Ile-ise olopaa tun ri gba lowo awon afurasi wonyi ni ibon- ilewo meji; ohun ija meta; keke alupupu ti a mo si okada mefa ati awon ohun miran bii: obe kan; ada eyo kan; ati owo to le die ni oke Merindinlogun ati aabo naira. Lára àwọn ohun tí Ilé-isẹ́ ọlọ́pàá tún rí gbà lọ́wọ́ àwọn afurasí wọ̀nyí ni ìbọn- ìléwọ́ méjì; ohun ìjà mẹ́ta; kẹ̀kẹ́ alùpùpù tí a mọ̀ sí ọ̀kadà mẹ́fà àti àwọn ohun mìràn bíi: ọ̀bẹ kan; àdá ẹyọ kan; àti owó tó lé díẹ̀ ní ọ̀kẹ́ Mẹ́rìndínlógún àti ààbọ̀ náírà. +Komisana Ile- ise olopaa, Shina Olukolu wa fi kun oro re pe ki awon eniyan ipinle Oyo mase foya nitori Ile- ise olopaa ti setan lati pese eto aabo to peye fun emi ati dukia won ni pataki julo ni asiko ikede konile- o- gbele to n lo lowo latari itankale ajakale aarun COVID-19 to n ba gbogbo orile ede agbaye woya ija. Kọmísánà Ilé- iṣẹ ọlọ́pàá, Shínà Olúkólù wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ máṣe fòyà nítorí Ilé- isẹ́ ọlọ́pàá tí setán láti pèsè ètò ààbò tó péye fún ẹ̀mí àti dúkìá wọn ní pàtàkì jùlọ ní àsìkò ìkéde kónílé- ó- gbélé tó ń lọ lọ́wọ́ látàrí ìtànkálẹ̀ àjàkálẹ̀ ààrùn COVID-19 tó ń bá gbogbo orílẹ̀ èdè àgbáyé wọ̀yá ìjà. +--- COVID-19. A o ni forijin eni to ba tapa sofin konile-gbele- Komisona ipinle Oyo --- COVID-19. A ò ní foríjin ẹni tó bá tàpá sófin kónílé-gbéle- Kọmísọ́nà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ +Komisona awon olopaa ipinle Oyo, Shina Olukolu ti fi ipe sita pe awon ko ni forijin eni to ba tapa sofin konile-gbele ni ipinle Oyo. Kọmísọ́nà àwọ̣n ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Shina Olúkolú ti fi ìpè síta pé àwọn kò ní foríjin ẹni tó bá tàpá sófin kónílé-gbélé ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. +O tesiwaju pe eni to ba fowo pa ida ijoba loju yoo foju ba ile-ejo lati je iya to ba to labe ofin. Ó tẹ̀síwájú pé ẹ̣ni tó bá fọwọ́ pa idà ìjọba lójú yóò fojú ba ilé-ẹjọ́ láti jẹ ìyà tó bá tọ́ lábẹ́ òfin. +Komisana awon olopaa lo siso loju oro yi lasiko ti o n se afihan awon afurasi odaran ti ko din ni ogun ni olu- ile ise olopaa ipinle Oyo to wa ni agbegbe Eleyele ni ilu Ibadan to wa ni ekun gusu iwo oorun orile ede Naijiria. Kọmísánà àwọn ọlọ́pàá ló ṣíṣọ lójú ọ̀rọ̀ yí lásìkò tí ó ń se àfihàn àwọn afurasí ọ̀daràn tí kò dín ní ogún ní olú- ilé isẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó wà ní agbègbè Ẹlẹ́yẹlé ní ìlú Ìbàdàn tó wà ní ẹkùn gúsù ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Ninu alaye re komisana je ki o di mimo pe Gomina ipinle Oyo, Seyi Makinde se agbekale ofin konile o gbele ni ara ona lati dena itankale ajakale aarun Corona virus ti a mo si COVID-19. Nínú àlàyé rẹ̀ komísánà jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Sèyí Mákindé se àgbékalè òfin kónílé ó gbélé ní ara ọ̀nà láti dènà ìtànkálẹ̀ àjàkálẹ̀ ààrùn Corona virus tí a mọ̀ sí COVID-19. +Ofin konile o gbele yii ni Gomina ipinle Oyo ti fi mule lati ojo kokandinlogbon osu keta odun 2020 yii, ninu eyi ti ijoba fi ofin de enikeni lati mase jade sita lati aago meje ale titi di aago mefa aaro ojo keji. Òfin kónílé ó gbélé yìí ní Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti fi múlẹ̀ láti ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n osù kẹta ọdún 2020 yìí, nínú èyí tí ìjọba fi òfin de ẹnikẹ́ni láti máse jáde síta láti aago méje alẹ́ títí di aago mẹ́fà àárò ọjọ́ kejì. +Ofin yii ko fi aaye gba enikeni labe bo ti wu kori lati se ohunkohun leyin aago meje ale lojoojumo. Òfin yìí kò fi ààyè gba ẹnikẹ́ni lábẹ́ bó ti wù kórí láti se ohunkóhun lẹ́yìn aago méje alẹ̣́ lójoojúmọ́. +Sugbon komisana wa fi aidunnu re han si iwa aigboran ti awon kan n hu lati maa ba awon olopaa woya ija to bee ti won fi di ero ile- iwosan. Sùgbọ́n komísánà wá fi àìdùnnú rẹ̀ hàn sí ìwà àìgbọràn tí àwọn kan ń hù láti máa bá àwọn ọlọ́pàá wọ̀yá ìjà tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi di èrò ilé- ìwòsàn. +--- COVID-19: Awon eniyan marun un (5) miran tun jeyo lorile ede Naijiria --- COVID-19: Àwọn ènìyàn márùn ún (5) míràn tún jẹyọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Awon eniyan marun un (5) miran tun jeyo tiwon ni aarun Corona (COVID 19 ) lorile ede Naijiria, ni eyi ti o je kiiye awon to ni aarun Corona je metalelogunleloodunrun (323), nigba ti awon eniyan bii marundinlaadorunun (85) ti gba iwosan , ti awon eniyan mewaa (10) si ti je Olorun nipe. Ajo to n gbogun ti ajakale aarun lorile ede Naijiria (NCDC) lo kede yii lori ero Twitter won, @NCDCgov,. Àwọn ènìyàn márùn ún (5) míràn tún jẹyọ tíwọ́n ní ààrùn Corona (COVID 19 ) lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ní èyí tí ó jẹ́ kíiye àwọn tó ní ààrùn Corona jẹ́ mẹ́tàlélógúnlélọ́ọ̀dúnrún (323), nígbà tí àwọn ènìyàn bíi márùndínláàdọ́rùnún (85) ti gba ìwòsàn , tí àwọn ènìyàn mẹ́wàá (10) ṣì ti j́ẹ Ọlọ́run nípè. Àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ ààrùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NCDC) ló kéde yìí lórí ẹ̀rọ Twitter wọn, @NCDCgov,. +Ninu awon mejo ti won sese jeyo ohun ,meji ( 2) ni ipinle Kwara ,meji (2) ni ipinle Eko ,eyo kan ( 1 ) ni ipinle Katsina. Ipinle ti aarun Corona ti je yo lorile ede Naijiria ti je ipinle mokandinlogun (19) bayii. Ademola Adepoju. Nínú àwọn mẹ́jọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹyọ ọ̣̀hún ,méjì ( 2) ní ìpínlẹ̀ Kwara ,méjì (2) ní ìpínlẹ̀ Èkó ,ẹyọ kan ( 1 ) ní ìpínlẹ̀ Katsina. Ìpínlẹ̀ tí ààrùn Corona ti jẹ yọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti jẹ́ ìpínlẹ̀ mọ́kàndínlógún (19) báyìí. Adémọ́lá Adépọ̀jù. +--- COVID-19: E maa lo oselu fun akitiyan ijoba nipa aarun Corona-IBB --- COVID-19: Ẹ máa lo òṣèlú fún akitiyan ìjọba nípa ààrùn Corona-IBB +Ajagunfeyinti , to tun je aare teleri fun orile ede Naijiria , Ibrahim Badamasi Babangida ti ro gbogbo awon ti oro lati maa se fi lo oselu fun akitiyan ijoba nipa aarun Corona. Ajagunfẹ̀yìntì , tó tún jẹ́ ààrẹ tẹ́lẹ̀rí fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà , Ibrahim Badamasi Babangida ti rọ gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ láti máá ṣe fi lo òṣèlú fún akitiyan ìjọba nípa ààrùn Corona. +O wa gbosuba fun awon osise ijoba lori akitiyan won lati dekun aarun Corona. Ajagunfeyinti, Ibrahim Babangida soro yii lojo Aiku niluu Minna, ni ipinle Niger, o tun wa gbosuba fun awon gomina ipinle, awon ajo eleto ilera fun ipa pataki ti won n ko lati dekun aarun Covid-19 lorile ede Naijiria , bo tile je pe iye awon to ni aarun ohun si n po si lojoojumo. Ó wá gbósùbà fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọ̣ba lórí akitiyan wọn láti dẹ́kun ààrùn Corona. Ajagunfẹ̀yìntì, Ibrahim Bàbángídá sọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́ Àìkú nílùú Minna, ní ìpínlẹ̀ Niger, ó tún wá gbósùbà fún àwọn gómìnà ìpínlẹ̀, àwọn àjọ elétò ìlera fún ipa pàtàkì tí wọ́n ń kó láti dẹ́kun ààrùn Covid-19 lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà , bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn tó ní ààrùn ọ̀hún sì ń pọ̀ si lójoojúmọ́. +O wa ro gbogbo omo orile ede Naijiria lati maa tele gbogbo ilana ti awon ajo eleto ilera ati ajo to n gbogun ti itankale aarun (NCDC) ba la sile lati dekun aarun COIVD-19. Ó wá rọ gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti máa tẹ̀lé gbogbo ìlànà tí àwọn àjọ elétò ìlera àti àjọ tó ń gbógun ti ìtànkálẹ̀ ààrùn (NCDC) bá là sílẹ̀ láti dẹ́kun ààrùn COIVD-19. +--- Easter: Abenugan ipinle Osun ro Naijiria lati ni ireti ninu Olorun --- Easter: Abẹnugan ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun rọ Nàìjíríà láti ní ìrètí nínú Ọlọ́run +Abenugan ile igbimo asofin ti ipinle Osun, ogbeni Timothy Owoeye,ti ro gbogbo awon omo leyin Krisiti ati orile ede Naijiria lati mu ireti won duro sinsin bo tile je pe ajakale wa lorile ede Naijiria. Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, ọ̀gbẹ́ni Timothy Owóèye,ti rọ gbogbo àwọn ọmọ lẹ́yìn Krísít̀i àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti mú ìrètí wọn dúro ṣinṣin bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀ wà lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Owoeye soro yii lojo Abameta ninu atejade re fun ajodun Ojo Ajinde , o ni ki i se aarun Corona ni yoo je ki opin aye de. Owóèye sọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́ Àbámẹ́ta nínú àtẹ̀jáde rẹ̀ fún àjọ̀dún Ọjọ́ Àjíǹde , ó ní kì í ṣe ààrùn Corona ni yóò jẹ́ kí òpin ayé dé. +O wa ro awon ojulowo omo orile ede Naijiria lati seranwo ohun iderun fun awon to nilo iranlowo. Ó wá rọ̣ àwọn ojúlówó ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ṣèrànwọ́ ohun ìdẹ̀rùn fún àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́. +O tesiwaju pe: A gbodo je ki ajodun Ajinde ti Krisiti yii ni ipa pataki ninu ibasepo pelu awon elomiran. Ó tẹ̀síwájú pé: A gbọdọ̀ jẹ́ kí àjọ̀dún Àjíǹde ti Krísítì yìí ní ipa pàtàkì nínú ìbásepọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. +A ko gbodo da eto iranwo fun awon eniyan lasiko aarun COVID-19 yii da ijoba ati awon oloselu nikan. A kò gbọdọ̀ dá ètò ìrànwọ́ fún àwọ̣n ènìyàn lásìkò ààrùn COVID-19 yìí dá ìjọba àti àwọn olósèlú nìkan. +Ko si ariyanjiyan pe asiko ti a wa yii le pupo sugbon a gbodo mu igbagbo wa duro sinsin ninu Olorun, ki a si ni ireti pe,bo tile wu ki o le to, igba si n bo wa de . Kò sí àríyànjiyàn pé àsìkò tí a wà yìí le púpọ̀ sùgbọ́n a gbọdọ̀ mú ìgbàgbọ́ wa dúró sinsin nínú Ọlọ́run, kí a sì ní ìrètí pé,bó tilẹ̀ wù kí ó le tó, ìgbà sì ń bọ̀ wá dẹ̀ . +--- Aarun COVID-19 --- Ààrùn COVID-19 +Aarun COVID-19 je aarun asekupani , to tun je ki gbogbo eto oro aje orile ede agbaye dojubole. Ààrun COVID-19 jẹ́ ààrùn asekúpani , tó tún jẹ́ kí gbogbo ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè àgbáyé dojúbolẹ̀. +Eyi lo mu ki ijoba apapo orile ede Naijiria gbe igbese lati sofin konile-gbele ni ipinle Eko, Ogun ati Abuja, lati daabo bo emi tonile-talejo to wa lorile ede Naijiria. Èyí ló mú kí ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gbé ìgbéṣẹ̀ láti sòfin kónílé-gbélé ní ìpínlẹ̀ Èkó, Ògùn àti Àbújá, láti dáàbò bò ẹ̀mí tonílé-tàlejò tó wà lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Nipa titele eto ilana ti ajo to n mojuto eto ilera la sile ati igboran si ofin igbele nikan lo lee mu wa bori. Nípa títẹ̀lé ètò ìlànà tí àjọ tó ń mójútó ètò ìlera là sílẹ̀ àti ìgbọràn sí òfin ìgbélé nìkan ló leè mú wa borí. +--- Easter: E je ki igbagbo yin duro sinsin – Seyi Makinde, Oyo State Governor --- Easter: Ẹ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ yín duro ṣinṣin – Sèyí Mákindé, Oyo State Governor +Gomina ipinle Oyo , Seyi Makinde ti ro awon omo leyin Krisiti lati mu igbagbo won duro sinisin ninu agbara Ajinde Krisiti paapaa julo lasiko ti gbogbo agbaye n koju ipenija aarun Corona. Góm̀inà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ , Sèyí Mákindé ti rọ àwọn ọmọ lẹ́yìn Krísítì láti mú ìgbàgbọ́ wọn dúró ṣiniṣin nínú agbára Àjíǹde Krísítì páàpáà jùlọ lásìkò tí gbogbo àgbáyé ń kojú ìpèníjà ààrùn Corona. +Gomina soro yii ninu oro Ajinde ti o fi ranse si awon omo ipinle Oyo. Góm̀inà ṣọ̀rọ̀ yìí nínú ọ̀rọ̀ Àjíǹde tí ó fi ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. +Makinde tun so pe, “Ayeye Ajinde, maa n ran awa omo leyin Kristi leti nipa igbagbo wa, Igbagbo ninu agbara Ajinde. Mákindé tún sọ pé, “Ayẹyẹ Àjíǹde, máa ń ran àwa ọmọ lẹ́yìn Kristi létí nípa ìgbàgbọ́ wa, Ìgbàgbọ́ nínú agbára Àjíǹde. +A gbodo nigbagbo nipa ohun ti a ko fojuri ,paapaa julo lasiko ti gbogbo agbaye wa ninu ewu aarun COVID-19. A gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nípa ohun tí a kò fojúrí ,pàápàá jùlọ lásìkò tí gbogbo àgbáyé wà nínú ewu ààrùn COVID-19. +O tesiwaju pe bo tile je pe ajakale aarun Corona ti je ki awon omo ipinle naa wa ninu igbele , ti ko si lee je ki won lo si ibi ise oojo won, ti o tun je ki o nira fun pupo awon omo ipinle naa lati pese fun awon ebi won gege bi ise won. Ó tẹ̀síwájú pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀ ààrùn Corona ti jẹ́ kí àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ náà wà nínú ìgbélé , tí kò sì leè jẹ́ kí wọ́n lọ sí ibi iṣẹ́ òòjọ́ wọn, tí ó tún jẹ́ kí ó nira fún púpọ̀ àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ náà láti pèsè fún àwọn ẹbí wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn. +Gomina Makinde wa seleri pe ijoba yoo mu igbaye-gbadun awon ara ipinle naa lokunkundun. Gómìnà Mákindé wá ṣèlérí pé ìjọba yóò mú ìgbáyé-gbádùn àwọn ará ìpínlẹ̀ náà lọ́kùńkúndùn. +Gomina wa ro awon omo ipinle naa lati duro sinu ile won, ki won si wa ni alaafia. Gómìnà wá rọ àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ náà láti dúró sínú ilé wọn, kí wọ́n sì wà ní àlàáfíà. +--- ORO AARE MUHAMMADU BUHARI FUN AYEYE OJO AJINDE KRISTI FUN ODUN 2020 SI GBOGBO OMO ORILE EDE NAIJIRIA --- Ọ̀RỌ̀ ÀÀRẸ MUHAMMADU BUHARI FÚN AYẸYẸ ỌJỌ́ ÀJÍǸDE KRISTI FÚN ỌDÚN 2020 SÍ GBOGBO ỌMỌ ORÍLẸ̀ ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ +Mo ba awon arakunrin, arabinrin omo leyin kristi ati gbogbo omo orile ede Naijiria yo lori ayeye ojo Ajinde Kristi ti odun yii. Mo bá àwọn arákùnrin, arábìnrin ọmọ lẹ́yìn kristi àti gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjirià yọ̀ lórí ayẹyẹ ọjọ́ Àjíǹde Kristi ti ọdún yìí. +Iranti Ajinde odun yii waye lasiko ti itankale aarun COVID-19 jeyo ni gbogbo agbaye. Ìrántí Àjíǹde ọdún yìí wáyé lásìkò tí ìtànkálẹ̣̀ ààrùn COVID-19 jẹyọ ní gbogbo àgbáyé. +Bo tile je pe gbogbo awon omo leyin Kristi ni won ba ara won lati se ayeye ojo Ajinde ni ona irele yato si bi won se maa n se ayeye ohun nile-ijosin won. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ọmọ lẹ́yìn Kristi ní wọn bá ara wọn láti ṣe ayẹyẹ ọjọ́ Àjíǹde ní ọ̀nà ìrẹ̀lẹ̀ yàtọ̀ si bí wọ́n ṣẹ máa ń ṣe ayẹyẹ ọ̀hún nílé-ìjọ́sìn wọn. +Eleyii je kayefi ati ibanuje pupo. Eleyìí jẹ́ kàyéfì àti ìbànújẹ́ púpọ̀. +Sibesibe, Mo fe ro gbogbo awon omo leyin kristi lati mu igbagbo won duro sinsin ninu Kristi, ti o bori inunibini, awon ijiya ati ifarada, ati ju gbogbo re lo, iwa-bi-Olorun. Síbẹ̀síbẹ̀, Mo fẹ́ rọ gbogbo àwọn ọmọ lẹ́yìn kristi láti mú ìgbàgbọ́ wọn dúró ṣinṣin nínú Kristi, tí ó borí inúnibíni, àwọn ìjìyà àti ìfaradà, àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìwà-bí-Ọlọ́run. +Jesu Kristi duro fun agbara eniyan lati farada awon irora igba die ni ireti ogo ayeraye. Jésù Kristi dúró fún agbára ènìyàn láti farada àwọn ìrora ìgbà díẹ̀ ní ìrètí ògo ayérayé. +Mo ro yin lati gbe igbe aye irele, ibawi, ifarada, irubo ati igboran, ni eyi ti Jesu Kristi se afihan re lakooko to wa nile aye. Mo rọ̀ yín láti gbé ìgbé ayé ìrẹ̣̀lẹ̀, ìbáwí, ìfaradà, ìrúbọ àti ìgbọràn, ní èyí tí Jésù Kristi ṣe àfihàn rẹ̀ lákòókò tó wà nílé ayé. +Ko si anfaani ti o dara ju eleyii lo fun gbogbo awon Kristieni, ni pataki julo, gbogbo awon omo orile ede Naijiria lapapo, lati je olootito, ki won tun ni ireti pe, pelu adura gbigba ati nipase idurosinsin yala lokookan tabi lapapo, o di dandan ki orile-ede wa bori awon ipenija wonyi. Kò sí ànfààní tí ó dára ju eléyìí lọ fún gbogbo àwọn Krìstìẹ́nì, ní pàtàkì jùlọ, gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀, láti jẹ́ olóòtítọ́, kí wọ́n tún ní ìrètí pé, pẹ̀lú àdúrà gbígbà àti nípasẹ̀ ìdúróṣinṣin yálà lọ́kọ̀ọ̀kan tàbí lápapọ̀, ó di dandan kí orílẹ̀-èdè wá borí awọn ìpèníjà wọ̀nyí. +Emi ko ni iyemeji pe ti gbogbo awon alabasepo, eni-kookan ati awon egbe, ba sa ipa won ni kikun, ti a si tele imoran lati odo awon onimo-ijinle ati awon to ni oye nipa isoogun to le dekun aarun COVID-19, o daju pe ipinnu ti awon eniyan wa ni, yoo je ki a bori. Èmi kò ní iyèméjì pé tí gbogbo àwọn alábàṣepọ̀, ẹnì-kọ̀ọ̀kan àti àwọn ẹgbẹ́, ba sa ipá wọn ní kíkún, tí a sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ àti àwọn tó ní òye nípa ìṣòògùn tó lè dẹ́kun ààrùn COVID-19, ó dájú pé ìpinnu tí àwọn ènìyàn wá ní, yóò jẹ́ kí a borí. +Gege bi mo ti salaye seyin ninu igbohunsafefe ti mo se fun orile-ede yii lojo Aiku, Ojo kokandinlogbon, odun 2020, pe , niwon igba ti ko si abere ajesara ti a mo lowolowo to le gbogun ti aarun naa, ona ti o dara julo ati ti o munadoko ni lati yago fun aarun ohun nipase sise eto imototo deede ati nipa yiyera fun ipejo apapo. Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣàlàyé sẹ́yìn nínú ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí mo ṣe fún orílẹ̀-èdè yìí lọ́jọ́ Àìkú, Ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, ọdún 2020, pé , níwọ̀n ìgbà tí kò sí abẹ́rẹ́ àjẹsára tí a mọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ tó lè gbógun ti ààrùn náà, ọ̀nà tí ó dára jùlọ àti tí ó múnádóko ni láti yàgò fún ààrùn ọ̀hún nípasẹ̀ ṣíse ètò ìmọ́tótó déédé àti nípa yíyẹra fún ìpéjọ àpapọ̀. +Mo tun n lo anfaani yii lati gbosuba fun igbimo ijoba apapo fun awon ilana ti won n gbe lati dekun aarun COVID-19. Mo tún ń lo ànfààní yìí láti gbósùbà fún ìgbìmọ̀ ìjọba àpapọ̀ fún àwọn ìlànà tí wọ́n ń gbé láti dẹ́kun ààrùn COVID-19. +Mo mo nipa awon inira ati ijiya ti enikookan ati awon eniyan n dojuko nipase igbese bii igbele ati bi a ko se je ki won lo sibi ise oojo won. Mo mọ̀ nípa àwọn ìníra àti ìjìyà tí ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àwọn ènìyàn ń dojúkọ nípasẹ̀ ìgbésẹ̀ bíí ìgbélé àti bí a kò ṣe jẹ́ kí wọ́n lọ síbi isẹ́ òòjọ́ wọn. +Bo se je pe o nii se pelu “oro iye ati iku,” awon ipenija wonyi la ni lati koju fun ife ara wa lati gba orile-ede yii lowo ajakale aarun. Bó se jẹ́ pé ó níí ṣe pẹ̀lú “ọ̀rọ̀ ìyè àti ikú,” àwọn ìpèníjà wọ̀nyí la ní láti kojú fún ìfẹ́ ara wa láti gba orílẹ̀-èdè yìí lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ ààrùn. +Igbaye-gbadun awon eniyan mi lo je mi logun julo. Ìgbáyé-gbádùn àwọ̣n ènìyàn mi ló jẹ mí lógún jùlọ. +Nitori naa, idagbasoke eto oro aje orile ede yii se pataki ninu erongba wa, A o si tun gbiyanju lati pese awon ohun ti enu n je fun awon eniyan. Nítorí náà, ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè yìí ṣe pàtàkì nínú èròǹgbà wa, A ó sì tún gbìyànjú láti pèsè àwọn ohun tí ẹnu ń jẹ fún àwọn ènìyàn. +Lakooko ti a ri ajakale-aarun COVID-19, to je ipenija kariaye, ijoba yii ko salaimo gbogbo wahala ti awon onijagidijagan ati olote n fa lori eto aabo orile-ede wa. Lákòókò tí a rí àjàkálẹ̀-ààrùn COVID-19, tó jẹ́ ìpèníjà káríayé, ìjọba yìí kò saláìmọ̀ gbogbo wàhálà tí àwọn oníjàgídíjàgan àti ọlọ̀tẹ̀ ń fà lórí ètò ààbò orílẹ̀-èdè wa. +Won le loo anfaani yii lati se awon ikolu kan si orile ede wa. Wọ́n le loo àǹfààní yìí láti ṣe àwọn ìkọlù kan sí orílẹ̀ èdè wa. +Sugbon awon iko oloogun, awon ajo eleto aabo ati ajo to n se itopinpin si duro sinsin lati maa gbogun ti gbogbo ikolu to ba fe sele. Ṣùgbọ́n àwọn ikọ̣̀ olóógun, àwọn àjọ elétò ààbò àti àjọ tó ń ṣe ìtọpinpin sì dúró ṣinṣin láti máa gbógun ti gbogbo ìkọ̣lù tó bá fẹ́ sẹlẹ̀. +Bii a se n sami si ojo Ajinde ti odun yii, ohunkohun to ba wu ko je, Mo gba yin niyanju lati samulo ipo ti a wa yii , ki a si gbiyanju lati setoju ara wa , ki a si wa ni ailewu. Bíi a ṣe ń sàmì sí ọjọ́ Àjíǹde ti ọdún yìí, ohunkóhun tó bá wù kó jẹ́, Mo gbà yín níyànjú làti ṣàmúlo ipò tí a wà yìí , kí a sì gbiyànjú láti sètọ́jú ara wa , kí a sì wà ní àìléwu. +Mo ki gbogbo yin ku ajodun ojo ajinde Kristi. Mo kí gbogbo yín kú àjọ̀dún ọjọ́ àjíǹde Kristi. +Muhammadu Buhari Aare orile ede Naijiria Muhammadu Buhari Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjirià +--- O gbona feli-feli:Ijamba ina sele nile-ise isiro –owo --- Ó gbóná fẹli-fẹli:Ìjàm̀bá iná ṣẹlẹ̀ nílé-iṣẹ́ ìsirò –owó +Ile-ise pana-pana ti ni awon ti pa ina to n jo ile- ise isiro –owo orile ede Naijiria (Accountant General of the Federation). Ilé-isẹ́ paná-paná ti ní àwọn ti pa iná tó ń jó ilé- iṣẹ́ ìṣirò –owó orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (Accountant General of the Federation). +--- COVID-19: Awon eniyan mefa (6) miran tun jeyo lorile ede Naijiria --- COVID-19: Àwọn ènìyàn mẹ́fà (6) míràn tún jẹyọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Awon eniyan mefa (6) miran tun jeyo ti won ni aarun Corona (COVID 19 ) lorile ede Naijiria Àwọn ènìyàn mẹ́fà (6) míràn tún jẹyọ tí wọ́n ní ààrùn Corona (COVID 19 ) lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Ni eyi ti o je ki iye awon to ni aarun Corona je ojilenigba din meji (238), nigba ti awon eniyan bi marundinlogoji(35) ti gba iwosan , ti awon eniyan marun un (5) si ti je Olorun nipe. Ní èyí tí ó jẹ́ kí iye àwọn tó ní ààrùn Corona jẹ́ òjìlénígba dín méjì (238), nígbà tí àwọn ènìyàn bí márùndínlógójì(35) ti gba ìwòsàn , tí àwọn ènìyàn márùn ún (5) sì ti jẹ́ Ọlọ́run nípè. +--- E pin iresi ti e gba lowo awon fayawo fun omo orile ede Naijiria-Buhari --- Ẹ pín ìrẹsì tí ẹ gbà lọ́wọ́ àwọn fàyàwọ́ fún ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíría-Buhari +Aare orile ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti pase pe ki ile-ise asobode pin oko aadojo (150) iresi ti won gba sile lowo awon fayawo fun gbogbo ipinle to wa lorile ede Naijiria. Ààrẹ̣ orílẹ̀ èdè Nàìjíría, Muhammadu Buhari ti pàṣẹ pé kí ilé-iṣẹ́ aṣọ́bodè pín ọkọ̀ àádọ́jọ (150) ìrẹsì tí wọ́n gbá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn fàyàwọ́ fún gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà lórílẹ̀ èdè Nàìjíría. +Minisita fun eto inawo, isuna ati eto ilana , abileko Zainab Ahmed lo soro yii pelu awon akoroyin , niluu Abuja. Mínísítà fún ètò ìnáwó, ìsúná àti ètò ìlànà , abilékọ Zainab Ahmed ló sọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn , nílùú Àbújá. +Ahmed tun so pe gbogbo awon oko iresi ohun ni won ti fi ranse si ajo to n mojuto eto omoniyan ati isele pajawiri lati pin awon iresi naa kaakiri. Ahmed tún sọ pé gbogbo àwọ̣n ọkọ̀ ìrẹsì ọ̀hún ni wọ́n ti fi ránsẹ́ sí àjọ tó ń mójútó ètò ọmọnìyàn àti ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì láti pín àwọn ìrẹsì náà káàkiri. +Ahmed ni aare tun ti fowosi awon eto iranwo irugbin ti won yoo ko lo si awon apa ibikan lorile ede Naijiria. Ahmed ní ààrẹ tún ti fọwọ́sí àwọn ètò ìrànwọ́ irúgbìn tí wọn yóò kó lọ sí àwọn apá ibìkan lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Minisita tun tesiwaju pe ijoba ti din owo ti awon agbe maa n fi ra ajile lati egberun marun un aabo si egberun marun un naira fun baagi ajile kan. Mínísítà tún tẹ̀síwájú pé ìjọba ti dín owó tí àwọn àgbẹ̀ máa ń fi ra ajílẹ̀ láti ẹgbẹ̀rún márùn ún ààbọ̀ sí ẹgbẹ̀rún márùn ún náírà fún báàgì ajílẹ̀ kan. +O tun so pe awon eto iranwo miiran yoo tun wa fun gbogbo awon omo orile ede Naijiria. Ó tún sọ̣ pé àwọn ètò ìrànwọ́ míiràn yóò tún wá fún gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +--- Ojo Ajinde kristi: Ijoba orile ede Naijiria pase ojo Eti, Aje fun isinmi --- Ọjọ́ Àjíǹde kristi: Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pàṣẹ ọjọ́ Ẹtì, Ajé fún ìsinmi +Ijoba orile ede Naijiria ti pase pe ki ojo Eti, ojo kewaa, osu kerin (April 10) ati ojo ketala , ojo Aje je isinmi lati fi sayeye ajodun Ajinde ti krisiti. Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti pàṣẹ pé kí ọjọ́ Etì, ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹrin (April 10) àti ọjọ́ kẹtàlá , ọjọ́ Aje ́ jẹ́ ìsinmi láti fi sayẹyẹ àjọ̀dún Àjíǹde ti krisiti. +Minisita fun eto abele, ogbeni Rauf Aregbesola lo kede yii nipase ijoba apapo lojo Aje, niluu Abuja. Mínísítà fún ètò abẹ̣́lé, ọ̀gbẹ́ni Rauf Arégbéṣọlá ló kéde yìí nípasẹ̀ ìjọba àpapọ̀ lọ́jọ́ Ajé, nílùú Àbújá. +Aregbesola wa ro gbogbo awon omoleyin kristi lati maa sawokose iwa ati abuda Jesu kristi nipa fifi emi ife, alaafia ati aanu han ninu iwa ati ise won. Arégbéṣọlá wá rọ gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn kristi láti máa ṣàwòkọ́ṣẹ ìwà àti àbùdá Jésù kristi nípa fífi ẹ̀mí ìfẹ́, àlááfìa àti àànú hàn nínú ìwà àti ìṣe wọn. +Aregbesola tun wa gbogbo omo leyin kristi lati lo asiko ayeye ohun fi gbadura fun orile ede Naijiria ati gbogbo agbaye lapapo paapaa julo lasiko ajakale aarun COVID-19 to gba gbogbo aye kan. Arégbéṣọlá tún wá gbogbo ọmọ lẹ́yìn kristi láti lo àsìkò ayẹyẹ ọ̀hún fi gbàdúrà fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti gbogbo àgbáyé lápapọ̀ páàpáà jùlọ lásìkò àjàkálẹ̀ ààrùn COVID-19 tó gba gbogbo ayé kan. +Minisita tun ro gbogbo omo orile ede Naijiria lati maa satileyin fun gbogbo igbiyanju ijoba apapo nipa gbigbogun ti aarun Corona. Mínísítà tún rọ̣ gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti máa sàtìlẹyìn fún gbogbo ìgbìyànjú ìjọ̣ba àpapọ̀ nípa gbígbógun ti ààrùn Corona. +O wa ran gbogbo omo orile ede Naijiria leti nipa awon eto ilana ti awon alase ti la sile lona ati dekun itankale aarun Corona lorile ede yii paapaa julo nipa yiyera fun eniyan ati sise imototo lasiko ayeye ohun. Ó wá rán gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà létí nípa àwọn ètò ìlànà tí àwọn aláṣẹ ti là sílẹ̀ lọ́nà àti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ ààrùn Corona lórílẹ̀ èdè yìí pàápàá jùlọ nípa yíyẹra fún ènìyàn àti ṣíṣe ìmọ́tótó lásìkò ayẹyẹ ọ̀hún. +Aregbesola wa ki gbogbo awon omo leyin kristi ku ayeye ajodun Ajinde. Arégbéṣọlá wá kí gbogbo àwọn omọ lẹ́yìn kristi kú ayẹyẹ àjọ̀dún Àjíǹde. +--- COVID-19: Gomina ipinle Oyo yege ayewo, yoo bere ise lonii --- COVID-19: Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yege àyẹ̀wò, yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lónìí +Gomina ipinle Oyo, Seyi Makinde ti ni oun yege nibi ayewo keji ti won se fun oun nipa aarun Corona, o wa seleri lati bere ise re lonii, to je ojo Aje. Gómìnà ìpínlẹ̣̀ Ọ̀yọ́, Ṣ̣èyí Mákindé ti ní òun yege níbi àyẹ̀wò kejì tí wọ́n ṣe fún òun nípa ààrùn Corona, ó wá ṣèlérí láti bẹ̣̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̣̀ lónìí, tó jẹ̣́ ọjọ́ Ajé. +Makinde soro yii lasaale ojo Aiku lori ero Twittre re lasiko ti o gba abajade esi ayewo keji ohun. Mákindé sọ̀rọ̀ yìí láṣàálẹ́ ọjọ́ Àìkú lórí ẹ̀rọ Twittre rẹ̀ lásìkò tí o gba àbájáde èsì àyẹ̀wò kejì ọ̀hún. +Ogboojo osu keta ni gomina Makinde soro lori ero Twitter re pe, oun ni aarun Conona, iyen COVID-19. Ọgbọ̀ọjọ́ oṣù kẹta ni gómìnà Mákindé sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ Twitter rẹ̀ pé, òuń ní ààrùn Conona, ìyẹn COVID-19. +Lati igba yen ni gomina ohun ti wa ninu igbele, ki o to di pe o gba abajade esi keji nipa aarun Corona, ni eyi ti o so pe ko ni aarun yii. Láti ìgbà yẹn ni gómìnà ọ̀hún ti wà nínú ìgbélé, kí ó tó di pé ó gba àbájáde èsì kejì nípa ààrùn Corona, ní èyí tí ó sọ pé kò ní ààrùn yìí. +--- COVID-19: Awon eniyan mejo (8) miran tun jeyo lorile ede Naijiria --- COVID-19: Àwọn ènìyàn mẹ́jọ (8) míràn tún jẹyọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Awon eniyan mejo (8) miran tun jeyo ti won ni aarun Corona (COVID 19 ) lorile ede Naijiria, ni eyi ti o je ki iye awon to ni aarun Corona je ojilenigbadinmejo (232). Àwọn ènìyàn mẹ́jọ (8) míràn tún jẹyọ tí wọ́n ní ààrùn Corona (COVID 19 ) lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ní èyí tí ó jẹ́ kí iye àwọn tó ní ààrùn Corona jẹ́ òjìlénígbadínmẹ́jọ (232). +Ajo to n gbogun ti ajakale aarun lorile ede Naijiria (NCDC) lo kede yii lori ero Twitter won, @NCDCgov,ni asale ojo Aiku,ojo karun un, osu kerin (Sunday 5th April ) ni deede aago Mesan an aabo( 9:30 P. m,Local Time). Àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ ààrùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NCDC) ló kéde yìí lórí ẹ̀rọ̀ Twitter wọn, @NCDCgov,ní àṣálẹ́ ọjọ́ Àìkú,ọjọ́ karùn ún, oṣù kẹrin (Sunday 5th April ) ní déédé aago Mẹ́sàn án ààbọ̀( 9:30 P. m,Local Time). +Ninu awon mejo ti won sese jeyo ohun ,marun un ( 5) ni ipinle Eko ,eyo kan ( 1 ) ni ilu Abuja, Federal Capital Territory (FCT) ati eyo kan (2) ni ipinle Kaduna. Nínú àwọn mẹ́jọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹyọ ọ̀hún ,márùn ún ( 5) ní ìpínlẹ̀ Èkó ,ẹyọ kan ( 1 ) ní ìlú Àbújá, Federal Capital Territory (FCT) àti ẹyọ kan (2) ní ìpínlẹ̀ Kàdúná. +--- COVID-19: Gomina ipinle Eko yoo tesiwaju nipa eto iranwo --- COVID-19: Gómìná ìpínlẹ̀ Èkó yóò tẹ̀síwájú nípa ètò ìrànwọ́ +Gomina ipinle Eko,ogbeni Babajide Sanwo-Olu, ti kede pe awon ko ni dawo eto iranwo ti won n pese fun awon to ku die fun ati awon ti ko rowo hori ti ofin igbele ojo merinla ti ijoba apapo kede re lee pa won lara. Gómìná ìpínlẹ̀ Èkó,ọ̀gbẹ́ni Babájíd�� Sanwó-Olú, ti kéde pé àwọn kò ní dáwọ́ ètò ìrànwọ́ tí wọ́n ń pèsè fún àwọn tó kù díẹ̀ fún àti àwọn tí kò rọ́wọ́ họrí tí òfin ìgbélé ọjọ́ mẹ́rínlà tí ìjọba àpapọ̀ kéde rẹ̀ leè pa wọ́n lára. +Sanwo-olu soro yii leyin ipade igbimo alaakoso fun eto aabo to waye ni ile-gomina ni ipinle Eko, pe gbogbo gbese ti awon alaisan, alaboyun awon to wa ninu ewu pajawiri, awon ti won fe se ise abe fun ti won wa nile-iwosan alabode tabi ti ijoba ipinle lasiko ofin igbele yii ni awon ti san gbogbo owo ti won je nile iwosan. Sanwó-olú sọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn ìpàdé ìgbìmọ̀ aláákóso fún ètò ààbò tó wáyé ní ilé-gomínà ní ìpínlẹ̀ Èkó, pé gbogbo gbèsè tí àwọn aláìsàn, aláboyún àwọn tó wà nínú ewu pàjáwìrì, àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ fún tí wọ́n wà nílé-ìwòsàn alábọ́dé tàbí tí ìjọba ìpínlẹ̀ lásìkò òfin ìgbélé yìí ni àwọn ti san gbogbo owó tí wọ́n jẹ nílé ìwòsàn. +Sanwo-Olu ni awon gbe igbese yii lati je ki ara tu awon alaisan , ti ofin igbele ohun pa ise won lara lasiko aarun COVID-19. Sanwó-Olú ní àwọn gbé ìgbésẹ̀ yìí láti jẹ́ kí ara tu àwọn aláìsàn , tí òfin ìgbélé ọ̀hún pa iṣẹ́ wọn lára lásìkò ààrùn COVID-19. +O wa ro awon omo ipinle Eko lati tunbo mu suuru fun ijoba, Sanwo-Olu ni ofin igbele naa ti n so eso rere, ni eyi ti o je ki ajo eto ilera ati ajo to n gbogun ti aarun lorile ede yii lee maa topinpin awon to ni aarun Corona, ti won ti si n gba itoju ni ile –itoju awon alaisan to wa ni, Yaba. Ó wá rọ̣ àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Èkó láti túnbọ̀ mú sùúrù fún ìjọba, Sanwo-Olu ní òfin ìgbélé náà tí ń so èso rere, ní èyí tí ó jẹ́ kí àjọ ètò ìlera àti àjọ tó ń gbógun tí ààrùn lórílẹ̀ èdè yìí leè máa tọpinpin àwọn tó ní ààrùn Corona, tí wọ́n tì si ń gba ìtọ́jú ní ilé –ìtọ́jú àwọn aláìsàn tó wà ní, Yaba. +Sanwo-Olu wa tepele mo igbese ijoba lati tubo maa daabo bo emi ati dukia awon ara ilu. Sanwó-Olú wa tẹpẹlẹ mọ́ ìgbesẹ̀ ìjọba láti túbọ̀ máa dáàbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ará ìlú. +O wa kilo fun awon janduku ti won lee fe maa lo asiko yii lati da omi alaafia ru, pe awon ti so fun agbofinro lati pese eto aabo fun ipinle naa fun wakati merinlelogun. Ó wá kìlọ̀ fún àwọn jàǹdùkú tí wọ́n leè fẹ́ máa lo àsìkò yìí láti da omi àlàáfíà rú, pé àwọn ti sọ fún agbófinró láti pèsè ètò ààbò fún ìpìnlẹ̀ náà fún wákàtí mẹ́rìnlélógún. +--- COVID-19: Awon eniyan mewaa (10) miran tun jeyo lorile ede Naijiria --- COVID-19: Àwọn ènìyàn mẹ́wàá (10) míràn tún jẹyọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Awon eniyan mewaa (10) miran tun jeyo ti won ni aarun Corona (COVID 19 ) lorile ede Naijiria, ni eyi ti o je ki iye awon to ni aarun Corona je okoolenigba ati merin (224). Àwọn ènìyàn mẹ́wàá (10) míràn tún jẹyọ tí wọ́n ní ààrùn Corona (COVID 19 ) lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ní èyí tí ó jẹ́ kí iye àwọn tó ní ààrùn Corona jẹ́ okòólénígba àti mẹ́rìn (224). +Ninu awon mewaa ti won sese jeyo ohun ,mefa ( 6) ni ipinle Eko ,meji ( 2 ) ni ilu Abuja, Federal Capital Territory (FCT) ati meji (2) ni ipinle Edo. Nínú àwọn mẹ́wàá tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹyọ ọ̀hún ,mẹ́fà ( 6) ní ìpínlẹ̀ Èkó ,méjì ( 2 ) ní ìlú Àbújá, Federal Capital Territory (FCT) àti méjì (2) ní ìpínlẹ̀ Edó. +--- COVID-19: Awon eniyan marun un miran tun jeyo lorile ede Naijiria --- COVID-19: Àwọn ènìyàn márùn ún míràn tún jẹyọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Awon eniyan marun un miran tun jeyo ti won ni aarun Corona (COVID 19 ) lorile ede Naijiria, ni eyi ti o je ki iye awon to ni aarun Corona je okoolenigba din mefa (214). Àwọn ènìyàn márùn ún míràn tún jẹyọ tí wọ́n ní ààrùn Corona (COVID 19 ) lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ní èyí tí ó jẹ́ kí iye àwọ̣n tó ní ààrùn Corona jẹ́ okòólénígba dín mẹ́fa (214). +Ajo to n gbogun ti ajakale aarun lorile ede Naijiria (NCDC) lo kede yii lori ero Twitter won, @NCDCgov,lasaale ojo Abameta ni deede aago Mewaa koja iseju mewaa( 10:10 p. m,Local Time). Àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ ààrùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NCDC) ló kéde yìí lórí ẹ̀rọ Twitter wọn, @NCDCgov,lásàálẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta ní déédé aago Mẹ́wàá kọjá ìsẹ́jú mẹ́wàá( 10:10 p. m,Local Time). +Ninu awon marun un ti won sese jeyo ohun, meta ( 3) ni ipinle Bauchi (Ariwa ila oorun ) ati meji ( 2 ) ni ilu Abuja, Federal Capital Territory (FCT). Nínú àwọn márùn ún tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹyọ ọ̀hún, mẹ́ta ( 3) ní ìpínlẹ̀ Bauchi (Àríwá ìlà oòrùn ) àti méjì ( 2 ) ní ìlú Àbújá, Federal Capital Territory (FCT). +--- A o sa ipa wa lati gbogun ti aarun Corona ni Naijiria- Chikwe Ihekweazu --- A ó sa ipá wa láti gbógun ti ààrùn Corona ní Nàìjíríà- Chikwe Ihekweazu +Igbimo ijoba apapo to n mojuto gbigbogun ti aarun Covid-19 ti ro awon oludari ile-ise ijoba ati aladaani lati maa tele gbogbo ilana ati ayewo to ni se nipa didekun aarun Corona. Ìgbìmọ̀ ìjọba àpapọ̀ tó ń mójútó gbígbógun ti ààrùn Covid-19 ti rọ̣ àwọn olùdarí ilé-iṣẹ́ ìjọba àti aládàáni láti máa tẹ̣̀lé gbogbo ìlànà àti àyẹ̀wò tó ní ṣe nípa dídẹ́kun ààrùn Corona. +Akowe agba fun ijoba apapo lorile ede Naijiria (SGF) ati alaga ijoba apapo to n mojuto gbigbogun ti aarun Covid-19 , Boss Mustapha lo soro yii niluu Abuja pelu awon akoroyin lojobo. Akọ̀wé àgbà fún ìjọba àpapọ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà (SGF) àti alága ìjọba àpapọ̀ tó ń mójútó gbígbógun ti ààrùn Covid-19 , Boss Mustapha ló sọ̀rọ̀ yìí nílùú Àbújá pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́bọ̀. +Ogbeni Mustapha ni aarun Corona yii lagbara lati fi emi awon eniyan ati eto oro aje, eto aabo orile ede Naijiria sinu ewu. Ọ̀gbẹ́ni Mustapha ní ààrùn Corona yìí lágbára láti fi ẹ̣̀mí àwọn ènìyàn àti ètò ọrọ̀ ajé, ètò ààbò orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sínú ewu. +O wa ro gbogbo omo orile ede yii pe ki won ri gbogbo igbese ti igbimo ohun n gbe gege bii ona lati daabo bo igbesi aye teru-tomo to wa lorile ede Naijiria. Ó wá rọ̣ gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè yìí pé kí wọ̣n rí gbogbo ìgbésẹ̀ tí ìgbìmọ̀ ọ̀hún ń gbé gẹ́gẹ́ bíi ọ̀nà láti dáàbò bo ìgbésí ayé tẹrú-tọmọ tó wà lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Minisita fun eto ilera lorile ede Naijiria, Osagie Ehanire, to je okan lara igbimo ohun so pe: Mínísítà fún ètò ìlera lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Osagie Ehanire, tó jẹ́ ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ ọ̀hún sọ pé: +"""A ro gbogbo omo orile ede Naijiria lati duro sinu ile won, ki won si mojuto eto ilera won, nipa titele eto ilana ti ajo eto ilera laa sile ayafi eni ti o ba sese de lati irinajo nikan lo ni anfaani lati rin pada lo sinu ile re ""." """A rọ gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti dúró sínú ilé wọn, kí wọ́n sì mójútó ètò ìlera wọn, nípa títẹ̀lé ètò ìlànà tí àjọ ètò ìlera làà sílẹ̀ àyàfi ẹni tí ó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ìrìnàjò nìkan ló ní àǹfààní láti rìn padà lọ sínú ilé rẹ̀ ""." +Oludari ajo to n gbogun ti aarun kokoro lorile ede Naijiria, (National Center for Disease Control, NCDC), Chikwe Ihekweazu ni: Olùdarí àjọ tó ń gbógun tí ààrùn kòkòrò lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, (National Center for Disease Control, NCDC), Chikwe Ihekweazu ní: +Lojoojumo ni a n fi awon osise ati ohun elo ranse si ipinle ti aarun Corona ba gbe jeyo ,a si n gbiyanju lati sa ipa wa lona ti a oo fi dekun aarun Corona lorile ede Naijiria, bo tile je pe awon nilo owo, irinse,awon oluranlowo ,ohun elo ati awon nnkan miran. Lójoojúmọ́ ni à ń fi àwọn òṣìṣẹ́ àti ohun èlò ránṣẹ́ sí ìpínlẹ̀ tí ààrùn Corona bá gbé jẹyọ ,a sì ń gbìyànjú láti sa ipá wa lọ́nà tí a óò fi dẹ́kun ààrùn Corona lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nílò owó, irinsẹ̀,àwọn olùrànlọ́wọ́ ,ohun èlò àti àwọn nǹkan míràn. +Igbiyanju yii ko rorun rara, sugbon a fi n da gbogbo ipinle to wa lorile ede Naijiria loju pe , a o ni kaa aare lati sa ipa wa nipa didekun aarun Corona ni awon ipinle ti aarun yii ba ti gbe n jeyo. Ìgbìyànjú yìí kò rọrùn rárá, sùgbọ́n a fi ń dá gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà lórílẹ̀ èdè Nàìjírìá lójú pé , a ò ní káá àárẹ̀ láti sa ipá wa nípa dídẹ́kun ààrùn Corona ní àwọn ìpínlẹ̀ tí ààrùn yìí bá ti gbé ń jẹyọ. +--- COVID-19: Ipinle Anambra ati ipinle miran ti bere gbigba owo iranwo --- COVID-19: Ìpínlẹ̀ Anambra àti ìpínlẹ̀ míràn ti bẹ̀rẹ̀ gbígba owó ìrànwọ́ +Ijoba apapo ti ni ipinle Anambra,Katsina ati Nasarawa yoo bere si ni maa gba owo iranwo lati odo ajo to n mojuto eto omoniyan, ijamba pajawiri ati idagbasoke ayika. Ìjọba àpapọ̀ ti ní ìpínlẹ̀ Anambra,Katsina àti Nasarawa yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní máa gba owó ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ àjọ tó ń mójútó ètò ọmọnìyàn, ìjàm̀bá pàjáwìrì àti ìdàgbàsókè àyíká. +Minisita fun ajo to n mojuto eto omoniyan, ijamba pajawiri ati idagbasoke ayika lorile ede Naijiria, odo ajo to n mojuto eto omoniyan, ijamba pajawiri ati idagbasoke ayika , Sadiya Umar Farouq salaye pe eto ti iranwo owo ti awon n se ohun wa lara ileri ti aare Muhammadu Buhari se lati pese eto iranwo lasiko igbele lona atidekun aarun Covid-19. Mínísítà fún àjọ tó ń mójútó ètò ọmọnìyàn, ìjàm̀bá pàjáwìrì àti ìdàgbàsókè àyíká lorilẹ èdè Nàìjíríà, ọ̀dọ̀ àjọ tó ń mójútó ètò ọm���nìyàn, ìjàm̀bá pàjáwìrì àti ìdàgbàsókè àyíká , Sadiya Umar Farouq ṣàlàyé pé ètò tí ìrànwọ́ owó tí àwọn ń ṣe ọ̀hun wà lára ìlérí tí ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe láti pèsè ètò ìrànwọ́ lásìkò ìgbélé lọ́nà àtidẹ́kun ààrùn Covid-19. +Eto iranwo naa waye ni ipinle Anambra , ni ijoba ibile Anyamelum (Woodu Anaku 1 & 2; Omor 1 & 2; Umerum Umumbo; Igbakwu; Ifite Ogwari 1 & 2; Umueje ati Omasi). Ètò ìrànwọ́ náà wáyé ní ìpínlẹ̀ Anambra , ní ìjọba ìbílẹ̀ Anyamelum (Wọọdu Anaku 1 & 2; Omor 1 & 2; Umerum Umumbo; Igbakwu; Ifite Ogwari 1 & 2; Umueje ati Omasi). +Eto iranwo owo ohun tun waye ni awon ibi meta kan ni Wamba, Wayo ati Nakere ni ipinle Nasarawa ,to je aarin gbungbun orile ede Naijiria. Ètò ìrànwọ́ owó ọ̀hún tún wáyé ní àwọn ibi mẹ́ta kan ní Wamba, Wayo àti Nakere ní ìpínlẹ́ Nasarawa ,tó jẹ́ ààrin gbùngbùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Bakan naa, won tun ri iranwo owo yii gba ni ijoba ibile metalelogbon ni ipinle Katsina. Bákan náà, wọ̣n tún rí ìrànwọ́ owó yìí gba ní ìjọ̣ba ìbílẹ̀ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ní ìpínlẹ̀ Katsina. +Awon ijoba ibile naa ni Bakori, Bindawa, Baure, Batagarawa, Dandume, Ingawa, Kaita, Mani, Musawa, Rimi ati Kankara. Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà ni Bakori, Bindawa, Baure, Batagarawa, Dandume, Ingawa, Kaita, Mani, Musawa, Rimi ati Kankara. +--- COVID-19: E maa san owo osu awon osise lasiko – aare Buhari --- COVID-19: Ẹ máa san owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ lásìkò – ààrẹ Buhari +Aare Naijiria, Muhammadu Buhari ti pase fun ajo amojuto eto inawo ati eto ilana lorileede lati maa sanwo osu awon osise. Ààrẹ Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti pàṣẹ fún àjọ amojuto ètò ìnáwó àti ètò ìlànà lórílèèdè láti máa sanwó oṣù àwọn òṣìṣẹ́. +Aare soro yii nile aare to wa niluu Abuja lasiko to n sepade pelu igbimo aare to n mojuto aarun COVID-19, nipa eto oro aje orileede yii. Ààrẹ sọ̀rọ̀ yìí nílé ààrẹ tó wà nílùú Àbújá lásìkò tó ń ṣèpàdé pẹ̣̀lú ìgbìmọ̀ ààrẹ tó ń mójútó ààrùn COVID-19, nípa ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀èdè yìí. +Aare tun wa pase fun ajo ohun lati mojuto eto amayederun bii awon oju popo oko ati oju oko irin, ki won si maa se amulo awon irinse orile ede yii. Ààrẹ tún wá pàṣẹ fún àjọ ọ̣̀hún láti mójútó ètò amáyédẹrùn bíi àwọn ojú pópó ọkọ̀ àti ojú ọkọ̀ irin, kí wọ́n ṣì máa ṣe àmúlò àwọn irinsẹ́ orílẹ̀ èdè yìí. +Alaga igbimo ohun, minisita fun eto inawo, isuna ati ilana orileede, Zainab Ahmed, lasiko to n bawon akoroyin ile aare soro, leyin ipade naa. Alága ìgbìmọ̀ ọ̀hún, mínísítà fún ètò ìnáwó, ìsúná àti ìlànà orílẹ̀èdè, Zainab Ahmed, lásìkò tó ń báwọn akọ̀ròyìn ilé ààrẹ sọ̀rọ̀, lẹ́yìn ìpàdé náà. +"Ahmed alaga igbimo naa ni ""Aare tun pase pe ki igbimo naa ri i pe won seto ilana ti yoo lee daabo bo awon akusee ati abarapa lawujo. """ "Ahmed alága ìgbìmọ̀ náà ní ""Ààrẹ tún pàsẹ pé kí ìgbìmọ̀ náà rí i pé wọ́n ṣètò ìlànà tí yóò leè dáàbò bò àwọn akús̩è̩é̩ àti abarapá láwùjọ. """ +Ninu alaye re si awon akoroyin, o nigbimo naa ti so isele lowolowo kaakiri agbaye fun aare nitori COVID-19 ati ipa to ni loro je wa. Nínú àlàyé rè̩ sí àwo̩n akò̩rò̩yìn, ó nígbìmò̩ náà ti so̩ ìs̩è̩lè̩ ló̩wó̩ló̩wó̩ káàkiri àgbáyé fún ààre̩ nítorí COVID-19 àti ipa tó ní ló̩rò̩ jé wa. +O ni, “loooto ni Aare ti ni ki won sanwo osu awon osise, ki won si mojuto awon eto amayederun bii awon oju popo oko, ati oju oko irin ki won si samulo irinse orileede yii Ó ní, “lóòótó ni Ààre̩ ti ní kí wó̩n sanwó os̩ù àwo̩n òs̩ìs̩é̩, kí wó̩n sì mójútó àwo̩n ètò amáyéde̩rùn bíi àwo̩n ojú pópó o̩kò̩, àti ojú o̩kò̩ irin kí wó̩n sì s̩àmúlò irins̩é̩ orílèèdè yìí +Ki iyi wa ma baa sonu. Bakan naa, ki won seto irorun fun alaini ati abarapa lawujo. Kí iyì wa má baà so̩nù. Bákan náà, kí wó̩n s̩ètò ìrò̩rùn fún aláìní àti abarapá láwùjo̩. +Lori idi abajo ipade naa, o ni, “eredi ipade naa ni lati soro soki fun aare lori bi isele asiko yii se n gbohun tuntun yo lojoojumo. Lórí ìdí abájo̩ ìpàdé náà, ó ní, “èrèdí ìpàdé náà ni láti sò̩rò̩ s̩ókí fún ààre̩ lórí bí ìs̩è̩lè̩ àsìkò yìí s̩e ń gbóhun tuntun yo̩ lójoojúmó̩. +Bi ipenija ilera se n gbooro si, o si n sakoba fun ipinle gbogbo ati igbele to wa lati kapa gbigbooro ipenija ilera yii. Bí ìpèníjà ìlera s̩e ń gbòòrò si, ó sì ń s̩àkóbá fún ìpínlè̩ gbogbo àti ìgbélé tó wà láti kápa gbígbòòrò ìpèníjà ìlera yìí. +“Ijiya igbele ni mimu oro aje naa fa bi igbin ati igbese ti o ye ni gbigbe lati le dena okunfa buburu lori fifa bii igbin awon oja oun okowo.” ���Ìjìyà ìgbélé ni mímú ò̩rò̩ ajé náà fà bí ìgbín àti ìgbésè̩ tí ó ye̩ ní gbígbé láti lè dènà okùnfà búburú lórí fífà bíi ìgbín àwo̩n o̩jà òun òkòwò.” +Okan lara igbimo ohun, iyen minisita ipinle fun eto epo robi lorileede yii, Timipre Sylva, ni eto oro aje orile ede yii ko fararo nitori aarun COVID-19, ati pe, owo epo n jabo lojoojumo, eyi lo se okunfa isonisoki fun aare loorekoore. Ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ ọ̀hún, ìye̩n mínísítà ìpínlẹ̀ fún ètò epo rọ̀bì lórílẹ̀èdè yìí, Timipre Sylva, ní ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè yìí kò fararọ nítorí ààrùn COVID-19, àti pé, owó epo ń jábó̩ lójoojúmó̩, èyí ló s̩e okùnfà ìso̩nís̩ókí fún ààre̩ lóòrèkóòrè. +Alaakoso ile-ifowopamo tijoba apapo (CBN), Godwin Emefiele, ni eto oro aje orile ede Naijiria ko reerin rara yato si bawon eniyan se ro o lokan. Aláákóso ilé-ìfowópamọ́ tìjọba àpapọ̀ (CBN), Godwin Emefiele, ní ètò ọ̣rọ̀ ajé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kò rẹ́ẹ́rìń rárá yàtọ̀ sí báwọn ènìyàn ṣe rò ó lọ́kàn. +O ni,”eto oro aje lagbaaye gan-an, baa se mo, yoo jiya awon isoro idagbasoke o si tun le mu akude ba eto oro aje lagbaaye. Ó ní,”ètò o̩rò̩ ajé lágbàáyé gan-an, báa s̩e mò̩, yóò jìyà àwo̩n ìs̩òro ìdàgbàsókè ó sì tún lè mú àkùdé bá ètò o̩rò̩ ajé lágbàáyé. +Nitori naa, a n gbiyanju lati ri ohun ta le se gege bii orileede lati bori isoro lowolowo ka ma ba kori sona aida topo lo. Nítorí náà, à ń gbìyànjú láti rí ohun tá lè s̩e gé̩gé̩ bíi orílèèdè láti borí ìs̩òro ló̩wó̩ló̩wó̩ ká má ba ko̩rí só̩nà àìda tó̩pò̩ lo̩. +“Ko ni rorun sugbon a kan le fi da awon eniyan wa loju pe a n sise gan-an lori re ati pe a oo wa ojutuu si, awon omo orile-ede Naijiria a si se rere sii. “Kò ní ro̩rùn s̩ùgbó̩n a kàn le fi da àwo̩n ènìyàn wa lójú pé à ń s̩is̩é̩ gan-an lórí rè̩ àti pé a óò wa ojútùú si, àwo̩n o̩mo̩ orílè̩-èdè Nàìjíríà á sì s̩e rere síi. +Awon to wa nibi igbimo ohun naa ni minisita ipinle fun eto isuna ati eto ilana orile ede, Clement Agba ati alaakoso ile-ise epo robi (NNPC), Mela Kyari. Àwọn tó wà níbi ìgbìmọ̀ ọ̀hún náà ni mínísítà ìpínlẹ̀ fún ètò ìsúná àti ètò ìlànà orílẹ̀ èdè, Clement Àgbà àti aláà́kóso ilé-iṣẹ́ epo rọ̀bì (NNPC), Mela Kyari. +--- Alakoso awon asobode gbosuba fun awon osise re --- Alákóso àwọn asọ́bodè gbósùbà fún àwọn òsìsẹ́ rẹ̀ +Alakoso awon asobode lorile ede Naijiria ti gbosuba fun awon osise re bi won se fakoyo ati iwa akinkanju ti won n hu lasiko ti ofin igbele lati dekun aarun Corona ti wo ojo meta bayii. Alákóso àwọn asọ́bodè lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti gbósùbà fún àwọn òṣìsẹ́ rẹ̀ bí wọ́n ṣe fakọyọ àti ìwà akínkanjú tí wọ́n ń hù lásìkò ti òfin ìgbélé láti dẹ́kun ààrùn Corona ti wọ ọjọ́ mẹ́ta báyìí. +Ogbeni Ali ni awon iroyin ti oun n gbo nipa awon osise re nipa iwa akinkanju ti won n hu lasiko ipenija to n dojuko orile ede Naijiria nipase aarun Corona, paapaa julo lati daabo bo awon ibudo oko oju omi. Ọ̀gbẹ́ni Àlí ní àwọn ìròyìn tí òun ń gbọ́ nípa àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ nípa ìwà akínkanjú tí wọ́n ń hù lásìkò ìpèníjà tó ń dojúkọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nípasẹ̀ ààrùn Corona, pàápàá jùlọ láti dáàbò bo àwọn ibùdó ọkọ̀ ojú omi. +O wa ro awon osise re lati maa tele ilana ti awon osise eto ilera la sile nipa fifo owo won, yiyera fun awon eniyan ati nipa lilo ose a-pa kokoro loore-koore. Ó wá rọ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ láti máa tẹ̀lé ìlànà tí àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera là sílẹ̀ nípa fífọ ọwọ́ wọn, yíyẹra fún àwọn ènìyàn àti nípa lílo ọsẹ a-pa kòkòrò lóòrè-kóòrè. +O wa gbadura pe ki Olorun wo awon ti aarun COVID-19 mu fun iwosan kiakia, ki Olorun si tun wo orile ede Naijiria ati agbaye san. Ó wá gbàdúrà pé kí Ọlọ́run wo àwọn tí ààrùn COVID-19 mú fún ìwòsàn kíákíá, kí Ọlọ́run sì tún wo orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti àgbáyé sàn. +--- COVID-19: ile-ise ologun ni iro ni fidio ti won n gbe kaakiri --- COVID-19: ilé-iṣẹ́ ológun ní irọ̣́ ni fídíò tí wọ́n ń gbé káàkiri +Ile-ise ologun ti ni iro ni fidio ti awon eniyan n gbe kaakiri lori ero ayelujara ati ni ile-ise iroyin lati ba ile-ise ohun loruko je. Ilé-iṣẹ́ ológun ti ní irọ́ ni fídíò tí àwọn ènìyàn ń gbé káàkiri lórí ẹ̀rọ ayélujára àti ní ilé-iṣẹ́ ìròyìn láti ba ilé-isẹ́ ọ̀hún lórúkọ jẹ́. +Oludari eka iroyin ati ikede fun ile-ise naa, ogagun John Enenche lo soro yii lojoru pe isele to wa ninu fidio ti awon eniyan n gbe kaakiri naa waye lodun 2012 ati 2013, ni eyi ti awon eni ibi n lo lasiko ti ijoba orile ede yii pase pe ki awon omo ogun wa lara awon osise eleto aabo lati ran won lowo lasiko ofin igbele, lati dekun itankale aarun COVID-19. Olùdarí ẹ̀ka ìròyìn àti ìkéde fún ilé-isẹ́ náà, ọ̀gágun John Enenche ló sọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́rú pé ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú fídíò tí àwọn ènìyàn ń gbé káàkiri náà wáyé lọ́dún 2012 àti 2013, ní èyí tí àwọn ẹni ibi ń lò lásìkò tí ìjọba orílẹ̀ èdè yìí pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ ogun wà lára àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò láti ràn wọ́n lọ́wọ́ lásìkò òfin ìgbélé, láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ ààrùn COVID-19. +Ogagun John Enenche ni Mo wa ro gbogbo awon omo orile ede Naijiria lati ri fidio ti won n gbe kaakiri gege bi ise owo awon eni ibi lati ba ile-ise ologun loruko je. Ọ̀gágun John Enenche ni Mo wá rọ gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti rí fídíò tí wọ́n ń gbé káàkiri gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ẹni ibi láti ba ilé-isẹ́ ológun lórúkọ jẹ́. +Ile-ise ologun ko ni ka a are nipa ojuse re lati maa tele ofin orile ede Naijiria ati lati maa daabo bo awon omo orile ede yii. Ilé-iṣẹ́ ológun kò ní ká à árẹ̀ nípa ojúṣe rẹ̀ láti máa tẹ́lẹ̀ òfin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà áti láti máa dáàbò bo àwọn omọ orílẹ̀ èdè yìí. +--- COVID-19: Awon metalelogun(23) miiran tun jeyo lorile ede Naijiria --- COVID-19: Àwọn mẹ́tàlélógún(23) mìíràn tún jẹyọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Awon metalelogun (23) miiran to je omo orile ede Naijiria ni won tun ni aarun Corona, (COVID-19) bayii. Àwọn mẹ́tàlélógún (23) mìíràn tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni wọ́n tún ní ààrùn Corona, (COVID-19) báyìí. +Awon kan to ni aarun Corona tun jeyo ni ipinle Eko, ilu Abuja, Akwa Ibom, Kaduna ati Bauchi. Àwọn kan tó ní ààrùn Corona tún jẹyọ ní ìpínlẹ̀ Èkó, ìlú Àbújá, Akwa Ibom, Kaduna ati Bauchi. +Gege bi ajo to n gbogun ti aarun kokoro (Nigerian Centre for Disease Control, NCDC,)se so pe , won ri mesan an( 9) ni ipinle Eko,meje (7)ni ilu Abuja, FCT, marun un (5) ni ipinle Akwa Ibom, eyo kan (1) ni ipinle Kaduna ati eyo kan (1) ni ipinle Bauchi. Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń gbógun tí ààrùn kòkòrò (Nigerian Centre for Disease Control, NCDC,)ṣe sọ pé , wọ́n rí mẹ́sàn án( 9) ní ìpínlẹ̀ Èkó,méje (7)ní ìlú Àbújá, FCT, márùn ún (5) ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom, ẹyọ kan (1) ní ìpínlẹ̀ Kàdúná àti ẹyọ kan (1) ní ìpínlẹ̀ Bauchi. +Gbogbo awon to ti ni aarun Corona lorile ede Naijiria wa je merinlelaadosan an (174) ti awon mesan an yege ati awon meji si ti gbemi mii. Gbogbo àwọn tó ti ní ààrùn Corona lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà wá jẹ́ mẹ́rìnléláàdọ́sàn án (174) tí àwọn mẹ́sàn án yege àti àwọn méjì sì ti gbẹ́mì mìì. +--- COVID-19: E wo ilu Abuja bo se pa lolo --- COVID-19: Ẹ wo ìlú Àbújá bó se pa lọ́lọ́ +To ba je pe alufaa tabi babalawo to mofa-mopele lo jise fun gbogbo omo orile ede Naijiria pe, aarun kan n bo , ti yoo je ki teru-tomo, tonile, talejo fidii mole won. Tó bá jẹ́ pé al̀ùfáà tàbí babaláwo tó mọfá-mọ̀pẹ̀lẹ̀ ló jíṣẹ́ fún gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pé, ààrun kan ń bọ̀ , tí yóò jẹ́ kí tẹrú-tọmo, tonílé, tàlejò fìdìí mọ́lẹ́ wọn. +Pe aarun kan n bo, ti yoo je ki onisowo ti soobu re pa, pe aarun kan n bo ti yoo je ki gbogbo awon to maa n teko leti lo si ile okeere nitori efori tabi aisan ranpe, ko lati salo bii ise won, pe won yoo jokoo sile , mo mo daju pe gbogbo omo orile ede Naijiria ni won yoo so pe ki onitohun tabi fun babalawo ohun pe ifa re ko fo rere. Pé ààrùn kan ń bọ̀, tí yóò jẹ́ kí onísòwò ti sọ́ọ̀bù rẹ̀ pa, pé ààrùn kan ń bọ̀ tí yóò jẹ́ kí gbogbo àwọn tó máa ń tẹkọ̀ létí lọ sí ilẹ̀ òkèèrè nítorí ẹ̀fọ́rí tàbí àìsàn ráńpẹ́, kọ̀ láti sálọ bíi ìṣe wọn, pé wọn yóò jókòó sílé , mo mọ̀ dájú pé gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni wọn yóò sọ pé kí onítọ̀hún tàbí fún babaláwo ọ̀hún pé ifá rẹ̀ kọ̀ fọ rere. +Amosa, se bo se wu oluwa lo n sola, bo se wu asedaa lo n huwa. Aarun COVID-19, aarun Corona wo orile ede Naijiria, gbogbo wa pa lolo, aarun ti ko mo olowo, talaka, ko da aarun ti ko mo ibi to ti wa, lorile ede China. Àmọ́sá, ṣé bó ṣe wu olúwa ló ń ṣọlá, bó ṣe wu aṣẹ̀dàá ló ń hùwà. Ààrùn COVID-19, ààrùn Corona wọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, gbogbo wa pa lọ́lọ́, ààrùn tí kò mọ olówó, tálákà, kó dà ààrùn tí kò mọ ibi tó ti wá, lórílẹ̀ èdè China. +Ohun ti o da mi loju ni pe, labe bo ti wu ko ri, orile ede Naijiria yoo yege, orile ede Naijiria yoo bo lowo aarun Corona. Ohun tí ó dá mi lójú ni pé, lábẹ́ bó ti wù kó rí, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yóò yege, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yóò bọ́ lọ́wọ́ ààrùn Corona. +O di dandan ka bo lowo aarun corona. Ó di dandan ká bọ̣́ lọ́wọ́ ààrùn corona. +Ti aarun Corona ba kuro lorile ede Naijiria, o ye ki gbogbo omo orile ede Naijiria ko ogbon kan tabi ikeji nibe pe, eni ti Olorun ko lee mu, o daju pe Olorun ko tii da onitohun. Tí ààrùn Corona bá kúrò lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ó yẹ kí gbogbo ọmọ orílẹ́ èdè Nàìjíríà kọ́ ọgbọ́n kan tàbí ìkejì níbẹ̀ pé, ẹni tí Ọlọ́run kò leè mú, ó dájú pé Ọlọ́run kò tíì dá onítọ̀hún. +O ye ki gbogbo wa lorile ede Naijiria ko ogbon pe, ajo ko da bii ile, bi oko si rokun, rosa, ile naa si ni abosimi oko. Ó yẹ kí gbogbo wa lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà kọ́ ọgbọ́n pé, àjò kò dà bíi ilé, bí ọkọ̀ sì ròkun, rọ̀sà, ilé náà sì ni àbọ̀simi oko. +To ba je pe, a ti tun gbogbo ile-iwosan ijoba yala ti ijoba apapo tabi ti ipinle, gbogbo ile itoju yala alabode tabi gbogbo awon ile-iwosan fasiti to wa lorile ede wa je ojulowo, je eyi to wa ni ibamu pelu gbogbo awon ile-iwosan to wa nile okeere, ti awon olowo wa maa n salo lasiko ti won ba ni aisan ranpe,to ba je pe gbogbo awon ile-iwosan wa gbounje fegbe gbawobo, iwonba ni wahala ati idaamu ti aarun Corona ko wa si lorile ede Naijiria iba je. Tó bá jẹ́ pé, a ti tún gbogbo ilé-ìwòsàn ìjọba yálá ti ìjọba àpapọ̀ tàbí ti ìpínlẹ̀, gbogbo ilé ìtọ́jú yálà alábọ́dé tàbí gbogbo àwọn ilé-ìwòsàn fásitì tó wà lórílẹ̀ èdè wa jẹ́ ojúlówó, jẹ́ èyí tó wà ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo àwọn ilé-ìwòsàn tó wà nílẹ̀ òkèèrè, tí àwọn olówó wa máa ń sálọ lásìkò tí wọ́n bá ní àìsàn ráńpẹ́,tó bá jẹ́ pé gbogbo àwọn ilé-ìwòsàn wa gbóuńjẹ fẹ́gbẹ́ gbàwobọ̀, ìwọ̀nba ni wàhálà àti ìdààmú tí ààrùn Corona kó wa sí lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà ìbá jẹ́. +Imoran mi ni wi pe, ki gbogbo wa fori-kori, fikun lukun, nitori pe agbajowo la fi n soya, owo kan ko gberu dori, Ki a gbiyanju lati yanju gbogbo awon kudie-kudie to wa lorile ede yii, yala nile iwosan wa gbogbo, tabi nipa eto oro aje, ki orile ede wa lee goke agba. Ìmọ̀ràn mi ni wí pé, kí gbogbo wa forí-korí, fikùn lukùn, nítorí pé àgbájọwọ́ la fi ń sọ̀yà, ọwọ́ kan kò gbẹ́rù dórí, Kí á gbìyànjú láti yanjú gbogbo àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó wà lórílẹ̀ èdè yìí, yálà nílé ìwòsàn wa gbogbo, tàbí nípa ètò ọrọ̀ ajé, kí orílẹ̀ èdè wa leè gòkè àgbà. +Abo oro la n so fomoluabi, to ba denu tan, yoo di odidi. e se pupo. Àbọ̀ ọ̀rọ̀ là ń sọ fọ́mọlúàbí, tó bá dénú tán, yóò di odidi. ẹ sẹ́ púpọ̀. +--- Titipa: ijoba apapo bere pinpin ogun egberun naira niluu Abuja --- Títìpa: ìjọba àpapọ̀ bẹ̀rẹ̀ pínpín ogún ẹgbẹ̀rún náírà nílùú Àbújá +Lona atimu irorun ba awon eniyan to n gbe niluu Abuja nipase ofin igbele ti aare Muhammadu Buhara kede re, ijoba orile ede Naijiria ti bere si n pin ogun egberun naira owo iranwo fun awon to n gbe ni ijoba ibile Kwali. Lọ́nà àtimú ìrọ̀rùn bá àwọn ènìyàn tó ń gbé nílùú Àbújá nípasẹ̀ òfin ìgbélé ti ààrẹ Muhammadu Buhara kéde rẹ̀, ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ sí ń pín ogún ẹgbẹ̀rún náírà owó ìrànwọ́ fún àwọn tó ń gbé ní ìjọba ìbílẹ̀ Kwali.̀ +Minisita fun eto omoniyan, isele pajawiri ati idagbasoke awujo, Hajiya Sadiya Umar Farouq lo so eleyii lasiko ti won n pin owo ohun ni owuro ojoru. Mínísítà fún ètò ọmọnìyàn, ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì àti ìdàgbàsókè àwùjọ, Hajiya Sadiya Umar Farouq ló sọ eléyìí lásìkò tí wọ́n ń pín owó ọ̣̀hún ní òwúrọ̀ ọjọ́rú. +Ile akede Naijiria so pe, awon eniyan ti iye won je aadowaa (190) ni won ti je anfaani ogun egberun (N20,000 ) ni ijoba ibile Kwali bayii. Ilé akéde Nàìjíríà sọ pé, àwọn ènìyàn tí iye wọn jẹ́ àádọ́wàá (190) ni wọ́n ti jẹ àǹfààní ogún ẹgbẹ̀rún (N20,000 ) ni ìjọba ìbílẹ̀ Kwali báyìí. +Hajiya Farouk ni awon eniyan ti won je anfaani owo ohun lo je pe egberun un marun un, ni won maa n gba tele, losoosu, ti won wa fun won ni ogun egberun lasiko yii fun owo osu merin leekan naa fun won. Hajiya Farouk ní àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ àǹfààní owó ọ̀hún ló jẹ́ pé ẹgbẹ̀rún ún márùn ún, ni wọ́n máa ń gbà tẹ́lẹ̀, lóṣooṣù, tí wọ́n wá fún wọn ní ogún ẹgbẹ̀rún lásìkò yìí fún owó oṣù mẹ́rin lẹ́èkan náà fún wọn. +O tesiwaju pe egberun marun un awon eniyan ni yoo je anfaani owo iranwo ohun niluu Abuja. Ó tẹ̀síwájú pé ẹgbẹ̀rún márùn ún àwọn ènìyàn ni yóò jẹ àǹfààní owó ìrànwọ́ ọ̀hún nílùú Àbújá. +--- Owo epo oko ayokele tun ti dinku si N123.50 --- Owó epo ọkọ̀ ayọ́kẹ́l��́ tún ti dínkù sí N123.50 +Ijoba orile ede Naijiria tun ti fowosi adinku owo epo oko ayokele lorile ede Naijiria si naira metalelogofa aabo (N123. 50, per Litre) fun lita kan. Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tún ti fọwọ́sí àdínkù owó epo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà sí náírà mẹ́tàlélọ́gọ́fà ààbọ̀ (N123. 50, per Litre) fún líta kan. +Alakooso agba fun ile-ise to n samojuto owo ori epo oko ayokele lorile ede Naijiria,(Petroleum Products Pricing Regulatory Agency) Abdulkadir Saidu, lo kede yii lasaale ojo Isegun. Alákòóso àgbà fún ilé-iṣẹ́ tó ń ṣàmójútó owó orí epo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà,(Petroleum Products Pricing Regulatory Agency) Abdulkadir Saidu, ló kéde yìí láṣàálẹ́ ọjọ́ Ìsẹ́gun. +Saidu ni adinku owo epo ohun yoo bere ni ojo kinni, osu kerin, Odun 2020 (April 1 2020), gbogbo ile-ise ti won gbe n ta epo oko ayokele ni jake-jado orile ede Naijiria lo gbodo tele ifilo yii. Sàídù ní àdínkù owó epo ọ̀hún yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kíńní, oṣù kẹrin, Ọdún 2020 (April 1 2020), gbogbo ilé-iṣẹ́ tí wọ́n gbé ń ta epo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ní jákè-jádò orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ló gbọdọ̀ tẹ̀lé ìfilọ̀ yìí. +--- COVID-19 : Awon mejila miran tun jeyo lorile ede Naijiria --- COVID-19 : Àwọn méjìlá míràn tún jẹyọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà +Awon alarun korona ni Naijiria (COVID-19 ) ti di mokanlelaadojo ( 151) lorile ede Naijiria bayii. Àwọn alárùn kòrónà ní Nàìjíríà (COVID-19 ) ti di mọ́kànléláàdọ́jọ ( 151) lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà báyìí. +Ajo to n mojuto ajakale aarun lorile ede Naijiria tun tikede lori ero Twitter won @NCDCgov, , pe awon mesan an (9) miiran tun ti jeyo ni ipinle Osun, meji (2) ni ipinle Edo, eyo kan(1) ni ipinle Ekiti. Àjọ tó ń mójútó àjàkálẹ̀ ààrùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà tún tikéde lórí ẹ̀ro Twitter wọn @NCDCgov, , pé àwọn mẹ́sàn án (9) mìíràn tún ti jẹyọ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, méjì (2) ní ìpínlẹ̀ Ẹdó, ẹyọ kan(1) ní ìpínlẹ̀ Èkìtì. +--- COVID-19: Aare Buhari dupe lowo awon eniyan, ile-ise fun atileyin --- COVID-19: Ààrẹ Buhari dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn, ilé-iṣẹ́ fún àtìlẹ́yìn +Aare Muhammadu Buhari ti fi idupe atinuwa re han si ise rere awon oludari ile-ise, awon ajihinrere, awon olorin ati enikookan to satileyin fun ijoba lati gbogun ti ajakale aarun COVID-19 to kolu eto oro aje agbaye. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti fi ìdúpẹ́ àtinúwá rẹ̀ hàn sí ìs̩e rere àwọn olúdarí ilé-iṣẹ́, àwọn ajíhìnrere, àwọn olórin àti ẹnìkọ̀ọ̀kan tó ṣàtìlẹ́yìn fún ìjọba láti gbógun ti àjàkálẹ̀ ààrùn COVID-19 tó kọlu ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé. +Aare dupe lowo ile-ise to n ta epo robi to fowosowopo pelu ile-ise (NNPC) lati fun won ni ogbon milionu dola, o tun dupe lowo okan lara agba egbe (APC), Asiwaju Bola Tinubu, Dr Mike Adenuga, iyaafin Folorunsho Alakija to ti ile-epo Famfa , ati Dr Emeka Offor, ti o darapo mo awon omo Naijiria lati seranwo eto ilera ati ile-eko. Ààrẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé-iṣe tó ń ta epo rọ̀bì to fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé-isẹ́ (NNPC) láti fun won ni ọgbọ́n mílíọ́nù dọ́là, ó tún dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀kan lára àgbà ẹgbẹ́ (APC), Asíwájú Bólá Tinubu, Dr Mike Adénúgà, ìyáàfin Fólórunshó Alákijà tó ti ilé-epo Famfa , àti Dr Emeka Offor, tí ò darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ṣèrànwọ́ ètò ìlera àti ilé-ẹ̀kọ́. +Aare tun fi inu didun dupe lowo awon oninu rere wonyi, ile-ifowopamo Zenith Bank PLC, ti o pese iranwo nibi eto ilera. Aare tun dupe lowo ile –ifowopamo Keystone bank, First Bank Plc ati oludari ile-ijosin Dunamis International Gospel Centre, Dr Paul Enenche, ati iyawo re, Dr Becky Enenche. Ààrẹ tún fi inú dídùn dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn onínú rere wọ̀nyí, ilé-ìfowópamọ́ Zenith Bank PLC, tí ó pèsè ìrànwọ́ níbi ètò ìlera. Ààrẹ tún dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé –ìfowópamọ́ Keystone bank, First Bank Plc àti olùdarí ilé-ìjọ́sìn Dunamis International Gospel Centre, Dr Paul Enenche, àti ìyàwó rẹ̀, Dr Becky Enenche. +Aare tun dupe gidigidi lowo ile-ise Stallion Group ati ajo to mojuto eto igbafe ati idaraya paapaa julo akorin ilu mo-on-ka, Innocent Idibia Tuface fun iranlowo won. Ààrẹ tún dúpẹ́ gidigidi lọ̣́wọ́ ilé-iṣẹ́ Stallion Group àti àjọ̣ tó mójútó ètò ìgbafẹ́ àti ìdárayá pàápàá jùlọ akọrin ìlú mọ̀-ọ́n-ká, Innocent Idibia Tuface fún ìrànlọ́wọ́ wo̩n. +Itunse eto ilera Ìtúns̩e ètò ìlera +Aare Buhari wa fi da gbogbo omo orile ede Naijiria loju pe, awon yoo lo owo naa bo se to lati fi gbogun ti itankale COVID-19 ati funtununse ile-iwosan. Ààrẹ Buhari wá fi dá gbogbo ���mọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lójú pé, àwọn yóò lo owó náà bó se tọ́ láti fi gbogun ti ìtànkálè̩ COVID-19 àti fúntùnúns̩e ilé-ìwòsàn. +O ro gbogbo afunni lati fowo naa ranse si iko aare amojuto aarun korona (COVID-19). Ó ro̩ gbogbo afúnni láti fowó náà ráns̩é̩ sí ikò̩ ààre̩ amójútó ààrùn kòrónà (COVID-19). +Aare tun wa ro awon omo orile ede Naijiria ki won tele ilana ti ile-ise ilera, ijoba ipinle ati iko amujoto aarun lorileede (NCDC), ti osise re n sise losan-an loru ki gbogbo eniyan lorileede le wa ni alaafia. Ààrẹ tún wá rọ̣ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kí wó̩n tè̩lé ìlànà tí ilé-is̩é̩ ìlera, ìjo̩ba ìpínlè̩ àti ikò̩ amújótó ààrùn lóríléèdè (NCDC), tí òs̩ìs̩é̩ rè̩ ń s̩is̩é̩ ló̩sàn-án lóru kí gbogbo ènìyàn lórílèèdè le wà ní àlááfíà. +O ni ipenija ti o n dojuko orile ede wa, ati awon orile ede yooku lagbaaye, yoo nilo atileyin owo, ironu ati eroja latodo ile-ise ati eniyan, pelu ifowosowopo omo Naijiria lati le kapa itankale aarun korona naa. Ó ní ìpèníjà tí ó ń dojúko̩ orílè̩ èdè wa, àti àwo̩n orílè̩ èdè yòókù lágbàáyé, yóò nílò àtile̩yìn owó, ìrònú ati èròjà látò̩dò̩ ilé-is̩é̩ àti ènìyàn, pè̩lú ìfo̩wó̩sowó̩pò̩ o̩mo̩ Nàìjíríà láti lè kápa ìtànkálè̩ ààrùn kòrónà náà. +--- Covid-19: Igbimo yoo tele ilana ki won to seranwo lasiko igbele --- Covid-19: Ìgbìmọ̀ yóò tẹ̀lé ìlàna kí wọ́n tó ṣèrànwọ́ lásìkò ìgbélé +Akowe agba ti ijoba apapo, Boss Mustapha ni igbimo ko ni pe se agbejade eto ilana ti won yoo tele lati se iranwo. Akọ̀wé àgbà ti ìjọba àpapọ̀, Boss Mustapha ní ìgbìmọ̀ kò ní pẹ́ s̩e àgbéjáde ètò ìlànà tí wọn yóò tẹ̀lé láti ṣe ìrànwọ́. +Aare Muhammadu Buhari ti fowosi yiyan igbimo ti yoo maa se amojuto eto okoowo ni orile ede Naijiria, ni eyi ti igbakeji aare, Yemi Osinbajo yoo maa dari re. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti fọ̣wọ́sí yíyan ìgbìmọ̀ tí yóò máa ṣe àmojútó ètò okòòwò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ní èyí tí igbákejì ààrẹ, Yemí Òsínbàjò yóò máa darí rẹ̀. +Akowe agba fun ijoba apapo, Mr Boss Mustapha lo soro eleyii lasiko ifilole ti igbimo naa ni ilu Abuja. Akọ̀wé àgbà fún ìjọba àpapọ̀, Mr Boss Mustapha ló sọ̀rọ̀ eléyìí lásìkò ìfilọ́lẹ̣̀ ti ìgbìmọ̀ náà ní ìlú Àbújá. +Akowe agba naa tun so pe ijoba yan igbimo ohun lati lee maa fun awon eniyan tara n ni niluu Abuja, Eko ati Ogun lasiko igbele yii, ki o le dekun itankale aarun Covid-19 ni Naijiria. Akọ̀wé àgbà náà tún sọ pé ìjọba yan ìgbìmọ̀ ọ̀hún láti lee máa fún àwọn ènìyàn tára ń ni nílùú Àbújá, Èkó àti Ògùn lásìkò ìgbélé yìí, kí ó lè dẹ́kun ìtànkálẹ̀ ààrùn Covid-19 ní Nàìjíríà. +A sese bere ni, a o tii mo igba ti isele yii maa tan, sugbon mo nigbagbo pe, a o bere eto naa laipe, awon eto ilana A ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni, a ò tíì mọ ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí máa tán, sùgbọ́n mo nígbàgbọ́ pé, a ó bẹ̀rẹ̀ ètò náà láìpẹ́, àwọn ètò ìlànà +Oun, igbimo naa yooo kede laipe ilana ti won yoo tele. Òun, ìgbìmọ̀ náà yóòọ̀ kéde láìpé̩ ìlànà tí wọn yóò tẹ̀lé. +--- Igbele COVID-19: Awon Gomina seleri mimojuto ilokiri eru pataki --- Ìgbélé COVID-19: Àwo̩n Gómìnà s̩èlérí mímójútó ìlo̩kiri e̩rù pàtàkì +Egbe awon gomina Naijiria (NGF) ti seleri pe awon yoo mojuto bi awon eru to se pataki yoo se maa lokiri lorileede Naijiria lasiko igbele lawon ipinle kookan wonyi. Ẹgbẹ́ àwọn gómìnà Nàìjíríà (NGF) ti ṣèlérí pé àwọn yóò mójútó bí àwọn ẹrù tó ṣe pàtàkì yóò ṣe máa lo̩kiri lóríléèdè Nàìjíríà lásìkò ìgbélé láwọn ìpínlẹ̀ kò̩ò̩kan wò̩nyí. +Ninu atejade kan ti egbe naa ko pe lasiko ipade ti won se lori ero ayelujara lojo Aiku, ni eyi talaga egbe ohun, Gomina ipinle Ekiti, Kayode Fayemi fowosi. Nínú àtẹ̀jáde kan tí ẹgbẹ́ náà kọ pé lásìkò ìpàdé tí wọ́n ṣe lórí ẹ̀rọ ayélujára lọ́jọ́ Àìkú, ní èyí tálága ẹgbẹ́ ọ̀hún, Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, Káyòdé Fáyẹmí fọwọ́ṣí. +Atejade ohun to te awon akoroyin lowo lojo aje ni Abuja so pe awon gomina sepade lori ero ayelujara, soro lori itankale korona kaakiri orileede Naijiria. Àtẹ̀jáde ọ̀hún tó te̩ àwọn akò̩ròyìn ló̩wó̩ lójó̩ ajé ní Abuja so̩ pé àwo̩n gómìná s̩èpàdé lórí è̩ro̩ ayélujára, sò̩rò̩ lórí ìtànkálè̩ kòrónà káàkiri orílèèdè Nàìjíríà. +Ninu abala atejade naa, o so pe: “awon gomina ti se ileri lati ri i daju pe awon eru pataki lo kaakiri orile ede yii ni akoko igbele. Nínú abala àtè̩jáde náà, ó so̩ pé: “àwo̩n gómìnà ti s̩e ìlérí láti rí i dájú pé àwo̩n è̩rù pàtàkì lo̩ káàkiri orílè̩ èdè yìí ní àkókò ìgbélé. +Ni Sekitariati NGF, ofin gbigbe awon eru pataki kaakiri yoo jade won a si fi fun gbogbo ijoba ipinle ni orile-ede. Ní Se̩kitáríàtì NGF, òfin gbígbé àwo̩n e̩rù pàtàkì káàkiri yóò jáde wo̩n á sì fi fún gbogbo ìjo̩ba ìpínlè̩ ní orílè̩-èdè. +Egbe to se atenumo idi fun fowosowopo laarin eto ilera ijoba apapo, ajo amojuto aarun ni Naijiria (NCDC) ati awon ile-ise ni ipinle lati kin igbese idena itankale aarun naa. E̩gbé̩ tó s̩e àte̩numó̩ ìdí fún fo̩wó̩sowó̩pò̩ láàrin ètò ìlèra ìjo̩ba àpapò̩, àjo̩ amójútó ààrùn ní Nàìjíríà (NCDC) àti àwo̩n ilé-is̩é̩ ní ìpínlè̩ láti kí́n ìgbésè ìdènà ìtànkálè̩ ààrùn náà. +Awon gomina tun fenuko lati maa sepade po loore-koore ati lose-ose lori ero ayelujara lori aarun corona ati igbese ti won n gbe lori re. Àwọn gómìnà tún fẹnukò láti máa ṣèpàdé pọ̀ lóòrè-kóòrè àti lọ́sẹ̀-ọ̀sẹ̀ lórí ẹ̀rọ̣ ayélujára lórí ààrùn corona àti ìgbésẹ̀ tí wọn ń gbé lórí rẹ̀. +Fayemi so fun awon gomina nipa igbese tIko ijoba apapo amojuto aarun Korona n gbe ati awon ile-ise aladaani, nipase ipese ounje, ohun mimu ati egbe oloogun eyi tegbe a-sohun-tita ti Naijiria (MAN) dari. Fáyemí sọ fún àwọn gómìnà nípa ìgbésẹ̀ tÍkò̩ ìjọba àpapọ̀ amójútó ààrùn Korona ń gbé àti àwọn ilé-iṣẹ́ aládàáni, nípasè̩ ìpèsè oúnje̩, ohun mímú àti e̩gbé̩ olóògùn èyí té̩gbé̩ a-sohun-títà ti Nàìjíríà (MAN) darí. +Awon Ile-ise aladaani yooku ni MTN Foundation ati awon egbe a-fi-nnkan le eyi ti Aliko Dangote ati Herbert Wigwe dari. Àwo̩n Ilé-iṣẹ́ aládàáni yòókù ni MTN Foundation àti àwo̩n e̩gbé̩ a-fi-nǹkan lè̩ èyí tí Aliko Dangote àti Herbert Wigwe darí. +Atejade naa ni awon gomina tun gba iroyin laipe lati odo minisita fun eto ilera, Dr Osagie Ehanire, ati oludari ajo NCDC, Dr Chikwe Ihekweazu, lori igbese ti ijoba apapo n gbe lati dekun itankale aarun COVID-19 lorileede. Àtẹ̀jáde náà ní àwo̩n gómìnà tún gba ìròyìn láìpé̩ láti ò̩do̩ mínísítà fún ètò ìlera, Dr Osagie Ehanire, àti olùdarí àjọ NCDC, Dr Chikwe Ihekweazu, lórí ìgbésẹ̀ tí ìjọba àpapọ̀ ń gbé láti dẹ́kun ìtànkálè̩ ààrùn COVID-19 lórílèèdè. +O fikun-un pe awon mejeeji fun awon gomina niroyin loorekoore lori eto lati mu ibi ayewo ati itoju alarun korona ni awon ipinle gbooro si. Ó fikún-un pé àwo̩n méjéèjì fún àwo̩n gómìnà níròyìn lóòrèkóòrè lórí ètò láti mú ibi àyè̩wò àti ìtó̩jú alárùn kòrónà ní àwo̩n ìpínlè̩ gbòòrò si. +--- COVID-19: Oludari osise fun Aare Buhari soro lori ipo re --- COVID-19: Olùdarí òs̩ìs̩é fún Ààre̩ Bùhárí sò̩rò̩ lórí ipò rè̩ +Oludari osise fun aare orile ede Naijiria, Abba Kyari, ti ni ko si ohun to se ilera oun sugbon oun yoo lo fun ayewo aarun Corona miiran ni ipinle Eko. Olùdarí òṣìṣẹ́ fún ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Abba Kyari, ti ní kò sí ohun tó ṣe ìlera òun sùgbọ́n òun yóò lọ fún àyẹ̀wò ààrùn Corona mìíràn ní ìpínlẹ̀ Èkó. +Adari oun soro lojo Aiku lori ero twitter re @NGRPresident so pe oun ti seto itoju fun ara oun lati lee din wahala awon osise eleto ilera ti won bo ku. Adarí ọ̀ún sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Àìkú lórí ẹ̀rọ twitter rẹ @NGRPresident sọ pé òun ti ṣètò ìtọ́jú fún ara òun láti leè dín wàhálà àwọn òṣ̣ìṣ̣ẹ́ elétò ìlera tí wó̩n bò kù. +“Mo ni awon alaboojuto temi nitori atile din wahala eto ilera ilu ku, ti won n koju ipenija,” Kyari lo so eyi. “Mo ní àwo̩n alábòójútó tèmi nítorí àtilè dín wàhálà èto ìlera ìlú kù, tí wó̩n ń kojú ìpèníjà,” Kyari ló so̩ èyí. +Kyari ni ara oun bale ati pe oun ko ni iriri gbigbona ati awon ohun ailera miiran to ro mo arun ohun. Kyari ní ara òun balè̩ àti pé òun kò ní ìrírí gbígbóná àti àwo̩n ohun àìléra mìíràn tó rò̩ mó̩ àrùn ò̩hún. +“Gege bi opolopo eniyan to je alarun korona, emi ko tii ni iriri igbonara tabi awon ohun ailera miiran to nii se pelu aarun Corona. “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó jé̩ alárùn kòrónà, èmi kò tíì ní ìrírí ìgbónára tàbí àwọn ohun àìléra mííràn tó níí ṣe pẹ̀lú ààrùn Corona. +Mo n se ise mi lati ile, mo si ni ireti pe maa tete pada senuuse. Mo ń ṣe iṣẹ́ mi láti ilé, mo sì ní ìrètí pé màá tètè padà sẹ́nuuṣ̣ẹ́. +Mo lawon odo , onimo, ologbon ati afifesise alabaasisepo , ti won si n sise lojo meje laarin ose , ti ko sojo kan fun isinmi. Mo láwọn ọ̀dọ́ , onímò̩, ọló̩gbó̩n àti afìfé̩s̩is̩é̩ alábàás̩is̩é̩pò̩ , tí wọ́n sì ń s̩iṣẹ́ lọ́jọ́ méje láàrín ọ̀sẹ̀ , tí kò sọjọ́ kan fún ìsinmi. +A o tun tesiwaju bi a ti n se lati bi odun marunun seyin lati maa sin aare ati awon eniyan orile ede Naijiria.” Kyari safikun. A ó tún tẹ̀síwájú bí a ti ń ṣe láti bí ọdún márùnún sẹ́yìn láti máa sin ààrẹ àti àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.” Kyari s̩àfikún. +Oro lati enu Oludari awon osise ti Aare, nipa ipo ilera re: Ò̩rò̩ láti e̩nu Olùdarí àwo̩n òs̩ìs̩é̩ ti Ààre̩, nípa ipò ìlera rè̩: +Ara re bale o si wapa– Lilo si Eko fun ayewo ati itoju si – “Mo ni awon alaboojuto temi nitori atile din wahala eto ilera ilu ku, ti won n koju ipenija.” Ara rè̩ balè̩ o sì wàpa– Lílo̩ sí Èkó fún àyè̩wò àti ìtó̩jú si – “Mo ní àwo̩n alábòójútó tèmi nítorí àtilè dín wàhálà èto ìlera ìlú kù, ti wó̩n ń kojú ìpèníjà.” +O tun dupe lowo awon osise eleto ilera to n sise jake-jado Naijiria, ti won n femi ara won wewu fun omo Naijiria gbogbo. O tun gbosuba fun omo Naijiria nitori itoju ti won fun alaini. Ó tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òṣ̣ìṣ̣ẹ́ elétò ìlera tó ń s̩is̩é̩ jákè-jádò Nàìjíríà, tí wọ́n ń fẹ̀mí ara wọn wéwu fún o̩mo̩ Nàìjíríà gbogbo. Ó tún gbós̩ùbà fun ọmọ Nàìjíríà nítorí ìtọ́jú tí wọn fun aláìní. +Kyari ro omo Naijiria fun suuru nigba igbaninimoran lori imototo ara, gbigba imoran rere latodo awon adari, kotiikun si awon iroyin oniro ati titele itosona ijinna-sira-eni. Kyari ro̩ o̩mo̩ Nàìjíríà fún sùúrù nígbà ìgbaninímò̩ràn lórí ìmó̩tótó ara, gbigba ìmò̩ràn rere látò̩dò̩ àwo̩n adarí, ko̩tíikún sí àwo̩n ìròyìn oníró̩ àti títèlé ìtó̩só̩nà ìjìnnà-síra-e̩ni. +--- COVID-19: Awon ti won sayewo fun to si ni aarun corona ni Naijiria ti di mokanlelaadofa (111) --- COVID-19: Àwọn tí wón s̩àyèwò fún tó sì ní ààrun corona ni Nàìjíríà ti di mọ́kànléláàdọ́fà (111) +Ile- ise to n gbogun ti ajakale aarun (NCDC) lorileede Naijiria ti kede pe awon merinla miiran ti ni aarun Corona (COVID-19) lorileede yii. Awon mesan an ni ipinle Eko ati marun un ni FCT, Abuja. Ilé- iṣẹ́ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ ààrùn (NCDC) lórílèèdè Nàìjíríà ti kéde pé àwọn mẹ́rìnlá mìíràn ti ní ààrùn Corona (COVID-19) lórílèèdè yìí. Àwọ̣n mẹ́sàn án ní ìpínlẹ̀ Èkó àti márùn ún ní FCT, Àbújá. +Lati aago mesan-an aabo, lojo kokandinlogbon, awon to ni aarun Corona ti di mokanlelaadofa, okan ku, sugbon ipinle Eko lo si n gbegba oroke bayii pelu alarun eniyan to je mejidinlaadorin. Láti aago mẹ́sàn-án ààbọ̀, lọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, àwọn tó ní ààrùn Corona ti di mọ́kànléláàdọ́fà, ò̩kán kú, s̩ùgbó̩n ìpínlẹ̀ Èkó ló sì ń gbégbá orókè báyìí pẹ̀lú alárùn ènìyàn tó jẹ́ méjìdínláàdọ́rín. +--- COVID-19:Aare Buhari pase pe ki won ti Eko, Ogun ati Abuja (FCT) pa --- COVID-19:Àar̀ẹ Buhari pàsẹ pé kí wọ́n ti Èkó, Ògùn àti Àbújá (FCT) pa +Lona ati dekun aarun Corona , ti a mo si COVID-19 , aare orile ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti pase pe ki o maa si wiwole tabi jijade yala awon eniyan tabi oko niluu Eko , Ogun ati Abuja. Lọ́nà àti dẹ́kun ààrùn Corona , tí a mọ̀ ṣí COVID-19 , ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti pàsẹ pé kí ó máa sì wíwọlé tàbí jíjáde yálà àwọn ènìyàn tàbí ọkọ̀ nílùú Èkó , Ògùn àti Àbújá. +Aare soro yii lasiko to n se igbohunsafefe, laasaale ojo Aiku, pe ofin wiwole tabi jijade yoo bere ni aago mokanla, ogboojo, osu keta, odun 2020. Ààrẹ sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń se ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, lááṣáálẹ́ ọjọ́ Àìkú, pé òfin wíwọlé tàbí jíjáde yóò bẹ̀rẹ̀ ní aago mọ́kànlá, ọgbọ̀ọjọ́, oṣù kẹta, ọdún 2020. +Nipa imoran lati odo awon ajo to n mojuto eto ilera ati ajo to n mojuto gbigbogun ti aarun lorile ede Naijiria, nitori naa mo pase, pe ko ni si wiwole tabi jijade niluu Eko, Ogun ati FCT Abuja fun odidi ojo merinla gbako bere lati aago mokanla, ogboojo, osu keta,odun 2020. Nípa ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ àwọn àjọ tó ń mójútó ètò ìlera àti àjọ tó ń mójútó gbígbógun ti ààrùn lórílẹ́ èdè Nàìjíríà, nítorí náà mo pàṣẹ, pé kó ní sí wíwọlé tàbí jíjáde nílùú Èkó, Ògùn àti FCT Àbújá fún odidi ọjọ́ mẹ́rìnlá gbáko bẹ̀rẹ̀ láti aago mọ́kànlá, ọgbọ̀ọjọ́, oṣù kẹta,ọdún 2020. +Ohun to faa ti ipinle Ogun ni pe ipinle naa sunmo ipinle Eko ati bi awon oko se po ni awon ipinle mejeeji naa. Ohun tó fàá ti ìpínlẹ̀ Ògùn ni pé ìpínlẹ̀ náà súnmọ́ ìpínlẹ̀ Èkó àti bí àwọn ọkọ̀ ṣe pọ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀ méjèèjì náà. +Gbogbo awon to wa ni awon ipinle wonyi gbodo wa ninu igbele. Ko ni si eto irinna lati ipinle kan si ekeji. Gbogbo àwọ̣n tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀ wọ̀nyí gbọ́dọ̀ wà nínú ìgbélé. Kò ní sí ètò ìrìnnà láti ìpínlẹ̀ kan ��í èkejì. +Gbogbo ile-ise ati ofiisi to wa ni awon agbegbe yii gbodo wa ni titi pa lasiko yii. Gbogbo ilé-iṣẹ́ àti ọ́fíísì tó wà ní àwọn agbègbè yìí gbọ́dọ̀ wà ní títì pa lásìkò yìí. +Aare Buhari ni awon gomina ipinle Eko, Ogun ati minisita ilu Abuja ti mo nipa igbele yii. Ààrẹ Buhari ní àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Ògùn àti mínísítà ìlú Àbújá ti mọ̣̀ nípa ìgbélé yìí. +Bakan naa, gbogbo awon adari ile-ise eleto aabo ati itopinipin ti mo nipa eto ohun. Bákan náà, gbogbo àwọn adarí ilé-iṣẹ́ elétò ààbò àti ìtọpinipin ti mọ̀ nípa ètò ọ̀hún. +Aare ni ijoba oun yoo lo asiko igbele ohun lati se itopinpin awon ti won ti salabaapade awon to ni aarun Korona naa. Ààrẹ ní ìjọba òun yóò lo àsìkò ìgbélé ọ̣̀hún láti ṣe ìtọpinpin àwọ̣n tí wọ́n ti ṣalábàápàdé àwọn tó ní ààrùn Korona náà. +Aare ni ofin naa ko mu awon ile-iwosan ati awon eleto ilera ati ile-ise epo ati pin egboogi oyinbo. Ààrẹ ní òfin náà kò mú àwọn ilé-ìwòsàn àti àwọn elétò ìlera àti ilé-iṣẹ́ epo àti pín egbòogi òyìnbó. +Bakan naa, gbogbo awon ile-ise to n pese ati awon to n ta ounje, ile-epo robi ati ile-ise to n ta epo oko ayokele, ile-ise mona-mona ati ile-ise aladaani alamoojuto eto aabo. Bákan náà, gbogbo àwọn ilé-iṣẹ́ tó ń pèṣè àti àwọn tó ń ta ouńjẹ, ilé-epo rọ̀bì àti ilé-iṣẹ́ tó ń ta epo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ilé-iṣẹ́ mọ̀nà-mọ́ná àti ilé-iṣẹ́ aládàáni alámòójútó ètò ààbò. +Aare ni bo tile je pe ofin eto igbele ko mu awon ile-ise wonyi sibe eto yoo wa nipa ibi ti won lee lo. Ààrẹ ní bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin ètò ìgbélé kò mú àwọn ilé-iṣẹ́ wọ̀nyí síbẹ̀ ètò yóò wà nípa ibi tí wọn leè lọ. +Awon osise ile-ise to n mojuto ero ibaraeni-soro ati ipe, ile-ise iroyin yala redio, mohun-maworan tabi lori ero ayelujara ti ko ba lee se ise lati ile re, ni won yoo gba laaye lati rin, sugbon irufe awon eniyan bayii gbodo lee fi kaadi idanimo won han. Àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó ẹ̀rọ ìbáraẹni-sọ̀rọ̀ àti ìpè, ilé-iṣẹ́ ìròyìn yálà rédíò, móhùn-máwòrán tábi lórí ẹ̀rọ ayélujára tí kò bá leè ṣe iṣẹ́ láti ilé rẹ̀, ni wọn yóò gbà láàyè láti rìn, sùgbọ́n irúfẹ́ àwọn ènìyàn báyìí gbọdọ̀ leè fi káàdì ìdánimọ̀ wọn hàn. +--- Ogota ojo lepo le de -NNPC --- O̩gọ́ta ọjọ́ lepo lè dé -NNPC +Ile–ise a-tepo-robi lorileede Naijiria (NNPC) ti ro awon omo Naijiria lati maa se beru nipa rira epo ayokele, nitori pe ile-ise naa ni epo ti Naijiria lee lo fun osu meji gbako. Ilé–iṣẹ́ a-tepo-rọ̀bì lórílẹ̀èdè Nàìjíríà (NNPC) ti rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti máa ṣe bẹ̀rù nípa ríra epo ayọ́kẹ́lẹ́, nítorí pé ilé-iṣẹ́ náà ni epo tí Nàìjíríà leè lò fún oṣù méjì gbáko. +Ogbeni Mele Kyari, to je alaakoso ile –ise ohun, lo so oro idaniloju lasiko to ba awon akoroyin soro lojo Aiku, niluu Abuja. Ọ̀gbẹ́ni Mele Kyari, tó jẹ́ aláákóso ilé –iṣẹ́ ọ̀hún, ló sọ ọ̀rọ̀ ìdánilójú lásìkò tó bá àwon akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Àìkú, nílùú Àbújá. +Kyari wa ro gbogbo omo orile ede Naijiria lati yago fun tito lesese nile- itaja epo, bi omiyale. Kyari wá rọ̣ gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti yàgò fún títò lẹ́sẹsẹ nílé- ìtajà epo, bí omíyalé. +O ni: “ko si aini nibi Kankan; oja wa kun, a ni epo ti yoo to orileede fun osu meji lai repo. Ó ní: “kò sí àìní níbì Kankan; o̩ja wa kún, a ní epo tí yóò tó orílèèdè fún os̩ù méjì láì repo. +“Loooto, eyin eniyan, nitori itankale aarun, a duro sile, e le gbiyanju lati se epo ku, e ko nilo lati se eyi. “Lóòótó̩, è̩yin ènìyàn, nítorí ìtànkálè̩ ààrùn, a dúró sílé, e lè gbìyànjú láti s̩e epo kù, e kò nílò láti s̩e èyí. +O ro awon omo Naijiria lati ma bo ile-epo gbogbo nitori ko si idi fun eyi. Ó ro̩ àwo̩n o̩mo̩ Nàìjíríà láti má bo ilé-epo gbogbo nítorí kò sí ìdí fún èyí. +Sisoro lori ase NARTO fun awon oloko agbepo ki won kuro niso won, Kyari ni ile-ise ohun a tunbo maa ran won kaakiri. Sísò̩rò̩ lóri às̩e̩ NARTO fún àwo̩n oló̩kò̩ agbépo kí wó̩n kúrò nísò̩ wo̩n, Kyari ní ilé-is̩é̩ ò̩hún a túnbò̩ máa rán wó̩n káàkiri. +"O tesiwaju pe, ""Bi a se n soro bayii, ko si idiwo fun awon awako epo oko ayokele, nitori pe won ri epo won gba deede, ko si ninu erongba ile –ise, lati da ise duro""." "Ó tè̩síwájú pé, ""Bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ báyìí, kò sí ìdíwọ́ fún àwọn awakọ̀ epo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, nítorí pé wọ́n rí epo wọn gbà déédé, kò sí nínú èròǹgbà ilé –iṣẹ́, láti dá iṣẹ́ dúró""." +--- Aare Buhari yoo ba Naijiria soro ni Sunnde --- Ààre̩ Buhari yóò bá Nàìjíríà sò̩rò̩ ní Súńńdè +Aare Muhammadu Buhari yoo ba omo Naijiria soro lonii Sunnde, March 29 ni aago meje ale. Ààre̩ Muhammadu Buhari yóò bá o̩mo̩ Nàìjíríà sò̩rò̩ lónìí Súnńdè, March 29 ní aago méje alé̩. +Olugbanimoran si Aare orileede Naijiria ti Iroyin ati ipolongo, Femi Adesina so eyi ninu oro re. Olùgbanímò̩ràn sí Ààre̩ orílèèdè Nàìjíríà ti Ìròyìn àti ìpolongo, Fé̩mi Adés̩ìnà so̩ èyí nínú ò̩rò̩ rè̩. +O gba awon ile-ise telifisan, ati ile-ise redio pelu ona isoroyin miiran niyanju lati darapo mo Ile-ise Telifisan akoko (NTA) ati Ile-ise Redio Apapo ti Naijiria (FRCN) fun oro Aare ohun. O gba àwo̩n ilé-is̩é̩ telifís̩àn, àti ilé-is̩é̩ rédíò pè̩lú ò̩nà ìsò̩rò̩yìn mìíràn níyànjú láti darapò̩ mó̩ Ilé-is̩é̩ Telifís̩àn àkó̩kó̩ (NTA) àti Ilé-is̩é̩ Rédíò Àpapò̩ ti Nàìjíríà (FRCN) fún ò̩rò̩ Ààre̩ ò̩hún. +Ohun Naijiria yoo maa ja geere ni aaye lori ero Twitter wa @voiceofnigeria. Ohun Nàìjíríà yóò máa já geere ní ààyè lóri è̩ro̩ Twitter wa @voiceofnigeria. +--- COVID-19: Gomina Ekiti pase igbele, ti gbogbo enuubode --- COVID-19: Gómìnà Èkìtì pàsẹ ìgbélé, ti gbogbo e̩nuubodè +Gomina Kayode Fayemi ti kede lojo Aiku pe won yoo ti ipinle Ekiti pa, ki o le dekun itankale aarun Korona. Gómìnà Káyòdé Fáyemí ti kéde lọ́jọ́ Àìkú pé wọ̣n yóò ti ìpínlẹ̀ Èkìtì pa, kí ó le dẹ́kun ìtànkalẹ̀ ààrun Korona. +Gomina ninu oro re, pase ki gbogbo okowo gbogbo duro gboin bakan naa ni ti irinajo yoowu, afi awon to n lokiri nitori oja pataki. Gómìnà nínú ò̩rò̩ rè̩, pàs̩e̩ kí gbogbo okòwò gbogbo dúró gbo̩in bákan náà ni ti ìrìnàjò yòówù, àfi àwo̩n tó ń lokiri nítorí o̩jà pàtàkì. +O ni eni ti o ba tapa si ofin tuntun ohun ti o wa lati dekun itankale korona ni ipinle naa yoo fewon osu mefa jura. Ó ní eni tí ó bá tàpá ṣi òfin tuntun ọ̀hún tí ó wà láti dé̩kun ìtànkálè̩ kòrónà ní ìpínlè̩ náà yóò fẹ̀wọ̀n oṣ̣ù mẹ́fà júra. +Gomina faidunnu re han sawon igbese isaaju lati kapa aarun yii sugbon awon eniyan mo-on-on keti ikun si. Gómìnà fàìdùnnú rè̩ hàn sáwo̩n ìgbésè̩ ìs̩áájú láti kápá ààrùn yìí s̩ùgbó̩n àwo̩n ènìyàn mò̩-ó̩n-ò̩n ketí ikún si. +O ni: “o seni laaanu gidgidi pe isesi awon kan tutu, ai-kobi-ara-si tabi fifoju tembelu pipa awon ilana ti o rorun amo to koju osunwon kikapa korona ati ijinna si ara eni lawujo lati le daabobo ara won ati se adinku itankale arun naa ni awon igberiko won.” O ní: “ó s̩eni láàánú gidgidi pé ìs̩esí àwo̩n kan tutu, àì-kobi-ara-si tàbí fífojú té̩ḿbé̩lú pípa àwo̩n ìlànà tí ó ro̩rùn àmó̩ tó kójú òs̩ùnwò̩n kíkápá kòrónà àti ìjìnnà sí ara e̩ni láwùjo̩ láti lè dáàbòbò ara wo̩n àti s̩e àdínkù ìtànkálè̩ àrùn náà ní àwo̩n ìgbéríkó wo̩n.” +“Bi mo se mo riri ifayaran wa, ireti ti o le ye ati idurosinsin ninu emi gege bi eniyan, o se pataki ka dogba eyi pelu ironu ati igbese kiakia to le daabobo emi ebi ati igberiko wa. “Bí mo s̩e mo̩ rírí ìfàyàrán wa, ìrètí tí ò le ye̩ àti ìdúrós̩ins̩in nínú è̩mí gé̩gé̩ bi ènìyàn, ó s̩e pàtàkì ká dó̩gba èyí pè̩lú ìrònú àti ìgbésè̩ kíákíá tó lè dáàbòbò è̩mí e̩bí àti ìgbéríko wa. +”Ta o ba gbegbeese to ye lati dekun aarun yii, o seese ko bori ile-ise eto ilera wa, seto oro aje wa nijamba, ki o si ijamba pupo ba Ekiti. ”Tá ò bá gbégbèésẹ̀ tó ye̩ láti dẹ́kun ààrùn yìí, ó s̩eés̩e kó borí ilé-iṣẹ́ ètò ìlera wa, ṣètò ọrọ̀ ajé wa níjàm̀bá, kí ó sì ìjàm̀bá púpọ̀ bá Èkìtì. +“Gege bi a se mo, ipo ti ipinle yii wa ko dara nitori owo po lapo ilu, eyi ti ipa aarun korona ko nibe ati si oro aje lagbaaye pelu owo epo robi to ti lole gan-an. “Gé̩gé̩ bí a s̩e mo̩, ipò tí ìpínlè̩ yìí wa kò dára nítorí owó pò̩ lápò ìlú, èyí ti ipa ààrùn kòrónà kó níbè̩ àti sí o̩rò̩ ajé lágbàáyé pè̩lú owó epo rò̩bì tó ti lo̩lè̩ gan-an. +“Nitori naa, a ko le faaye ailera lawujo. “Nítorí náà, a kò le fààyè àìléra láwùjo̩. +“Idi niyi ti o je akiyesi pataki lawujo pe, nipase oju ewe 8 ti ise isenimole, ofin ijoba apapo Naijiria, odun 2004 ati iwe ofin ijoba apapo ti Naijiria, odun 1999 (pelu atunse) so igbele lairi eniyan kan ti o n rinkiri di kannpa ni ipinle Ekiti. “Ìdí nìyí tí ó jé̩ àkíyèsí pàtàkì láwùjo̩ pé, nípasè̩ ojú ewé 8 ti ìs̩e ìsénimó̩lé, ofin ìjo̩ba àpapò̩ Nàìjíríà, o̩dún 2004 àti ìwé òfin ìjo̩ba àpapò̩ ti Nàìjíríà, o̩dún 1999 (pè̩lú àtúns̩e) so̩ ìgbélé láìrí ènìyàn kan tí ó ń rìnkiri di kànńpá ní ìpínlè̩ Èkìtì. +“Idi fun igbele naa ni lati dekun bi won yoo se maa ko awon eniyan ati eru laarin ipinle ohun fun odidi ojo merinla gbako. “Ìdí f��n ìgbélé náà ni láti dẹ́kun bí wọn yóò ṣe máa kó àwọn ènìyàn àti ẹrù láàrín ìpínlẹ̀ ọ̀hún fún odidi ọjọ́ mẹ́rìnlá gbáko. +“Nitori naa, lati 1:59pm losan-an lojo Aje, March 30, 2020 de 11:59pm lale lojo Aje, April 13, 2020, eniyan kankan ko gbodo rinkiri ni Ekiti, ki gbogbo enuubode naa si wa ni titi pa. “Nítorí náà, láti 1:59pm ló̩sàn-án lọ́jọ́ Ajé, March 30, 2020 dé 11:59pm lálé̩ lójọ́ Ajé, April 13, 2020, ènìyàn kankan kò gbọdọ̀ rìnkiri ní Èkìtì, kí gbogbo e̩nuubodè náà ṣì wà ní títì pa. +“Eyi ni isemole patapata ni ipinle Ekiti, ati igbele fun wakati mejila lati aago meje ale titi di aago meje owuro. “Èyí ni ìsémó̩lé pátápátá ní ìpínlè̩ Èkìtì, àti ìgbélé fún wákàtí méjìlá láti aago méje alẹ́ titi di aago méje òwúrọ̀. +Gbogbo omo ipinle Ekiti ni a ro lati duro sile won. Gbogbo o̩mo̩ ìpínlè̩ Èkìtì ní a rò̩ láti dúró sílé wo̩n. +“A n samulo ise isenimole lati daabobo gbogbo omo ilu Ekiti. Nitori naa, e je so ko ye yekeyeke. “À ń s̩àmúlò ìs̩e ìsénimó̩lé láti dáàbòbò gbogbo o̩mo̩ ìlú Èkìtì. Nítorí náà, e̩ jé̩ só̩ kó yé yékéyéké. +Ti o ko ba lo tabi duro sile fun ojo merinla bere lojo aje, 30 March, 2020, o le sanwo itanran repete tabi fewon jura. Tí o kò bá lo̩ tàbí dúró sílé fún o̩jó̩ mé̩rìnlá bè̩rè̩ ló̩jó̩ ajé, 30 March, 2020, o lè sanwó ìtanràn re̩pe̩te̩ tàbí fè̩wò̩n júra. +O ni, “Lasiko igbele ohun, lilo si ijoba ibilesibiile, ilusiilu, ileto si leto ti di eewo ni ipinle Ekiti; Bakan naa, gbogbo awon to ba wa ni ipinle Ekiti lasiko igba naa, ni eto igbele naa mu.” Ó ní, “Lásìkò ìgbélé ọ̀hún, lílọ sí ìjọba ìbílẹ̀síbìílẹ̀, ìlúsíìlú, ìletò sí letò ti di èèwọ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkìtì; Bákan náà, gbogbo àwọn tó bá wà ní ìpínlẹ̀ Èkìtì lásìkò ìgbà náà, ni ètò ìgbélé náà mú.” +O tun so pe gbogbo ile-ise ni ko wa ni titi pa, ayafi awon to ba n se ise to niise pelu emi awon eniyan. Ó tún sọ pé gbogbo ilé-iṣẹ́ ni kó wà ní títì pa, àyàfi àwọn tó bá ń ṣe isẹ́ tó nííṣe pẹ̀lú ẹ̀mí àwọn ènìyàn. +Awon oja, ile –itaja nla ati kekere lo gbodo wa ni titipa ayafi ibi i-ta-oja-pataki, won si gbodo wa ni imototo kaarun COVID-19 ma tan mo awon eniyan. Àwọn ọjà, ilé –ìtajà ńlá àti kékeré ló gbọ́dọ̀ wà ní títìpa àyàfi ibi ì-ta-o̩jà-pàtàkì, wọ́n sì gbọdọ̀ wà ní ìmọ́tótó káàrùn COVID-19 má tàn mó̩ àwo̩n ènìyàn. +Gbogbo ile ijosin, bi i ibi adura oun iyin, iso-oru, idapo ojule, ati ipade NASFAT; apejopo eniyan bii ayeye oku, igbeyawo, ipade ebi ati ile-ijo, ile-oti, ipade oselu, iwode, ipade egbe woodu ati awon ipade ati eto ayeye lorisiriisi ni o ti di eewo bayii pelu eto ilana yii. Gbogbo ilé ìjọ́sìn, bí i ibi àdúrà òun ìyìn, ìsọ́-òru, ìdàpò̩ ojúlé, àti ìpàdé NASFAT; àpéjo̩pò̩ ènìyàn bíi ayẹyẹ okú, ìgbéyàwó, ìpàdé ẹbí àti ilé-ijó, ilé-ọtí, ìpàdé òṣèlú, ìwọ́de, ìpàdé ẹgbẹ́ wọ́ọ̀dù àti àwọn ìpàdé àti ètò ayẹyẹ lóríṣiríísi ni ó ti di èèwọ̀ báyìí pẹ̀lú ètò ìlànà yìí. +Ipejopo bii isinku nikan ni a o gba laaye, sugbon ipejopo naa ko gbodo ju eniyan ogun lo, ko gbodo si iso-oru tabi ayeye. Ìpéjopọ̀ bíi ìsìnkú nìkan ni a ò gbà láàyè, sùgbọ́n ìpéjọpọ̀ náà kò gbọdọ̀ ju ènìyàn ogún lọ, kò gbọdọ̀ sí ìṣọ́-òru tàbí ayẹyẹ. +Gbogbo enubode Ekiti ni yoo wa ni titipa lasiko yii ayafi awako epo robi, awon olounje, egboogi oyinbo atawon oja asepataki. Gbogbo enubodè Èkìtì ni yóò wà ní títìpa lásìkò yìí àyàfi awakọ̀ epo rọ̀bì, àwọn olóúnjẹ, egbòogi òyìnbó àtàwọn ọjà aṣepàtàkì. +Gbogbo awon ti kii se omo ipinle Ekiti sugbon ti won de si ipinle naa lasiko tabi leyin ofin igbele naa gbodo wa nibi ti won n gbe ni ipinle ohun fun ojo merinla ikede naa, won yoo si tun sayewo aarun COVID-19, bakan naa ni won yoo tun wa ni igbele, ti o ba je dandan fun won. Gbogbo àwọn tí kìí ṣe ọmọ ìpínlẹ̀ Èkìtì sùgbọ́n tí wọ́n dé sí ìpínlẹ̀ náà lásìkò tàbí lẹ́yìn òfin ìgbélé náà gbọdọ̀ wà níbi tí wọ́n ń gbé ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún fún ọjọ́ mẹ́rìnlá ìkéde náà, wọn yóò sì tún ṣàyẹ̀wò ààrùn COVID-19, bákan náà ní wọn yóò tún wà ní ìgbélé, tí ó bá jẹ́ dandan fún wọn. +“Gbogbo awon awako bii boosi, ayokele, okada ati keke maruwa, ni ko gbodo sise; afi awon ti o n jade nitori isee kosemase, yi won n gba eru pataki, wiwa itoju, ayeye oku ati gbigba owo iranwo fun ounje abi ohun miiran. “Gbogbo àwo̩n awakò̩ bíi bó̩ò̩sì, ayó̩ké̩lé, ò̩kadà àti kè̩ké̩ márúwá, ni kò gbo̩dò̩ s̩is̩é̩; àfi àwo̩n tí ó ń jáde nítorí is̩é̩e̩ kò̩s̩émás̩e, yí wó̩n ń gb�� e̩rù pàtàkì, wíwá ìtó̩jú, aye̩ye̩ òkú àti gbígba owó ìrànwó̩ fun oúnje̩ àbí ohun mìíràn. +Awon to ba n se ise pataki ni won yoo fun laye lati maa lokiri, paapaa julo awon osise eto ilera, sugbon olori ile-ise won gbodo fun won ni kaadi idanimo. Àwo̩n tó bá ń s̩e is̩é̩ pàtàkì ní wo̩n yóò fún láyè látì máa lokiri, pàápàá jùlo̩ àwo̩n òs̩ìs̩é̩ ètò ìlera, s̩ùgbó̩n olóri ilé-is̩é̩ wo̩n gbo̩dò̩ fún wo̩n ní káàdì ìdánimò̩. +Fayemi salaye pe awon tofin igbele o mu ko ju awon eniyan kookan atile-ise to n pese ohun pataki: Fáye̩mí s̩àlàyé pé àwo̩n tófin ìgbélé ò mú kò ju àwo̩n ènìyàn kò̩ò̩kan àtilé-is̩é̩ tó ń pèsè ohun pàtàkì: +Awon ni omo ile – igbimo asoju, ijoba ipinle ati ile-ejo. Àwọn ni ọmọ ilé – ìgbìmọ̀ aṣojú, ìjọba ìpínlẹ̀ àti ilé-ẹjọ́. +Awon miiran ni oluse, olupin ati oluta ounje ati ohun mimu, ile-itaja egboogi oyinbo, ile –itawe ati abo, alamojuto ayika ati imototo, osise mona-mona, omi, ile-ibara-eni-soro, ile-ise ontaja lori ero ayelujara atawon olupese ero ayelujara. Àwọn mìíràn ni olùs̩e, olùpín àti olùta ouńjẹ àti ohun mímu, ilé-ìtajà egbòogi òyìnbó, ilé –ìtàwé àti abọ́, alámòjútó àyíká àti ìmọ́tótó, òṣìṣẹ́ mọ̀nà-mọ́ná, omi, ilé-ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀, ilé-iṣẹ́ òǹtajà lóri ẹ̀rọ ayélujára àtàwọn olùpèsè ẹ̀rọ ayélujára. +Awon miiran ni osise eleto aabo ti won gbese fun, osise awon ile-ifowopamo, eyi ti o jo o ati osise awon ile-epo robi. Àwọn mìíràn ní òṣìṣẹ́ elétò ààbò tí wó̩n gbés̩é̩ fún, òṣìṣẹ́ àwo̩n ilé-ìfowópamọ́, èyí tí ó jo̩ ó̩ àti òṣìṣẹ́ àwo̩n ilé-epo rọ̀bì. +Gomina ni, “eni to ba rufin yii yoo jebi esun naa, nigba ti won ba si dalebi, o le sanwo itanran tabi lo ewon ti o to osu mefa tabi sanwo itanran ko si lo ewon bakan naa”. Gómìnà ní, “e̩ni tó bá rúfin yìí yóò jè̩bi è̩sun náà, nígbà tí wó̩n bà sì dalé̩bi, ó lè sanwó ìtanràn tàbí lo̩ è̩wò̩n tí ò tó os̩ù mé̩fà tàbí sanwó ìtanràn kó sì lo̩ è̩wò̩n bákan náà”. +Fayemi, ni oun mo pe igbese yii yoo mu inira dani fun okowo ati molebi, o si ni ohun iranwo n lo lowo fun awon omo ipinle Ekiti, paapaa julo awon abarapa. Fáyemí, ní òun mọ̀ pé ìgbésẹ̀ yìí yóò mú ìníra dání fún okòwò àti mò̩lé̩bí, ó sì ní ohun ìrànwó ń lo̩ ló̩wó̩ fún àwo̩n ọ̣mọ ìpínlẹ̀ Èkìtì, pàápàá jùlọ àwọn abarapá. +--- COVID-19: Metadinlogorun lalarun korona di ni Naijiria --- COVID-19: Mé̩tàdínló̩gò̩rún lálàrún kòrónà dì ní Nàìjíríà +O ti di eniyan metadinlogorun to ti ni aarun Corona bayii ni Naijiria. Ó ti di ènìyàn mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn tó ti ní ààrùn Corona báyìí ní Nàìjíríà. +Ajo agbogunti aarun lo kede awon mejo to tun sese jeyo pe “ni deede 10:40am loooro, 28th, March lawon alarun Korona lorile ede yii ti di metadinlogorun, okan si ti ku. Àjọ agbógunti ààrùn ló kéde àwọn mẹ́jọ tó tún ṣ̣ẹ̀ṣẹ̀ jẹyọ pé “ní déédé 10:40am lóòórò̩, 28th, March làwọn àlárùn Korona lórílẹ̀ èdè yìí ti di mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn, ò̩kan sì ti kú. +“Bayii; Eko- 59, FCT - 16 Ogun- 3 Enugu- 2 Ekiti- 1 Oyo- 7 Edo- 2 Bauchi- 2 Osun-2 Rivers-1 Benue- 1 Kaduna- 1” “Báyìí; Èkó- 59, FCT - 16 Ògùn- 3 Enugu- 2 Èkìtì- 1 Oyo- 7 Edo- 2 Bauchi- 2 Òṣun-2 Rivers-1 Benue- 1 Kaduna- 1” +Awon alarun korona mejo tun ti jeyo lorile ede Naijiria; 2 ni FCT, 4 ni Oyo, 1 ni Kaduna ati 1 ni ipinle Osun Àwo̩n alárùn kòrónà mé̩jo̩ tún ti je̩yo̩ lórílè̩ èdè Nàìjíríà; 2 ní FCT, 4 ní Ò̩yó̩, 1 ní Kàdúná àti 1 ní ìpínlè̩ Ò̩s̩un +Ni deede 10:40am loooro, 28th, March lawon alarun Korona lorile ede yii ti di metadinlogorun, okan si ti ku. Ní déédé 10:40am lóòórò̩, 28th, March làwọn àlárùn Korona lórílẹ̀ èdè yìí ti di mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn, ò̩kan sì ti kú. +--- COVID-19: Aare Naijiria pase titi papa oko ofurufu ati enuubode --- COVID-19: Ààrẹ Nàìjíríà pàs̩e̩ títi pápá o̩kò̩ òfurufú àti e̩nuubodè +Lati dekun itankale aarun asekupani korona, aare orile ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti pase titi papa oko ofurufu ile okeere ni Naijiria ati enuubode ni kiakia fun ose merin gbako. Láti dẹ́kun ìtànkálè̩ ààrùn as̩ekúpani kòrónà, ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti pàṣẹ títi pápá ọkọ̀ òfurufú ilẹ̀ òkèèrè ní Nàìjíríà àti e̩nuubodè ní kíákíá fún ọ̀sẹ̀ mẹ́rin gbáko. +Aare so eyi lori Twitter re @MBuhari lale ojobo, o ni igbese naa wa lati ran ijoba lowo nipa fifi gbogbo ilana to ye, igbese lolokan-o-jokan, ohun amayederun lati le kapa alarun afunrasi ati eyi ti a ti sawari ni ile, lai mu buru si i pelu eyi to n tokeere wa. Ààrẹ so̩ èyí lórí Twitter rẹ @MBuhari lálé̩ o̩jó̩bò̩, ó ní ìgbésè̩ náà wà láti ran ìjo̩ba ló̩wó̩ nípa fífi gbogbo ìlànà tó ye̩, ìgbésè̩ ló̩ló̩kan-ò-jò̩kan, ohun amáyéde̩rùn láti lè kápá alárùn afunrasí àti èyí tí a ti s̩àwárí ní ilé, láì mu burú sí i pè̩lú èyí tó ń tòkèèrè wá. +Aare faidunnu han si inira ti titi papa oko ofurufu ati enuubode ti fun awon omo Naijiria to fe wale, o si fi kun un pe “o pondandan fun anfaani wa, mo dupe fun ifowosowopo ati igboniye gbogbo yin. Ààrẹ fàìdùnnú hàn sí ìnira tí títí pápá ọkọ̀ òfúrufú àti e̩nuubodè ti fún àwọn ọmọ Nàìjíríà tó fé̩ wálé, ó sì fi kún un pé “ó pondandan fún àǹfààní wa, mo dúpé̩ fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìgbó̩niye gbogbo yín. +Mo ti pase pe oko oju –omi eleru, olojo merinla o le, lori okun nikan, ni yoo de si ibudoko won, leyin ti ajo eleto ilera tolomi ba ti sayewo fun iko ohun ti won si rariidaju pe won o larun. Mo ti pàṣẹ pé ọkọ̀ ojú –omi e̩lé̩rù, o̩ló̩jó̩ mé̩rìnlá ó lé, lórí òkun nìkan, ni yóò dé sí ibùdókò wo̩n, lẹ́yìn tí àjọ elétò ìlera tolómi bá ti ṣàyẹ̀wò fún ikò̩ ọ̀hún tí wó̩n sì rárìídájú pé wo̩n ò lárùn. +O salaye pe, “igbele ojo - merinla yii ko nii se pelu awon to n gbe epo robi ati afefe gaasi niwon ti ifarakinra pelu eniyan kere. Ó s̩àlàyé pé, “ìgbélé o̩jó̩ - mé̩rìnlá yìí kò níí s̩e pè̩lú àwo̩n tó ń gbé epo rò̩bì àti afé̩fé̩ gáàsì níwò̩n tí ìfarakínra pè̩lú ènìyàn kéré. +Aare Buhari tun da ilokiri oko oju-irin duro lati le se adinku itankale aarun naa si eya ti o ku ni orile-ede. Ààrẹ Buhari tún dá ìlo̩kiri ọkọ̀ ojú-irin dúró láti lè s̩e àdínkù ìtànkálè̩ ààrùn náà sí è̩yà tí ó kù ní orílè̩-èdè. +Owo iranwo – Aare Buhari tun pase ki won yonnda owo iranwo bilionu mewaa naira fun ipinle Eko, nitori ibe ni ibudo itankale Korona ni Naijiria, gege bi o se so. Owó ìrànwọ́ – Ààre̩ Buhari tún pàṣẹ kí wọ́n yò̩nǹda owó ìrànwó̩ bílíọ̣́nù mẹ́wàá náírà fún ìpínlè̩ Èkó, nítorí ibè̩ ni ibùdó ìtànkálè̩ Kòrónà ní Nàìjíríà, gé̩gé̩ bí ó s̩e so̩. +Owo iranro yii maa mu Eko laaye si lati kapa ati dena itankale, yoo si tun ranpinle yooku lowo nipa kikole gbigbooro, o salaye. Owó ìrànró̩ yìí máa mú Èkó láàyè sí láti kápá àti dènà ìtànkálè̩, yóò sì tún ránpìnlé̩ yòókù ló̩wó̩ nípa kíkó̩lé gbígbóòrò, ó s̩àlàyé. +Aare tun wa pa ase yiyonda bilionu marun-un owo iranwo ti won ya soto fun ajo amojuto itankale aarun (NCDC) fun rira irinse, imugbooro ati wiwa kun awon osise si ile-ise ati awon ibi-ayewo wo jakejado orile-ede. Ààrẹ tún wá pa às̩ẹ yíyó̩ǹda bílíọ́nù márùn-ùn owó ìrànwó̩ tí wó̩n ya só̩tò̩ fún àjo̩ amójúto ìtànkálè̩ ààrun (NCDC) fún ríra irinsẹ́, ìmúgbòòrò àti wíwá kún àwo̩n òs̩ìs̩é̩ sí ilé-is̩é̩ àti àwo̩n ibi-àyè̩wò wo jákèjádò orílè̩-èdè. +“Mo ti pase ki NCDC pe gbogbo osise feyinti laipe pada si enuuse lati le kin awon osise wa lowo ni ifesi si itankale naa”. “Mo ti pàs̩e̩ kí NCDC pé gbogbo òs̩ìs̩é̩ fè̩yìntì láìpé̩ padà sí e̩nuus̩é̩ láti lè kín àwo̩n òs̩ìs̩é̩ wa ló̩wó̩ ní ìfèsì sí ìtànkálè̩ náà”. +Siwaju si i, gbogbo awon osise NCDC to wa lenu ikose ati lenu ise loke okun pada wa sile ni kiakia. Síwájú sí i, gbogbo àwo̩n òs̩ìs̩é̩ NCDC tó wà lé̩nu ìkó̩s̩é̩ àti lé̩nu is̩é̩ lókè òkun padà wá sílé ní kíákíá. +Fun ijafafa ninu ise yii, aare Naijiria ni iko ofurufu ologun ti Naijiria (NAF) ti n seto awon oko won fun iko aare amojuto korona, lati le samulo kaakiri orile-ede fun amojuto to ye kooro. Fún ìjáfáfá nínú is̩é̩ yìí, ààre̩ Nàìjíríà ní ikò̩ òfurufú ológun ti Nàìjíríà (NAF) ti ń s̩ètò àwo̩n o̩kò̩ wo̩n fún ikò̩ ààre̩ amójútó kòrónà, láti lè s̩àmúlò káàkiri orílè̩-èdè fún àmójútó tó yè kooro. +“Lowolowo, iko ofurufu ologun Naijiria (NAF) n gbegbeese lati ko awon onimo ijinle wa to wa ni Central Africa wale, lati fowo kun eto to n lo lowolowo”, o fikun-un. “Ló̩wó̩ló̩wó̩, ikò̩ òfurufú ológùn Nàìjíríà (NAF) ń gbégbèésè̩ láti kó àwo̩n onímò̩ ìjìnlè̩ wa tó wà ní Central Africa wálé, láti fo̩wó̩ kún ètò tó ń lo̩ ló̩wó̩ló̩wó̩”, ó fikún-un. +Eto inawo – “O gboriyin fun awon eka to n mojuto owo fun iranlowo ti won se fun awon ile-ise aladaani ”ni iru akoko lile yii”. Ètò ìnáwó – “Ó gbóríyìn fún àwo̩n è̩ka tó ń mójútó owó fún ìrànló̩wó̩ tí wó̩n s̩e fún àwo̩n ilé-is̩é̩ aládàáni ”ní irú àkókò líle yìí”. +Aare ni ijoba yoo wa ona lati pese owo itura fun araalu lati le din ipa buburu ti ajakale yii se ni igbe-aye ogunlogo omo orile-ede Naijiria. Ààre̩ ní ìjo̩ba y��ò wá ò̩nà láti pèsè owó ìtura fún aráàlú láti lè dín ipa búburú tí àjàkálè̩ yìí s̩e ní ìgbé-ayé ogunló̩gò̩ o̩mo̩ orílè̩-èdè Nàìjíríà. +Gege bi e se mo pe igbese lori atunyewo eto isunna lorileede ti bere. E maa gbabo ona abayo gbara ti atunyewo eto isunna ba ti pari. Gé̩gé̩ bí e̩ s̩e mò pé ìgbésè̩ lórí àtúnyè̩wò ètò ìsúnná lóríléèdè ti bè̩rè̩. E̩ máa gbàbò̩ ò̩nà àbáyo̩ gbàrà tí àtúnyè̩wò ètò ìsúnná bá ti parí. +Ni akoko yii, mo ti pase fun Minisita alaboojuto ile-ise isowo ati idokowo, lati sise pelu egbe oluse-ohun-tita ti Naijiria (MAN), lati ri i daju pe pipese ohun pataki bi i ounje, oniruuru oogun n tesiwaju lai si idiwo. Ní àkókò yìí, mo ti pàs̩e̩ fún Mínísítà alábòójútó ilé-is̩é̩ ìs̩òwò àti ìdókòwò, láti s̩is̩é̩ pè̩lú e̩gbé̩ olùs̩e-ohun-títà ti Nàìjíríà (MAN), láti rí i dájú pé pípèsè ohun pàtàkì bí i oúnje̩, onírúurú òògùn ń tè̩síwájú láì sí ìdíwó̩. +Imo ati atileyin – Aare Buhari so pe ijoba oun ti n takuroso pelu ore ati alabaase okeere lati pin imo ati gbigba iranwo won lori itankale aarun yii. Ìmò̩ àti àtile̩yìn – Ààre̩ Buhari so̩ pé ìjo̩ba òun ti ń tàkurò̩so̩ pè̩lú ò̩ré̩ àti alábàás̩e òkèèrè láti pín ìmò̩ àti gbígba ìrànwó wo̩n lórí ìtànkálè̩ ààrùn yìí. +“A moyi yin lori atileyin ti a ti ri gba bayii – A ti n gba awon eru kookan ti o wa fun riran igbiyanju wa lowo”. “A mo̩yì yín lórí àtìle̩yìn tí a ti rí gbà báyìí – A ti ń gba àwo̩n e̩rù kò̩ò̩kan tí ó wà fún ríran ìgbìyànjú wa ló̩wó̩”. +“E je n fi towotowo dupe pelu gbigboriyin fun ise akoni oun ribiribi ti osise ilera, NCDC, osise ilera olomi, ajo eleto aabo, ijoba ipinle, ati gbogbo osise ara pelu osise ofe ti se”. “E̩ jé̩ n fi tò̩wò̩tò̩wò̩ dúpé̩ pè̩lú gbígbóríyìn fún is̩é̩ ako̩ni òun ribiribi tí òs̩ìs̩é̩ ìlera, NCDC, òs̩ìs̩é̩ ìlera olómi, àjo̩ elétò ààbò, ìjo̩ba ìpínlè̩, àti gbogbo òs̩ìs̩é̩ àrà pè̩lú òs̩ìs̩é̩ ò̩fé̩ ti s̩e”. +Ijaya ati Iroyin aheso - Aare Buhari ro awon omo Naijiria lati sora fun awon to fe da ipaya ati aheso sile lati faporuuru lasiko yii. Ìjayà àti Ìròyìn àhésọ - Ààrẹ Buhari rọ̣ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti sọ́ra fún àwọn tó fẹ́ dá ìpayà àti àhéso̩ sílẹ̀ láti fàpòrúúru lásìkò yìí. +“A gbodo teti si ohun pataki ti awon asoju-ijoba ti o sise losan-an loru lati le mu iroyin ti o tewon fun araaye gbo”. “A gbó̩dò̩ té̩tí sí ohun pàtàkì tí àwo̩n as̩ojù-ìjo̩ba tí ó s̩is̩é̩ ló̩sàn-án lóru láti lè mú ìròyìn tí ó tè̩wò̩n fún arááyé gbó̩”. +“Mo maa tun ro gbogbo wa lati tele gbogbo ilana ati itosona ilera ti ijoba apapo ati ijoba ipinle lakale lori imototo ara ati jijinna si eniyan nile ati loko. “Mo máa tún ro̩ gbogbo wa láti tè̩lé gbogbo ìlànà àti ìtó̩só̩nà ìlera tí ìjo̩ba àpapò̩ àti ìjo̩ba ìpínlè̩ làkalè̩ lórí ìmó̩tótó ara àti jíjìnnà sí ènìyàn nílé àti lóko. +“Atunse a maa jeyo lori awon ilana wonyi loorekoore, bimoran atitoju tuntun ba se n wole. “Àtúnṣe a máa je̩yo̩ lórí àwọn ìlànà wò̩nyí lóòrèkóòrè, bímọ̀ràn àtìtọ́jú tuntun bá s̩e ń wo̩lé. +“Ni bayii, mo fe fi da gbogbo omo orile-ede Naijiria loju pe, ijoba apapo ko kere lati daabo bo yin. “Ní báyìí, mo fé̩ fi dá gbogbo o̩mo̩ orílè̩-èdè Nàìjíríà lójú pé, ìjo̩ba àpapò̩ kò kè̩rè̩ láti dáàbò bò yín. +A nilo atileyin ati ifowosowopo yin lasiko aiderun yii. A nílò àtìle̩yìn àti ìfo̩wó̩sowó̩pò̩ yín lásìkò àìdè̩rùn yìí. +Bi a ba fowosowopo, o daju pe a o bori aarun yii”. Bí a bá fo̩wó̩sowó̩pò̩, ó dájú pé a ó borí ààrùn yìí”. +--- COVID-19: Naijiria tun sawari eniyan merinla --- COVID-19: Nàìjíríà tún s̩àwárí ènìyàn mẹ́rìnlá +Ajo amojuto aarun korona lorileede Naijiria (NCDC) tun ti sawari eniyan alarun korona merinla ti a tun mo si COVID-19. Àjọ amójútó ààrùn kòrónà lórílèèdè Nàìjíríà (NCDC) tún ti s̩àwárí ènìyàn alárùn kòrónà mẹ́rìnlá tí a tún mọ̀ sí COVID-19. +Ajo NCDC lo gbe eyi jade lori ero Twitter won pe, won ri alarun Korona kan ni FCT, eyo kan ni Bauchi ati mejila ni ipinle Eko. Àjọ NCDC ló gbé èyí jáde lòrì ẹ̀rọ Twitter wọn pé, wó̩n rí alárùn Kòrónà kan ní FCT, ẹyọ kan ní Bauchi àti méjìlá ni ìpínlẹ̀ Èkó. +“Ninu merinla, won sawari mefa lori omi, meta je arinrinajo to n padabo ati meji to sunmo ara won ni won sawari”, NCDC salaye. “Nínú mé̩rìnlá, wó̩n s̩àwárí mé̩fà lórí omi, mé̩ta jé̩ arìnrìnàjò tó ń padàbò̩ àti méjì tó súnmó̩ ara wo̩n ni wó̩n s̩àwárí”, NCDC s̩àlàyé. +Eyi mu gbogbo alarun korona asawari ni Naijiria je marundinlaadorin, pelu meta ti won fiile, okan si papoda. Èyí mú gbogbo alárùn kòrónà as̩àwárí ní Nàìjíríà jé̩ márùndínláàdọ́rin, pè̩lú mé̩ta tí wó̩n fiílè̩, ò̩kan sì papòdà. +A ri asise ninu iroyin wan i 8:35pm, o ye ko je: A rí às̩ìs̩e nínú ìròyìn wan í 8:35pm, ó ye̩ kó jé̩: +Won se awari alarun korona merinla ni Naijiria; okan ni FCT, okan naa ni Bauchi ati mejila ni ilu Eko. Wó̩n s̩e àwárí alárùn kòrónà mé̩rìnlá ní Nàìjíríà; ò̩kan ní FCT, ò̩kan náà ní Bauchi àti méjìlá ní ìlú Èkó. +Ninu merinla, won sawari mefa lori omi, meta - arinrinajo to n padabo ati meji to sunmo ara won ni won sawari – NCDC (@NCDCgov) March 26,2020. Nínú mé̩rìnlá, wó̩n s̩àwárí mé̩fà lórí omi, mé̩ta - arìnrìnàjò tó ń padàbò̩ àti méjì tó súnmó̩ ara wo̩n ni wó̩n s̩àwárí – NCDC (@NCDCgov) March 26,2020. +--- COVID-19: Igbakeji aare, Osinbajo ko laarun Korona --- COVID-19: Igbákejì ààrẹ, Ọ̀sínbàjò kò láàrùn Kòrónà +Igbakeji aare Naijiria, ojogbon Yemi Osinbajo, ti yege ayewo aarun Korona. Igbákejì ààrẹ Nàìjíríà, ọ̀jọ̀gbọ́n Yemí Ọ̀sínbàjò, ti yege àyẹ̀wò ààrùn Kòrónà. +Eyi han ninu ayewo ti won se fungbakeji aare. Èyí hàn nínú àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe fúngbàkejì ààrẹ. +Agbenuso igbakeji aare, Laolu Akande, lo fi oro ohun mule lakooko ifesi si oro akoroyin nipaa re. Agbẹnusọ igbákejì ààrẹ, Láolú Àkàndé, ló fi ọ̀rọ̀ ọ̀hún múlẹ̀ lákòókò ìfèsì sí ò̩rò̩ akòrò̩yìn nípaa rẹ̀. +Ninu esi ti Akande gbe jade, o ni: “E kaaroo eyin okunrin ati obinrin: Opolopo ipe ni mo ti n gba boya igbakeji aare sayewo COVID-19 ati esi ayewo ohun. Nínú èsì ti Àkàndé gbé jáde, ó ní: “Ẹ káàrọ́ọ̀ ẹ̀yin ọkùnrin àti obìnrin: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpè ni mo ti ń gbà bóyá igbákejì ààrẹ ṣàyẹ̀wò COVID-19 àti èsì àyẹ̀wò ọ̀hún. +Beeni, igbakeji aare sayewo, sugbon ko ni aarun Korona, E se”. Bẹ́ẹ̀ni, igbákejì ààrẹ ṣàyẹ̀wò, sùgbọ́n kò ní ààrùn Kòrónà, Ẹ̣ sé”. +Akande soro lojoosegun lori Twitter pe igbakeji aare ti n dagbe o si n tile sise. Àkàndé sò̩rò̩ ló̩jò̩ó̩s̩é̩gun lórí Twitter pé igbákejì ààre̩ ti ń dágbé ó sì ń tilé s̩is̩é̩. +--- COVID-19: Igbakeji aare Osinbajo n dagbe. --- COVID-19: Igbákejì ààrẹ Òsínbàjò ń dágbé. +Igbakeji aare orile ede Naijiria, ojogbon Yemi Osinbajo ti fi ara re sinu igbele lati tele ilana ajo to n samojuto aarun (NCDC). Igbákejì ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ọ̀jọ̀gbọ́n Ye̩mí Òsínbàjò ti fi ara rẹ̀ sínú ìgbélé láti tẹ̀lé ìlànà àjọ tó ń sàmójútó ààrùn (NCDC). +Agbenuso igbakeji aare, Laolu Akande, lo soro yii lojo Isegun lati ori ero twitter re @akandeoj. Agbẹnusọ igbákejì ààrẹ, Láolú Àkàndé, ló sọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun láti orí ẹ̀rọ twitter rẹ̀ @akandeoj. +Akande ni: “Igbakeji aare lanaa (Monde) sepade ninu ofisii re lori fidio akoyanjo lati tele ilana yiyera fun eniyan. Àkàndé ní: “Igbákejì ààrẹ lánàá (Mó̩ńdè) s̩èpàdé nínú ọ́físìì rẹ̀ lórí fídíò akóyànjo̩ láti tè̩lé ìlànà yíye̩ra fún ènìyàn. +“Ni oni, o tesiwaju ninu ise re lati ile, nitori o wa ni igbele ni ilana pelu ofin NCDC”. “Ní òní, ó tè̩síwájú nínú is̩é̩ rè̩ láti ilé, nítorí ó wà ní ìgbélé ní ìlànà pè̩lú òfin NCDC”. +Akande ko soro lekununrere nipa awon ti igbakeji aare ti se alabaapade pelu ki o to di pe o lo se igbele araa re. Àkàndé kó sọ̀rọ̀ lé̩kùnúnré̩ré̩ nípa àwọn tí igbákejì ààrẹ̀ ti s̩e alábàápàdé pè̩lú kí ó tó di pé ó lo̩ ṣe ìgbélé araa rè̩. +Igbakeji aare Osinbajo lanaa se ipade ninu ofisii re lori fidio akoyanjo lati tele ilana yiyera fun eniyan. Igbákejì ààrẹ Osinbajo lánàá s̩e ìpàdé nínú ọ́físìì rẹ̀ lórí fídíò akóyànjo̩ láti tè̩lé ìlànà yíye̩ra fún ènìyàn. +Lonii, o tesiwaju ninu ise re lati ile, nitori o wa ni igbele ni ilana pelu ofin NCDC”. Lónìí, ó tè̩síwájú nínú is̩é̩ rè̩ láti ilé, nítorí ó wà ní ìgbélé ní ìlànà pè̩lú òfin NCDC”. +Lojo aje, ojogbon Osinbajo ye ko se ifilole National Traffic Road ni Olu ile-ise ajo amojuto ona ti ijoba apapo, FRSC, Wuse, Abuja. Ló̩jó̩ ajé, ò̩jò̩gbó̩n Òsínbàjò ye̩ kó s̩e ìfiló̩lè̩ National Traffic Road ní Olú ilé-is̩é̩ àjo̩ amójútó ò̩nà ti ìjo̩ba àpapò̩, FRSC, Wuse, Abuja. +Won fagi lee, won o si so idi kan pato funtesiwaju re. Wó̩n fagi lée, wo̩n ò si so̩ ìdí kan pàtó fúnté̩sìwájú rè̩. +---Aami ipinlemii ni ikolu t’o waye ni Garkida – Aare Buhari. ---Ààmì ìpinlẹ́mìí ni ìkọlù t’ó wáyé ní Garkida – Ààrẹ Buhari. +Aare Muhammadu Buhari ti da iko olote Boko Haram lebi latari ikolu t’o waye ni waye ni ilu Garkida ni ipinle Adamawa, Ariwa-ila-oorun orile-ede Naijiria. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti dá ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀ Boko Haram lẹ́bi látàrí ìkọlù t’ó wáyé ní wáyé ní ìlú Garkida ní ìpínlẹ̀ Adamawa, Àríwá-ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Aare Buhari so ninu atejade kan: “Awon ikolu t’o n waye ni awon agbegbe kan lati owo iko Boko Haram je apeere pe okan iko Boko Haram ko bale mo, nitori pe ijoba mi ti se iye apa iko omo-ogun olote Boko Haram lati ya wo agbegbe lai ni ikoju. Ààrẹ Buhari sọ nínú àtẹ̀jáde kan: “Àwọn ìkọlù t’ó ń wáyé ní àwọn agbègbè kan láti ọwọ́ ikọ̀ Boko Haram jẹ́ àpẹẹrẹ pé ọkàn ikọ̀ Boko Haram kò balẹ̀ mọ́, nítorí pé ìjọba mi ti ṣẹ́ ìyẹ́ apá ikọ̀ ọmọ-ogun ọlọ̀tẹ̀ Boko Haram láti ya wọ agbègbè láì ní ìkọjú. +Aare wa ba awon ebi to farapa ninu isele naa kedun, o si seleri fun awon omo orile-ede wi pe ko si agbegbe ti awon yoo da da kadara won. Ààrẹ wá bá àwọn ẹbí tó farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà kẹ́dùn, ó sì ṣèlérí fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wí pé kò sí agbègbè tí àwọn yóò dá dá kádàrá wọn. +“O ye ki a gbosuba fun awon akinkanju iko ologun wa fun kikoju iko awon akoluni sugbon won gbodo se ju eyi lo. “Ó yẹ kí a gbóṣùbà fún àwọn akínkanjú ikọ̀ ológun wa fún kíkojú ikọ̀ àwọn akọluni ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ ṣe ju èyí lọ. +Won ni atileyin wa lati tubo kolu iko olote naa, ki won si fimu won fon fere. Wọ́n ní àtìlẹyìn wa láti túbọ̀ kọlu ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀ náa, kí wọ́n sì fimú wọn fọn fèrè. +Mo fe fokan omo orile ede naa bale pe awon olote yoo tubo maa koju apapo agbara iko omo ogun titi ti won yoo fi ronupiwada nibi asise won. Mò fẹ́ fọkàn ọmọ orílẹ̀ èdè náà balẹ̀ pé àwọn ọlọ̀tẹ̀ yóò túbọ̀ máa kọjú àpapọ̀ agbára ikọ̀ ọmọ ogun títí tí wọn yóò fi ronúpìwàdà níbi àṣìṣe wọn. +"""Aare Buhari wa ni lati igba ti ijoba yii ti de ori aleefa, akitiyan iko Boko Haram lati doti tabi gba orile ede Naijiria, k’a ma so ti riri asia won mole, ni o ti ja si pabo." """Ààrẹ Buhari wá ní láti ìgbà tí ìjọba yìí ti dé orí àlééfà, akitiyan ikọ̀ Boko Haram láti dótì tàbí gba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, k’á má sọ ti ríri asia wọn mọ́lẹ̀, ni ó ti já sí pàbo." +---Omo ogun babuja ikolu Boko Haram ni Adamawa. ---Ọmọ ogun bàbujá ìkọlù Boko Haram ní Adamawa. +Iko omo ogun Egbe-omo-ogun 232 ti Egbe-ologun Ihamora 23 labe LAFIYA DOLE ti won ko lo si Garkida, ni ijoba ibile Gombi ni ipinle Adamawa ti ba ete ikolu Boko Haram je. Ikọ̀ ọmọ ogun Ẹgbẹ́-ọmọ-ogun 232 ti Ẹgbẹ́-ológun Ìhámọ́ra 23 lábẹ́ LAFIYA DOLE tí wọ́n kó lọ sí Garkida, ní ìjọba ìbílẹ̀ Gombi ní ìpínlẹ̀ Adamawa ti ba ète ìkọlù Boko Haram jẹ́. +Gege bi atejade kan ti Igbakeji Oludari Alukoro Iko Omo-ogun Egbe-ologun 23 ti Yola, Major Haruna Mohammed Sani, se so, awon iko olote naa wa si agbegbe ohun pelu awon Oko Ibon ijagun t’o to meje, pelu awon orisiirisii oko alupupu, ti won si bere si n tina bo awon ile kookan, ti o fa iberu-bojo ni aarin ilu naa. Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde kan ti Igbákejì Olùdarí Alukoro Ikọ̀ Ọmọ-ogun Ẹgbẹ́-ológun 23 ti Yola, Major Haruna Mohammed Sani, ṣe sọ, àwọn ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀ náà wá sí àgbègbè ọ̀hún pẹ̀lú àwọn Ọkọ̀ Ìbọn ìjagun t’ó tó méje, pẹ̀lú àwọn oríṣiiríṣii ọkọ̀ alùpùpù, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ń tiná bọ àwọn ilé kọ̀ọ̀kan, tí ó fa ìbẹ̀rù-bojo ní àárín ìlú náà. +Gege bi Major Sani se s’alaye “awon iko omo ogun anigboya yii woya ija pelu awon odaran awa-ikogunkiri ti won si dana bole gan-an ti pupo ninu awon odaranmoran naa si gbemii mi ti awon kan si tun tuka, ti opolopo won f’arapa yanna-yanna pelu eri ipa eje lona ibi ti won sa gba.” Gẹ́gẹ́ bí Major Sani ṣe ṣ’àlàyé “àwọn ikọ̀ ọmọ ogun anígboyà yìí wọ̀yá ìjà pẹ̀lú àwọn ọ̀daràn awa-ìkógunkiri tí wọ́n sì daná bolẹ̀ gan-an tí púpọ̀ nínú àwọn ọ̀darànmọràn náà sì gbẹ́mìí mì tí àwọn kàn sì tún túká, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn f’arapa yánna-yànna pẹ̀lú ẹ̀ri ipa ẹ̀jẹ̀ lọ́nà ibi tí wọ́n sá gbà.” +“O s’eni laaanu, pe okan ninu awon iko omo ogun anigboya kan so emi re nu, ti omiran f’arapa yanna-yanna loju. Omo ogun ti o f’arapa naa si ti n gba iwosan lowo-lowo bayii nile iwosan ologun. “Ó ṣ’eni láàánú, pé ọ̀kan nínú àwọn ikọ̀ ọmọ ogun anígboyà kan sọ ẹ̀mí rẹ nù, tí omiran f’arapa yánna-yànna lójú. Ọmọ ogun tí ó f’arapa náà sì ti ń gba ìwòsàn lọ́wọ́-lọ́wọ́ báyìí nílé ìwòsàn ológun. +Ni kete ti isele naa waye ni ojo Kejilelogun osu keji odun, 2020, ni Apase ogun Egbe-ologun Ihamora 23, Ogagun Sani Gambo Mohammed ti se abewo si iko naa ni Garkida Ní kété tí ìsẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní ọjọ́ Kéjìlélógún oṣù kejì ọdún, 2020, ni Apàṣẹ ogun Ẹgbẹ́-ológun Ìhámọ́ra 23, Ọ̀gágun Sani Gambo Mohammed ti ṣe àbẹ̀wò sí ikọ̀ náà ní Garkida +Nigba ti o se abewo re tan, t’o si gbosuba fun iko naa fun iforiti, isora ati ija fitafita ti o mu won segun ota. Nígbà tí ó ṣe àbẹ̀wò rẹ̀ tán, t’ó sì gbóṣùbà fún ikọ̀ náà fún ìforítì, ìṣọ́ra àti ìjà fitafita tí ó mú wọn ṣẹ́gun ọta. +O tun wa ro iko ohun naa lati ma se kaaree nitori pe o se e se, ki iko olote naa tun fe pada wa si agbegbe ohun. Ó tún wá rọ ikọ̀ ọ̀hún náà láti má ṣe káàrẹ́ẹ̀ nítorí pé ó se é se, kí ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀ náà tún fẹ́ padà wá sí àgbègbè ọ̀hún. +Lafikun, Ogagun naa tun wa ro, awon to n gbe agbegbe naa lati maa fi to iko ologun leti ni kete ti won ba gburoo awon afurasi tabi awon eniyan ti owo won ko mo on. Láfikun, Ọ̀gágun náà tún wá rọ, àwọn tó ń gbé àgbègbè náà láti máa fi tó ikọ̀ ológun létí ní kété tí wọn bá gbúròó àwọn afurasí tàbí àwọn ènìyàn tí ọwọ́ wọn kò mọ́ ọn. +O wa fi da awon eniyan agbegbe Garkida naa loju pe iko omo ogun orile ede Naijiria ko ni kaaree lati maa daabo bo dukia ati emi awon ara ilu. Ó wá fi dá àwọn ènìyàn àgbègbè Garkida náà lójú pé ikọ̀ ọmọ ogun orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kò ní káàrẹ́ẹ̀ láti máa dáàbò bo dúkìá àti ẹ̀mí àwọn ará ìlu. +---Aare Buhari dupe lowo awon ‘Dokita Laini Aala’ fun atileyin won ni Naijiria. ---Ààrẹ Buhari dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ‘Dókítà Láìní Ààlà’ fún àtìlẹ́yìn wọn ní Nàìjíríà. +Aare Muhammadu Buhari ti ni ijoba mo riri ifarada ati igbiyanju egbe Medecins Sans Frontieres (Dokita Laini Aala) ni awon agbegbe ti rogbodiyan ti n waye l’orile ede Naijiria. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ní ìjọba mọ rírì ìfaradà àti ìgbìyànjú ẹgbẹ́ Medecins Sans Frontieres (Dokita Láìní Ààlà) ní àwọn agbègbè tí rògbòdìyàn ti ń wáyé l’órílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Lasiko ti aare Buhari n tewogba Dokita Christos Christou, t’o je aare egbe ohun nile aare, niluu Abuja, lojo Ojobo, Aare ni igbiyanju ati ifarada ti egbe naa n se paapaa julo laigba owo, je eyi ti o yanilenu. Lásìkò tí ààrẹ Buhari ń tẹ́wọ́gba Dókítà Christos Christou, t’ó jẹ́ ààrẹ ẹgbẹ́ ọ̀hún nílé ààrẹ, nílùú Àbújá, lọ́jọ́ Ọjọ́bọ̀, Ààrẹ ní ìgbìyànjú àti ìfaradà tí ẹgbẹ́ náà ń se pàápàá jùlọ láìgba owó, jẹ́ èyí tí ó yanilẹ́nu. +Aare Buhari ni ijoba apapo naa ko kaaree ninu igbiyanju re bo tile je pe won n so opolopo oro abuku si ijoba oun. Ààrẹ Buhari ní ìjọba àpapọ̀ náà kò káàrẹ́ẹ̀ nínú ìgbìyànjú rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ àbùkù sí ìjọba òun. +Aare ni “a mo ipo ti awon omode ti ko mo ibi ti awon obi won wa, tabi awon agbegbe ti won ti wa, ati pe idi niyi ti a fi da Ile-ise to n mojuto omoniyan, Isakoso ajalu, ati Idagbasoke awujo sile. Ààrẹ ní “a mọ ipò tí àwọn ọmọdé tí kò mọ ibi tí àwọn òbí wọn wà, tàbí àwọn àgbègbè tí wọ́n ti wá, àti pé ìdí nìyí tí a fi dá Ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó ọmọnìyàn, Ìṣàkóso àjálù, áti Ìdàgbàsókè àwùjọ sílẹ̀. +Eyi ni lati s’eto iranwo fun iru awon eniyan bayii. Èyí ni láti ṣ’ètò ìrànwọ́ fún irú àwọn ènìyàn báyìí. +Aare wa seleri pe ijoba yoo fowosowopo pelu awon ogbontarigi omo bibi orile ede yii, awon ile-ise nla ati awon egbe ile okeere lati pese eto iranwo fun awon agbegbe ti rogbodiyan ti se lose. Ààrẹ wá ṣèlérí pé ìjọba yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ògbóǹtarìgì ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè yìí, àwọn ilé-iṣẹ́ ńlá àti àwọn ẹgbẹ́ ilẹ̀ òkèèrè láti pèsè ètò ìrànwọ́ fún àwọn àgbègbè tí rògbòdìyàn ti ṣe lọ́sẹ́. +---Minisita fun eto iroyin s’alaye nipa Eyawo Eedegbeta milionu dola lati China ---Mínísítà fún ètò ìròyìn ṣ’àlàyé nípa Ẹ̀yáwó Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mílíọ̀nù dọ́là láti China +Minisita fun eto iroyin ati asa, Alhaji Lai Mohammed ti so pe eedegbeta milionu dola ti won fe ya lati orile-ede China ki i se fun ile-ise mohun-maworan ti orile ede Naijiria (NTA) nikan. Mínísítà fún ètò ìròyìn àti àsà, Alhaji Lai Mohammed ti sọ pé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mílíọ̀nù dọ́là tí wọ́n fẹ́ yá láti orílẹ̀-èdè China kì í ṣe fún ilé-iṣẹ́ móhùn-máwòrán ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NTA) nìkan. +Minisita fun eto iroyin ati asa s’oro naa nigbati o n ba akoroyin s’oro niluu Abuja, ti se olu-ilu orile-ede Naijiria lori aheso oro lori owo ti won fe ya ohun fun awon ise akanse. Mínísítà fún ètò ìròyìn àti àsà s’ọ̀rọ̀ náà nígbàtí ó ń bá akọ̀ròyìn s’ọ̀rọ̀ nílùú Àbújá, tí ṣe olú-ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí àhesọ ọ̀rọ̀ lórí owó tí wọ́n fẹ́ yá ọ̀hún fún àwọn iṣẹ́ àkànṣe. +Mohammed ni eyawo naa wa fun ise akanse pataki meta ti won se l’orile ede Naijiria ti o yato si awuyewuye ile-ise akoroyin. Mohammed ní ẹ̀yáwó náà wà fún iṣẹ́ àkànse pàtàkì mẹ́ta tí wọ́n ṣe l’órílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó yàtò sí awuyewuye ilé-iṣẹ́ akọ̀ròyìn. +O ni awon ile-ise akoroyin kan gbe aheso oro naa jade lasiko ti oun wa nile igbimo asofin lati so nipa eto eyawo ohun, pe awon owo ohun lati lee je ki ile-ise NTA maa figa-gbaga pelu ile-ise mohun-maworan, America’s Cable Network News, CNN. Ó ní àwọn ilé-iṣẹ́ akọ̀ròyìn kan gbé àhesọ ọ̀rọ̀ náà jáde lásìkò tí òun wà nílé ìgbìmò aṣòfin láti sọ nípa ètò ẹ̀yáwó ọ̀hún, pé àwọn owó ọ̀hún láti leè jẹ́ kí ilé-iṣẹ́ NTA máa figa-gbága pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ móhùn-máwòrán, America’s Cable Network News, CNN. +Minisita wa s’alaye pe eto eyawo naa yoo je lilo fun kiko awon olu ile-ise agbohun safefe (ITS), ti o je irinse apin-afefe ka ti Ijoba Apapo ati awon ohun-elo ibosori-ero Igbohunsafefe Igbalode (DSO). Mínísítà wá ṣ’àlàyé pé ètò ẹ̀yáwó náà yóò jẹ́ lílò fún kíkọ́ àwọn olú ilé-iṣẹ́ agbóhùn sáfẹ́fẹ́ (ITS), tí ó jẹ́ irinṣẹ́ apin-afẹ́fẹ́ ká ti Ìjọba Àpapọ̀ àti àwọn ohun-èlò ìbọ́sórí-ẹ̀rọ Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Ìgbàlódé (DSO). +Bakan naa, o ni won yoo tun lo owo naa lati fi ko ile-ise igbalode fun ile-eko iroyin fun awon akoroyin ati oniroyin niluu Ikorodu, ni ipinle Eko, ti o ibi ere itage ile/ode, Isaworandaaye ati Eko Imo Eko Ikoroyin. Bákan náà, ó ní wọn yóò tún lo owó náà láti fi kọ́ ilé-iṣẹ́ ìgbàlódé fún ilé-ẹ̀kọ́ ìròyìn fún àwọn akọ̀ròyìn àti oníròyìn nílùú Ìkòròdú, ní ìpínlẹ̀ Èkó, tí ó ibi eré ìtàgé ilé/òde, Ìṣàwòrándààyè àti Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Ìkọ̀ròyìn. +Mohammed tun pe won yoo tun lo owo naa fun pipese ile-ise sinima Igbalode, Ile–itura Onirawo Merin, Gbongan ere- itage nla ati Ibi isere. Mohammed tún pé wọn yóò tún lo owó náà fún pípèsè ilé-iṣẹ́ sinimá Ìgbàlódé, Ilé–ìtura Oníràwọ̀ Mẹ́rin, Gbọ̀ngàn eré- ìtàgé ńlá àti Ibi ìṣere. +Minisita tun tesiwaju pe awon yoo tun lo owo naa lati fi ra irinse igbalode fun iyaworan fun yiya ati ipese ina mona-mona. Mínísítà tún tẹ̀síwájú pé àwọn yóò tún lo owó náà láti fi ra irinṣẹ́ ìgbàlódé fún ìyàwòràn fún yíyá àti ìpèsè iná mọ̀nà-mọ́ná. +O ni Ilu Ile-eko Ikoroyin ni ikeji iru re to wa ni Ile-Adulawo ti akoko wa ni orile ede Egypt. Ó ní Ìlú Ilé-ẹ̀kọ́ Ìkọ́ròyìn ni ìkejì irú rẹ̀ tó wà ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀ tí àkọ́kọ́ wà ní orílẹ̀ èdè Egypt. +Minisita tun so pe awon yoo tun lo owo ohun lati fi pese irinse igbalode fun ile-ise mohun-maworan NTA to wa niluu Abuja ati ekun mejila ati ni gbogbo ibi ti ile-ise naa wa ni gbogbo ipinle to wa l’orile ede Naijiria. Mínísítà tún sọ pé àwọn yóò tún lo owó ọ̀hún láti fi pèsè irinṣẹ́ ìgbàlódé fún ilé-iṣẹ́ móhùn-máwòrán NTA tó wà nílùú Àbújá àti ẹkùn méjìlá àti ní gbogbo ibi tí ilé-iṣẹ́ náà wà ní gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà l’órílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +---Aare Buhari fokan ipinle Plateau bale lori eto alaafia ati aseyori. ---Ààrẹ Buhari fọkàn ìpínlẹ̀ Plateau balẹ̀ lórí ètò àlàáfíà àti àṣeyọrí. +Aare orile ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti fokan awon eniyan ipinle Plateau bale pe ijoba ko ni kaaare lati tubo maa seto iranwo fun won nipa pipese eto alaafia, aseyori ati ifokanbale fun won. Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti fọkàn àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Plateau balẹ̀ pé ìjọba kò ní káàárẹ̀ láti túbọ̀ máa ṣètò ìránẁọ fún wọn nípa pípèsè ètò àlàáfíà, àṣeyọrí àti ìfọ̀kànbalẹ̀ fún wọn. +Lasiko ti aare Buhari n tewogba gomina ipinle Plateau ohun, Simon Lalong ati awon ti oro kan ni ipinle Plateau lojo Ojobo, Aare Buhari wa ro awon olugbe ati omo ipinle naa lati maa satileyin fun eto idagbasoke ti gominaa naa dawole lori. Lásìkò tí ààrẹ Buhari ń tẹ́wọ́gba gómìnà ìpínlẹ̀ Plateau ọ̀hún, Simon Lalong àti àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ní ìpínlẹ̀ Plateau lọ́jọ́ Ọjọ́bọ̀, Ààrẹ Buhari wá rọ àwọn olùgbé àti ọmọ ìpínlẹ̀ náà láti máa sàtìlẹyìn fún ètò ìdàgbàsókè tí gómínáà náà dáwọ́lé lórí. +Gomina naa wa ro aare Buhari lati seto popo ona oko ti yoo maa gba awon oko pupo, iranwo fun awon ti ogun ati ija le kuro ni agbegbe won, atunse lori ile –ise iwadii lori anamo. Gómìnà náà wá rọ ààrẹ Buhari láti ṣètò pópó ọ̀nà ọkọ̀ tí yóò máa gba àwọn ọkọ̀ púpọ̀, ìrànwọ́ fún àwọn tí ogun àti ìjà lé kúrò ní àgbègbè wọn, àtúnṣe lórí ilé –iṣẹ́ ìwádìí lórí ànàmọ́. +Aare Buhari wa so fun awon asoju ohun pe, inu ohun dun lori idagbasoke to wa nipa eto aabo ati idagbasoke awujo ti gomina naa n se ni ipinle naa Ààrẹ Buhari wá sọ fún àwọn aṣojú ọ̀hún pé, inú òhun dùn lórí ìdàgbàsókè tó wà nípa ètò ààbò àti ìdàgbàsókè àwùjọ tí gómìnà náà ń ṣe ní ìpínlẹ̀ náà +Lara awon eniyan t’o wa pelu gomina Lalong ni igbakeji gomina, ojogbon Sonni Tyoden ati awon ogbontarigii oloselu to wa lati ipinle naa Lára àwọn èníyàn t’ó wà pẹ̀lú gómìnà Lalong ní ìgbákejì gómìnà, ọ̀jọ̀gbọ̀n Sonni Tyoden àti àwọn ògbóntàrigìì olósèlú tó wá láti ìpínlẹ̀ náà +---Igbimo asofin yoo se iwadii bi ile-ise ero ibanisoro alagbeeka se n ja Naijiria lole lori ipe. ---Ìgbìmọ̀ aṣòfin yóò ṣe ìwádìí bí ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká ṣe ń ja Nàìjíríà lólè lórí ìpè. +Lojoru yii n ile igbimo asofin ti bere iwadii lori owo ti awon ile-ise to n pese ero ibanisoro alagbeeka ati ipe bi won se n ja awon omo orile ede lole lori ipe ti awon eniyan ko jegbadun re sugbon ti won n gba owo lowo onibara won. Lọ́jọ́rú yìí n ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí owó tí àwọn ilé-iṣẹ́ tó ń pèsè ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká àti ìpè bí wọ́n ṣe ń ja àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè lólè lórí ìpè tí àwọn ènìyàn kò jẹ̀gbádùn rẹ̀ sùgbọ́n tí wọ́n ń gbà owó lọ́wọ́ oníbárà wọn. +Gege bi alaga igbimo asofin to n mojuto eto ibanisoro, asofin Oluremi Tinubu, se so pe “Bi awon ile-ise ero ibanisoro se n ja owo lori ipe ti awon onibaraa won ko lo ati awon iwa miiran ti won n lo lati ja awon onibaraa won lole je iwa ibaje. Gẹ́gẹ́ bí alága ìgbìmọ̀ aṣòfin tó ń mójútó ètò ìbánisọ̀rọ̀, aṣòfin Olúrèmí Tinubu, se sọ pé “Bí àwọn ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ṣe ń já owó lórí ìpè tí àwọn oníbàráà wọn kò lò àti àwọn ìwà mííràn tí wọ́n ń lò láti ja àwọn oníbàráà wọn lólè jẹ́ ìwà ìbàjẹ́. +Iru iwa ti ile-ise ibanisoro MTN n hu lorile ede Naijiria ko lee sele lorile ede South Africa. Irú ìwà ti ilé-isẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ MTN ń hu lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà kó leè ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀ èdè South Africa. +O ye ki igbimo se iwadii si gbogbo owo ti awon ile-ise ero ibanisoro n gba lowo onibaraa won laije pe won je anfaani ohun ti won san owo naa fun. Ó yẹ kí ìgbìmọ̀ ṣe ìwádìí sí gbogbo owó tí àwọn ilé-isẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ń gbà lọ́wọ́ oníbàráà wọn láìjẹ́ pé wọ́n jẹ àǹfààní ohun tí wọ́n san owó náà fún. +Awon orile ede miiran maa n da owo pada. Àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn máa ń dá owó padà. +Sugbon nibi e fi dun wa ti e si ni fun wa ni Kobo. Sùgbọ́n níbí ẹ fi dùn wá ti ẹ sì ní fún wa ní Kọ́bọ̀. +“Iru oja to wa ni orile ede Naijiria, ko si iru re ni agbaye. “Irú ọjá tó wà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, kò sí irú rẹ̀ ní àgbáyé. +Nigbati awon omo orile ede Naijiria miiran yoo ni kaadi ipe meta, sibe a ko tun ni je anfaani si ohun ti a sanwo fun. Nígbàtí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà mìíràn yóò ní káàdì ìpè mẹ́ta, síbẹ̀ a kò tún ní jẹ àǹfààní sí ohun tí a sanwó fún. +Abenugan wa ro ile-ise to n mojuto gbogbo ero ibanisoro lorile ede Naijiria (NCC) lati mojuto ojuse won, paapaa julo bi awon ile-ise to n pese ipe ati ayelujara se n ja awon onibaraa won lole lorile ede yii. Abẹnugan wá rọ ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó gbogbo ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NCC) láti mójútó ojúse wọn, pàápàá jùlọ bí àwọn ilé-isẹ́ tó ń pèsè ìpè àti ayélujára se ń já àwọn oníbàráà wọn lólè lórílẹ̀ èdè yìí. +---Coronavirus: Ijoba Naijiria ti mura sile. ---Coronavirus: Ìjọba Nàìjíríà ti múra sílẹ̀. +Ijoba orile ede Naijiria ti ni ohun ti mura sile lati gbogun ti aarun corona ti a mo si COVID-19, logan ti won ba gburoo re lorile ede yii. Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ní òhun ti múra sílẹ̀ láti gbógun tí ààrùn corona tí a mọ̀ sí COVID-19, lọ́gán tí wọ́n bá gb́uròó rẹ̀ lórílẹ̀ èdè yìí. +Minisita fun iroyin ati asa lorile ede Naijiria, Lai Mohammed lo soro yii pelu awon akoroyin lojo Isegun lasiko ti won n se ayewo ohun elo ti won pese sile lati fi gbogun ti arun corona. Mínísítà fún ìròyìn àti àsà lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Lai Mohammed ló sọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́ Ìsẹ́gun lásìkò tí wọ́n ń se àyẹ̀wò ohun èlò tí wọ́n pèsè sílẹ̀ láti fi gbógun ti àrùn corona. +Minisita tun so pe awon ajo ati ile-ise ijoba ti n ba ara won sise papo lati gbogun ti arun corona ni kete to ba wo orile ede Naijiria. Mínísítà tún sọ pé àwọn àjọ àti ilé-iṣẹ́ ìjọba tí ń bá ara wọn ṣiṣẹ́ papọ̀ láti gbógun ti àrùn corona ní kété tó bá wọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +O ni igbimo ti ijoba apapo yan ti fokan orile ede Naijiria bale pe ko sewu loko longe nipa eto ilera, amosa won ko ni dawo igbiyanju naa duro. Ó ní ìgbìmọ̀ tí ìjọba àpapọ̀ yàn ti fọkàn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà balẹ̀ pé kò séwu lóko lóngẹ́ nípa ètò ìlera, àmọ́sá wọn kò ní dáwọ́ ìgbìyànjú náà dúró. +Awon minisita merin orile ede yii lo wa nibi eto ayewo naa, Minisita fun eto oko oju ofuurufu, Minisita ipinle fun eto ilera, Minisita fun eto omoniyan, ajalu ati idagbasoke awujo, ni won jo wa ni papa ofurufu fun eto ayewo ohun. Àwọn mínísítà mẹ́rin orílẹ̀ èdè yìí ló wà níbi ètò àyẹ̀wò náà, Mínísítà fún ètò ọkọ̀ ojú òfuurufú, Mínísítà ìpínlẹ̀ fún ètò ìlera, Mínísítà fún ètò ọmọníyán, àjálù àti ìdàgbàsókè àwùjọ, ni wọ́n jọ wà ní pápá òfúrufú fún ètò àyẹ̀wọ̀ ọ̀hún. +Lai mohammed tun ni awon ile-ise iroyin ijoba orile ede yii, ile-ise iroyin ati mohun-maworan orile ede Naijiria, ile-ise agbohun safefe orile ede Naijiria, ile-ise akoroyin ti ijoba orile ede Naijiria, Ohun Naijiria ati ile-ise eleto ilaniloye naa ko gbeyin lati maa se ipolongo ati ilaniloye fun awon ara ilu lori arun corona ohun. Lai mohammed tún ní àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn ìjọba orílẹ̀ èdè yìí, ilé-iṣẹ́ ìròyìn àti móhùn-máwòrán orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, ilé-iṣẹ́ agbóhùn sáfẹ́fẹ́ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, ilé-iṣẹ́ akọ̀ròyìn ti ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, Ohùn Nàíjíríà àti ilé-iṣẹ́ elétò ìlanilọ́yẹ̀ náà kò gbẹ́yìn láti máa ṣe ìpolongo àti ìlanilọ́yẹ̀ fún àwọn ará ìlú lórí àrùn corona ọ̀hún. +O tun te siwaju pe eto ilaniloye ohun ni won tun n so ni ede abinibi. Ó tún tẹ̀ síwájú pé ètò ìlanilọ́yẹ̀ ọ̀hún ni wọ́n tún ń sọ ní èdè abínibí. +Ile igbimo asofin Naijiria ati Iran yoo fowosowopo Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Nàìjíríà àti Iran yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ +Ile igbimo asofin orile ede Naijiria ti ni orile ede Naijiria yoo fowosowopo pelu ile igbimo asofin orile ede Iran. Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ní orílẹ̀ èdè Nàíjíríà yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé ìgbìmọ̀ asòfin orílẹ̀ èdè Iran. +Abenugan Femi Gbajabiamila soro yii lasiko to n gba asoju orile ede Iran si Naijiria, ogbeni Morteza Rahimi Zarchi, lalejo niluu Abuja, o so pe ibasepo laarin ile igbimo asofin orile ede Naijiria ati Iran yoo tunbo gbile sii laarin orile ede mejeeji ohun. Abẹnugan Fẹ́mi Gbàjàbíàmílà sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń gba aṣojú orílẹ̀ èdè Iran sí Nàìjíríà, ọ̀gbẹ́ni Morteza Rahimi Zarchi, lálejò nílùú Àbújá, ó sọ pé ìbásepọ̀ láàrin ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀ èdè Nàíjíríà àti Iran yóò túnbọ̀ gbilẹ̀ síi láàrin orílẹ̀ èdè méjèèjì ọ̀hún. +Abenugan Gbajabiamila ni “Inu wa maa n dun lati tewogba awon alejo lati ile okeere, nitori pe o maa n je ki ibasepo to wa laarin orile ede Naijiria ati orile naa tun tunbo muna-doko. Abẹnugan Gbàjàbíàmílà ní “Inú wa máa ń dùn láti tẹ́wógba àwọn àlejò láti ilẹ̀ òkèèrè, nítorí pé ó máa ń jẹ́ kí ìbásepọ̀ tó wà láàrín orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti orílẹ̀ náà tún túnbọ̀ múná-dóko. +“Mo mo pe orile ede Iran n la ipenija koja bii orile ede Naijiria. “Mo mọ̀ pé orílẹ̀ èdè Iran ń la ìpèníjà kọjá bíi orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +"""Saaju eyi ni, ogbeni Zarchi so pe leyin ibasepo pelu ile igbimo asofin orile ede mejeeji ohun, o tun je dandan pe ki orile ede mejeeji naa ni ibasepo lori eto oro aje ati asa." """Sáájú èyí ni, ọ̀gbẹ́ni Zarchi sọ pé lẹ́yìn ìbásepọ̀ pẹ̀lú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀ èdè méjéèjì ọ̀hún, ó tún jẹ́ dandan pé kí orílẹ̀ èdè méjèèjì náà ní ìbásepọ̀ lórí ètò ọrọ̀ ajé àti àsà." +O ni orile ede Iran ti se gudugudu meje, yaya mefa lati gbogun ti iko oloote paapaa julo ni ekun won. Ó ní orílẹ̀ èdè Iran ti ṣe gudugudu méje, yàyà mẹ́fà láti gbógun ti ikọ̀ ọlọ̀ọ̀tẹ̀ pàápàá jùlọ ní ẹkùn wọn. +---Ile igbimo asofin fonte lu adari ile–ise oko ofuurufu tuntun. ---Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin fòǹtẹ̀ lu adarí ilé–iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú tuntun. +Ile igbimo asofin ti fonte lu adari ile-ise oko ofurufu tuntun, Nigerian Civil Aviation Authority, NCAA,Captain Musa Shuaibu Nuhu gege bi adari tuntun fun ajo naa. Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti fòǹtẹ̀ lu adarí ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfúrufú tuntun, Nigerian Civil Aviation Authority, NCAA,Captain Musa Shuaibu Nuhu gẹ́gẹ́ bi adarí tuntun fún àjọ náà. +Eyi waye leyin ayewo ti igbimo asofin to n mojuto ile-ise oko ofurufu se fun, Musa Shuaibu Nuhu, ti o si yege nibe. Èyí wáyé lẹ́yìn àyẹ̀wò tí ìgbìmọ̀ aṣòfin tó ń mójútó ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfúrufú ṣe fún, Musa Shuaibu Nuhu, tí ó sì yege níbẹ̀. +Alaga igbimo ohun, Smart Adeyemi, so pe “Awon yan, Musa Shuaibu Nuhu nitori imo ati eko ti o ni nipa oko ofuurufu. Alága ìgbìmọ̀ ọ̀hún, Smart Adéyẹmí, sọ pé “Àwon yàn, Musa Shuaibu Nuhu nítorí ìmọ̀ àti ẹ̀kọ́ tí ó ní nípa ọkọ̀ òfuurufú. +Lojo kejidinlogbon osu kinni, odun 2020, ni abenugan ile igbimo asofin, Ahmad Lawan, ka iwe ti aare Muhammadu Buhari fi ranse si ile igbimo asofin nipa yiyan Captain Musa Shuaibu Nuhu gege bii adari tuntun fun ajo naa. Lọ́jọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kínní, ọdún 2020, ni abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, Ahmad Lawan, ka ìwé tí ààrẹ Muhammadu Buhari fi ránsẹ́ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin nípa yíyan Captain Musa Shuaibu Nuhu gẹ́gẹ́ bíi adarí tuntun fún àjọ náà. +Captain Musa Shuaibu Nuhu je ogbontarigi awako ofuurufu, ti o si tun se ise naa fun ogbon odun. Captain Musa Shuaibu Nuhu jẹ́ ògbóǹtarìgì awakọ̀ òfuurufú, tí ó sì tún ṣe iṣẹ́ náà fún ọgbọ̀n ọdún. +---Abenugan ile igbimo asofin, Ahmad Lawan ti se ifilole ita gbangba lati je ki awon ara ilu wa soro nipa iwa ifipa banilopo. ---Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ asòfin, Ahmad Lawan ti se ìfilọ́lẹ̀ ìta gbangba láti jẹ́ kí àwọn ará ilú wá sọ̀rọ̀ nípa ìwà ìfipá bánilòpọ̀. +Asofin Lawan ni iwa ifipa-banilopo ati idunkooko moni lati fipa ba eniyan lopo je iwa odaran. Aṣòfin Lawan ní ìwà ìfipá-bánilòpọ̀ àti ìdúnkookò mọ́ni láti fipá bá ènìyàn lòpọ̀ jẹ́ ìwà ọ̀daràn. +Nitori naa, awon ti oro kan gbodo lee forikori lati sofin ti yoo fiya to to je eni to ba hu iwa ibaje ohun. Nítorí náà, àwọn tí ọ̀rọ́ kàn gbọdọ̀ leè foríkorí láti ṣòfin tí yóò fìyà tó tọ́ jẹ ẹni tó bá hu ìwà ìbàjẹ́ ọ̀hún. +---Ile-ise Aare ro omo orile ede Naijiria lati yago fun awon akoroyin ayederu ---Ilé-iṣẹ́ Ààrẹ rọ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti yàgò fún àwọn akọ̀ròyìn ayédèrú +Ile-ise Aare ti ro omo orile ede Naijiria lati yago fun awon iroyin eleje ati aheso ti awon akoroyin kan gbe jade pe aare Muhammadu Buhari yoo te oko leti lo si ile okeere lati ojoru, osu keji ojo kokandinlogun titi di ojo kerin, osu kerin. Ilé-iṣẹ́ Ààrẹ ti rọ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti yàgò fún àwọn ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ àti àhesọ ti àwọn akọ̀ròyìn kán gbé jáde pé ààrẹ Muhammadu Buhari yóò tẹ ọkọ̀ létí lọ sí ilẹ̀ òkèèrè láti ọjọ́rú, osù kejì ọjọ́ kọkàndínlógún títí di ọjọ́ kẹrin, osù kẹrin. +Oluranwo aare lori iroyin ati ikede, Femi Adesina lo soro yii lojo Aje pelu awon akoroyin pe iro patapata ni awon iroyin to jade lori ero ayelujara lojo Aiku. Olùrànwọ́ ààrẹ lórí ìròyìn àti ìkéde, Fẹ́mi Adésínà lọ́ sọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́ Ajé pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn pé irọ́ pátápátá ni àwọn ìròyìn tó jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára lọ́jọ́ Àìkú. +O ni: “Iroyin t’o jade pe aare orile ede Naijiria, Muhammadu Buhari fe lo si United Kingdom fun ogun ojo, yoo si gba ibe lo si orile ede Saudi Arabia, tun lo si orile ede Austria, iro to jinna si otito ni eyi, lati odo awon eni ibi. Ó ní: “Ìròyìn t’ó jáde pé ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari fẹ́ lọ sí United Kingdom fún oguń ọjọ́, yóò sì gba ibẹ̀ lọ sí orílẹ̀ èdè Saudi Arabia, tún lọ sí orílẹ̀ èdè Austria, irọ́ tó jìnnà sí òtítọ́ ni èyí, láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni ibi. +Agbenuso aare tun ni awon eniyan ibi yii ko tun fi mo lori aare nikan, won tun n so awon aheso oro wonyi nipa ebi ati awon ti wɔn jo n se ijoba. Agbẹnusọ ààrẹ tún ní àwon ènìyàn ibi yìí kò tún fi mọ lórí ààrẹ nìkan, wọ́n tún ń sọ àwọn àhesọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa ẹbí àti àwọn tí wɔ̣́n jọ́ ń se ìjọba. +“Won tun gbe iroyin eleje jade pe, awon janduku kolu oko oju irin ti minisita fun eto irinna, Rotimi Amaechi wa nibe ni Rigasa ni ipinle Kaduna, won tun so pe omo aare Buhari, Zahra, gba ise nile itaja epo robi orile ede yii gege bi igbakeji adari ile-ise naa, iro to jinna si otito ni eyi. “Wọ́n tún gbé ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ jáde pé, àwon jàndùkú kọlu ọkọ̀ ojú irin tí mínísítà fún ètò ìrìnnà, Rótìmí Amaechi wà níbẹ̀ ní Rigasa ní ìpínlẹ̀ Kàdúná, wọ́n tún sọ pé ọmọ ààrẹ Buhari, Zahra, gba iṣẹ́ nílé ìtajà epo rọ̀bì orílẹ̀ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí igbákejì adarí ilé-iṣẹ́ náà, irọ́ tó jìnnà sí òtítọ́ ni èyí. +---Gomina Borno sabewo si Niger lati gba awon atipo to wa nibe pada ---Gómìnà Borno sàbẹ̀wò ṣí Niger láti gba àwọn àtìpó tó wà níbẹ̀ padà +Gomina ipinle Borno, ojogbon Babagana Umara-Zulum ti se abewo si Diffa, ni orile ede Niger, lati wa ona si bi awon ti ogun Boko Haram le kuro ni agbegbe, ti won si n se atipo ni orile ede Niger, pada si ipinle Borno. Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, ọ̀jọ̀gbọ́n Babagana Umara-Zulum ti ṣe àbẹ̀wò sí Diffa, ní orílẹ̀ èdè Niger, láti wá ọ̀nà sí bí àwọn tí ogun Boko Haram lé kúrò ní agbègbè, tí wọ́n sì ń ṣe àtìpó ní orílẹ̀ èdè Niger, padà sí ìpínlẹ̀ Borno. +Lasiko ti gomina se abewo si awon atipo ohun, ti won le ni ogofa, to si je pe pupo ninu won lo wa lati apa iwo oorun ipinle Borno. Lásìkò tí gómìnà ṣe àbẹ̀wò sí àwọn àtìpó ọ̀hún, tí wọ́n lé ní ọgọ́fà, tó sì jẹ́ pé púpọ̀ nínú wọn ló wá láti apá ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Borno. +Awon atipo ohun lo je okunrin, obinrin ati awon omode, ti won sa kuro ni agbegbe won nitori ikolu lati owo Boko Haram lati odun 2014, ni eyi ti o ti so opolopo won di eni ti ko nile lori. Àwon àtìpó ọ̀hún ló jẹ́ ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọmọdé, tí wọ́n sá kúrò ní agbègbè wọn nítorí ìkọlù láti ọwọ́ Boko Haram láti ọdún 2014, ní èyí tí ó ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn di ẹni tí kò nílé lórí. +Iroyin so pe pupo ninu awon atipo naa lo rin ona jinjin si awon orile-ede agbegbe. Ìròyìn sọ pé púpọ̀ nínú àwọn àtìpó náà ló rin ona jínjìn sí àwọn orílẹ̀-èdè agbègbè. +Gomina Diffa, Isa Lameen, to je olugbalejo ni o dari gomina Zulum, ati abenugan ile igbimo asofin ipinle Borno, Abdulkarim Lawan. Gómìnà Diffa, Isa Lameen, tó jẹ́ olùgbàlejò ni ó darí gómìnà Zulum, àti abẹnugan ilé ìgbìmò asòfin ìpínlẹ̀ Borno, Abdulkarim Lawan. +Ojogbon Zulum wa fi idunnu re han si ijoba ekun Diffa, ijoba orile ede Niger ati awon agbegbe to wa ni orile ede naa fun iwa ifi-omoniyan se ti won hu si awon omo ipinle Borno. Ọ̀jọ̀gbọ́n Zulum wá fi ìdùnnú rẹ̀ hàn sí ìjọba ẹkùn Diffa, ìjọba orílẹ̀ èdè Niger àti àwọn agbègbè tó wà ní orílẹ̀ èdè náà fún ìwà ìfi-ọmọnìyàn ṣe tí wọ́n hù sí àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Borno. +Gomina ipinle Katsina, Aminu Masari ti kilo fun awon eniyan agbegbe ipinle naa lati ma se dajo lati owo ara won nitori wahala to be sile ni ipinle naa. Gómìnà ìpínlẹ̀ Katsina, Aminu Masari ti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn agbègbè ìpínlẹ̀ náà láti má ṣe dájọ́ láti ọwọ́ ara wọn nítorí wàhálà tó bẹ́ sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà. +Masari soro yii lojo Aiku ni Malumfashi lasiko to n pin awon ohun elo ironilagbara ti asofin Bello Mandiya pese fun awon eniyan to n gbe ni ekun Funtua ni ipinle ohun. Masari sọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́ Àìkú ní Malumfashi lásìkò tó ń pín àwọn ohun èlò ìrónilágbára tí asòfin Bello Mandiya pèsè fún àwọn ènìyàn tó ń gbé ní ẹkùn Funtua ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún. +Masari tesiwaju pe pipa awon eniyan ogbon to n gbe ni agbegbe Tsanwa ati Dankar ni ijoba ibile Batsari wa lati owo awon olote ti won wa ninu igbo Zamfara lati gbesan. Masari tẹ̀síwájú pé pípa àwọn ènìyàn ọgbọ́n tó ń gbé ní agbègbè Tsanwa àti Dankar ní ìjọba ìbílẹ̀ Batsari wá láti ọwọ́ àwọn ọlọ́tẹ̀ tí wọ́n wà nínú igbó Zamfara láti gbẹ̀san. +Gomina naa wa ro awon to n gbe ninu agbegbe naa lati maa hu iwa ti won yoo fi gbesan sugbon ti won ba fura si awon eniyan ti owo won ko mo, ki won fi to awon agbofinro leti. Gómìnà náà wá rọ àwọn tó ń gbé nínú agbègbè náà láti máa hu ìwá tí wọn yóò fi gbẹ̀san sùgbọ́n tí wón bá fura sí àwọn ènìyàn tí ọwọ́ wọn kò mọ́, kí wọn fi tó àwọn agbófinró létí. +Masari tun wa ro won lati mu suuru pe ijoba ati awon ajo eso eleto aabo si n se ise lori isele naa. Masari tún wá rọ̀ wọ́n láti mú sùúrù pé ìjọba àti àwọn àjọ ẹ̀sọ́ elétò ààbò sì ń ṣe isẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. +O wa ba awon agbegbe meji to kabaamo ninu isele naa kedun. Ó wá bá àwọn agbègbè méjì tó kábàámọ̀ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà kẹ́dùn. +O ni awon odaran ti won wa lati ipinle Zamfara ni won wa si agbegbe Tsanwa ati Dankar lojo Eti, nibi ti won ti pa eniyan ogbon, paapaa julo awon obinrin ati omode, ko to di pe won dana sun awon agbegbe ohun. Ó ní àwọn ọ̀daràn tí wọ́n wá láti ìpínlẹ̀ Zamfara ni wọ́n wá sí àgbègbè Tsanwa àti Dankar lọ́jọ́ Ẹtì, níbi tí wọ́n ti pa ènìyàn ọgbọ̀n, pàápàá jùlọ àwọn obìnrin àti ọmọdé, kó tó di pé wón dáná sun àwọn àgbègbè ọ̀hún. +Ile-ise olopaa ipinle naa ti ni awon ti mu okan lara odaran ohun. Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ti ní àwọn ti mú ọ̀kan lára ọ̀daràn ọ̀hún. +---Minisita pe fun ibaleokan ni ipinle Bayelsa-. ---Mínísítà pè fún ìbálẹ̀ọkàn ní ìpínlẹ̀ Bayelsa-. +Minisita ipinle fun oro epo robi, Timipre Sylva ti ro awon omo ipinle Bayelsa lati yago fun iwa jagidi-jagan, ipa ati aibowo fun ofin. Mínísítà ìpínlẹ̀ fún ọ̀rọ̀ epo rọ̀bì, Timipre Sylva ti rọ àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Bayelsa láti yàgò fún ìwà jàgídí-jàgan, ipá àti àìbọ̀wọ̀ fún òfin. +Sylva soro yii lojo Aiku ninu atejade kan ti o gbe sita niluu Abuja. Sylva sọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́ Àìkú nínú àtẹ̀jáde kan tí ó gbé síta nílùú Àbújá. +“Mo fe lo asiko yii lati ro gbogbo omo ipinle Bayelsa lati yago fun iwa jagidi-jagan, ipa ati aibowo fun ofin. “Mo fẹ́ lo àsìkò yìí láti rọ gbogbo ọmọ ìpínlẹ̀ Bayelsa láti yàgò fún ìwà jàgídí-jàgan, ipá àti àìbọ̀wọ̀ fún òfin. +“Mo tun fe lo asiko yii lati fi toro aforijin lowo aare orile ede Naijiria, Muhammadu Buhari, lori isele buruku to waye, ni eyi ti o mu ki aare yi ipinnu re pada lati wa si ipinle Bayelsa. “Mo tún fẹ́ lo àsìkò yìí láti fi tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari, lórí ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tó wáyé, ní èyí tí ó mú kí ààrẹ yí ìpinnu rẹ̀ padà láti wá sí ìpínlẹ̀ Bayelsa. +Silva tun wa ro awon omo ipinle Bayelsa ohun pe, awon adari egbe APC ti n se ise takun-takun lati ri i pe won yanju wahala to be sile ni ipinle naa, ni eyi ti won ti dari awon agbejoro won lati gbe igbese lori re. Silva tún wá rọ àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Bayelsa ọ̀hún pé, àwọn adarí ẹgbẹ́ APC tí ń ṣe iṣẹ́ takun-takun láti rí i pé wọn yanjú wàhálà tó bẹ́ sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà, ní èyí tí wọn ti darí àwọn agbẹjọ́rọ̀ wọn láti gbé ìgbẹ́sẹ̀ lórí rẹ̀. +Aare Buhari ki Nasir el-Rufai ku ori-ire ogota odun. Ààrẹ Buhari kí Nasir el-Rufai kú orí-ire ọgọ́ta ọdún. +Aare orile ede Naijiria, Muhammadun Buhari ti darapo mo igbimo ijoba ati gbogbo omo ipinle Kaduna lati ba gomina ipinle Kaduna Nasir el-Rufai sajoyo ogota (60) odun ti yoo pe lojo Aiku. Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, Muhammadun Buhari ti darapọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀ ìjọba àti gbogbo ọmọ ìpínlẹ̀ Kaduna láti bá gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna Nasir el-Rufai sàjọyọ̀ ọgọ́ta (60) ọdún tí yóò pé lọ́jọ́ Àìkú. +Ninu atejade kan ti, aare Buhari gbe jade lati fi ki gomina naa ku ori-ire fun ise takun-takun ti o ti gbe se fun idagbasoke orile ede Naijiria. Nínú àtẹ̀jáde kàn tí, ààrẹ Buhari gbé jáde láti fi kí gómìnà náà kú orí-ire fún iṣẹ́ takun-takun tí ó ti gbé ṣe fún ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Aare tun salaye pe bo tile je pe gomina naa ba ara re lenu ise ijoba lairotele sugbon ipa ribi-ribi ti o ti ko lorile ede ko lafiwe rara. Ààrẹ tún sàlàyé pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé gómìnà náà bá ara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba láìròtẹ́lẹ̀ sùgbọ́n ipa ribi-ribi tí ó ti kó lórílẹ̀ èdè kò láfiwé rárá. +Igbakeji Aare orile ede Naijiria, Ojogbon Yemi Osinbajo ti ni oun ni igbekele ninu ogbon, imo ati oye awon omo orile ede yii lati yanju isoro to n dojuko orile ede Naijiria lai nilo iranwo lati ile okeere. Igbákejì Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí Òsínbàjò ti ní òun ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí láti yanjú ìsoro tó ń dojúkọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ĺài nílò ìrànwọ́ láti ilẹ̀ òkèèrè. +Ojogbon Yemi osinbajo ni pelu aseyori ti awon omo orile ede Naijiria yii ti se nile yii ati ni ile okeere fihan pe awon omo orile ede yii lee yanju isoro ati ipenija to n dojuko orile ede yii funra won. Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí òsínbàjò ní pẹ̀lú àṣeyọrí ti àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yìí ti ṣe nílẹ̀ yìí àti ní ilẹ̀ òkèèrè fihàn pé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí leè yanjú ìṣòro àti ìpèníjà tó ń dojúkọ orílẹ̀ èdè yìí fúnra wọn. +Ojogbon Osinbajo soro yii lasiko to n gba iko awon onise abe lati ile -eko West African College of Surgeons (WACS), nile-ise re lalejo lojo Eti. Ọ̀jọ̀gbọ́n Òsínbàjò sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń gba ikọ̀ àwọn onísẹ́ abẹ láti ilé -ẹ̀kọ́ West African College of Surgeons (WACS), nílé-iṣẹ́ rẹ̀ lálejò lọ́jọ́ Ẹtì. +Awon omo orile ede Naijiria to n se ise abe ni won da ile eko naa sile ni ogota (60) odun seyin, saaju igba ti won da ajo ile afirika sile. Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó ń ṣe iṣẹ́ abẹ ni wọ́n dá ilé ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀ ní ọgọ́ta (60) ọdún sẹ́yìn, sáájú ìgbà tí wọn dá àjọ ilẹ̀ áfíríkà sílẹ̀. +Ojogbon Ibrahim Yakasai, lo dari iko naa wa sile aare lati so nipa awon ojuse ati akitiyan ile -eko naa ati lati so nipa ipade ogota odun ajo naa, ni eyi ti yoo waye niluu Abuja. Ọ̀jọ̀gbọ́n Ibrahim Yakasai, ló darí ikọ̀ náà wá sílé ààrẹ láti sọ nípa àwọn ojúṣe àti akitiyan ilé -ẹ̀kó náà àti láti sọ nípa ìpàdé ọgọ́ta ọdún àjọ náà, ní èyí tí yóò wáyé nílùú Àbújá. +Ojogbon Yakasai ni oludari ayeye ohun. Ọ̀jọ̀gbọ́n Yakasai ni olùdarí ayẹyẹ ọ̀hún. +Ojogbon King-David Yawe, to je aare ile-eko naa teleri salaye nipa awon aseyori ti WACS ti se paapaa julo nipa awon iwosan ofe ti won ti se ni pupo ninu awon agbegbe to wa lorile ede Naijiria. Ọ̀jọ̀gbọ́n King-David Yawe, tó jẹ́ ààrẹ ilé-ẹ̀kọ́ náà tẹ́lẹ̀rí sàlàyé nípa àwọn aseyọrí tí WACS ti ṣe pàápàá jùlọ nípa àwọn ìwòsàn ọ̀fẹ́ tí wọ́n ti ṣe ní púpọ̀ nínú àwọn agbègbè tó wà lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +---Orile ede Naijiria gba orisirisi ilana lati tun oju popo se. ---Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gba orísirísi ìlànà láti tún ojú pópó ṣ̣e. +Minisita fun eto ise ati ile lorile ede Naijiria, Babatunde Fashola ti fidi re mule pe lati wa orisirisi ilana fun itoju oju popo ni jake –jado orile ede Naijiria nikan lo le je ki gbogbo ona oju popo wa lee gbounje-fegbe gbawo bo lodoodun. Mínísítà fún èto iṣẹ́ àti ilẹ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Babátúndé Fásholá ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé láti wá orísirísi ìlànà fún ìtọ́jú ojú pópó ní jákè –jádò orílẹ̀ èdè Nàíjíríà nìkan ló le jẹ́ kí gbogbo ọ̀nà ojú pópó wa leè gbóúnjẹ-fẹ́gbẹ́ gbàwo bọ̀ lọ́dọọdún. +Minisita soro yii ni Ugep to wa ni ijoba ibile Yakurr, to je agbegbe ti o tobi julo nile Afirika lasiko eto ayewo ise oju popo ni ipinle Cross River. Mínísítà sọ̀rọ̀ yìí ní Ugep tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Yakurr, tó jẹ́ agbègbè tí ó tóbi jùlọ nílẹ̀ Áfíríkà lásìkò ètò àyẹ̀wò iṣẹ́ ojú pópó ní ìpínlẹ̀ Cross River. +Fasola, ti awon osise re jo kowoorin tun so pe itoju oju popo paapaa julo lasiko ojo je ojuse gbogbo awon eniyan. Fáṣọlá, tí àwon òṣìṣẹ́ rẹ̀ jọ kọ́wọ̀ọ́rìn tún sọ pé ìtọ́jú ojú pópó pàápàá jùlọ lásìkò òjò jẹ́ ojúṣe gbogbo àwọn ènìyàn. +“A duro ni oju ona Calabar-Itu, ti o maa n je wahala fun awon oloko ati eniyan lati gba lasiko ojo gege bi oju ona Calabar-Ikom-Ogoja. “A dúró ní ojú ọ̀nà Calabar-Itu, tí ó máa ń jẹ́ wàhálà fún àwọn ọlọ́kọ̀ àti ènìyàn láti gbà lásìkò òjò gẹ́gẹ́ bí ojú ọ̀nà Calabar-Ikom-Ogoja. +Nitori naa gbogbo oju ona to maa n fa wahala fun awon oloko lati gba lasiko ojo, awon bii Numanchan to lo si Taraba, Calabar-Itu, Abeokuta si Otta-Lagos – a oo wa eto ilana ti yoo je ki awon agbasese lee maa ro ti awon to n wa oko lasiko ti won ba n se ise won. Nítorí náà gbogbo ojú ọ̀nà tó máa ń fa wàhálà fún àwọn ọlọ́kọ̀ láti gbà lásìkò òjò, àwọn bíi Numanchan tó lọ sí Taraba, Calabar-Itu, Abéòkúta sí Òttà-Lagos – a óò wá ètò ìlànà tí yóò jẹ́ kí àwọn agbaṣẹ́ṣe leè máa ro ti àwọn tó ń wa ọkọ̀ lásìkò tí wọn bá ń ṣe isẹ́ wọn. +Oludari ile–ise SEMATECH, Isioma Eziashi so pe awon ipenija ti o maa n dojuko won ni owo ti awon ko tete maa ri gba bo tile je ile-ise naa ti setan lati tete pari ise naa lasiko ti won fun won. Olùdarí ilé–iṣẹ́ SEMATECH, Isioma Eziashi sọ pé àwọn ìpèníjà tí ó máa ń dojúkọ wọn ni owó tí àwọn kò tètè máa rí gbà bó tilẹ̀ jẹ́ ilé-iṣẹ́ náà ti ṣetán láti tètè parí isẹ́ náà lásìkò tí wọn fún wọn. +---Ajo eleto idibo orile ede Naijiria,( Independent National Electoral Commission ,INEC) ti fun Duoye Diri to je oludije fun ipo gomina labe egbe oselu Peoples Democratic Party (PDP) ni iwe eri gege bi gomina to jawe olubori ninu idibo to waye ni ipinle Bayelsa lodun 2019, ni ibamu pelu idajo ti ile-ejo giga to wa l’orile ede Naijiria da. ---Àjọ elétò ìdìbò orílẹ̀ èdè Nàìjíríà,( Independent National Electoral Commission ,INEC) ti fún Duoye Diri tó jẹ́ olùdíje fún ipò gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlù Peoples Democratic Party (PDP) ní ìwé ẹ̀rí gẹ́gẹ́ bí gómìnà to jáwé olúborí nínú ìdìbò tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Bayelsa lọ́dún 2019, ní ìbámu pẹ̀lú ìdájọ́ tí ilé-ẹjọ́ gíga tó wà l’órílẹ̀ èdè Nàìjíríà dá. +Komisana fun ajo INEC ni ekun ila iwo oorun arabinrin May Agbamuche-Mbu lo fun Diri ni iwe eri ohun lojo Eti niluu Abuja to je olu-ilu ajo naa to wa ni orile ede Naijiria. Kọmíṣánà fún àjọ INEC ní ẹkùn ìlà ìwọ̀ oòrùn arabìnrin May Agbamuche-Mbu ló fún Diri ní ìwé ẹ̀rí ọ̀hún lọ́jọ́ ��tì nílùú Àbújá tó jẹ́ olú-ìlú àjọ náà tó wà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Saaju eyi ni alaga ajo INEC, ojogbon Mahmood Yakubu, ti kede pe Diri gege bi olubori ninu idibo gomina ipinle naa. Sáájú èyí ni alága àjọ INEC, ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood Yakubu, ti kéde pé Diri gẹ́gẹ́ bí olúborí nínú ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ náà. +Diri wa gbosuba fun ajo INEC ati ile-ejo fun bi won se je “Eyi ti awon eniyan lee ni igbekele ninu won. Diri wá gbósùbà fún àjọ INEC àti ilé-ẹjọ́ fún bí wọ́n ṣe jẹ́ “Èyí tí àwọn ènìyàn leè ní ìgbẹkẹ̀lé nínú wọn. +"""Diri tun ni “ki Olorun wo ile Bayelsa san ati orile ede Naijiria lapapo. Olorun ti mu wa rin oju ona, ti a o maa gba lati lee ba ara wa se papo." """Diri tún ní “kí Ọlọ́run wo ilẹ̀ Bayelsa sàn àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀. Ọlọ́run ti mú wa rin ojú ọ̀nà, tí a ó máa gbà láti leè bá ara wa ṣe papọ̀." +Lojobo ni ile-ejo to ga julo lorile ede Naijiria yo David Lyon ati Biobarakuma Degi-Eremienyo kuro gege bi gomina ipinle Bayelsa Lọ́jọ́bọ̀ ní ilé-ẹjọ́ tó ga jùlọ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà yọ David Lyon ati Biobarakuma Degi-Eremienyo kúrò gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Bayelsa +---Aare Buhari de si New York fun Ipade Apero Ajo UN. ---Ààrẹ Buhari dé sí New York fún Ìpàdé Àpérò Àjọ UN. +Aare orile-ede Naijiria Muhammadu Buhari wa ni New York, fun Apero Ajo Isokan Agbaye ti o je ikerinlelaadorin (74) ipade apero iru re. Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Muhammadu Buhari wà ní New York, fún Àpérò Àjọ Ìṣòkan Àgbáyé tí ó jẹ́ ìkẹrìnléláàdọ́rin (74) ìpàdé àpérò irú rẹ̀. +Aare Buhari, eni ti o de si New York ni oganjo ojo Aiku, ti asoju orile-ede Naijiria fun ile Amerika, Sylvanus Adiewere, Minisita fun oro okeere, Geoffrey Onyama ati Minisita fun eto ilera, Osagie Ehanire ati awon miiran wa pade re. Ààrẹ Buhari, ẹni tí ó dé sí New York ní ọ̀gànjọ́ ọjọ́ Àìkú, tí aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Sylvanus Adiewere, Mínísítà fún ọ̀rọ̀ òkèèrè, Geoffrey Onyama àti Mínísítà fún ètò ìlera, Osagie Ehanire àti àwọn mìíràn wá pàde rẹ̀. +Aare Buhari ni eniti yoo je ikarun-un ninu awon ti yoo maa soro nibi Ipade Apero Ajo Isokan Agbaye ohun, ni eyi ti yoo bere lojo Isegun. Ààrẹ Buhari ni ẹnití yóò jẹ́ ìkarùn-ún nínú àwọn ti yóò máa sọ̀rọ̀ níbi Ìpàdé Àpérò Àjọ Ìṣòkan Àgbáyé ọ̀hún, ní èyí tí yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun. +Aare Buhari yoo maa soro lori isejoba ati ipinnu meta ti o fe gunle nibi isejoba re leyin ti opo omo Naijiria fibo da a pada sori alefa. Ààrẹ Buhari yóò máa sọ̀rọ̀ lórí ìṣèjọba àti ìpinnu mẹ́ta tí ó fẹ́ gúnlẹ̀ níbi ìṣèjọba rẹ̀ lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà fìbò dá a padà sórí àléfà. +Yoo si salaye awon ipo ti orile-ede Naijiria wa lori awon oran ti o kan gbogbo agbaye gbongbon. Yóò sì ṣàlàyé àwọn ipò tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà lórí àwọn ọ̀ràn tí ó kan gbogbo àgbáyé gbọ̀ngbọ̀n. +Ikopa Aare ninu ipejo awon olori orile-ede agbaye odun yii se pataki nitori o se pekinreki pelu Orile-ede Naijiria gege bi Aare Ipade Apero Ajo UN. Ìkópa Ààrẹ nínú ìpéjọ àwọn olórí orílẹ̀-èdè àgbáyé ọdún yìí ṣe pàtàkì nítorí ó ṣe pẹ̀kínrẹ̀kí pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Ìpàdé Àpérò Àjọ UN. +Akori ipade Apero Ajo Isokan Agbaye eleekerinlelaadorin (UNGA74) naa ni, ‘Igbiyanju Nilopo-ona lati Mu Osi Kuro, Eto Eko to ye Kooro ati Mimojuto Iyipada Oju-ojo ati Ifi-awon-eniyan-gbogbo-kun-eto-gbogbo. Àkórí ìpàdé Àpérò Àjọ Ìṣòkan Àgbáyé ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnléláàdọ́rin (UNGA74) náà ni, ‘Ìgbìyànjú Nílopo-ọ̀nà láti Mú Òṣì Kúrò, Ètò Ẹ̀kọ́ tó yè Kooro àti Mímójútó Ìyípadà Ojú-ọjọ́ àti Ìfi-àwọn-ènìyàn-gbogbo-kun-ètò-gbogbo. +---Arun Ebola akoko sele ni ilu Goma ni Orile-ede Ijoba Awarawa Olominira Congo. ---Àrùn Ebola àkọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ ní ìlú Goma ní Orílẹ̀-èdè Ìjọba Àwarawa Olómìnira Congo. +Awon asoju ijoba so wi pe, arun Ebola akoko seyo ni ilu Goma ni ila-oorun Orile-ede Ijoba Awarawa Olominira Congo, ni ojo Aiku, ti o n ba won leru nitori o se e se ki arun oloje naa o tan kia ni agbegbe ti o mu ala pelu orile-ede Rwanda. Àwọn aṣojú ìjọba sọ wí pé, àrùn Ebola àkọ́kọ́ ṣẹ́yọ ní ìlú Goma ní ìlà-oòrùn Orílẹ̀-èdè Ìjọba Àwarawa Olómìnira Congo, ní ọjọ́ Àìkú, tí ó ń bà wọ́n lẹ́rù nítorí ó ṣe é ṣe kí àrùn ọlọ́jẹ̀ náà ó tàn kíá ní agbègbè tí ó mú àlà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Rwanda. +O to aadota-oke kan awon eniyan to n gbe ilu Goma, t’o sunmo bebe adagundo, to ibuso 350 ni guusu apa ibi ti o sikeji agbegbe ti arun Ebola ti o po j u lo ti seyo ni bi odun kan seyin. Ó tó àádọ́ta-ọ̀kẹ́ kan àwọn ènìyàn tó ń gbé ìlú Gómà, t’ó súnmọ́ bèbè adágúndò, tó ìbùsọ̀ 350 ní gúúsù apá ibí tí ó ṣìkejì agbègbè tí àrùn Ebola tí ó pọ̀ j ù lọ ti ṣẹ́yọ ní bí ọdún kan sẹ́yìn. +Sugbon arun iba oloje naa ti n se werewere tan ka de guusu, ti o ti ran awon eniyan 2,500 ti o si pa awon 1,600. Ṣùgbọ́n àrùn ibà ọlọ́jẹ̀ náà tí ń ṣe wérewère tàn ká dé gúúsù, tí ó ti ran àwọn ènìyàn 2,500 tí ó sì pa àwọn 1,600. +Bi arun Ebola se wo ilu Goma Bí àrùn Ebola ṣ̣e wọ ìlú Goma +Gege bi awon osise ile–iwosan naa se so, alufaa ni eni ti o lugude arun naa lasiko t’o wa si ilu Butembo, ibuso 200 si ariwa Goma, nibi ti o ti sagbako awon eniyan to ni arun Ebola. Gẹ́gẹ́ bí àwọn òṣìṣẹ́ ilé–ìwòsàn náà ṣe sọ, àlùfáà ni ẹni tí ó lugúdẹ àrùn náà lásìkò t’ó wá sí ìlú Butembo, ìbùsọ̀ 200 sí àríwá Goma, níbi tí ó ti ṣàgbákò àwọn ènìyàn tó ní àrùn Ebola. +Awon ami arun naa bere si ni maa jeyo lose t’o koja lasiko ki o t o woko akeropupo lo si Goma lojo Eti. Nigba ti o de Goma lojo Aiku ni o lo sile iwosan, nibi ti ayewo ti fi han pe o ni arun Ebola. Àwọn àmì àrùn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní máa jẹyọ lọ́sẹ̀ t’ó kọ́ja lásìkò kí ó t ó wọ́kọ akéròpúpọ̀ lọ sí Goma lọ́jọ́ Ẹtì. Nígbà tí ó dé Goma lọ́jọ́ Àìkú ni ó lọ sílé ìwòsàn, níbi tí àyẹ̀wò ti fi hàn pé ó ní àrùn Ebola. +Gege bi ileese eto ilera se so “latari ijafara kefin alarun naa ati bi o ti se wa ni iyasotooto, ati isedanimo gbogbo awon ero oko lati Butembo, ewu ifonka si awon agbegbe ti o ku ni Goma kere.” won ni gbogbo ibudoko Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ètò ìlera ṣe sọ “látàrí ìjáfara kẹ́fin alárùn náà àti bí ó ti ṣe wà ní ìyàsọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àti ìṣèdánimọ̀ gbogbo àwọn èrò ọkọ̀ láti Butembo, ewu ìfọ́nká sí àwọn agbègbè tí ó kù ní Goma kéré.” wọn ní gbogbo ibùdókọ̀ +Ilu Goma ti n gbaradi fun arun Ebola lati odun to koja, siseto ibi ti awon eniyan naa yoo ti maa fi omi fo owo, ti won si tun se aridaju pe awon awakeke-alupupu ko ya ara won ni akoto. Ìlú Goma ti ń gbaradì fún àrùn Ebola láti ọdún tó kọjá, ṣíṣètò ibi tí àwọn ènìyàn náà yóò ti máa fi omi fọ ọwọ́, tí wọ́n sì tún ṣe àrídájú pé àwọn awakẹ̀kẹ́-alùpùpù kò yá ara wọn ní akoto. +Amo ni awon igberiko, arun oloje naa ti soro lati kapa. Aifokantan awon osise eleto ilera ati ija igboro ti di awon akitiyan ikapa lowo, o si ti fa ki awon ti o lugbadi o po si i. Àmọ́ ní àwọn ìgbèríko, àrùn ọlọ́jẹ̀ náà ti ṣòro láti kápá. Àìfọkàntán àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera àti ìjà ìgboro ti di àwọn akitiyan ìkápá lọ́wọ́, ó sì tí fa kí àwọn tí ó lùgbàdì ó pọ̀ sí i. +Arun Ebola maa n fa arun igbe gbuuru, eebi, ati arun iba eleje ti o le ran nipase oje ara. Àrùn Ebola máa ń fa àrùn ìgbẹ́ gbuuru, èébì, àti àrùn ibà ẹlẹ́jẹ̀ tí ó lè ràn nípase oje ara. +Ajakale kan ni aarin odun 2013 ati 2016 pa ju eniyan ti o le ni egberun mokanla (11,300) ni Iwo-oorun Ile-Adulawo. Àjàkálẹ̀ kan ní àárín ọdún 2013 àti 2016 pa ju ènìyàn tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá (11,300) ní Ìwọ̀-oòrùn Ilẹ̀-Adúláwọ̀. +WHO fesi WHO fèsì +Isele arun Ebola akoko iru e ni Orile-ede Ijoba Awarawa Olominira Congo ni ila-oorun ilu Goma je isipopada ti o se koko ninu ipele ajakale naa, Oloye Tedros Adhanom Ghebreyesus Ajo Eleto Ilera Agbaye so. Ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn Ebola àkọ́kọ́ irú ẹ̀ ní Orílẹ̀-èdè Ìjọba Àwarawa Olómìnira Congo ní ìlà-oòrùn ìlú Goma jẹ́ ìṣípòpadà tí ó ṣe kókó nínú ìpele àjàkálẹ̀ náà, Olóyè Tedros Adhanom Ghebreyesus Àjọ Elétò Ìlera Àgbáyé sọ. +Tedros so wi pe oun nireti pe ko ni si itankale arun naa ni ilu naa, sugbon o n k o awon igbimo pajawiri ajo WHO jo lati se ipinnu boya ajakale naa je eto ilera pajawiri agbaye. Tedros sọ wí pé òun nírètí pé kò ní sí ìtànkálẹ̀ àrùn náà ní ìlú náà, ṣùgbọ́n ó ń k ó àwọn ìgbìmọ̀ pàjáwìrì àjọ WHO jọ láti ṣe ìpinnu bóyá àjàkálẹ̀ náà jẹ́ ètò ìlera pàjáwìrì àgbáyé. +— Ajo Eleto Ilera Agbaye (WHO) — Àjọ Elétò Ìlera Àgbáyé (WHO) +Ibi Iwosan arun Ebola ni Goma, DRC, ti n sise lati osu Erele, ti onitohun si ti n gba itoju nibe. Gege bi igbaradi naa, osise eleto ilera 3000 ni a ti bupa fun ni ilu naa nikan. Ibi Ìwòsàn àrùn Ebola ní Goma, DRC, ti ń ṣiṣẹ́ láti oṣù Èrèlé, tí onítọ̀hún sì ti ń gba ìtọ́jú níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìgbaradì náà, òṣìṣẹ́ elétò ìlera 3000 ni a ti bupá fún ní ìlú náà nìkan. +---NMA da awon Ipinle lebi fun ipo aidara eto ilera abele ---NMA dá àwọn Ìpínlẹ̀ lẹ́bi fún ipò àìdára ètò ìlera abẹ́lé +Egbe awon Osise Onisegun Oyinbo orile-ede Naijiria, (Nigeria Medical Association, NMA), ti benu ate lu bi awon gomina ipinle se pa ile iwosan abele orile-ede naa ti segbee kan. Ẹgbẹ́ àwọn Òṣìṣẹ́ Oníṣègùn Òyìnbó orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, (Nigeria Medical Association, NMA), ti bẹnu àtẹ́ lu bí àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ ṣe pa ilé ìwòsàn abẹ́lé orílẹ̀-èdè náà tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. +Aare egbe NMA, Dr Francis Faduyile, lo so fun awon akoroyin niluu Abuja pe, bi awon gomina Ipinle lorile-ede Naijiria ko se kobiara si ile-iwosan abele lo fa a ti awon ile-iwosan naa se denu kole. Ààrẹ ẹgbẹ́ NMA, Dr Francis Faduyile, ló sọ fún àwọn akọ̀ròyìn nílùú Àbújá pé, bí àwọn gómìnà Ìpínlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò ṣe kọbiara sí ilé-ìwòsàn abẹ́lé ló fà á tí àwọn ilé-ìwòsàn náà ṣe dẹnu kọlẹ̀. +O so pe awon ijoba ipinle ti pa ile iwosan abele awon ipinle naa ti, ti o n tenu mo o wi pe won ti je ki o ni ifaseyin ti o po. Ó sọ pé àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ ti pa ilé ìwòsàn abẹ́lé àwọn ìpínlẹ̀ náà tì, tí ó ń tẹnu mọ́ ọ wí pé wọ́n ti jẹ́ kí ó ní ìfàsẹ́yìn tí ó pọ̀. +Gege bi o ti se so, ikawo awon ijoba ipinle ni awon ile iwosan abele wa ati pe akata won ni awon ile iwosan gbogbo wa, ti ijoba ipinle ko si se to ati sa ipa ni ti eyi. Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sọ, ìkáwọ́ àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ ni àwọn ilé ìwòsàn abẹ́lé wà àti pé àkàtà wọn ni àwọn ilé ìwòsàn gbogbó wà, tí ìjọba ìpínlẹ̀ kò sì ṣe tó ati sa ipá ní ti èyí. +O so pe NMA ti jara mo agbawi, yoo si ijiroro pelu ijoba ipinle lati wa ojutuu si ipo adojutini naa. Ó sọ pé NMA ti jára mo àgbàwí, yóò sì ìjíròrò pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ láti wá ojútùú sí ipò adójútini náà. +“A nireti lati lo si Apero Awon Gomina nigba miiran ti won ba ni ipade lati siju won si awon ohun ti o kan gbongbon. “A nírètí láti lọ sí Àpérò Àwọn Gómìnà nígbà mìíràn tí wọ́n bá ní ìpàdé láti ṣíjú wọn sí àwọn ohun tí ó kàn gbọ̀ngbọ̀n. +Eto ilera abele je konti ninu atunse eto ilera ni orile-ede.” Ètò ìlera abẹ́lé jẹ́ kọnti nínú àtúnṣe ètò ìlera ní orílẹ̀-èdè.” +Faduyile so pe ki Ijoba Apapo o wa nnkan se si ti iwagbe opolo ti o le se igbapada eka ilera. Faduyile sọ pé kí Ìjọba Àpapọ̀ ó wá nnkan ṣe sí ti ìwàgbẹ ọpọlọ tí ó lè ṣe ìgbàpadà ẹ̀ka ìlera. +Gege bi aare egbe NMA se so, a ti s’akiyesi wi pe ijoba ko se daadaa ninu eka ilera. Gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ẹgbẹ́ NMA ṣe sọ, a ti ṣ’àkíyèsí wí pé ìjọba kò ṣe dáadáa nínú ẹ̀ka ìlera. +Faduyile so pe lara awon igbese lati se igbapada eka ilera, NMA ti gbe igbese lati gbaruku ti Eto Madaanilofo Awujo. Faduyile sọ pé lára àwọn ìgbésẹ̀ láti ṣe ìgbàpadà ẹ̀ka ìlera, NMA ti gbé ìgbésẹ̀ láti gbárùkù ti Ètò Mádàánilófò Àwùjọ. +O so pe ajo naa yoo se atileyin fun awon ipinle ti won n se agbekale eto madaanilofo ilera ti won, won ro won lati beere fun itona lowo NMA ni ona ti o ye. Ó sọ pé àjọ náà yóò ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n ń ṣe àgbékalẹ̀ ètò mádàánilófò ìlera ti wọn, wọ́n rọ̀ wọ́n láti béèrè fún ìtọ́nà lọ́wọ́ NMA ní ọ̀nà tí ó yẹ. +---Naijiria tun ipinnu re so lati se igbelaruge eto omoniyan ---Nàìjíríà tún ìpinnu rẹ̀ sọ láti ṣe ìgbélárugẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn +Ijoba orile-ede Naijiria ti ni oun ko ni fi aye gba lilo iwa ijiya ipalara lati gba ijewo lowo eni tabi ifiyaja eni ti a fi esun kan mo. Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ní òun kò ní fi àyè gba lílọ ìwà ìjìyà ìpalára láti gba ìjẹ́wọ́ lọ́wọ́ ẹni tàbí ìfìyàja ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn mọ́. +Agbejero Agba fun Orile-ede ati Akowe Agba ni ile–ise Eto Idajo, Ogbeni Dayo Akpata l’o s’oro yii niluu Abuja, nibi ayeye lati sami si ajodun Ajo Isokan Agbaye odun 2019 ni Atileyin fun Awon ti o n Jiya ipalara. Agbẹjẹ́rò Àgbà fún Orílẹ̀-èdè àti Akọ̀wé Àgbà ní ilé–iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́, Ọ̀gbẹ́ni Dayọ̀ Akpata l’ó s’ọ̀rọ̀ yìí nílùú Àbújá, níbi ayẹyẹ láti sàmì sí àjọ̀dún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ọdún 2019 ní Àtìlẹ́yìn fún Àwọn tí ó ń Jìyà ìpalára. +Ogbeni Akpata eni ti o je onimo-egbo inu opolo so wi pe eto ominira ijiya ipalara ki i se ohun idunadura. Ọ̀gbẹ́ni Akpata ẹni tí ó jẹ́ onímọ̀-egbò inú ọpọlọ sọ wí pé ètò òmìnira ìjìyà ìpalára kì í ṣe ohun ìdúnàdúrà. +Akowe Agba naa ni egbeegberun awon eniyan, ebi ati awon legbelegbe jakejado ile-aye n jiya ara ati egbo-inu opolo latari ijiya ipalara. Akọ̀wé Àgbà náà ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún awon ènìyàn, ebi ati àwọn lẹ́gbẹ́lẹ́gbẹ́ jákèjádò ilé-ayé ń jìyà ara àti egbò-inú ọpọlọ látàrí ìjìyà ìpalára. +"O ni, “gbogbo omo orile-ede Naijiria l’o ni eto si ibowofun iyin omo-eniyan, lati ihin lo, ko si enikeni ko gbodo fiya je elomiran tabi iwa aisenia.""" "Ó ní, “gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà l’ó ní ẹ̀tọ́ sí ìbọ̀wọ̀fún ìyìn ọmọ-ènìyàn, láti ìhín lọ, kò sí ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fì̀yà jẹ ẹlòmíràn tàbí ìwà àìṣènìà.""" +Ni oro re, “orile-ede Naijiria je okan lara orile-ede ti o t’owobo iwe ajo UN l’ori ijiya ipalara ti o ka ijiya ipalara leewo. Ní ọ̀rọ̀ rẹ̀, “orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ ọ̀kan lára orílẹ̀-èdè tí ó t’ọwọ́bọ ìwé àjọ UN l’órí ìjìyà ìpalára tí ó ka ìjìyà ìpalára léèwọ̀. +"“Ofin orile-ede Naijiria ti fun Ile-Ise eto idajo l’agbara lati mu aba d’ofin itako iwa ipalara se.""" "“Òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti fún Ilé-Iṣẹ́ ètò ìdájọ́ l’ágbára láti mú àbá d’òfin ìtako ìwà ìpalára ṣe.""" +Ogbeni Hamza l’o soju fun ogbeni Akpata nibi ayeye naa . Ọ̀gbẹ́ni Hamza l’ó ṣójú fún ọ̀gbẹ́ni Akpata níbi ayẹyẹ náà . +---Igbakeji Aare Osinbajo yoo sepade pelu Mike Pence, ati awon t’o ku l’orile-ede Amerika ---Igbákejì Ààrẹ Ọ̀ṣínbájò yóò ṣèpàdé pẹ̀lú Mike Pence, àti àwọn t’ó kù l’órílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà +Igba-keji Aare Yemi Osinbajo n lo si orile Amerika, United States nibi ti yoo ti maa sepade pelu akegbe re ti o je igba-keji Aare orile-ede Amerika ogbeni Mike Pence, ati awon eniyan jankan-jankan lorile-ede naa. Igbá-kejì Ààrẹ Yẹmí Ọ̀ṣínbájò ń lọ sí orílẹ̀ Amẹ́ríkà, United States níbi tí yóò ti máa ṣẹ̀pàdè pẹ̀lú akẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ igbá-kejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ọ̀gbẹ́ni Mike Pence, àti àwọn ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn lorílẹ̀-èdè náà. +Atejade kan ti o wa lati ile-ise igba-keji Aare so pe “Igba-keji Aare ojogbon Yemi Osinbajo yoo koko se ipade pelu igbimo alase lori oro to je mo ti ile okeere lojo Aje ni New York, ki o to maa sepade pelu igba-keji Aare orile-ede Amerika ni Washington DC ni ojo Ojoru. Àtẹ̀jáde kan tí ó wà láti ilé-iṣẹ́ igbá-kejì Ààrẹ sọ pé “Igbá-kejì Ààrẹ ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí Ọ̀ṣínbájò yóò kọ́kọ́ ṣe ìpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ aláṣẹ lórí ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ti ilẹ̀ òkèèrè lọ́jọ́ Ajé ní New York, kí ó tó máa ṣèpàdé pẹ̀lú igbá-kejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní Washington DC ní ọjọ́ Ọjọ́rú. +“Lara nnkan ti igba-keji Aare, Yemi Osinbajo yoo maa ba akegbe re jiroro ni lori bi idagbasoke yoo se tubo maa gbile si i lori ibasepo t’o wa laaarin orile-ede mejeeji, bakan naa, ni igbakeji Aare Osinbajo yoo tun maa soro lori eto oro aje. “Lára nǹkan tí igbá-kejì Ààrẹ, Yẹmí Ọ̀ṣínbájò yóò máa bá akẹgbẹ́ rẹ̀ jíròrò ni lórí bí ìdàgbàsókè yóò ṣe túbọ̀ máa gbilẹ̀ sí i lórí ìbáṣẹpọ̀ t’ó wà láàárín orílẹ̀-èdè méjèèjì, bákan náà, ni igbákejì Ààrẹ Ọ̀ṣínbájò yóò tún máa sọ̀rọ̀ lórí ètò ọ̀rọ̀ ajé. +"""Igbakeji Aare fi ilu sile ni osan ojo Abameta, ireti wa pe yoo pada si Abuja ni ojo Ojobo." """Igbákejì Ààrẹ fi ìlú sílẹ̀ ní ọ̀sán ọjọ́ Àbámẹ́ta, ìrètí wa pé yóò padà sí Àbújá ní ọjọ́ Ọjọ́bọ̀." +---Muhammad-Bande di Aare Apero Ajo UN ---Muhammad-Bande di Ààrẹ Àpérò Àjọ UN +Asoju orile-ede Naijiria fun Ajo Isokan Agbaye (United Nations) Tijjani Muhammad-Bande ni o ti jawe olubori gege bi Aare kerinlelaaadorin Apero Ajo Isokan Agbaye. Aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún Àjọ Ìṣòkan Àgbáyé (United Nations) Tijjani Muhammad-Bande ni ó ti jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ kẹrìnléláàádọ́rin Àpérò Àjọ Ìṣòkan Àgbáyé. +Muhammad-Bande, nikan l’o dije fun ipo yii, a dibo yan an nipase pipa ohun po lasiko ipade apero ajo agbaye ketadinlaadorun-un t’o waye ni New York lojo Isegun, ojo kerin osu kefa. Muhammad-Bande, nìkan l’ó díje fún ipò yìí, a dìbò yàn án nípasẹ̀ pípa ohùn pọ̀ lásìkò ìpàdé àpérò àjọ àgbáyé kẹ́tàdínláàdọ́rùn-ún t’ó wáyé ni New York lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹrin oṣù kẹfà. +Oun ni yoo je omo Naijiria keji ti yoo di ipo naa mu leyin ti ajagun feyin ti Joseph Garba ti o je asoju tele ri ati ogbon oselu, eni ti o dari iko naa laaarin odun 1980 si 1990. Òun ni yóò jẹ́ ọmọ Nàìjíríà kejì tí yóò di ipò náà mú lẹ́yìn tí ajagun fẹ̀yìn tì Joseph Garba tí ó jẹ́ aṣojú tẹ́lẹ̀ rí àti ọgbọ́n òṣèlú, ẹni tí ó darí ikọ̀ náà láàárín ọdún 1980 sí 1990. +Osu Kesan-an odun 2019 ni o bere ise. Oṣù Kesan-an ọdún 2019 ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. +---Awon omo orile-ede Naijiria ni eyin odi n s’alagbaawi fun idibo lati ilu okeere. ---Awon ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ẹ̀yìn odi ń ṣ’alágbàáwí fún ìdìbò láti ìlú òkèèrè. +Won ti ro gbogbo awon omo orile-ede Naijiria to n gbe ni ilu okeere lati se agbawi fun ofin ti yoo gba won laaye lati maa dibo lasiko eto idibo nibikibi leyin odi. Wọ́n ti rọ gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń gbé ní ìlú òkèèrè láti ṣe àgbáwí fún òfin tí yóò gbà wọ́n láàyè láti máa dìbò lásìkò ètò ìdìbò níbikíbi lẹ́yìn odi. +Alaga, Ajo Awon Omo orile-ede Naijiria nile okeere, ti o tun je Oludamoran Pataki fun Aare Muhammadu Buhari, Abike Dabiri-Erewa, l’o pe ipe yii lasiko apeje ti won se fun awon asoju omo egbe APC t’o n gbe niluu okeere, ni ilu Abuja, orile-ede Naijiria. Alága, Àjọ Àwọn Ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nílẹ̀ òkèèrè, tí ó tún jé Olùdámọ̀ràn Pàtàkì fún Ààrẹ Muhammadu Buhari, Àbíkẹ́ Dábírí-Erewa, l’ó pe ìpè yìí lásìkò àpèjẹ tí wọ́n ṣe fún àwọn aṣojú ọmọ ẹgbẹ́ APC t’ó ń gbé nílùú òkèèrè, ní ìlú Àbújá, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +""" e seun pupo ti e wa sile nitori wi pe e fe wa darapo mo eto ifinijoye Aare Buhari." """ ẹ ṣéun púpọ̀ tí ẹ wá sílé nítorí wí pé ẹ fẹ́ wá darapọ̀ mọ́ ètò ìfinijoyè Ààrẹ Buhari." +Gbogbo yin ni e ti se ise takuntakun fun aseyori re, pelu oore-ofe Olorun ati ipinnu, Aare ba a yin soro lanaa, ko ni ja gbogbo yin kule. Gbogbo yín ni ẹ ti ṣe iṣẹ́ takuntakun fún àṣeyọrí rẹ̀, pẹ̀lú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti ìpinnu, Ààrẹ bá a yín sọ̀rọ̀ lánàá, kò ní já gbogbo yín kulẹ̀. +"O ni "" Oun ti mo lero pe ilepa ti o se Pataki ju lo fun wa ni aseyege idibo lati ilu okeere." "Ó ní "" Oun tí mo lérò pé ìlépa tí ó ṣe Pàtàkì jù lọ fún wa ni àṣeyege ìdìbò láti ìlú òkèèrè." +Gbogbo wa ni a ni lati sise po lati se aseyori. Gbogbo wa ni a ní lati ṣiṣẹ́ pọ̀ lati ṣe àṣeyọrí. +O so “Mo fe ro gbogbo yin, bi Apejo kesan-an se n ile wole, e je ki a bere lesekese, ki a gbiyanju lati lo si Igbimo-asofin, k’a si ko si won lemii lati ri i daju wi pe awon omo orile-ede Naijiria ni eyin odi lati le dibo, nitori naa o se koko”. Ó sọ “Mo fẹ́ rọ̀ gbogbo yín, bí Àpéjọ kẹsàn-án ṣe ń ilé wọlé, ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kí á gbìyànjú láti lọ sí Ìgbìmọ̀-aṣòfin, k’á sì kó sí wọn lẹ́mìí láti rí i dájú wí pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ẹ̀yìn odi láti lè dìbò, nítorí náà ó ṣe kókó”. +O so “ni bayii e ti ni Ajo Omo orile-ede nile okeere, e fowosowopo pelu Ajo naa, ki eyi ba le di mimuse, bi awon orile-ede kerejekereje ba lee se e, mi ko ri idi kan ti awon Omo orile-ede Naijiria ko lee dibo”. Ó sọ “ní báyìí ẹ ti ní Àjọ Ọmọ orílẹ̀-èdè nílẹ̀ òkèèrè, ẹ fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Àjọ náà, kí èyí ba lè di mímúṣẹ, bí àwọn orílẹ̀-èdè kéréjekéréje bá leè ṣe é, mi kò rí ìdí kan tí àwọn Ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò leè dìbò”. +"O tenumo "" yoo je ogun ti o soro lati ja, sugbon a gbodo se aridaju wi pe idibo leyin odi di amuse”." "Ó tẹnumọ "" yóò jẹ́ ogun tí ó ṣòro láti jà, ṣùgbọ́n a gbọdọ̀ ṣe àrídájú wí pé ìdìbò lẹ́yìn odi di àmúṣẹ”." +---Aare Buhari forile orile-ede Saudi Arabia fun Ipade apero OIC. ---Ààrẹ Buhari forílé orílẹ̀-èdè Saudi Arabia fún Ìpàdé àpérò OIC. +Aare Muhammadu Buhari ti fi Abuja sile lati lo fun Ipade apero Egbe Ajumose awon Elesin Islam, OIC niluu Makkah ni orile-ede Saudi Arabia. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti fi Abuja sílẹ̀ láti lọ fún Ìpàdé àpérò Ẹgbẹ́ Àjùmọ̀ṣe àwọn Ẹlẹ́sìn Islam, OIC nílùú Makkah ní orílẹ̀-èdè Saudi Arabia. +Ipade apero gbogbogboo OIC eleekerinla iru re, ti yoo waye lojo Eti (Friday) ojokankandinlogbon, osu Karun-un, ti Oba Salman Abdulaziz Al Saud yoo gbalejo, ti awon Olori orile-ede ti won je omo egbe ajo naa yoo lo fun. Ìpàdé àpérò gbogbogboò OIC ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá irú rẹ̀, tí yóò wáyé lọ́jọ́ Ẹtì (Friday) ọjọ́kankàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Karùn-ún, tí Ọba Salman Abdulaziz Al Saud yóò gbàlejò, tí àwọn Olórí orílẹ̀-èdè tí wọn jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àjọ náà yóò lọ fún. +"Gege bi ile-ise Akowe egbe OIC se fi lede, akori ipade apero naa ni: “Apero Makkah al-Mukarramah: Ifowosowopo fun ojo-ola "" lati mu idagbasoke ba isokan awon elesin Musulumi lagbaaye." "Gẹ́gẹ́ bí ilé-iṣẹ́ Akọ̀wé ẹgbẹ́ OIC ṣe fi léde, àkórí ìpàdé àpérò naa ni: “Àpérò Makkah al-Mukarramah: Ìfọwọ́sọwọ́pọ̀ fún ọjọ́-ọ̀la "" láti mú ìdàgbàsókè bá ��ṣọ̀kan àwọn ẹlẹ́ṣin Mùsùlùmí lágbàáyé." +Aare Buhari yoo soro nibi ipade naa ati imenuba idi ti awon orile-ede ti won je omo egbe ajo naa fi gbodo fimo-sokan, lati sise papo lati gbogun ti awon ipenija bi i iwa idunkooko-moni ati laasigbo awon alakata-kiti. Ààrẹ Buhari yóò sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé náà àti ìmẹ́nuba ìdí tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àjọ náà fi gbọdọ̀ fìmọ̀-ṣọ̀kan, láti ṣiṣẹ́ papọ̀ láti gbógun ti àwọn ìpèníjà bí i ìwà ìdúnkookò-mọ́ni àti làásìgbò àwọn alákata-kítí. +---Naijiria rawo ebe iranwo si U.S lati koju isoro airisese. ---Nàìjíríà rawọ́ ẹ̀bẹ̀ ìrànwọ́ sí U.S láti kojú ìṣòro àìríṣẹ́ṣe. +Orile-ede Naijiria n beere fun iranlowo lati odo orile-ede Ipinle Isokan Amerika lati gbogun ti isoro airise lorile-ede naa. Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń béèrè fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ orílẹ̀-èdè Ìpínlẹ̀ Ìṣọ̀kan Amẹ́ríkà láti gbógun ti ìṣòro àìríṣẹ́ lorílẹ̀-èdè náà. +"Akowe Agba fun Ajo to-n-ri-si eto ise ati Igbanisise (Federal Ministry of Labour and Employment), William Alo, so pe orile-ede Naijiria nilo iranlowo lati odo U.S lati “doju ija ko ipenija airise to n koju orile-ede naa.""" "Akọ̀wé Àgbà fún Àjọ tó-ń-rí-sí ètò iṣẹ́ àti Ìgbanisíṣẹ́ (Federal Ministry of Labour and Employment), William Alo, sọ pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nilo ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ U.S láti “dojú ìjà kọ ìpèníjà àìríṣé tó ń kojú orílẹ̀-èdè náà.""" +Lasiko t’o n gba iko Eka ile-ise eto ise lati orile-ede Amerika, ti Kurt Petermeyer, eni ti o je Alaboojuto Eka Isakoso Eto aabo ati Ilera se adari, ogbeni Alo so pe iranlowo lati odo U.S. lati mu awon ibi ikoni ni ogbon imoose yoo se anfaani ribiribi fun orile-ede Naijiria, ni ti imudara ipese ise. Lásìkò t’ó ń gba ikọ̀ Èka ilé-iṣé ètò iṣẹ́ láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tí Kurt Petermeyer, ẹni tí ó jẹ́ Alábòójútó Èka Ìṣàkóso Ètò ààbò àtì Ìlera ṣe adarí, ọ̀gbẹ́ni Alo sọ pé ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ U.S. láti mú àwọn ibi ìkọ́ni ní ọgbọ́n ìmọ̀ọ̀ṣe yóò ṣe ànfààní ribiribi fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ní ti ìmúdára ìpèsè iṣẹ́. +---Aare Buhari tesiwaju ninu eto ilana esin ni Makkah ---Ààrẹ Buhari tẹ̀síwájú nínú ètò ìlànà ẹ̀sìn ní Makkah +Aare Muhammadu Buhari de si Makkah, ni Saudi Arabia, lati ilu Madinah nibi ti o ti bere igbese ti o siwaju ise Umrah ni Ile-oba naa. Ààrẹ Muhammadu Buhari dé sí Makkah, ní Saudi Arabia, láti ìlú Madinah níbi tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ tí ó ṣíwájú iṣẹ́ Umrah ní Ilẹ̀-ọba náà. +Leyin adura asale ni Mosalasi Ojise nla, a mu Aare lo si iboji ojise nla Mohammed nibiti o ti gbadura fun orile ede, ebi re ati oun funra re. Lẹ́yìn àdúrà àṣálẹ́ ní Mọ́sálásí Òjíṣẹ́ ńlá, a mú Ààrẹ lọ sí ibojì òjíṣẹ́ ńlá Mohammed níbití ó ti gbàdúrà fún orílẹ̀ èdè, ẹbí rẹ̀ àti òun fúnra rẹ̀. +Gomina ekun Madinah Prince Khalid Bin Faisal Al-Saud, sin aare jade ni Papako Ofuurufu ti Prince Mohammed Bin Abdulaziz Madina International Airport. Gómìnà ẹkùn Madinah Prince Khalid Bin Faisal Al-Saud, sin ààrẹ jáde ní Pápákọ̀ Òfuurufú tí Prince Mohammed Bin Abdulaziz Madina International Airport. +Gomina agbegbe Makkah, Prince Khalid Bin Faisal Al-Saud ni o ki Aare kaabo ni Makkah. Gómìnà agbègbè Makkah, Prince Khalid Bin Faisal Al-Saud ni ó kí Ààrẹ káàbọ̀ ní Makkah. +Bakannaa lara awon t’o wa lati tewogba Aare ni Asoju orile ede Naijiria ni Saudi Arabia, Onidajo toti feyinti Isa Dodo, oga agba pata fun Ajo Otelemuye, Asoju Ahmed Rufa’i Abubakar ati awon osise Asoju ijoba orile ede Nigeria ni Jeddah. Bákannáà lára àwọn t’ó wá láti tẹ́wọ́gba Ààrẹ ni Aṣojú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní Saudi Arabia, Onídájọ́ tóti fẹ̀yìntì Isa Dodo, ọ̀gá àgbà pátá fún Àjọ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, Aṣojú Ahmed Rufa’i Abubakar àti àwọn òṣìṣẹ́ Aṣojú ìjọba orílẹ̀ èdè Nigeria ní Jeddah. +Leyin igbalejo, logan ni o bere ise Umrah ni asale ojo eti. Lẹ́yìn ìgbàlejò, lógán ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Umrah ní àṣálẹ́ ọjọ́ ẹtì. +---Aare Buhari yoo wa ni Saudi Arabia lati se awon ilana-esin ti Umrah. ---Ààrẹ Buhari yóò wà ní Saudi Arabia láti ṣe àwọn ìlànà-ẹ̀sìn ti Umrah. +Aare orile-ede Naijiria Muhammadu Buhari ti gba iwe ipe lati odo Oba ti Saudi Arabia, Salman Bin Abdulaziz, lati wa se awon ilana-esin Umrah (irinajo ile-mimo kekere) ni orile-ede naa. Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Muhammadu Buhari ti gba ìwé ìpè láti ọ̀dọ̀ Ọba ti Saudi Arabia, Salman Bin Abdulaziz, láti wá ṣe àwọn ìlànà-ẹ̀sìn Umrah (ìrìnàjò ilẹ̀-mímọ́ kékeré) ní orílẹ̀-èdè náà. +Lara awon ti yoo tele Aare lo si orile-ede Saudi Arabia ni awon oluranlowo re pataki, Aare yoo gunle si orile-ede Saudi Arabia ni ojo Ojobo, ojo kerindinlogun, osu Karun-un. Lára àwọn ti yóò tẹ̀lé Ààrẹ lọ sí orílẹ̀-èdè Saudi Arabia ni àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ pàtàkì, Ààrẹ yóò gúnlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Saudi Arabia ní ọjọ́ Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Karùn-ún. +---Orile-ede Naijiria ati Angola yoo fowosowopo lati mu eto aabo agbegbe-sagbegbe gbopon si i. ---Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Angola yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ láti mú ètò ààbò agbègbè-ságbègbè gbópọn sí i. +Orile-ede Naijiria ati Angola yoo fowosowopo lati jo mu ki eto alaafia o ga si i, idurosinsin ati eto aabo ni ekun ile-Adulawo papaa ju lo ni Iwo-oorun ati agbegbe Aarin-gbungbun ile-Adulawo. Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Angola yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ láti jọ mú kí ètò àlàáfíà ó ga sí i, ìdúróṣinṣin àti ètò ààbò ni ẹ̀kùn ilẹ̀-Adúláwọ̀ papàá jù lọ ní Ìwọ̀-oòrùn àti agbègbè Àárín-gbùngbùn ilẹ̀-Adúláwọ̀. +Orile-ede mejeeji naa jo t’owobo iwe adehun leyin ipade kan laaarin Minisita to n ri si oro to je mo ile okeere, Geoffrey Onyeama ati Minisita fun Ibasepo Orile-ede Okeere ti Orile-ede Angola, Manuel Augusto, ni ojo Ojoru niluu Abuja. Orílẹ̀-èdè méjèèjì náà jọ t’ọwọ́bọ ìwé àdéhùn leyin ìpàdé kan láàárín Mínísítà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ilẹ̀ òkèèrè, Geoffrey Onyeama àti Mínísítà fún Ìbáṣepọ̀ Orílẹ̀-èdè Òkèèrè ti Orílẹ̀-èdè Angola, Manuel Augusto, ni ọjọ́ Ọjọ́rú nílùú Àbújá. +Augusto ati Onyeama ni won jo towobo iwe adehun naa. Augusto àti Onyeama ni wọ́n jọ tọwọ́bọ ìwé àdéhùn náà. +Orile-ede mejeeji naa jo forikori lori ona ti won yoo gba mu eto iselu, awujo ati oro-aje rinle ati ajosepo asa ni itesiwaju agbese idagbasoke orile-ede mejeeji ati Ile-Adulawo naa. Orílẹ̀-èdè méjèèjì náà jọ foríkorí lórí ọ̀nà tí wọn yóò gbà mú ètò ìṣèlú, àwùjọ àti ọrọ̀-ajé rinlẹ̀ àti àjọṣepọ̀ àṣà ní ìtẹ̀síwájú àgbéṣe ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè méjèèjì àti Ilẹ̀-Adúláwọ̀ náà. +Awon orile-ede mejeeji ti gba awon wahala, awon ipenija iyipada oju-ojo ati iwa ipaniyan. Àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì ti gba àwọn wàhálà, àwọn ìpèníjà ìyípadà ojú-ọjọ́ àti ìwà ìpànìyàn. +Won pinnu lori koko ajosepo igbese lati gbogunti, gbogbo irokeke imuro idagbasoke awon orile-ede mejeeji ati Ile-Adulawo. Wọ́n pinnu lórí kókó àjọṣepọ̀ ìgbésẹ̀ láti gbógunti, gbogbo ìrókẹ́kẹ́ ìmúró ìdàgbàsókè àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì àti Ilẹ̀-Adúláwọ̀. +Awon orile-ede mejeeji naa yoo tun jo maa jiroro lori pipese eto alaafia to yi dande, idurosinsin ati eto aabo ni agbegbe naa. Àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì náà yóò tún jọ máa jíròrò lórí pípèsè ètò àlàáfíà to yí dandé, ìdúróṣinṣin àti ètò ààbò ní agbègbè náà. +---Ile igbimo asofin f’onte lu Abike Dabiri-Erewa gege bi adari Ajo Eyin odi ---Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin f’ọ̀ǹtẹ̀ lu Àbíké Dábírí-Erewa gẹ́gẹ́ bí adarí Àjọ Ẹ̀yìn odi +Ile igbimo asofin ti f’onte lu ipinnu Aare Muhammadu Buhari lati fi Abike Dabiri-Erewa se Oga-agba/Alaga Ajo Oro-to-je-mo-ile-okeere paapaa julo oro t’o ba kan omo orile-ede Naijiria nile okeere. Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti f’ọ̀ǹtẹ̀ lu ìpinnu Ààrẹ Muhammadu Buhari láti fi Àbíkẹ́ Dábírí-Erewa ṣe Ọ̀gá-àgbà/Alága Àjọ Ọ̀rọ̀-tó-jẹ-mọ́-ilẹ̀-òkèèrè pàápàá jùlọ ọ̀rọ̀ t’ó bá kan ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nílẹ̀ òkèèrè. +Iyaafin Dabiri-Erewa, t’o je omo ile igbimo asoju teleri, ni Oluranlowo Pataki lori oro to je mo ile okeere fun Aare Buhari lowolowo. Ìyáàfin Dábírí-Erewa, t’ó jẹ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojú tẹ́lẹ̀rí, ni Olùrànlọ́wọ́ Pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ilẹ̀ òkèèrè fún Ààrẹ Buhari lọ́wọ́lọ́wọ́. +"O ni “leyin ti igbimo asofin ti pari iwadii finnifinni won tan lori iwe eri eko-atise ati awon iwe miiran nipa awon eni-a-yan, ti otito re, irita, ibamu, ikaju-osuwon ati iriri re ninu eto oselu ati ise ilu si te won lorun, igbimo naa ri Eni-owo Abike Dabiri Erewa bi eni ti o danto ati eni ti ipo alaga/oga-agba yanyan Ajo oro omo orile-ede Naijiria ni ile okeere""." "Ó ní “lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ aṣòfin ti parí ìwádìí fínnífínní wọn tán lórí ìwé ẹ̀rí ẹ̀kọ́-àtiṣẹ́ àti àwọn ìwé mìíràn nípa àwọn ẹni-a-yàn, tí òtítọ́ rẹ̀, ìríta, ìbámu, ìkájú-òṣùwọ̀n àti ìrírí rẹ̀ nínú ètò òṣèlú àti iṣẹ́ ìlú sì tẹ́ wọn lọ́rùn, ìgbìmọ̀ náà rí Ẹni-ọ̀wọ̀ Àbíkẹ́ Dábírí Erewa bí ẹni tí ó dántọ́ àti ẹni tí ipò alága/ọ̀gá-àgbà yányán Àjọ ọ̀rọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ilẹ̀ òkèèrè""." +O ni pe Dabiri-Erewa yege lati bo si ipo naa leyin ti awon igbimo ti se ayewo finnifinni ni ibamu pelu alaale ofin orile-ede Naijiria. Ó ní pé Dábírí-Erewa yege láti bọ́ sí ipò náà lẹ́yìn tí àwọn ìgbìmọ̀ ti ṣe àyẹ̀wò fínnífínní ní ìbámu pẹ̀lú àlàálẹ̀ òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Asofin Oko s’afikun wi pe eni-a-fa-sile naa gba imo ijinle ninu Ona (ede Geesi) lodun 1983; o tesiwaju ninu eko imo ijinle lati tun gba oye miiran ninu eko Ibaraenisoro Olopo lodun 1986, o si tun ni iwe-eri akosemose lati Ileewe imo eko Isejoba John Kennedy, ti Fafiti Harvard, lorile-ede United States, ni osu kefa Odun 2002. Aṣòfin Oko ṣ’àfikún wí pé ẹni-a-fà-sílẹ̀ náà gba ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú Ọnà (èdè Gẹ̀ẹ́sì) lọ́dún 1983; ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ láti tún gba oyè mìíràn nínú ẹ̀kọ́ Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ Ọlọ́pọ̀ lọ́dún 1986, ó sì tún ní ìwé-ẹ̀rí akọ́ṣẹ́mọṣẹ láti Iléèwé ìmọ̀ ẹ̀kó Ìṣèjọba John Kennedy, ti Fáfit̀i Harvard, lórílẹ̀-èdè United States, ní oṣù kẹfà Ọdún 2002. +---Iji-lile kolu ilu ile-isin l’orile-ede India leyin ti opo eniyan sa kuro nibugbe won ---Ìjì-líle kọlu ìlú ilé-ìsìn l’órílé-ẹ̀dè India lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sá kúrò níbùgbé wọn +Opo eniyan ni o ti padanu ibugbe won, ti awon miiran si padanu ohun ini won ni agbegbe Puri, lorile-ede India latari isele iji lile ti o waye lojo Eti, Iroyin fi mule pe, iji lile naa ba awon ohun amayederun je pupo bii opo ina mona-mona, opo ero ibanisoro abbl. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ti pàdánù ibùgbé wọn, tí àwọn míìrán sì pàdánù ohun ìní wọn ní agbègbè Puri, lórílé-èdè India látàrí ìṣèlè ìjì líle tí ó wáyé lọ́jó Ẹtì, Iròyìn fi múlẹ̀ pé, ìjì líle náà ba àwọn ohun amáyéderùn jẹ́ púpọ̀ bíi òpó iná mọ̀nà-mọ́ná, òpó ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ abbl. +Gege bi ajo to n mojuto isele pajawiri, won ni isele iji lile naa koko sose ni eka ila oorun ilu Bengal ki o to sun lo si Ipinle Odisha ni aago mejo owuro. Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, wọ́n ní ìṣẹ̀lẹ̀ ìjì líle náà kọ́kọ́ ṣọṣẹ́ ní ẹ̀ka ìlà oòrùn ìlú Bengal kí ó tó sún lọ sí Ìpínlẹ̀ Odisha ní aago mẹ́jọ òwúrọ̀. +---Opo farapa yanayana, enikan padanu emi re ninu ikolu Venezuela. ---Ọ̀pọ̀ farapa yánayàna, ẹnìkan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìkọlù Venezuela. +Ninu ikolu ti o waye lorile-ede Venezuela laaarin omo-ogun ijoba orile-ede naa ati awon ololufe egbe oselu alatako ni ojo Ojoru, iroyin fi mule pe omobinrin kan padanu emi re latari ota ibon ti o fara gba, ti opo eniyan si farapa yanayana. Nínú ìkọlù tí ó wáyé lórílẹ̀-èdè Venezuela láàárín ọmọ-ogun ìjọba orílè-èdè náà àti àwọn olólùfẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ní ọjọ́ Ọjọ́rú, ìròyìn fi múlẹ̀ pé ọmọbìnrin kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ látàrí ọta ìbọn tí ó fara gbà, tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì farapa yánayàna. +Adari egbe oselu alatako ohun, Juan Guaido ti pe lati sawari awon ti o ba wa nidii iku omobinrin omo odun metadinlogbon naa. Adarí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ọ̀hún, Juan Guaidó ti pè láti ṣàwárí àwọn tí ó bá wà nídìí ikú ọmọbìnrin ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n náà. +O wa ro awon osise ni ojo Ojobo lati wa fi ehonu won han, eleyii ti o si le e s’okunfa idasile. Ó wá rọ àwọn òṣìṣẹ́ ní ọjọ́ Ọjọ́bọ̀ láti wá fi èhónú wọn hàn, eléyìí tí ó sì le è ṣ’okùnfà ìdásílẹ̀. +Ogbeni Guaido kede ara re gege bi oludari ijoba orile-ede Venezuela losu Kinni odun ti a wa yii, bee si ni opo orile-ede ti o lamii-laaka lagbaaye bi ile Amerika, UK abbl satileyin fun lati tuko orile-ede naa. Ọ̀gbẹ́ni Guaidó kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi olùdarí ìjọba orílè-èdè Venezuela lóṣù Kinní ọdún tí a wà yìí, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀pọ̀ orílè-èdè tí ó làmìi-laaka lágbàáyé bí ilẹ̀ Amẹ́ríkà, UK abbl ṣàtilẹ́yìn fún láti túkọ̀ orílè-èdè náà. +Aare benu ate lu iroyin aheso kan ti o so pe Oun fe fi orile-ede oun sile, bee si ni o tun fesun kan orile-ede Amerika fun dida oro naa lona ti o to. Ààrẹ bẹnu àtẹ lu ìròyìn àhẹ́sọ kan tí ó sọ pé Òun fẹ́ fi orílè-èdè òun sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ó tún fẹ̀sùn kan orílè-èdè Amẹ́ríkà fún dídá ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tí ò tọ̀. +---Ipade apero lori idagbasoke eto oro-aje laaarin orile-ede Naijiria-UK waye niluu Abuja. ---Ìpàdé àpérò lórí ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀-ajé láàárín orílẹ̀-èdè Nàìjíríà-UK wáyé nílùú Àbújá. +Igbakeji Aare orile-ede Naijiria, Ojogbon Yemi Osinbajo, ti ni pupo ninu awon onisowo l’o ti nifee lati da eto okoowo sile lorile-ede Naijiria bayii. Igbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí Òsínbàjò, ti ní púpọ̀ nínú àwọn oníṣòwò l’ó ti nífẹ̀ẹ́ láti dá ètò okòòwò sílẹ̀ lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà báyìí. +Igbakeji Aare soro yii lasiko ipade apero lori eto oro aje laaarin orile-ede Naijiria ati UK, ni eyi ti o je akoko iru re ti o waye ni Ile Agbara Aare, niluu Abuja. Igbákejì Ààrẹ sọ̀rọ̀ yìí lásìkò ìpàdé àpérò lórí ètò ọrọ̀ ajé láàárín orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti UK, ní èyí tí ó jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tí ó wáyé ní Ilé Agbára Ààrẹ, nílùú Àbújá. +Osu keje odun 2018 ni Aare Muhammadu Buhari ati oludari ijoba niluu London, Theresa May, towobo iwe adehun lasiko Ipade apero lori idagbasoke eto oro-aje laaarin orile-ede Naijiria ati orile-ede United Kingdom. Oṣù kéje ọdún 2018 ni Ààrẹ Muhammadu Buhari àti olùdarí ìjọba nílùú London, Theresa May, tọwọ́bọ ìwé àdéhùn lásìkò Ìpàdé àpérò lórí ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀-ajé láàárín orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti orílẹ̀-èdè United Kingdom. +Gege bi Igbakeji Aare se so, “awon onisowo ti won nifee lati da okoowo won sile lorile-ede Naijiria tun ti po si bayii laaarin odun 2017 si odun 2018. Gẹ́gẹ́ bí Igbákejì Ààrẹ ṣe sọ, “àwọn oníṣòwò tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti dá okòòwò wọn sílẹ̀ lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà tún ti pọ̀ si báyìí láàárín ọdún 2017 si ọdún 2018. +---Aare Buhari p’ase fun Adajo Agba orile-ede Naijiria lati da si oran Zainab ---Ààrẹ Buhari p’àṣẹ fún Adájọ́ Àgbà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti dá sí ọ̀ràn Zainab +Aare Muhammadu Buhari ti p’ase fun Adajo Agba orile-ede ati Minisita fun Eto idajo ogbeni Abubakar Malami, lati wa woroko fi sada nipa gbigbe igbese lori bi won yoo se yo arabinrin Zainab Aliyu, to je akekoo, ti awon odaran kan ko sinu wahala nipa gbigbe oogun oloro sinu eru re, ti o si wa ni igbekun ijoba orile-ede Saudi Arabia. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti p’àṣẹ fún Adájọ́ Àgbà orílẹ̀-èdè àti Mínísítà fún Ètò ìdájọ́ ọ̀gbẹ́ni Abubakar Malami, láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá nípa gbígbé ìgbésẹ̀ lórí bí wọn yóò ṣe yọ arábìnrin Zainab Aliyu, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́, tí àwọn ọ̀daràn kan kó sínú wàhálà nípa gbígbé oògùn olóró sínú ẹrù rẹ̀, tí ó sì wà ní ìgbèkùn ìjọba orílẹ̀-èdè Saudi Arabia. +Ninu atejade kan ti Abdur-Rahman Balogun, oluranlowo lori Iroyin fun Eni-owo Abike Dabiri, Oludamoran Pataki Agba fun Aare lori Oro omo Naijiria ni ile okeere, gbe jade niluu Abuja so wi pe Aare pa ase naa ni ose meji seyin nigbati oran naa to oun leti. Nínú àtẹ̀jáde kan tí Abdur-Rahman Balógun, olùrànlọ́wọ́ lórí Ìròyìn fún Ẹni-ọ̀wọ̀ Àbíkẹ́ Dábírí, Olùdámọ̀ràn Pàtàkì Àgbà fún Ààrẹ lórí Ọ̀rọ̀ ọmọ Nàìjíríà ní ilẹ̀ òkèèrè, gbé jáde nílùú Àbújá sọ wí pé Ààrẹ pa àṣẹ náà ní ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn nígbàtí ọ̀ràn náà tó òun létí. +“Aare Muhammadu Buhari pa ase naa nikete ti o gbo isele ohun ni ose meji seyin. “Ààrẹ Muhammadu Buhari pa àṣẹ náà níkété tí ó gbọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ní ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn. +“Ibi-ise mi ti n sise pelu Adajo Agba orile-ede Naijiria ati Ajo t’o n ri si oro t’o jemo ti ile okeere lori oro naa”. “Ibi-iṣẹ́ mi ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Adájọ́ Àgbà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Àjọ t’ó ń rí sí ọ̀rọ̀ t’ó jẹmọ́ ti ilẹ̀ òkèèrè lórí ọ̀rọ̀ náà”. +Oluranlowo Aare fi daniloju wi pe ise n tesiwaju ninu oran Zainab, pelu awon meji miiran ti o wa ninu ipo kan naa ni ile Saudi Arabia. Olùrànlọ́wọ́ Ààrẹ fi dánilójú wí pé iṣẹ́ ń tẹ̀síwájú nínú ọ̀ràn Zainab, pẹ̀lú àwọn méjì mìíràn tí ó wà nínú ipò kan náà ní ilẹ̀ Saudi Arabia. +Dabiri-Erewa so wi pe, loooto Zainub wa ni atimole, ijoba ile Saudi Arabia ko tii fi oju re ba ile ejo. Ti o si le lati gba eri wi pe won ti mu awon ti won ko ba a gbo, ejo ti o lagbara ni a fe pe awon alase Saudi. Dábírí-Erewa sọ wí pé, lóòótọ́ Zainub wà ní àtìmọ́lé, ìjọba ilẹ̀ Saudi Arabia kò tíì fi ojú rẹ̀ ba ilé ẹjọ́. Tí ó sì le láti gba ẹ̀rí wí pé wọ́n ti mú àwọn tí wọ́n kó bá a gbọ́, ẹjọ́ tí ó lágbára ni a fẹ́ pe àwọn aláṣẹ Saudi. +Ajo JAMB se idanwo ni orile-ede meje ni ilu okeere. Àjọ JAMB ṣe ìdánwò ní orílẹ̀-èdè méje ní ìlú òkèèrè. +Ajo to n mojuto idanwo fun awon t’o fe wo fafiti, ile-eko gbogbonise ati ile-eko awon oluko l’orile-ede Naijiria ti se idanwo fun awon omo orile-ede yii to wa niluu okeere ati awon omo orile-ede miiran ti won fe tesiwaju nipa eko won ni orile-ede Naijiria. Àjọ tó ń mójútó ìdánwò fún àwọn t’ó fẹ́ wọ fáfitì, ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe àti ilé-ẹ̀kọ́ àwọn olùkọ́ l’órílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ṣe ìdánwò fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí tó wà nílùú òkèèrè àti àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn tí wọ́n fẹ́ tẹ̀síwájú nípa ẹ̀kọ́ wọn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Igbimo naa ni awon seto idanwo yii lati je ki gbogbo awon omo orile-ede Naijiria t’o wa nile okeere ati awon omo orile-ede miiran to nifee lati kekoo ni Ileeko-giga t’o ye kooro l’orile ede Naijiria ni anfaani kan naa. Ìgbìmọ̀ náà ní àwọn ṣètò ìdánwò yìí láti jẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà t’ó wà nílẹ̀ òkèèrè àti àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn tó nífẹ̀ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ní Ilẹ́ẹ̀kọ́-gíga t’ó yé kooro l’órílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní àǹfààní kan náà. +Awon orile-ede ti ajo naa ti se idanwo naa ni orile-ede Ghana, United Kingdom, Cameroon, Benin Republic, Cote d’Ivoire, South Africa ati Ile-oba Saudi Arabia. Àwọn orílẹ̀-èdè tí àjọ náà ti ṣe ìdánwò náà ní orílẹ̀-èdè Ghana, United Kingdom, Cameroon, Benin Republic, Cöte d’Ivoire, South Africa àti Ilẹ̀-oba Saudi Arabia. +Ajo naa so eyi di mimo ninu atejade kan ti Alukoro ajo naa, Omowe Fabian Benjamin gbe jade. Àjọ náà sọ èyí di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tí Alukoro àjọ náà, Ọ̀mọ̀wé Fabian Benjamin gbé jáde. +Ajo naa ni “O le ni igba awon akekoo t’o se idanwo UTME ti o waye nigbakanaa ni ojo Abameta, ojo ketadinlogbon, osu kerin, odun, 2019 ni awon ibi gbogbo ti a daruko tele. Àjọ náà ní “Ó lé ní igba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ t’ó ṣe ìdánwò UTME tí ó wáyé nígbàkanáà ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹ́rin, ọdún, 2019 ní àwọn ibi gbogbo tí a dárúkọ tẹ́lẹ̀. +Ajo naa tun tenpele mo oro re pe, esi idanwo UTME ti odun 2019 ko tii jade. Àjọ náà tún tẹnpẹlẹ mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, èsì ìdánwò UTME ti ọdún 2019 kò tíì jáde. +"""O wa ro awon eniyan paapaa julo awon obi ati akekoo naa pe ki won sora fun awon onijibiti, ti won a so pe won fe lo ona eburu lati ran won lowo fun esi idanwo ti won se." """Ó wá rọ àwọn ènìyàn pàápàá jùlọ àwọn òbí àti àkẹ́kọ̀ọ́ náà pé kí wọ́n ṣọ́ra fún àwọn oníjìbìtì, tí wọn á sọ pé wọ́n fẹ́ lo ọ̀nà ẹ̀bùrú láti ràn wọ́n lọ́wọ́ fún èsì ìdánwò tí wọ́n ṣe." +Ajo naa tun so pe “Ajo naa yoo polongo esi idanwo naa, nigba ti o ba jade Àjọ náà tún sọ pé “Àjọ náà yóò polongo èsì ìdánwò náà, nígbà tí ó bá jáde +"""Owo awon agbofinro ti te awon odaran kan, ni eyi ti won si n wa awon yooku" """Ọwọ́ àwọn agbófinro ti tẹ àwọn ọ̀daràn kan, ní èyí tí wọ́n ṣì ń wá àwọn yòókù" +Amerika kan saara si fowosowopo pelu orile-ede Naijiria lati fopin si aisan iba. Amẹ́ríkà kan sáárá sí fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti fòpin sí àìsàn ibà. +Ijoba orile-ede Amerika ti fi idunnu han bi won se fowosowopo ati lati satileyin fun orile-ede Naijiria nipa gbigbogun ti aisan iba. Ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti fi ìdùnnú hàn bí wọ́n ṣe fọwọ́sowọ́pọ̀ àti láti ṣàtìlẹyìn fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nípá gbígbógun ti àìsàn ibà. +"Asoju orile-ede Amerika si orile-ede Naijiria, W. Stuart Symington l’o soro yii l’asiko ayeye lati fi sami ayajo Ojo Aisan iba Lagbaaye ti won pe akori re ni: “Lati gbogun ti aisan iba bere lati odo mi""." "Aṣojú orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, W. Stuart Symington l’ó sọ̀rọ̀ yìí l’ásìkò ayẹyẹ láti fi sàmì àyájọ́ Ọjọ́ Àìsán ibà Lágbàáyé tí wọ́n pe àkórí rẹ̀ ní: “Láti gbógun ti àìsàn ibà bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ mi""." +Asoju Symington wa gbosuba fun awon ajo eleto ilera orile-ede Naijiria fun akitiyan won lati ori awon osise eleto ilera, de ori awon iya, awon apoogun oyinbo, awako, akoroyin, awon oniwadii, oluko de ori awon alakooso ile-ikonnkanpamo ati gbogbo awon to ko ipa pataki lati gbogun ti aisan iba lorile-ede Naijiria. Aṣojú Symington wá gbóṣùbà fún àwọn àjọ elétò ìlera orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún akitiyan wọn láti orí àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera, dé orí àwọn ìyá, àwọn apòògùn òyìnbó, awakọ̀, akọ̀ròyìn, àwọn oníwàdìí, olùkọ́ dé orí àwọn alákòóso ilé-ìkónnkanpamọ́ àti gbogbo àwọn tó kó ipa pàtàkì láti gbógun ti àìsàn ibà lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Asoju Symington so pe gege bi awujo agbaye, won ti se aseyori nipase igbogunti arun naa. Aṣojú Symington sọ pé g���́gẹ́ bí àwùjọ àgbáyé, wọ́n ti ṣe àṣeyọrí nípasẹ̀ ìgbógunti àrùn náà. +---Aare Buhari fe imoriya fun awon agbe. ---Ààrẹ Buhari fẹ́ ìmóríyá fún àwọn àgbẹ̀. +Aare Muhammadu Buhari ti ni sise imoriya fun awon agbe lorile-ede Naijiria ni yoo je ohun akoko ti o wa lokan oun lati se ninu ijoba re. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ní ṣíṣe ìmóríyá fún àwọn àgbẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni yóò jẹ́ ohun akọ́kọ́ tí ó wà lọ́kàn òun láti ṣe nínú ìjọba rẹ̀. +"Aare so pe oun ti pase fun Ajo to n mojuto Ise Ogbin ati Ile-Ifowopamo ti Ijoba Orile-ede Naijiria lati yo awon isoro ati idiwo ti ko je ki awon agbe ri owo ya lati fi se ise ogbin kuro nibe, ni eyi ti o pe ni “Iwa amunisin buruku""." "Ààrẹ sọ pé òun ti pàsẹ fún Àjọ tó ń mójútó Iṣẹ́ Ọ̀gbìn àti Ilé-Ìfowópamọ́ tí Ijọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti yọ àwọn ìṣòro àti ìdíwọ́ tí kò jẹ́ kí àwọn àgbè rí owó yá láti fi ṣe iṣẹ́ ọ̀gbìn kúrò níbẹ̀, ní èyí tí ó pè ní “Ìwà àmúnisìn burúkú""." +Fifopin si iwa fayawo Fífòpin sí ìwà fàyàwọ́ +Aare Buhari wa benu ate lu iwa fayawo ti o n sakoba fun ohun ogbin ati ise agbe lorile-ede Naijiria, o si seleri pe oun ko ni kaaare lati tubo maa gbogun ti iwa buruku yii pelu gbogbo agbara to ba wa ni ikawo oun. Ààrẹ Buhari wá bẹnu àtẹ́ lu ìwà fàyàwọ́ tí ó ń ṣàkóbá fún ohun ọ̀gbìn àti iṣẹ́ àgbẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó sì ṣèlérí pé òun kò ní káàárẹ̀ láti túbọ̀ máa gbógun ti ìwà burúkú yìí pẹ̀lú gbogbo agbára tó bá wà ní ìkáwọ́ òun. +Aare ni ijoba oun yoo tubo maa sa ipa re lori eto aabo, idagbasoke eto oro-aje ati gbigbogun ti iwa ibaje, saa tuntun ijoba oun yoo tenpele mo eto eko ati ilera. Ààrẹ ni ìjọba òun yóò túbò máa sa ipá rẹ̀ lórí ètò ààbò, ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀-ajé àti gbígbógun ti ìwà ìbàjẹ́, sáà tuntun ìjọba òun yóò tẹnpẹlẹ mọ́ ètò ẹ̀kọ́ àti ìlera. +Aare so fun awon omo egbe naa pe “Mo mo isoro wa. Mo mo ojuse mi si Olorun ati orile-ede mi. N o maa tesiwaju lati sa ipa mi.” Ààrẹ sọ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà pé “Mo mọ ìsòro wa. Mo mọ ojúṣe mi sí Ọlọ́run àti orílẹ̀-èdè mi. N ó máa tẹ̀síwájú láti sa ipá mi.” +"""Saaju eyi ni adari iko naa, Omowe Arabo Ibrahim Bayo, ni awon wa si orile-ede Naijiria nitori ife ti awon ni si idagbasoke orile-ede yii ati igbagbo ti won ni si isejoba Aare Muhammadu Buhari." """Ṣáájú èyí ni adarí ikọ̀ náà, Ọ̀mọ̀wé Arabo Ibrahim Báyọ̀, ní àwọ́n wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nítorí ìfẹ́ tí àwọn ní sí ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè yìí àti ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní sí ìṣèjọba Ààrẹ Muhammadu Buhari." +Awon omo egbe naa wa seleri atileyin won fun Aare lati se ohun malegbagbe lorile-ede Naijiria. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà wá ṣèlérí àtìlẹ̀yìn wọn fún Ààrẹ láti ṣe ohun málegbàgbé lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +---Orile-ede Naijiria pe fun eto aabo lori imo ero igbalode. ---Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pè fún ètó ààbò lórí ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé. +Aare orile-ede Naijiria Muhammadu Buhari ti ro awon adari orile ede agbaye lati wa woroko fi sada lori bi imo ero igbalode yoo se wa larowoto awon eniyan ati eyi ti eto aabo to peye yoo tun wa nibe. Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Muhammadu Buhari ti rọ àwọn adaŕi orílè èdè àgbáyé láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí bí ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé yóò ṣe wà lárọ̀wọ́tó àwọn ènìyàn àti èyí tí ètò ààbò tó péye yóò tún wà níbẹ̀. +Ninu oro re nibi Ipade eto Okoowo ti odun 2019 (AIM) t’o waye ni ilu Dubai lojo Aje, Aare ni eto ilana gbodo wa nipa eyi ti yoo maa daabo bo imo ero igbalode lori eto oro aje. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ níbi Ìpàdé ètò Okoòwò ti ọdún 2019 (AIM) t’ó wáyé ní ìlú Dubai lọ́jọ́ Ajé, Ààrẹ ní ètò ìlànà gbọdò wà nípa èyí tí yóò máa dáàbò bo ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé lórí ètò ọrọ̀ ajé. +Akori ipade apero naa ni: ‘Wiwa ojo iwaju to dara fun eto okoowo: Mimu idagbasoke ba eto okoowo agbaye nipa lilo Imo-ero igbalode. Àkórí ìpàdé àpérò náà ni: ‘Wíwá ọjọ́ iwájú tó dára fún ètò okoòwò: Mímú ìdàgbàsókè bá ètò okoòwò àgbáyé nípa lílo Ìmọ̀-ẹ̀rọ ìgbàlódé. +’’Aare orile-ede Naijiria ni pipese eto ilana fun lilo imo ero igbalode nikan lo le din wahala ati isoro to maa n waye nipa re. ’’Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni pípèsè ètò ìlànà fún lílo ìmọ̀ ẹ̀ro ìgbàlódé nìkan ló lè dín wàhálà àti ìsòro tó máa ń wáyé nípa rẹ̀. +Aare fi aidunnu re han nipa bi won se n lo imo ero igbalode lati se ayeduru eto idibo, ni eyi ti o tako eto omoniyan, ti o si tun maa n da rogbodiyan sile laarin ilu. Ààrẹ fi àìdunnú rẹ̀ hàn nípa bí wọ́n ṣe ń lo ìmò èrọ ìgbàlódé láti ṣe ayédùrú ètò ìdìbò, ni èyí tí ó tako ẹ̀tọ̀ ọmọnìyàn, tí ó sì tún máa ń dá rògbòdìyàn sílẹ́ láàrín ìlú. +Aare Buhari, wa ro awon adari ile-ise ijoba ati ile-ise aladaani lati fowosowopo lati wa ojutuu si wahala ati isoro to maa n waye nipa lilo imo ero igbalode. Ààrẹ Buhari, wá rọ àwọn adarí ilé-iṣẹ́ ìjọba àti ilé-iṣẹ́ aládàáni láti fọwọ́sowọ́pọ̀ láti wá ojútùú sí wàhálà àti ìsoro tó máa ń wáyé nípa lílo ìmọ̀ èrọ ìgbàlódé. +---ile-riri lorile-ede Indonesia: o to eniyan marundinlogun ti o ti ku leyin opo odun ijamba ---ilẹ̀-rírì lórílè-èdè Indonesia: ó tó ènìyàn màrúndínlógún tí ó ti kú lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún ìjàmbá +Iko alaabo to n mojuto isele pajawiri lorile-ede Indonesia ti n wa awon eniyan ti o fara kaasa ninu isele ijamba ile riri ti o gba emi eniyan marundinlogun lojo Odun Tuntun, leyin irufe isele naa ti o waye lodun kan seyin ti o sekupa ogoro eniyan. Ikọ̀ aláàbò tó ń mójútò ìṣèlẹ̀ pàjáwìrì lórílé-èdé Indonesia ti ń wá àwọn ènìyàn tí ó fara káásà nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ilẹ̀ rírì tí ó gba ẹ̀mí ènìyàn màrúndínlógún lọ́jọ́ Ọdún Tuntun, lẹ́yìn irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí ó wáyé lọ́dún kan ṣẹ́yìn ti o ṣekúpa ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn. +Okere tan ogun eniyan ni o padanu emi won sinu isele ohun, bee si ni ile ogbon si ba isele naa lo niluu Sukabumi. Ókéré tán ogún ènìyàn ni ó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún, bẹ́ẹ̀ sì ni ilé ọgbọ̀n sì bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lo nílùú Sukabumi. +Gege bi agbenusoro iko alaabo naa, Sutopo Purwo Nugroho se so,“O le pupo fun awon osise onisele pajawiri lati gba awon eniyan sile lasiko isele ile riri.” Gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ̀rọ̀ ikọ̀ aláàbò náà, Sutopo Purwo Nugroho ṣe sọ,“Ó le púpọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ oníṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì láti gba àwọn ènìyàn sílẹ̀ lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ ilè rírì.” +Wayii o, aroro da ojo ti o ro lojo Isegun ohun ni o dena ise awon alaabo naa. Wàyìí o, àrọ̀rọ̀ dá òjò tí ó rọ̀ lọ́jọ́ Ìṣégun ọ̀hún ni ó dènà iṣẹ́ àwọn aláàbó náà. +Isele ijamba ile riri je ohun ti o maa n sele lopolopo lorile-ede Indonesia, eleyii ti o si sekupa egberun meta eniyan ni awon agbegbe lorisirisi lodun 2018. Ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàm̀bá ilẹ̀ ríri jẹ́ ohun tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ lórílè-èdè Indonesia, eléyìí tí o sì ṣekúpa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ènìyàn ní àwọn agbègbè lóríṣiríṣi lọ́dún 2018. +---Orile-ede Korea fun Naijiria ni egberun lona eedegbeta owo dola. ---Orílẹ̀-èdè Korea fún Nàìjíríà ni ẹ̀gbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó dọ́là. +Eto Ounje Ajo Isokan Agbaye Orile-ede Naijiria ti fi egberun lona eedegbeta dola owo ile okeere ran awon eniyan ti iye won din ni eedegbeje egberun fun awon ipinle Borno, Adamawa ati Yobe ti iko olote Boko Haram so di alainile lori. Ètò Oúnjẹ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti fi ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta dọ́là owó ilẹ̀ òkèèrè ran àwọn ènìyàn tí iye wọn dín ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje ẹ̀gbẹ̀rún fún àwọn ìpínlẹ̀ Borno, Adamawa àti Yobe tí ikọ̀ ọlọ́tẹ̀ Boko Haram sọ di aláìnílé lórí. +Asoju orile-ede Korea fun orile-ede Naijiria ajagun feyinti In-Tae Lee, lo so pe ijoba orile-ede Korea ti n gbiyanju lati wa ona ti yoo gbe seranwo fun awon eniyan ti iko omo gun Boko Haram so di alainile lori. Aṣojú orílẹ̀-èdè Korea fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ajagun fẹ̀yìnti In-Tae Lee, ló sọ pé ìjọba orílẹ̀-èdè Korea ti ń gbìyànjú láti wá ọ̀nà tí yóò gbé ṣèrànwó fún àwọn ènìyàn tí ikọ̀ ọmọ gun Boko Haram sọ di aláìnílé lórí. +O ni ijoba orile-ede Korea yoo fowosowopo pelu ijoba orile-ede Naijiria lati gbogun ti aisan ebi ati osi lorile-ede Naijiria. Ó ní ìjọba orílẹ̀-èdè Korea yóò fọwọsowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti gbógun ti àìsàn ebi àti òṣì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Asoju Ajo Agbaye ni orile-ede Naijiria, Myrta Kaulard wa gbosuba fun orile-ede Korea fun eto iranwo ti won se fun orile-ede Naijiria, pe iru eto bayii yoo tun je ki igbe aye iderun ba awon omo orile-ede Naijiria. Aṣojú Àjọ Àgbáyé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Myrta Kaulard wá gbósùbà fún orílẹ̀-èdè Korea fún ètò ìránwó tí wọ́n ṣe fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, pé irú ètò báyìí yóò tún jẹ́ kí ìgbé ayé ìdẹ̀rùn bá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +---Eka ede Yoruba, Ohun Naijiria (VON) bere igbohun safefe ni ilu Abuja. ---Èka èdè Yor��bá, Ohùn Nàìjíríà (VON) bẹ̀rẹ̀ ìgbòhùn sáfẹ́fẹ́ ní ìlú Àbújá. +Ohun Naijiria (Voice of Nigeria) ni eka ede Yoruba ti bere igbohun safefe lati ilu Abuja. Ohùn Nàìjíríà (Voice of Nigeria) ní ẹ̀ka èdè Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ láti ìlú Àbújá. +Adari eka ede Yoruba ni ilu Abuja Abiodun Popoola so fun awon eniyan pe, opolopo eto ni awon ti ya soto fun igbadun awon ololufe jake-jado agbaye. Adarí ẹ̀ka èdè Yorùbá ní ìlú Àbújá Abíọ́dún Pópóọlá sọ fún àwọn ènìyàn pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò ni àwọ́n ti yà sọ́tọ̀ fún ìgbádùn àwọn olólùfẹ́ jákè-jádò àgbáyé. +"O tesiwaju pe"" Ife awon olugbo wa lo je wa logun, idi niyi ti awon alase Ohun Naijiria, Voice of Nigeria se bere igbohun safefe lati ilu Abuja." "Ó tẹ̀síwájú pé"" Ìfẹ́ àwọn olùgbọ́ wa ló jẹ wá lógún, ìdí nìyí tí àwọn aláṣẹ Ohùn Nàìjíríà, Voice of Nigeria ṣe bẹ̀rẹ̀ ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ láti ìlú Àbújá." +Bakan naa, ni a ti ya awon opolopo eto sile fun igbadun awon to n gbo wa, paapaa julo ile Afirika. Bákan náà, ni a ti ya àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò sílẹ̀ fún ìgbádùn àwọn tó ń gbọ́ wa, pàápàá jùlo ilẹ̀ Áfíríkà. +"""Ewe, ti o je adari imo ero labe eka Yoruba naa tun so pe bi eka ede Yoruba se bere igbohun safefe lati ilu Abuja je ohun ti yoo tun je ki awon olugbo Ohun Naijiria lati ile okeere tun maa gbo won yeke-yeke." """Ewe, tí ó jẹ́ adarí ìmọ̀ ẹ̀rọ lábẹ́ ẹ̀ka Yorùbá náà tún sọ pé bí ẹ̀ka èdè Yorùbá ṣe bẹ̀rẹ̀ ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ láti ìlú Àbújá jẹ́ ohun tí yóò tún jẹ́ kí àwọn olùgbọ Ohùn Nàìjíríà láti ilẹ̀ òkèèrè tún máa gbọ́ wọn yéké-yéké." +O ni ko si ohun to dara julo pe ki inu awon eniyan to n gbo wa lati ile akede dun lati maa teti si won. Ó ní kò sí ohun tó dára jùlọ pé kí inú àwọn ènìyàn tó ń gbọ́ wa láti ilé akéde dùn láti máa tẹ́tí sí wọn. +Lara awon osise ti yoo maa kopa lori eto ohun naa ni iyaafin Aderonke Osundiya, Tobi Sangotola ati Maryam Yusuf. Lára àwọn òṣìṣẹ́ tí yóò máa kópa lórí ètò ọ̀hún náà ni ìyáàfin Adérónkẹ́ Ọ̀súndíyà, Tóbi Ṣàngótọ́lá àti Maryam Yusuf. +E o maa gbo Ohun Naijiria lati ikanni 31m 9690khz ni deede aago mokanla aabo owuro titi di aago mokanla koja iseju marundinlaadota ati ni irole ni deede aago marun koja iseju marundinlogun titi di aago marun aabo. Ẹ ó máa gbọ́ Ohùn Nàíjíríà láti ìkànnì 31m 9690khz ní déédé aago mọ̀kànlá ààbọ̀ òwúrọ̀ títí di aago mọ̀kànlá kọjá ìṣẹ́jú márùndínláàdọ́ta àti ní ìrọ̀lẹ́ ní déédé aago màrún kọjá ìṣẹ́jú màrúndínlógún tít́i di aago màrún ààbọ̀. +---Igbakeji Aare yoo kopa nibi ipade Africa-Europe ni Austria. ---Igbákejì Ààrẹ yóò kópa níbi ìpàdé Africa-Europe ni Austria. +Igbakeji Aare orile-ede Naijiria Yemi Osinbajo yoo maa darapo mo awon akegbe re lati orile-ede Afirika ati Europe nibi ijiroro ti yoo waye ni Vienna lorile-ede Austria lojo Aje, osu Kejila, ojo kejidinlogun ati ojo kerindinlogun. Igbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Yemí Ọ̀sínbàjò yóò máa darapọ̀ mọ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ láti orílẹ̀-èdè Áfíríkà àti Europe níbi ìjíròrò tí yóò wáyé ní Viénna lórílẹ̀-èdè Austria lọ́jọ́ Ajé, oṣù Kejìlá, ọjọ́ kej̀idínlógún àti ọjọ́ kẹrìndínlógún. +Ninu atejade kan t’o wa lati Ibi-ise igbakeji Aare, o so pe Ojogbon Osinbajo yoo maa soro lori akori ’Gbigbe ajumose de ori ero igbalode’ ni ipade naa ti ijoba orile-ede Austria je olugbalejo ti o duro fun Ajo Europe ati Ajo Africa. Nínú àtẹ̀jáde kan t’ó wá láti Ibi-iṣẹ́ igbákej̀i Ààrẹ, ó sọ pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀ṣínbàjò yóò máa sọ̀rọ̀ lórí àkórí ’Gbígbé àjùmọ̀ṣe dé orí ẹ̀rọ ìgbàlódé’ ní ìpàdé náà tí ìjọba orílẹ̀-èdè Austria jẹ́ olùgbàlejò tí ó dúró fún Àjọ Europe àti Àjọ Africa. +Apero awon eeyan jankanjankan naa yoo se igbelaruge idagbasoke imo ero igbalode ati ogbon atinuda bi awon oluseto ni EU ati AU, “gege bi awon ohun t’o se onigbonwo idagbasoke ojo ola wa, ki gbogbo eniyan o le je anfaani ti eniyan yoo je lati ara awon ayipada imo ero igbalode.” Àpérò àwọn èèyàn jànkànjànkàn náà yóò ṣe ìgbélárugẹ ìdàgbàsókè ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé àti ọgbọ́n àtinudá bí àwọn olùṣètò ní EU àti AU, “gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun t’ó ṣe onígbọ̀nwọ́ ìdàgbàsókè ọjọ́ ọ̀la wa, kí gbogbo ènìyàn ó lè jẹ àǹfààní tí ènìyàn yóò jẹ láti ara àwọn àyípadà ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé.” +"Ipade naa yoo tun maa wo ""bi ibasepo to wa laaarin Europe ati Afirika se lowo si alepa yii, asekun imuse ti o n lo lowo ti won fenuko le lori nibi ipade Abidjan to waye lodun 2017 ati awon nnkan miiran, won yoo tun maa jiroro lori ipa pataki ti imo ero igbalode yoo tun fi wulo fun idagbasoke eto oro aje fun Europe ati Afirika." "Ìpàdé náà yóò tún máa wo ""bí ìbaṣepọ tó wà láàárín Europe àti Áfíríkà ṣe lọ́wọ́ sí alépa yìí, àṣekún ìmúṣe tí ó ń lọ lọ́wọ́ tí wọ́n fẹnukò lé lórí níbi ìpàdé Abidjan tó wáyé lọ́dún 2017 àti àwọn nǹkan mìíràn, wọn yóò tún máa jíròrò lórí ipa pàtàkì tí ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé yóò tún fi wúlò fún ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀ ajé fún Europe àti Áfíríkà." +O lepa idasi Ajose fun Imuro Idokoowo ati ipese Ise.” Ó lépa ìdásí Àjọṣe fún Ìmúrò Ìdókoòwò àti ìpèsè Iṣé.” +Lasiko irinajo re lo si Vienna, Ojogbon Osinbajo yoo maa se ipade abele pelu awon omo orile Naijiria t’o n gbe ni orile-ede Austria; bakan naa ni yoo tun maa se ipade po pelu awon olori orile-ede Europe, lara won ni Adari ijoba ti orile-ede Czech Republic, Andrej Babis; Adari ijoba ti orile-ede Finland, H.E. Juha Petri Sipila; Oba orile-ede Austria, alaye julo, Sebastian Kurz; ati Minisita ile alawo funfun (UK ) to n soju fun ile Africa, Harriet Baldwin. Lásìkò ìrìnàjò rẹ̀ lọ sí Vienna, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀ṣínbàjò yóò máa ṣe ìpàdé abẹ́lé pẹ̀lú àwọn ọmọ orílè Nàìjíríà t’ó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Austria; bákan náà ni yóò tún máa ṣe ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí orílẹ̀-èdè Europe, lára wọn ni Adarí ìjọba ti orílẹ̀-èdè Czech Republic, Andrej Babis; Adarí ìjọba ti orílẹ̀-èdè Finland, H.E. Juha Petri Sipilä; Ọba orílẹ̀-èdè Austria, alayé jùlọ, Sebastian Kurz; àti Mínísítà ilẹ̀ aláwọ̀ funfun (UK ) tó ń sojú fún ilẹ̀ Africa, Harriet Baldwin. +Ojogbon Osinbanjo yoo tun maa sepade po pelu awon osise agba ile ise Bill ati Melinda Gates Foundation. Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀ṣínbànjò yóò tún máa ṣèpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ àgbà ilé iṣẹ́ Bill àti Melinda Gates Foundation. +Igbakeji Aare fi ilu Abuja sile l’asale ojo Aiku, yoo si pada wa si orile-ede Naijiria lojo Isegun. Igbákejì Ààrẹ fi ìlú Àbújá sílẹ̀ l’áṣàlẹ́ ọjọ́ Àìkú, yóò sì padà wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun. +---Aare Buhari sebowo fun awon to padanu emi won lasiko Isele-ipaninipakupa. ---Ààrẹ Buhari ṣèbọ̀wọ̀ fún àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò Ìṣẹ̀lẹ̀-ìpaninípakúpa. +Aare orile-ede Naijiria Muhammadu Buhari ti lo si ibi ti won n ko awon Ile-ona ohun alumooni ati ami idagbere si ni Auschwitz-Birkenau ati Oswiecim lati lo bowo fun awon to padanu emi won lasiko ogun. Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Muhammadu Buhari ti lọ sí ibi tí wọ́n ń kó àwọn Ilé-ọnà ohun àlùmọ́ọ́ni àti àmì ìdàgbére sí ni Auschwitz-Birkenau àti Oświęcim láti lọ bọ̀wọ̀ fùn àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò ogun. +Leyin wakati kan ati iseju mewaa ti Aare ti rin Ile-ona, fun awon ti won padanu emi won lasiko Ogun Agbaye keji, Aare Buhari tun towobo iwe lati bowo fun awon akoni naa ninu iwe alejo, ti o si lo ori ‘Julius Caesar ti Shakespeare: Lẹ́yìn wákàtí kan àti ìṣéjú mẹ́wàá tí Ààrẹ ti rin Ilé-ọnà, fún àwọn tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò Ogun Àgbáyé kejì, Ààrẹ Buhari tún tọwọ́bọ ìwé láti bọ̀wọ̀ fún àwọn akọni náà nínú ìwé àlejò, tí ó sì lo ọ̀rí ‘Julius Caesar ti Shakespeare: +"Iwa buruku ti awon eniyan ba wu, maa n tele won; sugbon iwa rere maa n wonu eegun lo.""" "Ìwà burúkú tí àwọn ènìyàn ba wù, máa ń tẹ̀lé wọn; ṣùgbón ìwà rere máa ń wọnú eegun lọ.""" +Aare tun gbe ododo iboji si Ile keji ti ile-ona, ti a mo si “Ile iku.” Ààrẹ tún gbé òdódó ibojì si Ilé kejì ti ilé-ọnà, tí a mọ̀ sí “Ilé ikú.” +Gege bi won se ko sori Ile iku naa: ’’Awon elewon l’okunrin ati l’obinrin lati gbogbo ile ipago naa ni won ko sinu ile yii...leyin iforowanilenuwo ijiya, ti won si da won lejo iyinbon pa.” Gẹ́gé bí wọ́n ṣe kọ sórí Ilé ikú náà: ’’Àwọn ẹlẹ́wọ̀n l’ọ́kùnrin àti l’óbìnrin láti gbogbo ilé ìpàgọ́ náà ni wọ́n kó sínú ilé yìí...lẹ́yìn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwo ìjìyà, ti wọ́n sí dá wọn lẹ́jọ́ ìyìnbọn pa.” +"""Leyin ti Aare kuro nibe tan, lo n bere si n dahun ibeere lati odo awon akoroyin ti o tele lati ile –ise Aare pe awon to n da wahala sile lorile-ede Naijiria’’ je alailekoo ati alaimokan." """Lẹ́yìn ti Ààrẹ kúrò níbẹ̀ tán, ló ń bẹ̀rẹ̀ sí ń dáhùn ìbéèrè láti ọ̀dọ àwọn akọ̀ròyìn tí ó tẹ̀lẹ́ láti ilé –iṣé Ààrẹ pé àwọn tó ń dá wàhálà sílẹ̀ lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà’’ jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìmọ̀kan." +"""Aare lo fun irinajo olojo merin si orile-ede Poland, nibi ti yoo ti darapo mo ipade Apero Ayipada Oju-ojo ti UN agbaye ni Katowice, o se agbekale oro orile-ede re ni ipade olojo mejila ti COP24, sepade pelu awon olori agbaye ti won si be ibi afihan orile-ede Naijiria ni apero oju-ojo naa." """Ààrẹ lọ fún ìrìnàjọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́rin sí orílẹ̀-èdè Poland, níbi tí yóò ti darapọ̀ mọ́ ìpàdé Àpérò Àyípadà Ojú-ọjọ́ ti UN àgbáyé ní Katowice, ó ṣe àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè rẹ̀ ní ìpàdé ọlọ́jọ́ méjìlá ti COP24, ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn olórí àgbáyé tí wọ́n sì bẹ ibi àfihàn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àpérò ojú-ọjọ́ náà." +Aare tun ba awon omo orile-ede Naijiria ti won wa ni Poland soro lojo keji ti o de si orile-ede Poland. Ààrẹ tún bá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n wà ní Poland sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ kejì tí ó dé sí orílẹ̀-èdè Poland. +---Naijiria ba Amerika kedun lori iku George Bush. ---Nàìjíríà bá Amẹ́ríkà kẹ́dùn lórí ikú George Bush. +Aare Muhammadu Buhari ti darapo mo awon adari orile-ede lagbaaye lati ba orile-ede Amerika kedun lori iku Aare ana George H. Bush, ti o gbe igbe aye re lati fi sin ilu ati awon eniyan. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti darapọ̀ mọ́ àwọn adarí orílẹ̀-èdè lágbàáyé láti bá orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kẹ́dùn lórí ikú Ààrẹ àna George H. Bush, tí ó gbé ìgbé ayé rẹ̀ láti fi sin ìlú àti àwọn ènìyàn. +Aare Buhari fi iwe ikedun naa ranse si awon omo orile-ede Amerika, ore ati ebi oloogbe naa, ti o je Aare ikokanlelogoji ni orile-ede naa, eni ti gbogbo awon eniyan n kan saara si fun ipa pataki ti o ko lagbaaye. Ààrẹ Buhari fi ìwé ìkẹ́dùn náà ránṣé sí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọ̀rẹ́ àti ẹbí olóògbé náà, tí ó jẹ́ Ààrẹ ìkọkànlélógójì ní orílẹ̀-èdè náà, ẹni tí gbogbo àwọn ènìyàn ń kan sáárá sí fún ipa pàtàkì tí ó kó lágbàáyé. +Aare tun tesiwaju pe iku George H. Bush, kii se orile-ede Amerika nikan ni yoo dun,sugbon ajo gbaye ati awon eniyan ti o ti ko ipa rere ni igbesi aye won pelu. Ààrẹ tún tẹ̀síwájú pé ikú George H. Bush, kìí ṣe orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan ni yóò dùn,ṣùgbọ́n àjọ gbayé àti àwọn ènìyàn tí ó ti ko ipa rere ní ìgbésí ayé wọn pẹ̀lú. +Aare wa gbosuba fun ipa rere ti oloogbe naa ti ko ni igbesi aye awon omo re, ni eyi ti o n ran won lowo lati ko ipa pataki ninu ipo adari lagbaaye. Ààrẹ wá gbóṣùbà fún ipa rere tí olóògbé náà tí kó ní ìgbésí ayé àwọn ọmọ rẹ̀, ní èyí tí ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kó ipa pàtàkì nínú ipò adarí lágbàáyé. +Aare wa gbadura pe ki Olorun dun orile-ede naa, ebi, ore oloogbe naa ninu, ati isinmi fun emi re. Ààrẹ wá gbàdúrà pé kí Ọlórun dun orílẹ̀-èdè náà, ẹbí, ọ̀rẹ́ olóògbé náà nínú, àti ìsinmi fún ẹ̀mi rẹ̀. +---Naijiria ko ni pe gbe awon akosile iwe asa fun idagbasoke igbafe jade. ---Nàìjíríà kò ní pẹ́ gbé àwọn àkọsílẹ̀ ìwé àṣà fún ìdàgbàsókè ìgbáfẹ́ jáde. +Ajo to n mojuto asa ati igbafe lorile-ede Naijiria ti so pe awon ko ni pe gbe iwe akosile ti yoo safihan gbogbo awon asa to wa jake-jado orile-ede Naijiria sita lati le mu idagbasoke ba asa ati igbafe lorile-ede yii. Àjo tó ń mójútó àṣà àti ìgbáfẹ́ lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti sọ pé àwọn kò ní pẹ́ gbé ìwé àkosílè ti yóò sàfihàn gbogbo àwọn àṣà tó wà jákè-jádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà síta láti lè mú ìdàgbàsókè bá àṣà àti ìgbáfẹ́ lorílẹ̀-èdè yìí. +Minisita fun ilaniloye ati asa lorile-ede Naijiria, Lai Mohammed lo soro yii ni Istanbul, lorile-ede Turkey nibi ayeye asa ati igbafe ti ajo agbaye (UNWTO/UNESCO World Conference on Tourism and Culture) se,eleyii lo je iketa iru re ti ajo agbaye yoo se. Mínísítà fún ìlanilóye àti àṣà lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Lai Mohammed ló sọ̀rọ̀ yìí ni Istanbul, lorílẹ̀-èdè Turkey níbi ayẹyẹ àṣà àti ìgbáfẹ́ tí àjọ àgbáyé (UNWTO/UNESCO World Conference on Tourism and Culture) ṣe,eléyìí ló jẹ́ ìkẹta irú rẹ̀ tí àjọ àgbáyé yóò ṣe. +Minisita so pe o le ni aarundinlaadorinle oodunrun ni awon asa to wa ni jake-jado orile-ede Naijiria, iyen ni pe orile-ede yii le e se asa kan lojumo kan, ni eyi ti yoo je ki idagbasoke ba eto igbafe ati oro aje orile-ede yii. Mínísítà sọ pé o lé ni aárùndínláàdọ́rinlé ọ́ọ̀dúnrún ni àwọn àṣà tó wà ní jákè-jádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìyẹn ni pé orílẹ̀-èdè yìí lè e ṣe àṣà kan lójúmọ́ kan, ní èyí tí yóò jẹ́ kí ìdàgbàsókè bá ètò ìgbafẹ́ àti ọ̀rọ̀ ajé orílẹ̀-èdè yìí. +Asa orisirisi Alhaji Mohammed ni orile-ede Naijiria fidi mule ninu ede ati asa ni eyi ti awon asa miiran tun ti jeyo bi I Durbar, isu tuntun, Eyo ati odun egungun abbl. Àṣà oríṣiríṣi Alhaji Mohammed ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fìdí múlẹ̀ nínú èdè àti àṣà ni èyí ti àwọn àṣà mííràn tún ti jẹyọ bi I Durbar, iṣu tuntun, Ẹ̀yọ̀ àti ọdún egúngún abbl. +O tesiwaju pe awon ijoba ni gbogbo eka lorile-ede Naijiria n sa gbogbo ipa ni agbegbe won lati gbe asa laruge, bakan naa ni ijoba apapo naa si n seto iranwo lati fun won ni agbegbe to se e gbe, ni eyi ti yoo mu itesiwaju ba asa lorile-ede yii. Ó tẹ̀síwájú pé àwọn ìjọba ni gbogbo ẹ̀ka lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń sa gbogbo ipá ní agbègbè wọn láti gbé àṣà láruge, bákan náà ni ìjọba àpapò náà sì ń ṣètò iranwọ láti fún wọn ní agbègbè tó ṣe é gbé, ní èyí tí yóò mú itẹ̀síwájú bá àṣà lorílẹ̀-èdè yìí. +Minisita tun tesiwaju pe ayeye ajodun asa ti o maa n waye niluu Abuja je ohun ti o wa lati gbe asa laruge, ni eyi ti gbogbo awon ipinle merindinlogoji ati ilu Abuja to wa lorile-ede Naijiria maa n kopa nibe. Mínísítà tún tẹ̀síwájú pé ayẹyẹ àjọ̀dún àṣà tí ó máa ń wáyé nílùú Àbújá jẹ́ ohun tí ó wá láti gbé àṣà lárugẹ, ní èyí tí gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójí àti ìlú Àbújá tó wà lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà máa ń kópa níbẹ̀. +O ni ayeye ajodun asa kii se fun ere idaraya nikan, bi kii se lati tun pese ise ati idagbasoke fun eto oro-aje lorile-ede Naijiria. Ó ní ayẹyẹ àjọ̀dún àṣà kìí ṣe fún eré ìdárayá nìkan, bí kìí ṣe láti tún pèsè iṣẹ́ àti ìdàgbàsókè fún ètò ọrọ̀-ajé lọrílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Awon Minisita to le logbon lo wa nibi ayeye ajodun agbaye yii, ojo meta gbako ni won yoo fi se ayeye yii. Àwọn Mínísítà tó lé lọ́gbọ̀n ló wà níbi ayẹyẹ ajọdún agbaye yìí, ọjọ́ mẹ́ta gbáko ni wọn yóò fi se ayẹyẹ yìí. +---WANEP, AU se idanilekoo nipa aabo lasiko ijamba eto idibo. ---WANEP, AU ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa ààbò lásìkò ìjàm̀bá ètò ìdìbò. +Gege bi eto idibo odun 2019 se n sunmo etile ajo to n mojuto eto alaafia lorile-ede Afirika West Africa Network for Peace building ati Ajo Afirika ati ajo Ecowas ti se idanileko fun awon eniyan to le ni ogorin, paapaa julo awon ile-ise aladaani ti ki i se ti ijoba lati ko won lona ti won yoo fi le maa daabo bo ara won nigba ti ijamba ba waye lasiko eto idibo. Gẹ́gẹ́ bí ètò ìdìbò ọdún 2019 ṣe ń súnmọ́ etílé àjọ tó ń mójútó ètò àlàáfíà lórílẹ̀-èdè Áfíríkà West Africa Network for Peace building àti Àjọ Áfíríkà àti àjọ Ecowas ti ṣe ìdánilẹ̀kọ̀ fún àwọn ènìyàn tó lé ní ọgọ́rin, pàápàá jùlọ àwọn ilé-iṣẹ́ aládàáni tí kì í ṣe ti ìjọba láti kọ́ wọn lọ́nà tí wọn yóò fi lè máa dáàbò bo ara wọn nígbà tí ìjàm̀bá bá wáyé lásìkò ètò ìdìbò. +Egbe naa so pe awon olukopa nibi idanilekoo naa wa lati gbogbo ipinle merindinlogoji to wa lorile-ede Naijiria ati ilu Abuja. Ẹgbẹ́ náà sọ pé àwọn olùkópa níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà wá láti gbogbo ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tó wà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ìlú Àbújá. +Egbe naa so pe awon se idanilekoo yii fun awon eniyan ti yoo kopa lati mojuto eto idibo, ni pataki julo ni igberiko ati ni ipinle to wa lorile-ede Naijiria. Ẹgbẹ́ náà sọ pé àwọn ṣe ìdánilékọ̀ọ́ yìí fún àwọn ènìyàn tí yóò kópa láti mójútó ètò ìdìbò, ní pàtàkì jùlo ní ìgbèríko àti ní ìpínlẹ̀ tó wà lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Egbe WANEP tun tesiwaju pe opolopo awon eniyan ni eru ti n ba nitori eto idibo to n bo , paapaa julo nipa eto aabo ti ko fese mule , bi awon oloselu se n bu ara won ati bi won se n dun ikooko mo ara won. Ẹgbẹ́ WANEP tún tẹ̀síwájú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni ẹ̀rú ti ń bà nítorí ètò ìdìbò tó ń bò , pàápàá jùlọ nípa ètò ààbò tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ , bi àwọn olóṣèlú ṣe ń bú ara wọn àti bí wọ́n ṣe ń dún ìkookò mọ́ ara wọn. +Alakooso egbe yii Chukwuemeka Eze tun ni awon egbe meteeta yii fowosowopo lati se idanilekoo yii lati le dena awon ijamba to maa n sele lasiko eto idibo. Alákòóso ẹgbẹ́ yìí Chukwuemeka Eze tún ni àwọn ẹ̀gbẹ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí fọwọ́sowọ́pọ̀ láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí láti lè dénà àwọn ìjàm̀bá tó máa ń ṣẹlẹ̀ lásìkò ètò ìdìbò. +Eze tun so pe “WANEP, ECOWAS/AU ti ni awon yoo gbe awon ise akanse kan dide lori ero ayelujara, ni eyi ti yoo maa jabo, ti yoo si tun maa topinpin bi eto idibo se n lo si. Eze tún sọ pé “WANEP, ECOWAS/AU ti ní àwọn yóò gbé àwọn iṣẹ́ àkànṣe kan dìde lórí èrọ ayélujára, ní èyí tí yóò máa jábọ̀, tí yóò sì tún máa tọpinpin bí ètò ìdìbò ṣe ń lọ sí. +Bakan naa, ni egbe naa yoo tun gbe ise akanse miiran dide ti yoo ran awon ti oro kan lowo lati lee gbogun ti ijamba to ba lee waye lasiko eto idibo , awon bi i ajo eleto idibo, ile-ise olopaa,ajo to n mojuto oro to je mo ilu, egbe onigbagbo (kristeni) egbe awon musulumi ati ajo to n pese alaafia. Bákan náà, ni ẹgbẹ́ náà yóò tún gbé iṣẹ́ àkànṣe mìíràn dìde tí yóò ran àwọn ti ọ̀rọ̀ kàn lọ́wọ́ láti lèe gbógun ti ìjàm̀bá tó bá lèe wáyé lásìkò ètò ìdìbò , àwọn bí i àjọ elétò ìdìbò, ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá,àjọ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìlù, ẹgbẹ́ onígbàgbọ́ (kristeni) ẹgbẹ́ àwọn mùsùlùmí àti àjọ tó ń pèsè àlàáfíà. +Aare Buhari ni oun ki i se eda. Ààrẹ Buhari ní òun kì í ṣe ẹda. +Aare Muhammadu Buhari ti soro nigba akoko lati tako aheso oro pe oun ki i se eniyan, pe eda ni oun. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti sọ̀rọ̀ nígbà àkọ́kọ́ láti tako àhesọ ọ̀rọ̀ pé òun kì í ṣe ènìyàn, pé ẹ̀dà ni òun. +O tako oro yii lojo Aiku ni orile-ede Poland lasiko to n ba awon omo orile-ede Naijiria to wa ni orile-ede Poland soro. Ó tako ọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́ Àìkú ní orílẹ̀-èdè Poland lásìkò tó ń bá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó wà ni orílẹ̀-èdè Poland sọ̀rọ̀. +Omo orile-ede Naijiria to wa ni Poland fe mo boya Aare je eniyan tabi eda, lati fi otito oro ti won n so mule, eleyii waye ni gbongan to wa ni Krakow lojo Aiku. Ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó wà ni Poland fẹ́ mọ̀ bóyá Ààrẹ jẹ́ ènìyàn tàbí ẹ̀dà, láti fi òtítọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ múlè, eléyìí wáyé ní gbọ̀ngán tó wà ní Krakow lọ́jọ́ Àìkú. +Aare Buhari ni opolopo awon eniyan ni won fe ki oun ti ku lasiko ti o n saisan. Ààrẹ Buhari ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n fẹ́ kí òun ti kú lásìkò tí ò ń ṣàìsàn. +"O sapejuwe awon ti o n soro yii gege bi ""Alaimokan ati alailesin." "Ó ṣàpèjúwe àwọn tí ó ń sọ̀rọ̀ yìí gege bi ""Aláìmọ̀kan àti aláìlẹ́sìn." +"""Aare so pe: “Opolopo awon eniyan ni won fe ki n ku lasiko ti mo n saisan." """Ààrẹ sọ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n fẹ́ kí n kú lásìkò tí mo ń ṣàìsàn." +Emi ko ni pe se ayeye ojo ibi kerindinlogorin mi. Èmi kò ní pẹ́ ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí kẹrìndínlọ́gọ́rin mi. +"""Ipade yii tun fun awon alase orile-ede yii lati jiroro pelu awon omo orile-ede Naijiria to n gbe ni Poland, eleyii ni yoo je akoko iru re ti Aare yoo wa si ipade awon igbimo to wa lara ajo agbaye ti won n ri si bi oju ojo se n yi pada (COP24 of Climate Change (UNFCCC), ni eyi ti yoo waye ni ojo keji si ojo kerin, osu kejila odun yii." """Ìpàdé yìí tún fún àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè yìí láti jíròrò pẹ̀lú àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń gbé ní Poland, eléyìí ni yóò jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tí Ààrẹ yóò wá sí ìpàdé àwọn ìgbìmọ̀ tó wà lára àjọ àgbáyé tí wọ́n ń rí sí bí ojú ọjọ́ ṣe ń yí padà (COP24 of Climate Change (UNFCCC), ní èyí tí yóò wáyé ní ọjọ́ kejì sí ọjọ́ kẹ́rin, oṣù kejìlá ọdún yìí." +Aare fi idunnu re han pelu iroyin ti asoju orile-ede Poland Eric Adagogo Bell-Gam so nipa awon omo orile-ede Naijiria to n gbe inu ilu naa. Ààrẹ fi ìdùnnú rẹ̀ hàn pẹ̀lú ìròyìn tí aṣojú orílẹ̀-èdè Poland Eric Adagogo Bell-Gam sọ nípa àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń gbé inú ìlú náà. +Lori eto oro-aje, aare ni ijoba oun ti da kiko ounje lati oke okun wa si orile-ede Naijiria duro, paapaa julo iresi. Lórí ètò ọrọ̀-ajé, ààrẹ ní ìjọba òun ti dá kíkó oúnjẹ láti òkè òkun wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dúró, pàápàá jùlọ ìrẹsì. +“Mo n gbiyanju lati ma se owo orile-ede yii basubasu, mo n jade nigba ti o ba pon dandan.” “Mò ń gbìyànjú láti má ṣe owó orílẹ̀-èdè yìí báṣubàṣu, mò ń jáde nígbà tí ó bá pọn dandan.” +Inu mi kii dun nigba ti mo n ba ri awon omode ti won toro owo ati ounje loju titi. Inú mi kìí dùn nígbà tí mo ń bá rí àwọn ọmọdé tí wọ́n tọrọ owó àti oúnjẹ lójú títì. +---Iko omo-ogun olote Taliban seku-pa olopaa Afghan mejilelogun. ---Ikọ̀ ọmọ-ogun ọlọ̀tẹ̀ Taliban ṣekú-pa ọlọ́pàá Afghan méjìlélógún. +O kere tan olopaa mejilelogun l’o padanu emi won ninu ikolu iko omo ogun olote Taliban sile-ise olopaa Afghan lagbegbe Farah lojo Aiku. Ó kéré tán ọlọ́pàá méjìlélógún l’ó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù ikọ̀ ọmọ ogun ọlọ́tẹ̀ Taliban sílé-iṣẹ́ ọlọ́pàá Afghan lágbègbè Farah lọ́jọ́ Àìkú. +Agbenusoro fun ile-ise olopaa Afghan, Mohebullah Moheb lo jabo oro naa sugbon ti salaye bi oro ohun se lo lekunrere. Agbẹnusọ̀rọ̀ fún ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá Afghan, Mohebullah Moheb ló jábọ̀ ọ̀rọ̀ náà ṣùgbọ́n ti ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ ọ̀hun ṣe lọ lẹ́kùnrẹ́rẹ́. +Agbenusoro iko olote Taliban, Qari Yousuf Ahmadi so pe, olopaa marundinlogbon ti o fi mo awon oga agba olopaa ni won seku-pa, ti won si dana sun oko olopaa merin. Agbenusọ̀rọ̀ ikọ̀ ọlọ́tẹ̀ Taliban, Qari Yousuf Ahmadi sọ pé, ọlọ́pàá márùndínlógbọ́n tí o fi mọ àwọn ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ni wọ́n ṣekú-pa, tí wọ́n sì dáná sun ọkọ̀ ọlọ́pàá mẹ́rin. +Ewe, agbenusoro nile iwosan ti won gbe awon ti o fara kaasa ikolu ohun lo so pe, eniyan mejilelogun ni won ti gbe wo ile iwosan naa lati ibi ti isele ohun ti waye. Ẹ̀wẹ̀, agbenusọ̀rọ̀ nílé ìwòsàn tí wọ́n gbé àwọn tí ó fara kaasa ìkọlu ọ̀hún ló sọ pé, ènìyàn méjìlélógún ni wọ́n ti gbé wọ ilé ìwòsàn náà láti ibi tí ìṣ̀ẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ti wáyé. +Ipadanu naa ti n waye ni lemo-lemo, ti o fi je pe osise akoroyin ile Amerika siluu Afghan ti pe fun ijiroro alaafia pelu iko olote Taliban. Ìpàdànù náà ti ń wáyé ní lemọ́-lemọ́, tí ó fi jẹ́ pé òṣìṣẹ́ akọ̀ròyìn ilẹ̀ Améríkà sílùú Afghan ti pè fún ìjíròrò àlááfíà pẹ̀lú ikọ̀ ọlọ́tẹ̀ Taliban. +---Aare Buhari gba ami eye fun akitiyan lati dena arun romolapa-romolese. ---Ààrẹ Buhari gbà àmì ẹ̀yẹ fún akitiyan láti dénà àrùn rọmọlápá-rọmọlẹ́sẹ̀. +Aare Muhammadu Buhari ti gba ami eye ti arun romolaparomolese fun gudugudu meje, yaya mefa ti ijoba re ti se lati gbogun ti aarun yii l’orile-ede Naijiria. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti gba àmì ẹ̀yẹ ti àrùn rọmọlaparọmọlẹ́sẹ̀ fún gudugudu méje, yàyà mẹfà tí ìjọba rẹ̀ ti ṣe láti gbógun ti ààrùn yìí l’órílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Aare egbe Rotary International, Barry Rassin, ti o wa fun irinajo olojo merin si orile-ede Naijiria, l’o gbe ami eye naa fi da Aare Buhari lola nile Aare t’o wa lorile-ede Naijiria, ni ojo Ojobo. Ààrẹ ẹgbẹ́ Rotary International, Barry Rassin, tí ó wá fún ìrìnàjò ọlọ́jọ́ mẹ́rin sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, l’ó gbé àmì ẹ̀yẹ náà fi dá Ààrẹ Buhari lọ́lá nílé Ààrẹ t’ó wà lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ní ọjọ́ Ọjọ́bọ̀. +Egbe Rotary international ti maa n fun awon adari orile-ede ati ile ise ti o ba fakoyo ninu igbiyanju won lati dena arun romo-lapa-romo-lese l’orile-ede won. Ẹgbẹ́ Rotary international ti máa ń fún àwọn adarí orílẹ̀-èdè àti ilé iṣẹ́ tí ó bá fakọyọ nínú ìgbìyànjú wọn láti dénà àrùn rọ́mọ-lapa-rọ́mọ-lẹ́sẹ̀ l’órílẹ̀-èdè wọn. +Eni t’o gba ami eye ohun keyin ni Justin Trudeau, ti o je Adari Ijoba orile-ede Canada. Ẹni t’ó gba àmì ẹ̀yẹ ọ̀hún kẹ́yìn ni Justin Trudeau, tí ọ́ jẹ́ Adarí Ìjọba orílẹ̀-èdè Canada. +Lara awon eniyan ti o tun ti gba ami eye ohun ni adari ijoba orile-ede Japan Shinzo Abe, adari orile-ede Germany Angela Merkel ati akowe agba fun ajo agbaye teleri Ban Ki-Moon. Lára àwọn ènìyàn tí ó tún ti gba àmì ẹ̀yẹ ọ̀hún ni adarí ì̀jọba orílẹ̀-èdè Japan Shinzo Abe, adarí orílẹ̀-èdè Germany Angela Merkel àti akòwe àgbà fún àjọ àgbáyé tẹ́lẹ̀rí Ban Ki-Moon. +Nigba ti Aare n tewogba ami eye yii, o dupe lowo egbe Rotary International fun ami eye ti won fi da a lola. Nígbà tí Ààrẹ ń tẹ́wọ́gba àmì ẹ̀yẹ yìí, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ Rotary Internàtional fún àmì ẹ̀yẹ tí wọn fi da a lọ́lá. +’’Iran mi mo egbe Rotary International bi eni m’owo. Ni t’ooto, ise yin ni i se pelu omoniyan; ko si iye ohunkohun ti o le san awon ise ribi-ribi ti e n gbe se, a dupe lowo yin gidi gan-an. ’’Ìran mi mọ́ ẹgbẹ́ Rotary International bí ẹní m’owó. Ní t’òóto, iṣẹ́ yín ní í ṣe pẹ̀lú ọmọnìyàn; kò sí iye ohunkóhun tí ó lè san àwọn iṣẹ́ ribi-ribi tí ẹ̀ ń gbé ṣe, a dúpẹ́ lọ́wọ́ yín gidi gan-an. +‘‘Inu mi dun si ipa pataki ti e n ko lawujo, e je alagbara fun awon ti ko lagbara, mo gbadura pe ki Olorun san awon oore ti e n se wonyin fun un yin ni ilopo fun ise omoniyan yin. ‘‘Inú mi dùn sí ipa pàtàkì tí ẹ̀ ń kó láwùjọ, ẹ jẹ́ alágbára fún àwọn tí kò lágbára, mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run san àwọn oore tí ẹ ń ṣe wọ̀nyín fún un yín ní ìlópo fún iṣẹ́ ọmọnìyàn yín. +Aare ni “inu mi dun pe mo ni akosemose Minisita fun eto ilera, ti o n bojuto ise naa. Ààrẹ ní “inú mi dùn pé mo ní akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ Mínísítà fún ètò ìlera, tí ó ń bójútó iṣẹ́ náà. +’’Ogbeni Rassin wa gbosuba fun Aare Buhari fun ise gudu gudu meje yaya mefa ti o n se lati dekun arun romolaparomolese l’orile-ede Naijiria. ’’Ọ̀gbẹ́ni Rassin wá gbóṣùbà fún Ààrẹ Buhari fún iṣẹ́ gudu gudu méje yàyà mẹfà tí ó ń ṣe láti dẹ́kun àrùn rọmọlápárọmọlẹ́sẹ̀ l’órílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +O tun ro Aare lati tubo mu ki eto iselu ati owo ayasoto o gbe fuke si i ki gbogbo ipele fun eto ibupa ati ilera abele o ba kesejari. Ó tún rọ Ààrẹ láti túbọ̀ mú kí ètò ìṣèlú àti owó àyàsọ́tọ̀ ó gbé fúkẹ́ sí i kí gbogbo ìpele fún ètò ìbupá àti ìlera abélé ó ba kẹ́sẹjárí. +---Trump yoo yan ogagun teleri gege bi asoju sile Saudi Arabia. ---Trump yóò yan ọ̀gágun tẹ́lẹ̀rí gẹ́gẹ́ bí aṣojú sílẹ̀ Saudi Arabia. +Aare ile Amerika, Donald Trump ti yan ogagun iko omo ogun orile-ede naa ti o ti feyin ti gege bi asoju ile Amerika si orile-ede Saudi Arabia, gege bi ilu Washington naa se n koju idojuko latari iku akoroyin omobibi ile Saudi, Jamal Khashoggi ti o ku si Ile-ise Asoju Ijoba Saudi ni Istanbul. Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Donald Trump ti yan ọ̀gágun ikọ̀ ọmọ ogun orílé-èdè náà tí ó ti fẹ̀yìn tì gẹ́gẹ́ bí aṣojú ilẹ̀ Amẹ́ríkà sí orílé-èdè Saudi Arabia, gẹ́gẹ́ bí ìlú Washington náà ṣe ń kojú ìdojúkọ látàrí ikú akọ̀ròyìn ọmọbíbí ilẹ̀ Saudi, Jamal Khashoggi tí ó kú sí Ilé-iṣẹ́ Aṣojú Ìjọba Saudi ní Istanbul. +Ile-ise Aare soro ohun di mimo pe Aare Trump ti yan ogagun teleri ohun, John Abizaid, leni ti o tuko omo ogun ile Amerika lasiko ogun pelu orile-ede Iraq. Ilé-iṣẹ́ Ààrẹ sọ̀rọ̀ ọ̀hún di mímọ̀ pé Ààrẹ Trump ti yan ọ̀gágun tẹ́lẹ̀rí ọ̀hún, John Abizaid, lẹ́ni tí ó tukọ̀ ọmọ ogun ilẹ̀ Amẹ́ríkà lásìkò ogun pẹ̀lú orílé-èdè Iraq. +Ni bayii, ireti wa pe ile igbimo asofin ile Amerika yoo sepade lati bowolu iyansipo tuntun naa. Ní báyìí, ìrètí wà pé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà yóò ṣèpàdé láti bọwọ́lu ìyànsípò tuntun náà. +Ni afikun si iku Khashoggi, ile Washington fesun kan awon asofin ile Amerika fun sise atileyin fun iko omo ogun ile Saudi Arabia ninu ogun ile Yemen. Ní àfikún sí ikú Khashoggi, ilẹ̀ Washington fẹ̀sùn kan àwọn aṣòfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà fún ṣíṣe àtìlẹ́yìn fún ikọ̀ ọmọ ogun ilẹ̀ Saudi Arabia nínú ogun ilẹ̀ Yemen. +Orile-ede Amerika ko i tii ni asoju sile Saudi Arabia lati igba ti Aare Trump ti gori aleefa lodun 2017. Orílé-èdè Amẹ́ríkà kò ì tíì ní aṣojú sílẹ̀ Saudi Arabia láti ìgbà tí Ààrẹ Trump ti gorí àlééfà lọ́dún 2017. +Olugbani-nimoran lori eto aabo nile ise Aare Trump John Bolton so lojo isegun pe, oun ko ro pe awon akasile aworan ti o ro mo iku Khashoggi, ti awon ara ile Turkey n pin kaakiri, lowo omooba ile Saudi, Mohammed bin Salman ninu. Olùgbani-nímọ̀ràn lórí ètò ààbò nílé iṣẹ́ Ààrẹ Trump John Bolton sọ lọ́jọ́ ìṣẹ́gun pé, òun kò rò pé àwọn àkásílẹ̀ àwòran tí ó rọ̀ mọ́ ikú Khashoggi, ti àwọn àra ilẹ̀ Turkey ń pín káàkiri, lọ́wọ́ ọmọọba ilẹ̀ Saudi, Mohammed bin Salman nínú. +Naijiria fe ijiya to nipon fun awon t’o n se owo ilu mokumoku. Nàìjíríà fẹ́ ìjìyà tó nípọn fún àwọn t’ó ń ṣe owó ìlú mọ́kumọ̀ku. +Aare orile-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ni Paris lojo Aiku, pe fun igbese ijiya ti o gbopon fun awon onijibiti owo, titi kan isegi owo palaba awon ibi ibapamo won. Ààrẹ orílé-èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ní Paris lọ́jọ́ Àìkú, pè fún ìgbésẹ̀ ìjìyà tí ó gbópọn fún àwọn oníjìbìtì owó, títí kan ìségi ọwọ́ pálábá àwọn ibi ìbapamọ́ wọn. +O kilo pe abale-abale iwa kosenimaamfumi yoo tubo mu ki ise owo ilu mokumoku o po si i ti o maa n se akoba fun awon mekunnu ati awon ara ilu. Ó kìlọ̀ pé àbálé-àbálé ìwà kòsẹ́nimáamfúmi yóò túbọ̀ mú kí ìṣe owó ìlú mọ́kumọ̀ku ó pọ̀ sí i tí ó máa ń ṣe àkóbá fún àwọn mẹ̀kúnnù àti àwọn ará ìlú. +Aare soro yii lasiko ipade to waye ni Paris, Aare ni orile-ede Naijiria ti satunse si awon ofin ati ilana re lati gbogun ti iwa ibaje ati lati gba awon owo ti awon oniwa ibaje kan ko salo si orile-ede miiran, ki won si tun fi imu awon obayeje naa jofin. Ààrẹ sọ̀rọ̀ yìí lásìkò ìpàdé tó wáyé ní Paris, Ààrẹ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ṣàtúnṣe sí àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ láti gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ àti láti gba àwọn owó tí àwọn oníwà ìbàjẹ́ kán kó sálọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, kí wọn sì tún fi imú àwọn ọ̀bàyéjẹ́ náà jófin. +Oro Aare da lori “Ibaje sise owo ilu basu-basu ati Riba: Ipenija lori Isejoba Agbaye’’ eyi ti awon aadorin adari orile-ede agbaye ati ijoba wa nibi ipade naa. Ọ̀rọ̀ Ààrẹ dá lórí “Ìbàjẹ́ ṣíṣe owó ìlú báṣu-bàṣu ati Rìbà: Ìpèníjà lórí Ìṣèjọba Àgbáyé’’ èyí tí àwọn àádọ́rin adarí orílẹ̀-èdè àgbáyé àti ìjọba wà níbi ìpàdé náà. +“A gbodo gbogun ti iwa ibaje ni gbogbo ona. “A gbọ́dọ̀ gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ ní gbogbo ọ̀nà. +Aare tun so pe “mo ti ba awon egbe agbofinro, ile–ifowopamo, awon osise ijoba ati awon miiran soro lati satileyin fun ijoba nipa gbigbogun ti iwa ibaje. Ààrẹ tún sọ pé “mo ti bá àwọn ẹgbẹ́ agbófinró, ilé–ìfowópamọ́, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àti àwọn mìíràn sọ̀rọ̀ láti ṣàtìlẹ́yìn fún ìjọba nípa gbígbógun ti ìwà ìbàjẹ́. +“Iriri wa lorile-ede Naijiria ti fihan pe iwa ibaje nipa sise owo ilu kumo-kumo maa n je ki awon eniyan je ere nibi ti won ko sise si ti ijiya lilo si ewon ko to lati je ki awon oniwa ibaje wonyi ronu piwada “Ìrírí wà lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti fihàn pé ìwà ìbàjẹ́ nípa ṣíṣe owó ìlú kúmọ-kùmọ máa ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn jẹ èrè níbi tí wọn kò ṣiṣé sí tí ìjìyà lílọ sí ẹ̀wọ̀n kò tó láti jẹ́ kí àwọn oníwà ìbàjẹ́ wọ̀nyí ronú pìwàdà +"""Adari orile-ede Naijiria wa ro awon adari ijoba agbaye lati tepele mo ilana ti won towobo nibi ipade to waye niluu London lodun 2016 nipa gbigbogun ti iwa ibaje." """Adarí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wá rọ àwọn adarí ìjọba àgbáyé láti tẹpẹlẹ mọ́ ìlànà tí wọ́n tọwọ́bọ̀ nibi ìpàdé tó wáyé nílùú London lọ́dún 2016 nípa gbígbógun ti ìwà ìbàjẹ́." +Aare ni awon orile-ede Afirika ti gbosuba fun oun nipa igbese ti o n gbe lati gbokun ti iwa ibaje lorile-ede Naijiria, ni eyi ti o ti je ki ibasepo laaarin awon orile-ede Afirika won tun gun rege. Ààrẹ ni àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà ti gbóṣùbà fún òun nípa ìgbésẹ̀ tí ó ń gbé láti gbókun ti ìwà ìbàjẹ́ lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ní èyí tí ó ti jẹ́ kí ìbáṣepọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà wọn tún gún régé. +Aare Buhari tun ni eto ti ijoba oun fi gunle lati maa sofofo awon t’o ba ji owo ilu, ti so eso rere nipa pe opolopo owo bilionu ni won ti ri gba pada lowo awon obayeje, ni eyi ti won ti lo lati pese awon ohun amayederun ati eto ti awon omo orile-ede Naijiria yoo je anfaani re ati afojuba awon Imuro Ilepa Idagbasoke. Ààrẹ Buhari tún ní ètò tí ìjọba òun fi gúnlẹ̀ láti máa ṣòfófó àwọn t’ó bá jí owó ìlú, ti so èso rere nípa pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó bílíọ́nù ni wọ́n ti rí gbà padà lọ́wọ́ àwọn ọ̀bàyéjẹ́, ní èyí tí wọ́n ti lọ láti pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn àti ètò tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò jẹ ànfààní rẹ̀ àti àfojúba àwọn Ìmúró Ìlépa Ìdàgbàsókè. +Adarikunrin ati Adaribinrin ti Cornwall de si orile-ede Naijiria. Adaríkùnrin àti Adaríbìnrin ti Cornwall dé sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Omooba Wales, to tun je aremo si ipo oba ni orile-ede Britain, Charles ati Adaribinrin Cornwall, Camilla ti de si ilu Abuja. Ọmọoba Wales, tó tún jẹ́ àrẹ̀mọ sí ipò ọba ní orílẹ̀-èdè Britain, Charles àti Adaríbìnrin Cornwall, Camilla ti dé sí ìlú Àbújá. +Wiwa si orile-ede Naijiria wa lara irinajo re lo si ilu Afirika. Wíwá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà lára ìrìnàjò rẹ̀ lọ sí ìlú Áfíríkà. +Awon eto ti won yoo ti maa kopa. Awon omooba yii yoo maa kopa ninu awon eto olokan-o-jokan niluu Abuja ati ni ilu Eko. Àwọn ètò tí wọn yóò ti máa kópa. Àwọn ọmọọba yìí yóò máa kópa nínú àwọn ètò ọlọ́kan-ò-jọ̀kan nílùú Àbújá àti ní ìlú Èkó. +Won yoo maa ba awon odo orile-ede yii soro ati awon oba alade, awon onisowo, awon omo–ologun, awon ayaworan, awon onise-owo ati awon ile-ise ti kii se ti aladaani. Wọn yóò máa bá àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè yìí sọ̀rọ̀ àti àwọn ọba aládé, àwọn oníṣòwò, àwọn ọmọ–ológun, àwọn ayàwòrán, àwọn oníṣe-òwò àti àwọn ilé-iṣé tí kìí ṣe ti aládàáni. +Lara awon ohun ti orile-ede mejeeji naa yoo maa jiroro ni bi ibasepo won yoo se tun tubo maa tesiwaju, okoowo, eko fun awon obinrin ati omidan ati nnkan miiran. Lára àwọn ohun tí orílẹ̀-èdè méjèèjì náà yóò máa jíròrò ni bi ìbáṣepọ̀ wọn yóò ṣe tún túbọ̀ máa tẹ̀síwájú, okoòwò, ẹ̀kọ́ fún àwọn obìnrin àti omidan àti nǹkan mìíràn. +Eleyii ni yoo je igba keta ti Omooba Wales naa yoo wa se ibewo ni orile-ede Naijiria, o koko wa si orile-ede Naijiria lodun 1990, 1999, ati odun 2006, sugbon igba akoko niyi fun Adari-obinrin ti ilu Cornwall lati wa si orile-ede Naijiria. Eléyìí ni yóò jẹ́ ìgbà kẹta tí Ọmọọba Wales náà yóò wa ṣe ìbẹ̀wò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó kọ́kọ́ wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dún 1990, 1999, àti ọdún 2006, ṣùgbọ́n ìgbà àkọ̀kọ́ nìyí fún Adarí-obìnrin ti ìlú Cornwall láti wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +---Naijiria seleri lati je ki awon eniyan jegbadun eto ijoba tiwa-n-tiwa. ---Nàìjíríà ṣèlérí láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn jẹ̀gbádùn ètò ìjọba tiwa-n-tiwa. +Ijoba orile-ede ti ni ohun ko ni kaaree lati tubo lowo ninu idagbasoke ohun amayederun jake-jado orile-ede Naijiria. Ìjọba orílẹ̀-èdè ti ní ohun kò ní káàrẹ́ẹ̀ láti túbọ̀ lọ́wọ́ nínú ìdàgbàsókè ohun amáyédẹrùn jákè-jádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Aare Muhammadu Buhari lo so eleyii lojo Aje, nibi oro ikeyin to so nile Aare t’o wa niluu Abuja lasiko eto idagbere ti won se fun asoju orile-ede Britain, Paul Arkwright ti o n pada lo siluu re. Ààrẹ Muhammadu Buhari lọ́ sọ eléyìí lọ́jọ́ Ajé, níbi ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tó sọ nílé Ààrẹ t’ó wà nílùú Àbújá lásìkò ètò ìdágbére ti wọn ṣe fún asojú orílẹ̀-èdè Britain, Paul Arkwright tí ó ń padà lọ sílùú rẹ̀. +O so pe: “Ifojusun wa ni lati mu idagbasoke ba ohun amayederun; oju-popo, oju irin, ina mona-mona, ati awon ohun miiran. Ó sọ pé: “Ìfojúsùn wá ni láti mú ìdàgbàsókè bá ohun amáyéderùn; ojú-pópó, ojú irin, iná mọ̀nà-mọ́ná, àti àwọn ohun mìíràn. +Inu mi iba dun pupo t’o ba je pe, a ti se gbogbo eleyii nigba ti a ni owo lowo Inú mi ìbá dùn púpọ̀ t’ó bá jẹ́ pé, a ti ṣe gbogbo eléyìí nígbà tí a ní owó lọ́wọ́ +O so wi pe pelu owo to wole si apo isuna orile-ede yii lati odun 1999 si 2014 wa ninu akosile sugbon won ko lo owo yii dara-dara lati fi pese ohun amayederun nigba naa. Ó sọ̀ wí pé pẹ̀lú owó tó wọlé sí àpò ìṣúná orílẹ̀-èdè yìí láti ọdún 1999 sí 2014 wà nínú àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n wọn kò lo owó yìí dára-dára láti fi pèsè ohun amáyéderùn nígbà náà. +Aare Buhari wa gbosuba fun Asoju orile-ede Britan fun gudu-gudu, meje yaya mefa ti o se lasiko igba ti o je asoju orile-ede yii. Ààrẹ Buhari wá gbóṣùbà fún Aṣojú orílẹ̀-èdè Britan fún gudu-gudu, méje yàyà mẹfà tí ó ṣe lásìkò ìgbà tí ó jẹ́ aṣojú orílẹ̀-èdè yìí. +Aare tun ni “Mo maa n ri o ni gbogbo awon ipinle orile-ede yii. Ààrẹ tún ní “Mo máa ń rí ọ ní gbogbo àwọn ìpínlẹ̀ orílẹ̀-èdè yìí. +""" Arkwright, t’o ti lo odun meta lorile-ede Naijiria naa so pe ohun ti lo si ipinle ogbon ninu ipinle merindinlogoji, o si ni awon omo orile-ede yii je olopolo t’o nifee alejo, o wa seleri pe orile-ede Britain yoo tubo maa seto iranwo fun agbegbekagbegbe ni orile-ede naa." """ Arkwright, t’ó ti lo ọdún mẹ́ta lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà náà sọ pé òhún ti lọ sí ìpínlẹ̀ ọgbọ̀n nínú ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì, ó sì ní àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí jẹ́ ọlọ́pọlọ t’ó nífẹ̀ẹ́ àlejò, ó wá ṣèlérí pé orílẹ̀-èdè Britain yóò túbọ̀ máa ṣètò ìràńwọ́ fún agbègbèkágbègbè ní orílẹ̀-èdè náà." +O wa dupe lowo Aare Buhari fun atileyin re, o ni ibasepo to wa laaarin orile-ede Britain ati orile-ede Naijiria ti tun ni idagbasoke ju bi o se wa tele lo laaarin odun meta. Ó wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ààrẹ Buhari fún àtìlẹ́yìn rẹ̀, ó ní ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín orílẹ̀-èdè Britain àti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti tún ní ìdàgbàsóké ju bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ lọ láàárín ọdún mẹ́ta. +---Awon to n wa ekusa l’orile-ede Naijiria yoo je anfaani bilionu marun-un owo iranwo. ---Àwọn tó ń wa ekùsà l’órílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò jẹ́ àǹfààní bílíọ́nù márùn-ún owó ìrànwó. +Ijoba apapo ti fi oruko egbe awon to n wa ekusa lorile-ede Naijiria si ara awon ti yoo je anfaani bilionu marun-un ti won ya soto lati fi ran awon onise–owo ati onisowo keekeeke lowo ni jake–jado orile-ede. Ìjọba àpapọ̀ ti fi orúkọ ẹgbẹ́ àwọn tó ń wa ekùsà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà sí ara àwọn tí yóò jẹ àǹfààní bílíónù márùn-ún tí wọ́n yà sọ́tọ̀ láti fi ran àwọn oníṣẹ́–ọwọ́ àti oníṣòwò kéékèèké lọ́wọ́ ní jáke–jádò orílẹ̀-èdè. +Igbimo alase naa so pe ijoba apapo ti seleri lati fi egbe naa si ara awon ti yoo je anfaani bilionu marun un naa. Ìgbìmọ̀ aláṣẹ náà sọ pé ìjọba àpapọ tí ṣèlérí láti fi ẹgbẹ́ náà sí ara àwọn tí yóò jẹ àǹfààní bílíọ́nù márùn ún náà. +Aare egbe naa, Alhaji Sani Shehu lo so eleyii niluu Abuja pe ajo to n mojuto wiwa ekusa ati irin lorile-ede Naijiria ni won gbe igbese yii. Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Alhaji Sani Shehu ló sọ eléyìí nílùú Àbújá pé àjọ tó ń mójútó wíwa ekùsà àti irin lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n gbé ìgbésẹ̀ yìí. +O ni bi won se fi egbe naa sinu ipinnu won yoo je ki idagbasoke tubo ba awon to n wa ekusa lorile-ede Naijiria. Ó ní bí wọ́n ṣe fi ẹgbẹ́ náà sínú ìpinnu wọn yóò jẹ́ kí ìdàgbàsókè túbọ̀ ba àwọn tó ń wa ekùsà lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Egbe to n wa ekusa lorile-ede Naijiria ti koko fi edun okan won nipa isoro ti egbe won n dojuko lati ri owo gba lati odo Banki to n moju to oro to je mo idagbasoke ise, ti o letoo lati fi owo ran won lowo fun idagbasoke ise won. Egbẹ́ tó ń wa ekùsà lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti kọ́kọ́ fi ẹ̀dùn ọkàn wọn nípa ìṣòro tí ẹgbẹ́ wọn ń dojúko láti rí owó gbà láti ọ̀dọ̀ Báńkì tó ń mójú tó ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìdàgbàsókè iṣẹ́, tí ó lẹ́tọ̀ọ́ láti fi owó ràn wọn lọ́wọ́ fún ìdàgbàsókè iṣẹ́ wọn. +Idagbasoke ile-ise igbese naa wa lara ipinnu ijoba apapo lati ran awon ile-ise keekeeke lowo, ni eyi ti idagbasoke yoo fi de ba eto oro-aje orile-ede yii. Ìdàgbàsókè ilé-iṣẹ́ ìgbésè náà wà lára ìpinnu ìjọba àpapọ̀ láti ran àwọn ilé-iṣẹ́ kéékéékè lọ́wọ́, ní èyí tí ìdàgbàsókè yóò fi dé ba ètò ọrọ̀-ajé orílẹ̀-èdè yìí. +Igbese yii tun wa lara ipinnu ijoba lati tan isoro t’o maa n dojuko awon onise owo ati awon onisowo iwakusa keekeeke. Ìgbésẹ̀ yìí tún wà lára ìpinnu ìjọba láti tán ìṣòro t’ó máa ń dojúko àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ àti àwọn oníṣòwò ìwakùsà kéékéékè. +O ni ajo naa ti ri isoro ti o n dena awon to n wa ekusa lati maa jeki won ri anfaani eyawo ohun. Ó ní àjọ náà ti rí ìṣòro tí ó ń dènà àwọn tó ń wa èkùsà láti máa jẹ́kí wọ́n rí àǹfààní èyáwó òhún. +O tun so pe “ijoba ti fun wa ni anfaani lati lowo nibi eto eyawo naa, won si ti seleri pe awon omo egbe wa yoo je anfaani eto eyawo ohun. Ó tún sọ pé “ìjọba ti fún wa ní àǹfààní láti lọ́wọ́ níbi etò ẹ̀yáwó náà, wọ́n sí ti ṣèlérí pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa yóò jẹ àǹfààní ètò ẹ̀yáwó ọ̀hún. +O so pe “inu wa dun si eyi, ajo to n mojuto oro to je mo wiwa ekusa ati irin, banki to n ri si oro to je mo ile-ise ati egbe wa yoo fowosowopo lati se ipinnu lori ona ti awon omo egbe wa yoo se maa je anfaani eto eyawo naa.” Ó sọ pé “inú wa dùn sí èyí, àjọ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ wíwá ekùsà àti irin, báńkì tó ń rí sí ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ilé-iṣẹ́ àti ẹgbẹ́ wa yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ láti ṣe ìpinnu lórí ọ̀nà tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa yóò ṣe máa jẹ àǹfààní ètò èyáwó náà.” +Shehu tun so pe gbogbo igbese ni awon ti gbe bayii lati ri i pe won ri eto eyawo naa gba, bakan naa ni egbe naa ni yoo duro fun omo egbe won lati ya owo naa. Shehu tún sọ pé gbogbo ìgbésẹ̀ ni àwọn ti gbé báyìí láti rí i pé wọ́n rí ètò èyáwó náà gbà, bákan náà ni ẹgbẹ́ náà ni yóò dúró fún ọmọ ẹgbẹ́ wọn láti yá owó náà. +---NIBUCAA: Ajo Isokan Agbaye yoo satileyin fun Naijiria lati gbogun ti arun kogboogun. ---NIBUCAA: Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé yóò sàtìlẹ́yìn fún Nàìjíríà láti gbógun ti àrùn kògbóògùn. +Ajo agbaye ti ni aarun kogboogun HIV/AIDS ni i se pelu ilera awon eniyan, nitori naa, ajo agbaye ti setan lati se awon eto ti yoo maa satileyin fun orile-ede Naijiria, ni eyi ti yoo fi dekun itankale aarun kogboogun lorile-ede Naijiria. Àjọ àgbáyé ti ní ààrùn kògbóògùn HIV/AIDS ní í ṣe pèlú ìlera àwọn ènìyàn, nítorí náà, àjọ àgbáyé ti ṣetán láti ṣe àwọn ètò tí yóò máa ṣàtìlẹ́yìn fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ni èyí tí yóò fi dẹ́kun ìtànkálẹ̀ ààrùn kògbóògùn lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Asoju ajo agbaye ni eka eto to n ri si gbigbogun ti arun kogboogun Erasmus Murah l’o soro yii nibi eto ti ajo t’o n gbogunti arun kogboogun lorile-ede Naijiria NIBUCAA se niluu Abuja, lojoRu ose yii. Aṣojú àjọ àgbáyé ní ẹ̀ka ètò tó ń rí sí gbígbógun tí àrùn kògbóògùn Erasmus Murah l’ó sọ̀rọ̀ yìí níbi ètò tí àjọ t’ó ń gbógunti àrùn kògbóògùn lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà NIBUCAA ṣe nílùú Àbújá, lọ́jọ́Rú ọ̀ṣẹ̀ yìí. +Musa Shuabu, alaga igbimo ajo NiBUCAA naa so pe ipinnu lati je ki awon ile-ise aladaani lorile-ede Naijiria fowosowopo pelu ijoba apapo lati gbogun ti arun kokoro inu eje ati arun kogboogun (HIV/AIDS) bere ni odun marundinlogun seyin lasiko ijoba Aare ana olusegun Obasanjo. Musa Shuabu, alága ìgbìmọ̀ àjọ NiBUCAA náà sọ pé ìpinnu láti jẹ́ kí àwọn ilé-iṣẹ́ aládàáni lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ láti gbógun ti àrùn kòkòrò inú ẹ̀jẹ̀ àti àrùn kògbóògùn (HIV/AIDS) bẹ̀rẹ̀ ní ọdún màrúndínlógún ṣéyìn lásìkò ìjọba Ààrẹ àna olúṣégun Ọbásanjọ́. +"Musa Shuabu so pe ""a ti mu ipinnu wa se, nitori ife ti a ni si orile-ede Naijiria lati da ajo kan sile, ti yoo maa gbogun ti itankale arun kogboogun." "Musa Shuabu sọ pé ""a ti mú ìpinnu wá ṣẹ, nítorí ìfẹ́ tí a ní sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti dá àjọ kan sílẹ, ti yóò máa gbógun ti ìtànkálẹ̀ àrùn kògbóògùn." +Ajo NIBUCAA ti awon kan da sile ni odun marundinlogun seyin, ni o ti di gbaju-gbaja kaakiri gbogbo agbaye. Ajọ NIBUCAA tí àwọn kán dá sílẹ̀ ní ọdún màrúndínlógún sẹ́yìn, ni ó ti di gbajú-gbajà káàkiri gbogbo àgbáyé. +Musa Shuabu wa dupe lowo gbogbo awon ile-ise ati ajo fun atileyin won lati bi i odun marundinlogun seyin lati gbogun ti itankale arun kogboogun lorile-ede Naijiria, bi o tile je pe awon ipenija kan wa to n koju ajo naa. Musa Shuabu wá dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ilẹ́-iṣẹ́ àti àjọ fún àtileyin wọn láti bí i ọdún màrúndínlógún ṣẹ́yìn láti gbógun ti ìtànkálẹ̀ àrùn kògbóògùn lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìpẹ̀níjà kán wà tó ń kojú àjọ náà. +O tun wa ro won lati ma kaaare lati tubo maa se atileyin fun ajo NIBUCAA, nitori pe ise si tun n be lati se. Ó tún wà rọ̀ wọn láti má káàárẹ láti túbọ̀ máa ṣe àtìlẹ́yìn fún àjọ NIBUCAA, nítorí pé iṣẹ́ si tún ń bẹ láti ṣe. +Alakooso ajo NIBUCAA, Gbenga Alabi naa tun so pe ifowosowopo awon ile-ise aladaani pelu ijoba lati gbogun ti arun kogboogun se pataki pupo nitori pe owo kan ko gberu dori. Alákóòso àjọ NIBUCAA, Gbénga Àlàbí náà tún sọ pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ aládàáni pẹ̀lú ìjọba láti gbógun ti àrùn kògbóògùn ṣe pàtàkì púpọ̀ nítorí pé ọwọ́ kan kò gbẹ́rù dórí. +A ti ni omo egbe metadinlogoji bayii sibe anfaani si wa lati gba awon omo egbe tuntun to ba fe darapo mo wa, ki a le jo gbogunti itankale arun kogboogun lorile-ede Naijiria. A ti ní ọmọ ẹgbẹ́ mẹ́tàdínlógójì báyìí síbẹ̀ àǹfààní ṣì wà láti gba àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tuntun tó bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ wa, kí a lè jọ gbógunti ìtànkálẹ̀ àrùn kògbóògùn lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Ogbeni Gbenga Alabi tun tesiwaju pe ajo NIBUCAA tun n fowosowopo pelu ile-ise NACA lorile-ede Naijiria lati gbogun ti arun kogboogun, bee si ni opolopo awon aseyori ni won ti se nipa ifowosowopo yii. Ọ̀gbẹ́ni Gbénga Àlàbí tún tẹ̀síwájú pé àjọ NIBUCAA tún ń fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ NACA lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti gbógun ti àrùn kògbóògùn, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àṣeyọrí ni wọ́n ti ṣe nípa ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yìí. +O wa ro awon ile-ise aladaani lati ma kaaare nipa iranwo won lati tubo gbogun ti arun kogboogun lorile-ede Naijiria Ó wá rọ àwọn ilé-iṣẹ́ aládàáni láti má káàárẹ̀ nípa ìrànwọ́ wọn láti túbọ̀ gbógun ti àrùn kògbòógùn lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà +O tun tesiwaju pe opolopo aseyori ni ajo NiBUCAA ti se lati dekun itankale arun kogboogun lorile-ede Naijiria. Ó tún tẹ̀síwájú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣeyọrí ni àjọ NiBUCAA ti ṣe láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àrùn kògbóògùn lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Alabi so pe “Ajo NIBUCAA pelu ibasepo awon oluranlowo ti se gudu-dudu meje, yaya mefa lorile-ede Naijiria, lati gbogun ti arun kogboogun. Àlàbí sọ pé “Àjọ NIBUCAA pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ àwọn olùrànlọ́wọ́ ti ṣe gudu-dudu méje, yàyà mẹfà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, láti gbógun ti àrùn kògbóògùn. +Ajo NIBUCAA ti ran awon ipinle wonyi lowo. Àjọ NIBUCAA ti ran àwọn ìpínlẹ̀ wọ̀nyí lọ́wọ́. +Awon ipinle naa ni: Abia, Anambra, Akwa-Ibom, Cross River, Edo, FCT, Kaduna, Katsina, Ekiti, Imo, Enugu, Katsina, Plateau ati ipinle Oyo. Àwọn ìpínlẹ̀ náà ni: Abia, Anambra, Akwa-Ibom, Cross River, Edo, FCT, Kaduna, Katsina, Èkìtì, Imo, Enugu, Katsina, Plateau àti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. +Leyin ijiroro ni awon ile–ise aladaani, ile-ise ijoba ati awon ti oro kan fenuko lori ipinnu wonyii,: Lẹ́yìn ìjíròrò ni àwọn ilé–iṣẹ́ aládàáni, ilé-iṣẹ́ ìjọba àti àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn fẹnukò lórí ípinnu wọ̀nyìí,: +---Orile-ede Naijiria seleri lati pese eto iranwo fun Sao Tome ati Principe. ---Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣèlérí láti pèsè ètò ìrànwọ́ fún Sao Tome àti Principe. +Orile-ede Naijiria ti seleri lati pese eto iranwo lori ise akanse fun orile-ede Sao Tome ati Principe lasiko eto idibo ile igbimo asoju-sofin orile-ede naa, ti yoo waye ni ojo keje osu Kewaa odun yii Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ṣèlérí láti pèsè ètò ìránwọ́ lórí iṣẹ́ àkànṣe fún orílẹ̀-èdè Sao Tome àti Principe lásìkò ètò ìdìbò ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin orílẹ̀-èdè náà, ti yóò wáyé ní ọjọ́ keje oṣù Kẹwàá ọdún yìí +Minisita fun oro ile okeere lorile-ede Naijiria, ogbeni Geoffrey Onyeama lo soro yii lasiko iforowero, pelu awon akoroyin lati fi se ayeye ifeyinti lenu ise fun Olukunle Bamgbose, t’o je akowe agba fun ajo to n mojuto oro to je mo ile okeere. Mínísítà fún ọrọ̀ ilé òkèèrè lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ọ̀gbẹ́ni Geoffrey Onyeama ló sọ̀rọ̀ yìí lásìkò ìfọ̀rọ̀wérò, pẹ̀lú àwọn akọròyìn láti fi ṣe ayẹyẹ ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ fún Olúkúnlé Bámgbóṣé, t’ó jẹ́ akọ̀wé àgbà fún àjọ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ilẹ̀ òkèèrè. +Ogbeni Onyeama so pe, oun lo soju Aare orile-ede Niajiria, Muhammadu Buhari ni orile-ede Sao Tome ati Principe nipa ona ti won yoo gba lati pese eto iranwo ise akanse fun orile-ede naa. Ọ̀gbẹ́ni Onyeama sọ pé, òun lọ ṣojú Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nìàjíríà, Muhammadu Buhari ní orílẹ̀-èdè Sao Tome àti Principe nípa ọ̀nà tí wọn yóò gbà láti pèsè ètò ìrànwọ́ iṣẹ́ àkànṣe fún orílẹ̀-èdè náà. +Ogbeni Onyeama s’alaye pe “nipa ona ti a o gba lati pese eto iranwo ise akanse fun orile-ede Sao Tome ati Principe ni a se ran mi lo sibe. Ọ̀gbẹ́ni Onyeama ṣ’àlàyé pé “nípa ọ̀nà tí a ó gbà láti pèsè ètò ìrànwọ́ iṣẹ́ àkànṣe fún orílẹ̀-èdè Sao Tome àti Principe ni a ṣe rán mi lọ síbẹ̀. +"""O tun tesiwaju pe, “Aare nigbagbo lati pese eto iranwo fun awon orile-ede to fegbekegbe pelu orile-ede Naijiria, idi niyi ti Aare se pese eto iranwo fun won.”" """Ó tún tẹ̀síwájú pé, “Ààrẹ nígbàgbọ́ láti pèsè ètò ìrànwọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè tó fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìdí nìyí tí Ààrẹ ṣe pèsè ètò ìrànwọ́ fún wọn.”" +"""Minisita wa gbosuba fun akowe agba ana, Bamgbose, fun ise ribi-ribi ti o se lati mu idagbasoke ba ajo naa." """Mínísítà wá gbóṣùbà fún akọ̀wé àgbà àná, Bámgbóṣé, fún iṣẹ́ ribi-ribi tí o ṣe láti mú ìdàgbàsókè bá àjo náà." +“O je akinkanju eniyan, ti o fe lati fi gbogbo okan re se ise re, o ni gbogbo iwa abuda eniyan rere, o je oloooto lenu ise, mo si feran re. “Ó jẹ́ akínkanjú ènìyàn, tí ó fẹ́ láti fi gbogbo ọkàn rẹ̀ ṣe iṣẹ́ rẹ̀, ó ní gbogbo ìwà àbùdá ènìyàn rere, ó jẹ́ olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́, mo sì fẹ́ràn rẹ̀. +O so pe “Mo feran iru eniyan bayii lati ba se ise papo, ti ko ba fe nnkan kan, yoo salaye fun mi, a si tun gba mi nimoran, idi ti ko se fe iru re, nitori naa, a feran ara wa. Ó sọ pé “Mo fẹ́ràn irú ènìyàn báyìí láti bá ṣe iṣẹ́ papọ̀, tí kò bá fẹ́ nǹkan kan, yóò ṣàlàyé fún mi, á sì tún gbà mí nímọ̀ràn, ìdí tí kò ṣe fẹ́ irú rẹ̀, nítorí náà, a fẹ́ràn ara wa. +"""Bamgbose naa wa so pe, inu oun dun lati je akowe agba fun ajo naa, ati pe gbogbo ipinnu oun, ni oun mu se fun ajo naa lasiko to wa lori ipo naa." """Bámgbóṣé náà wá sọ pé, inú òun dùn láti jẹ́ akòwé àgbà fún àjọ náà, àti pé gbogbo ìpinnu òun, ni òún mú sẹ fún àjo náà lásìkò tó wà lórí ipò náà." +“Mo wa lati wa pelu “ibori werewere”, laaarin odun kan, gbogbo ipinnu mi, ni mo mu se, nitori naa, mo n lo gege bi Akowe Agba alaseyori. “Mo wà láti wá pẹ̀lú “ìborí wéréwéré”, láàárín ọdún kan, gbogbo ìpinnu mi, ni mo mú ṣe, nítorí náà, mò ń lọ gẹ́gẹ́ bí Akọ̀wé Àgbà aláṣeyọrí. +“Emi o lo gege bi eni ti inu re n baje, mo ti se ohun t’o ye ki n se. “Èmi ò lọ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí inú rẹ̀ ń bàjẹ́, mo ti ṣe ohun t’ó yẹ kí n ṣe. +“Inu mi dun pe, mo koju awon ipenija ti mo ba lenu ise yii, mo sc se aseyori lori re.” “Inú mí dùn pé, mo kọjú àwọn ìpèníjà tí mo bá lẹ́nu iṣẹ́ yìí, mo sc sẹ àṣeyọrí lórí rẹ̀.” +Ni oro tire “ohun ti o se koko ni pe ise n tesiwaju, mo ti se temi, awon yooku yoo se ti won, ti o ba se iwon tire, ise yoo lo siwaju. Ní ọ̀rọ̀ tirẹ̀ “ohun tí ó ṣe kókó ni pé iṣẹ́ ń tẹ̀síwájú, mo ti ṣe tèmi, àwọn yòókù yóò ṣe ti wọn, tí o bá ṣe ìwọn tìrẹ, iṣẹ́ yóò lọ síwájú. +"""Mo n ro eyin t’o wa leyin mi, lati tele gbogbo ilana ti mo ti la sile." """Mò ń rọ èyin t’ó wà lẹ́yìn mi, láti tẹ̀lẹ́ gbogbo ìlànà tí mo ti là sílè." +“Pelu ajosepo, a le e se aseyori lori awon ipenija ti a n dojuko nile ise wa. “Pẹ̀lú àjọṣepọ̀, a le è ṣe àṣeyọrí lórí àwọn ìpèníjà tí a ń dojúko nílé iṣẹ́ wa. +Akowe agba ti o n lo naa wa ro awon osise ajo naa, lati ma kaaare lori igbiyanju won, ki won si fi apeere rere lele. Akòwe àgbà tí ó ń lọ náà wá rọ àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà, láti má káàárẹ̀ lórí ìgbìyànjú wọn, kí wọ́n sì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ. +Asoju Olukunle Bamgbose n feyinti leyin odun marundinlogoji ti o lo lenu ise ijoba ni ajo naa. Aṣojú Olúkúnlé Bámgbóṣé ń fẹ̀yìntì lẹ́yìn ọdún márùndínlógójì tí ó lò lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba ní àjọ náà. +---Awon orile-ede t’o wa labe ECOWAS seleri lati se okoowo pelu China. ---Àwọn orílẹ̀-èdè t’ó wà lábẹ́ ECOWAS ṣèlérí láti ṣe okoòwò pẹ̀lú China. +Aare Muhammadu Buhari ti so pe orile-ede to wa labe ajo ECOWAS yoo tesiwaju lati maa se okoowo pelu orile-ede China nitori ibasepo to dan mooran to wa laaarin won ati awon orile-ede Asian. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti sọ pé orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ àjọ ECOWAS yóò tẹ̀síwájú láti máa ṣe okòòwò pẹ̀lú orílẹ̀-èdè China nítorí ìbáṣepọ tó dán mọ́ọ́rán tó wà láàárín wọn àti àwọn orílẹ̀-èdè Asian. +O soro yii lojo Aje, gege bi Alaga ajo ECOWAS nibi ipade to waye laaarin awon omo orile-ede China ati awon adari orile-ede Afirika ni China. Ó sọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́ Ajé, gẹ́gẹ́ bí Alága àjọ ECOWAS níbi ìpàdé tó wáyé láàárín àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè China àti àwọn adarí orílẹ̀-èdè Áfíríkà ní China. +Aare Muhammadu Buhari ni irinajo aare orile-ede China Xi Jinping ti salaye ni pataki ibasepo re pelu awon orile-ede Afirika. Ààrẹ Muhammadu Buhari ni ìrìnàjo ààrẹ orílẹ̀-èdè China Xi Jinping ti ṣàlàyé ni pàtàkì ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà. +Aare so pe: “Ajo ECOWAS yoo tun tesiwaju lati maa se ohun iwuri fun awon t’o ba da okoowo sile lati ile okeere. Ààrẹ sọ pé: “Àjọ ECOWAS yóò tún tẹ̀síwájú láti máa ṣe ohun ìwúrí fún àwọn t’ó bá dá okoòwò sílẹ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè. +Nitori naa, awon omo egbe ECOWAS n fe ki orile-ede China fun won ni anfaani lati maa ra tabi ta oja si orile-ede China. Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ECOWAS ń fẹ́ kí orílẹ̀-èdè China fún wọn ní àǹfààní láti máa rà tàbí ta ọjà sí orílẹ̀-èdè China. +"""Eto Ilana tuntun gege bi aare Xi Jinping se so, o ni ajo ECOWAS ko ni pe gbe eto ilana kan jade ni eyi ti yoo tun je ki awon omo egbe ECOWAS tun wa ona miiran nipa eto oro-aje ati lati maa se okoowo pelu orile-ede China." """Ètò Ìlànà tuntun gẹ́gẹ́ bi ààrẹ Xi Jinping ṣe sọ, ó ní àjọ ECOWAS kò ní pẹ́ gbé ètò ìlànà kan jáde ni èyí tí yóò tún jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ECOWAS tún wá ọ̀nà mìíràn nípa ètò ọrọ̀-ajé àti láti máa ṣe okoòwò pẹ̀lú orílẹ̀-èdè China." +“Awon omo egbe ECOWAS ti n seto ilana ti yoo tun je ki eto oro-aje won ni idagbasoke sii. “Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ECOWAS ti ń ṣ̀etò ìlànà ti yóò tún jẹ kí ètò ọrọ̀-ajé wọn ní ìdàgbàsókè sii. +Omo egbe ECOWAS tun fe ki awon omo orile-ede China wa fun ere igbafe lorile-ede Afirika. Ọmọ ẹgbẹ́ ECOWAS tún fẹ́ kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè China wá fún eré ìgbáfẹ́ lorílẹ̀-èdè Áfíríkà. +Awon ekun wa ni opolopo ohun nnkan igbafe. Àwọn ẹ̀kùn wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun nǹkan ìgbáfẹ́. +Pelu iranwo orile-ede China awon ibi igbafe yoo tun ni idagbasoke si i, ni eyi ti yoo se maa pese ise lopo janturu ati eyi ti yoo tun je ki osi di ohun afiseyin ti eegun n fi aso. Pẹ̀lú ìrànwọ́ orílẹ̀-èdè China àwọn ibi ìgbáfẹ́ yóò tún ní ìdàgbàsókè sí i, ní èyí tí yóò ṣe máa pèsè iṣẹ́ lọ́pọ̀ janturu àti èyí tí yóò tún jẹ́ ki òṣì di ohun àfìsẹ́yìn tí eégún ń fi aṣọ. +Alaga ECOWAS dupe lowo orile-ede China fun eto okoowo won nile Afirika. Alága ECOWAS dúpẹ́ lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè China fún ètò okoòwò wọn nílẹ̀ Áfíríkà. +“Lati odo ijoba, awon omo orile-ede Naijiria, awon Alase ati ijoba ajo ECOWAS, mo fe fi idupe wa han si ijoba ati awon omo Ile Olominira awon Eniyan China fun bi won se gba wa ni alejo nigba ti a de si orile-ede China. “Láti ọ̀dọ̀ ì̀jọba, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn Aláṣẹ àti ìjọba àjọ ECOWAS, mo fẹ́ fi ìdúpé wa hàn si ìjọba àti àwọn ọmọ Ilẹ̀ Olómìnira awon Ènìyàn China fún bí wọ́n ṣe gbà wá ní àlejò nígbà tí a dé sí orílẹ̀-èdè China. +“Orile-ede China lonii, ni oludokoowo t’o ga julo ni ekun ile Afirika yala ni ile-ise aladaani ati ile-ise ijoba, ti won si lowo ninu; ohun amayederun, ina mona-mona, eto agbe, ohun alumoni -ile, iyipada ojo ati eto ilera. “Orílẹ̀-èdè China lónìí, ni oludokoowo t’ó ga jùlọ ni ẹ̀kùn ìlé Áfíríkà yálà ní ilé-iṣẹ́ aládàáni àti ilé-iṣẹ́ ìjọba, tí wọn sì lọ́wọ́ nínú; ohun amáyédẹrùn, iná mọ̀nà-mọ́ná, ètò àgbẹ̀, ohun àlùmọ́nì -ilẹ̀, ìyípadà ọjọ́ àti ètò ìlera. +“China tun n pese eto iranwo fun awon alaini. “China tún ń pèsè ètò ìrànwọ́ fún àwọn aláìní. +opolopo ise akanse l’o n lo lowo ti o si je pe awon omo orile-ede China ni won n se awon ise akanse bi i oju-irin, ina mona-mona, oko oju ofuurufu ati opolopo oju ona oko t’o je owo orile-ede China. ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àkànṣe l’ó ń lọ lọ́wọ́ tí ó sì jẹ́ pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè China ni wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ àkànṣe bí i ojú-irin, iná mọ̀nà-mọ́ná, ọkọ̀ ojú òfuurufú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojú ònà ọkọ̀ t’ó jẹ́ owó orílẹ̀-èdè China. +Aare Muhammadu Buhari tun ran orile-ede China leti nipa kiko ile-ise ajo ECOWAS tuntun, Aare wa seleri pe awon omo egbe ECOWAS yoo maa se ohun iwuri lati je ki awon onisowo ile okeere wa da ile-ise sile ni ekun won. Ààrẹ Muhammadu Buhari tún rán orílẹ̀-èdè China létí nípa kíkọ́ ilé-iṣẹ́ àjọ ECOWAS tuntun, Ààrẹ wá ṣèlérí pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ECOWAS yóò máa ṣe ohun ìwúrí láti jẹ́ kí àwọn oníṣòwò ilè òkèèrè wá dá ilé-iṣẹ́ sílẹ́ ní ẹ̀kùn wọn. +O ni: “olola julo, a dupe fun ipade to waye laaarin orile-ede China ati ajo ECOWAS, a tun dupe lowo Aare Xi Jinping fun ileri ti o se lati ko ile-ise ECOWAS tuntun fun ajo naa. Ó ní́: “ọlọ́lá jùlọ, a dúpẹ́ fún ìpàdé tó wáyé láàárín orílẹ̀-èdè China àti àjọ ECOWAS, a tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ààrẹ Xi Jinping fún ìlérí tí ó ṣe láti kọ́ ilé-iṣẹ́ ECOWAS tuntun fún àjọ náà. +Jordan kilo lori ohun to le sele ti Amerika ba fopin si iranlowo Palestine. Jordan kìlò lórí ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tí Amẹ́ríkà bá fòpin sí ìrànlọ́wọ́ Palestine. +Minista fun oro ile okeere ni Jordan, ti se ikilo pe o lewu ti Amerika ba fopin si iranlowo yii nitori pe ajo to n risi oro awon asatipo Palestine UNRWA ko ni agbara lati pese ohun to ye fun won lasiko yii. Mínístà fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè ni Jordan, ti ṣe ìkìlọ̀ pé ó léwu tí Amẹ́ríkà bá fòpin sí ìrànlọ́wọ́ yìí nítorí pé àjọ tó ń rísí ọ̀rọ̀ àwọn aṣàtìpó Palestine UNRWA kò ní agbára láti pèsè ohun tó yẹ fún wọn lásìkò yìí. +Bayii, o le ni milionu meji asatipo ti won n satipo lati aarin gbungbun ila oorun ni eyi ti yoo yo sile ni kete ti Amerika ba ti yowo kuro. Báyìí, ó lé ní mílíọ́nù méjì aṣàtìpó tí wọn ń sàtipo láti àárín gbungbùn ilà oòrùn ní èyí tí yóò yọ sílẹ̀ ní kété tí Amẹ́ríkà bá ti yọwọ́ kúrò. +Ayman Safadi to je minisita fun ile okeere ni o bani lokan je pe Washington yowo owo iranwo iranlowo Ajo isokan Agbaye ati Ise (UNRWA) ti won n pese fun Palestine. Ayman Safadi tó jẹ́ mínísítà fún ilẹ̀ òkèèrè ni ó bani lọ́kàn jẹ́ pé Washington yọwọ́ owo ìrànwọ́ ìrànlọ́wọ́ Àjọ ìṣọ̀kan Àgbáyé àti Iṣẹ́ (UNRWA) tí wọ́n ń pèsè fún Palestine. +Minisita naa ni ijoba yoo tubo maa gbiyanju lati maa wa awon oluranlowo miran lati fopin si isoro ti ajo naa n koju bayii fun owo nina. Mínísítà náà ní ìjọba yóò túbọ̀ máa gbìyànjú láti máa wa àwọn olùrànlọ́wọ́ míràn láti fòpin sí ìṣòro tí àjọ náà ń kojú báyìí fún owó níná. +---Ohun to ko iwaju si enikan ni oro naa nitori minisita otelemuye fun Isreal, Isreal Katz yombo igbese Aare Amerika lati da gbogbo owo iranwo ajo UNRWA – t’o n safikun si isoro awon ogunlende Palestine. ---Ohun tó kọ iwájú sí ẹnìkan ni ọ̀rọ̀ náà nítorí mínísítà ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ fún Isreal, Isreal Katz yòmbó ìgbésẹ̀ Ààrẹ Amẹ́ríkà láti dá gbogbo owó ìrànwọ́ àjọ UNRWA – t’ó ń ṣàfikún sí ìṣoro àwọn ogúnléndé Palestine. +Ajo UNRWA, ti o bere ise lati odun 1950 ni eyi ti o ti pese iranlowo fun o le ni milionu marun-un ogunlende Palestine. Àjọ UNRWA, tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti ọdún 1950 ní èyí tí ó ti pèsè ìrànlọ́wọ́ fún ó lè ní mílíọ́nù márùn-ún ogúnléndé Palestine. +Naijiria, Germany ati UN yoo sepade lori iko olote Boko haram. Nàìjíríà, Germany àti UN yóò ṣèpàdé lórí ikọ̀ ọlọ́tẹ̀ Boko haram. +"Orile-ede Naijiria, Germany, Norway, ati ajo agbaye (United Nations)ti pade ni Berlin, lojo Aje lati “sepade lori iko olote boko haram""." "Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Germany, Norway, àti àjọ àgbáyé (United Nàtions)ti pàdé ní Berlin, lọ́jọ́ Ajé láti “ṣèpàdé lórí ikọ̀ ọlọ́tẹ̀ boko haram""." +Ipade ti yoo waye ni Berlin lati ojo keta si ikerin lo je pe awon orile-ede meta ati ajo agbaye (UN) lo se onigbowo re, ipade ohun ni eyi ti o lagbara julo lodun 2018 fun ekun Lake Chad. Ìpàdé ti yóò wáyé ni Berlin láti ọjọ́ kẹta sí ìkẹrin lo jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́ta àti àjọ àgbáyé (UN) ló ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀, ìpàdé ọ̀hún ní èyí tí ó lágbára jùlọ lọ́dún 2018 fún ẹ̀kùn Lake Chad. +Ipade naa ni yoo da lori pipese eto iranwo owo milionu kan le ni merindinlogota dola fun awon ekun ti ofo se si ati pipese eto aabo. Ìpàdé náà ni yóò dá lórí pípèsè ètò ìrànwọ́ owó mílíọ́nù kan lé ní mẹ́rìndínlọ́gọ́ta dọ́là fún àwọn ẹ̀kùn ti ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ sí àti pípèsè ètò ààbò. +bakan naa ni ipade yii yoo tun pese eto iranwo fun awon ekun Ila -oorun Ariwa lorile-ede Naijiria ati apa ibikan lorile-ede Niger, Chad ati Cameroon ti iko Boko Haram ti sose si. bákan náà ni ìpàdé yìí yóò tún pèsè ètò ìrànwọ́ fún àwọn ẹ̀kùn Ìlà -oòrùn Àríwá lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti apá ibìkan lórílẹ̀-èdè Niger, Chad àti Cameroon tí ikọ̀ Boko Haram ti ṣọṣẹ́ sí. +Nibi ipade naa ni, won yoo tun maa jiroro nipa erongba, imoran ati iranwo lati odo awon ile-ise ti ki i se ti ijoba ati ona ti won yoo gba lati maa fowosowopo pelu awon orile-ede ti ajalu naa kolu ati awon egbe ti won ti n pese eto irawo fun awon orile-ede wonyi. Níbi ìpàdé náà ni, wọn yóò tún máa jíròrò nípa èròǹgbà, ìmọ̀ràn àti ìrànwọ́ láti ọ̀dọ àwọn ilé-iṣẹ́ tí kì í ṣe ti ìjọba àti ọ̀nà tí wọn yóò gbà láti máa fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tí àjálù náà kọlù àti àwọn ẹgbẹ́ tí wọ́n ti ń pèsè ètò ìràwọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí. +Ojogbon Tijjani Bande, t’o je asoju orile-ede Naijiria ni ajo UN lo soju orile-ede Naijiria nibi ipade naa to waye ni Berlin. Ọ̀jọ̀gbọ́n Tijjani Bándé, t’ó jẹ́ aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àjọ UN ló ṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi ìpàdé náà tó wáyé ní Berlin. +Asoju orile-ede Naijiria ni orile-ede Naijiria ti seto ilana owo to le ni bilionu meje dola lati fi satunse si awon ekun ti iko boko Haram baje. Aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ṣètò ìlànà owó tó lé ní bílíọ́nù méje dọ́là láti fi ṣàtúnṣe sí àwọn ẹ̀kùn tí ikọ̀ boko Haram bàjẹ́. +O so pe ifowosowopo ati ibasepo laaarin awon orile-ede to wa ni lake Chad ati awon ti yoo pese eto iranwo se pataki pupo. Ó sọ pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìbáṣepọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní lake Chad àti àwọn tí yóò pèsè ètò ìrànwọ́ ṣe pàtàkì púpọ̀. +Awon ekun Lake Chad gbodo le e pese ohun amayederun, ise lopo janturu ati ise kiko, lona ti yoo fi din wahala t’o n sele ni awon ekun naa ku. Àwọn ẹ̀kùn Lake Chad gbọ́dọ̀ le è pèsè ohun amáyédẹrùn, iṣẹ́ lọ́pọ̀ janturu àti iṣẹ́ kíkọ́, lọ́nà tí yóò fi dín wàhálà t’ó ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ẹ̀kùn náà kù. +Lati le se aseyori nipa awon eto idagbasoke wonyi, ajo agbaye bi i ile ifowopamo agbaye, ile ifowopamo ti orile-ede Afirika ati awon ile-ise miiran ti setan lati seto iranlowo fun awon orile-ede yii, ti won ba lee fowosowopo lati le gbogun ti awon isoro to n doju ko won. Láti le ṣe àṣeyorí nípa àwọn ètò ìdàgbàsókè wọ̀nyí, àjọ àgbáyé bí i ilé ìfowópamọ́ àgbáyé, ilé ìfowópamọ́ ti orílẹ̀-èdè Áfíríkà àti àwọn ilé-iṣẹ́ mìíràn ti ṣetán láti ṣètò ìrànlọ́wọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè yìí, tí wọ́n bá lèe fọwọ́sowọ́pọ̀ láti le gbógun ti àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ wọ́n. +Ajo UN ti ni oun yoo pese eto irawo fun awon ti iye won le ni milionu mefa lorile-ede Naijiria , ti iko Boko Haram kolu ni ekun Ila -oorun Ariwa lorile-ede Naijiria ki odun 2018 o to pari. Àjọ UN ti ní òun yóò pèsè ètò ìràwọ́ fún àwọn tí iye wọn lé ní mílíọ́nù mẹ́fà lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà , tí ikọ̀ Boko Haram kọlù ní ẹ̀kùn Ìlà -oòrùn Àríwá lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà kí ọdún 2018 ó tó parí. +Edward Kallon, t’o je asoju ajo UN ni eka eto iranwo fun orile-ede Najiria soro ni New York nibi ipade kan pe orile-ede Naijiria n koju awon isoro pupo. Edward Kallon, t’ó jẹ́ aṣojú àjọ UN ni ẹ̀ka ètò ìrànwọ́ fún orílẹ̀-èdè Nàjíríà sọ̀rọ̀ ní New York níbi ìpàdé kan pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń kojú àwọn ìṣòro púpò. +O le ni milionu mewaa awon eniyan to wa ni ipinle meta lorile-ede Naijiria to wa ni ekun Ila -oorun Ariwa ti won nilo eto iranwo. Ó lé ní mílíọ́nù mẹ́wàá àwọn ènìyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ mẹ́ta lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó wà ní ẹ̀kùn Ìlà -oòrùn Àríwá tí wọ́n nílò ètò ìrànwọ́. +August 30, 2018 --- Gomina ipinle Eko gba adari ijoba Britain lalejo. August 30, 2018 --- Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó gba adarí ìjọba Britain lálejò. +Gomina ipinle Eko, Akinwunmi Ambode gba adari ijoba orile-ede Britain, Theresa May lalejo , o so fun un pe ipinle Eko je ibi ti awon onisowo tedo si. Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Akínwùnmí Ambode gba adarí ìjọba orílẹ̀-èdè Britain, Theresa May lálejò , ó sọ fún un pé ìpínlẹ̀ Èkó jẹ́ ibi tí àwọn oníṣòwò tẹ̀dó sí. +Gomina fi idunnu re han lati tewo gba adari ijoba orile-ede Britain ni alejo, o so pe ibasepo to wa laaarin orile-ede Naijiria ati Britain ti wa lati ojo pipe. Gómìnà fi ìdùnnú rẹ̀ hàn láti tẹ́wọ́ gba adarí ìjọba orílẹ̀-èdè Britain ni àlejò, ó só pé ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín orílẹ̀-èdè Nàíjíríà àti Britain ti wà láti ọjọ́ pípẹ́. +O ni imo eko, asa, iselu ti awon omo orile-ede Naijiria n mulo, lo je pe lati orile-ede Britain ni won ti koo. Ó ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́, àṣà, ìṣèlú ti àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń múlò, ló jẹ́ pé láti orílẹ̀-èdè Britain ni wọ́n ti kọ́ọ. +Ibi ti o dara lati da okoowo sile, Ambode fi kun oro re pe, ilu Eko fi aaye gba awon onisowo lati da ile-ise won sile, paapaa julo ,won ni eto isejoba ti o fese mule, bi eto oro-aje ilu Eko se tobi pupo si, iye awon eniyan to n gbe inu ilu naa, ibowo fun ofin ati eto idajo to fese mule. Ibi tí ó dára láti dá okoòwò sílẹ̀, Ambode fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ìlú Èkó fi ààyè gba àwọn oníṣòwò láti dá ilé-iṣẹ́ wọn sílẹ̀, pàápàá jùlọ ,wọ́n ní ètò ìṣèjoba tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀, bí ètò ọrọ̀-ajé ìlú Èkó ṣe tóbi púpọ̀ sí, iye àwọn ènìyàn tó ń gbé inú ìlú náà, ìbọ̀wọ̀ fún òfin àti ètò ìdájọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀. +O so pe “a jiroro pelu adari ijoba orile-ede Britain, paapaa julo lori bi awon onisowo orile-ede Britain yoo se mu idagbasoke ba eto okoowo niluu Eko. Ó sọ pé “a jíròrò pẹ̀lú adarí ìjọba orílẹ̀-èdè Britain, pàápàá jùlọ lórí bí àwọn oníṣòwò orílẹ̀-èdè Britain yóò ṣe mú ìdàgbàsókè bá et̀ò okoòwò nílùú Èkó. +Gege bi e se mo pe ilu Eko ni ibi ti awon onisowo gunle si lorile-ede Naijiria. Gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe mọ̀ pé ìlú Èkó ni ibi tí àwọn oníṣòwò gúnlẹ̀ sí lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Opo awon omo orile-ede Britain lo ni okoowo niluu Eko. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Britain ló ní okoòwò nílùú Èkó. +"""Gomina tun so pe bi May se wa siluu Eko, yoo tun je ki eto okoowo ati aabo tun ni idagbasoke si i." """Gómìnà tún sọ pé bí May ṣe wá sílùú Èkó, yóò tún jẹ́ kí ètò okoòwò àti ààbò tún ní ìdàgbàsókè sí i." +O ni awon omo orile-ede Britain ni anfaani lati lowo ninu opolopo okoowo to wa niluu Eko, bi i eto agbara, imo ero, eto isuna owo, ohun amaye-derun ati ile–ise. Ó ní àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Britain ní àǹfààní láti lọ́wọ́ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ okoòwò tó wà nílùú Èkó, bi i ètò agbára, ìmọ̀ ẹ̀rọ, ètò ìṣúná owó, ohun amáyé-dẹrùn àti ilé–iṣẹ́. +Opolopo igbese ni ilu Eko ti n gbe lati mu ohun iwuri de ba awon onisowo lati da okoowo sile. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbésẹ̀ ni ìlú Èkó ti ń gbé láti mú ohun ìwùrí dé bá àwọn oníṣòwò láti dá okoòwò sílẹ̀. +Opolopo ise lati se, lori eto idajo, inu adari ijoba orile-ede Britain si dun si eleyii. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ lati ṣe, lórí ètò ìdájọ́, inú adarí ìjọba orílẹ̀-èdè Britain sì dùn sí eléyìí. +O si ti setan lati se atileyin fun wa lati seranwo eto eyawo ati idagbasoke lori eto inawo. Ó sì ti ṣetán láti ṣe àtìlẹyìn fún wa láti ṣèrànwọ́ ètò èyáwó àti ìdàgbàsókè lórí ètò ìnáwó. +"""Eto ibasepo Gomina so pe ijoba ohun yoo gbiyanju lati se ohun to wa nikawoo re lati tubo fese ibasepo to wa laaarin ilu Eko ati Britain mule si i." """Ètó ìbáṣepọ̀ Gómìnà sọ pé ìjọba òhun yóò gbìyànjú láti ṣe ohun tó wà níkàwọ́ọ́ rẹ̀ láti túbọ̀ feṣè ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín ìlú Èkó àti Britain múlẹ̀ sí i." +O so pe ‘a ti soro nipa imo ero, ohun amayederun ati idasile ile-ise. Ó sọ pé ‘a ti sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ, ohun amáyédẹrùn àti ìdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́. +Ibasepo to wa laaarin ilu Eko ati orile-ede Britain bere lati opolopo odun seyin. Ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín ìlú Èkó àti orílẹ̀-èdè Britain bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣ́eyìn. +Bi e ti mo pe, ilu Eko ni orile-ede Britain fi se olu-ilu lasiko ijoba amunisin, Idi niyi ti a gbodo se ri i pe opolopo okoowo lati orile-ede Britain lo gbodo wa niluu Eko. Bí ẹ ti mọ̀ pé, ìlú Èkó ni orílẹ̀-èdè Britain fi ṣe olú-ìlú lásìkò ìjọba amúnisìn, Ìdí nìyí tí a gbọ́dọ̀ ṣe ri i pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ okoòwò láti orílẹ̀-èdè Britain ló gbọ́dọ̀ wà nílùú Èkó. +Adari ijoba orile-ede Britain ti lo yika ilu Eko, o si ti setan lati tun fowosowopo pelu wa, lati tun je ki awon omo orile-ede Britain tun da okoowo sile si i. Adarí ìjọba orílẹ̀-èdè Britain ti lọ yíká ìlú Èkó, ó sì ti ṣetán láti tún fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wa, láti tún jẹ́ kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Britain tún dá okoòwò sílẹ̀ si i. +"""Adari ijoba orile-ede Britain fi idunnu re han nigba ti o n ba awon akoroyin soro ni papa baalu to wa niluu Eko, pe inu ohun dun lati wa si orile-ede Naijiria paapaa julo si ilu Eko lati ri bi awon ile ise se n se aseyori." """Adarí ìjọba orílẹ̀-èdè Britain fi ìdùnnú rẹ̀ hàn nígbà tí ó ń bá àwọn akọròyìn sọ̀rọ̀ ni pápá bàálù tó wà nílùú Èkó, pé inú òhun dùn láti wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pàápàá jùlọ sí ìlú Èkó láti rí bí àwọn ilé iṣẹ́ ṣe ń ṣe àṣeyọrí." +O so pe “Inu mi dun lati wa si orile-ede Naijiria, paapaa julo si ilu Eko, ibasepo to dan monran wa laaarin orile-ede Naijiria ati Britain, a si ni opolopo nnkan pataki lati se lojo iwaju. Ó sọ pé “Inú mi dùn láti wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, pàápàá jùlọ sí ìlú Èkó, ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́nrán wà láàárín orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Britain, a sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan pàtàkì láti ṣe lọ́jọ́ iwájú. +Mo gbadun ilu Abuja ati Eko, inu mi si dun bi eto oro-aje se n se aseyori nibe. Mo gbádùn ìlú Àbújá àti Èkó, inú mi sì dùn bi ètò ọrọ̀-ajé ṣe ń ṣe àṣeyọrí níbẹ̀. +“A fe ki idagbasoke ba eto oro-aje orile-ede Naijiria ati Uk, ki a da opolopo ise sile lorile-ede Naijiria, ise to wa lorile-ede Britain yoo wulo lorile-ede Naijiria. “A fẹ́ kí ìdàgbàsókè bá ètò ọrọ̀-ajé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Uk, kí a dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ sílẹ̀ lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà, iṣẹ́ tó wà lorílẹ̀-èdè Britain yóò wúlò lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Mo dupe lowo gomina ipinle Eko. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó. +’’O ni ilu Eko ti se gudugudu meje, yaya mefa lati lee mu iwuri ba awon onisowo ni ipinle naa. ’’Ó ní ìlú Èkó ti ṣe gudugudu méje, yàyà mẹfà láti leè mú ìwúrí bá àwọn oníṣòwò ní ìpínlẹ̀ náà. +Arabinrin May, so pe awon ti seto eyawo ti iye re to milionu eedegberinlelaadota owo poun ti ilu Eko naa si le e je anfaani re. Arábìnrin May, sọ pé àwọn ti ṣètò èyáwó tí iye rẹ̀ tó mílíọ́nù ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rinléláàdọ́ta owó pọ́ùn tí ìlú Èkó náà sì le è jẹ àǹfààní rẹ̀. +Adari ijoba orile-ede Britain tun so pe oun wa pelu awon asoju re to ni imo ero, ni eyi ti ilu Eko lee je anfaani re. Adarí ìjọba orílẹ̀-èdè Britain tún sọ pé òun wà pẹ̀lú àwọn aṣojú rẹ̀ tó ní ìmọ̀ ẹ̀rọ, ní èyí tí ìlú Èkó lèe jẹ àǹfààní rẹ̀. +Dida okoowo sile. O tun so pe orile-ede Britain ti setan lati ran ilu Eko lowo nipa eto okoowo ati pe orile-ede Naijiria ni won ti se aso jaaketi ti oun n wo. Dídá okoòwò sílẹ̀. Ó tún sọ pé orílẹ̀-èdè Britain ti ṣetán láti ran ìlú Èkó lọ́wọ́ nípa ètò okoòwò àti pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n ti ṣe aṣo jáákẹ́tì tí òun ń wọ̀. +Lara awon to wa pade adari ijoba orile-ede Britain nigba to de si papa oko ofuurufu ni deede aago merin abo osan, ni gomina ati Igbakeji Gomina, Omowe Oluranti Adebule, akowe ijoba ipinle, Ogbeni Tunji Bello ati oluranlowo pataki ijoba ati oludari oro t’o je mo ti ile okeere, ojogbon Ademola Abass. Lára àwọn tó wá pàdé adarí ìjọba orílẹ̀-èdè Britain nígbà tó dé sí pápá ọkọ̀ òfuurufú ní déédé aago mẹ́rin àbọ̀ ọ̀san, ni gómìnà àti Igbákejì Gómìnà, Ọ̀mọ̀wé Olúrántí Adébulé, akọ̀wé ìjọba ìpínlẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Túnjí Bello àti olùrànlọ́wọ́ pàtàkì ìjọba àti olùdarí ọ̀rọ̀ t’ó jẹ mọ́ ti ilẹ̀ òkèère, ọ̀jọ̀gbọ́n Adémọ́lá Abass. +---Aare Buhari se ipade bonkele pelu Adari ijoba orile-ede Britain. ---Ààrẹ Buhari ṣe ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ pẹ̀lú Adarí ìjọba orílẹ̀-èdè Britain. +Aare orile-ede Naijiria Muhammadu Buhari ati Adari ijoba orile-ede Britain, Theresa May se ipade bonkele nile Aare t’o wa niluu Abuja. Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàíjíríà Muhammadu Buhari àti Adarí ìjọba orílẹ̀-èdè Britain, Theresa May ṣe ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ nílé Ààrẹ t’ó wà nílùú Àbújá. +Ipade naa bere ni ofiisi ile Aare, ni kete ti May de si ile–Aare ni deede aago mejila osan. Ìpàdé náà bẹ̀rẹ̀ ní ófíísì ile Ààrẹ, ní kété tí May dé sí ilé–Ààrẹ ní déédé aago méjìlá ọ̀sán. +Aare Buhari ati awon Adari ile-ise ijoba apapo ni won wa pade May. Ààrẹ Buhari àti àwọn Adarí ilé-iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ ni wọ́n wá pàdé May. +Ipade naa ni yoo da lori ona ti ibasepo orile-ede Naijiria ati Britain yoo se tubo fese mule sii. Ìpàdé náà ni yóò dá lórí ọ̀nà tí ìbáṣepọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Britain yóò ṣe túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ sii. +Orile-ede mejeeji yii, ni yoo tun maa towobo iwe igbora-eni ye (ibasepo) lori eto aabo ati idagbasoke. Orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí, ni yóò tún máa tọwọ́bọ ìwé ìgbọ́ra-ẹni yé (ìbáṣepọ̀) lórí ètò ààbò àti ìdàgbàsókè. +Orile-ede Naijiria wa lara orile-ede ti May fe kan si nile Afirika. Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà lára orílẹ̀-èdè tí May fẹ́ kàn sí nílẹ̀ Áfíríkà. +---Turkey ti awon afurasi mole latari ikolu sile asoju orile-ede Amerika. ---Turkey ti àwọn afurasí mọ́lé látàrí ìkọlù sílé aṣojú orílẹ̀-èdè Améríkà. +Ile-ise olopaa lorile-ede Turkey tun ti mu awon afurasi meji miiran latari esun ti won fi kan won pe, won lowo si ikolu sile asoju orile-ede Amerika (United States embassy) eyi ti o waye lojo Aje ni olu-ilu orile-ede ohun ti n se Ankara. Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá lórílẹ̀-èdè Turkey tún ti mú àwọn afurasí méjì mííràn látàrí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n pé, wọ́n lọ́wọ́ sí ìkọlù sílé aṣojú orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (United States embassy) èyí tí ó wáyé lọ́jọ́ Ajé ní olú-ìlú orílẹ̀-èdè ọ̀hún tí ń ṣe Ankara. +Gege bi iroyin se so, ikolu naa ni awon toro kan so pe, o seese ko je pe awon omo ogun olote NATO ni o wa nidi re. Gẹ́gẹ bí ìròyìn ṣe sọ, ìkọlù náà ni àwọn tọ́rọ̀ kàn sọ pé, ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun ọlọ́tẹ̀ NATO ni ó wà nídì rẹ̀. +Ni bayii, apapo awon afurasi ti o wa ninu atimole je merin pelu awon meji ti o sese darapo mo won. Ni báyìí, àpapọ̀ àwọn afurasí tí ó wà nínú àtìmọ́lé jẹ́ mẹ́rin pẹ̀lú àwọn méjì tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ darapọ̀ mọ́ wọn. +Ile-ise olopaa so pe, meji ninu awon afurasi naa mu oti amupara lasiko ikolu naa. Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá sọ pé, méjì nínú àwọn afurasí náà mu otí àmupara lásìkò ìkọlù náà. +Ewe, iroyin tun fi mule pe enikeni ko farapa ninu ikolu naa. Ẹ̀wẹ̀, ìròyìn tún fi múlẹ̀ pé ẹnikẹ́ni kò farapa nínú ìkọlù náà. +---Awon eniyan meji ni o ku nibi idije ere idaraya ori ero agbaworan ni ipinle Florida. ---Àwọn ènìyàn méjì ni ó kú níbi ìdíje eré ìdárayá orí ẹ̀rọ agbáwòrán ní ìpínlẹ̀ Florida. +Olukopa kan ninu idije ere-idaraya ori ero agbaworan niluu Jacksonville, ni ipinle Florida, lorile-ede Amerika ti gbemi ara re leyin ti o yinbon mo eniyan meji ti won si padanu emi won lesekese. Olùkópa kan nínú ìdíje ere-ìdárayá orí ẹ̀rọ agbáwòrán nílùú Jacksonville, ní ìpínlẹ̀ Florida, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí gbẹ̀mí ara rẹ̀ lẹ́yìn tí ó yìnbọn mọ́ ènìyàn méjì tí wọ́n sí pàdánù ẹ̀mí wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. +Gege bi ile-ise olopaa se so, won ni, oruko afurasi ohun n je David Katz, omo odun merinlelogun ti o wa lati ilu Baltimore. Gẹ́gẹ bí ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe sọ, wọ́n ní, orúkọ afurasí ọ̀hún ń jẹ́ David Katz, ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún tí ó wá láti ìlú Baltimore. +Bakan naa, eniyan mokanla miiran tun farapa yanayana ni gbagede igbafe lagbegbe Jacksonville lojo Aiku (Sunday). Bákan náà, ènìyàn mọ́kànlá mìíràn tún farapa yánayàna ní gbàgede ìgbáfẹ́ lágbègbè Jacksonville lọ́jọ́ Àìkú (Sunday). +Gege bi awon ti isele ohun soju won, won fi mule pe, inu lo bi Katz lataari pe ko jawe olubori ninu idije boolu Amerika ohun (American football eSports event), ni eyi ti o mu wu iwa lona aito. Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ṣojú wọn, wọ́n fi múlẹ̀ pé, inú ló bí Katz látààrí pé kò jáwé olúborí nínú ìdíje bọ́ọ̀lù Amẹ́ríkà ọ̀hún (American football eSports event), ní èyí tí ó mú wu ìwà lọ́nà àìtọ́. +Ni bayii, won koi tii kede oruko awon ti o fara kaasa ijamba naa, di igba ti won ba to fojuri awon ebi won, bi o ti le je pe awon miiran ti n sedaro lori ibudo-itakun esport. Ní báyìí, wọn kòì tíì kéde orúko àwọn tí ó fara kááṣá ìjàmbá náà, di ìgbà tí wọ́n bá tó fojúri àwọn ẹbí wọn, bí ó ti lè jẹ́ pé àwọn mìíràn tí ń ṣèdárò lórí ibùdó-ìtakùn esport. +Orisirisi ijamba lo ti n waye ni ipinle Florida lati odun meloo kan seyin, ti o fi mo ijamba ti o waye ni gbagede igbafe ale niluu Orlando lodun 2016 (Pulse nightclub), isele ti o seku pa eniyan mokandinlaadota, bee si ni isele ti o tun seku pa eniyan metadinlogun nile iwe Marjory Stoneman Douglas ni agbegbe Parkland ninu osu keji osu yii. Oríṣiríṣi ìjàmbá ló tí ń wáyé ní ìpínlẹ̀ Florida láti ọdún mélòó kan ṣẹ́yìn, tí ó fi mọ́ ìjàmbá tí ó wáyé ní gbàgede ìgbáfẹ́ alẹ́ nílùú Orlando lọdún 2016 (Pulse nightclub), ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣekú pa ènìyàn mọ́kàndínláàdọ́ta, bẹ́ẹ̀ sì ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó tún ṣekú pa ènìyàn mẹ́tàdínlógún nílé ìwé Marjory Stoneman Douglas ní agbègbè Parkland nínú oṣù kejì oṣù yìí. +---Iran seleri lati satileyin fun atunse orile-ede Syria. ---Iran ṣèlérí láti ṣàtìlẹyìn fún àtúnṣe orílẹ̀-èdè Syria. +Orile-ede Iran ti sepinnu lati mu ileri re se lojuna lati satileyin fun atunse orile-ede Syria nipase pipese eto isuna, oselu ti o fese mule ati atileyin iko omo ogun. Orílẹ̀-èdè Iran ti ṣèpinnu láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ lójúnà láti sàtìlẹyìn fún àtúnṣe orílẹ̀-èdè Syria nípasẹ̀ pípèsè ètò ìṣúná, òṣèlú tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ àti àtìlẹyìn ikọ̀ ọmọ ogun. +Amir Hatami ti o je Minisita to n mojuto eto aabo lorile-ede Iran lo jabo oro naa fun awon akoroyin lasiko ipade re pelu Aare orile-ede Syria Bashar al-Assad ati Minisita to n mojuto eto aabo, Ali Abdullah Ayyoub lorile-ede naa. Amir Hatami tí ó jẹ́ Mínísítà tó ń mójútó ètò ààbò lorílẹ̀-èdè Iran ló jábọ̀ ọ̀rọ̀ náà fún àwọn akọròyìn lásìkò ìpàdé rẹ̀ pẹ̀lú Ààrẹ orílẹ̀-èdè Syria Bashar al-Assad àti Mínísítà tó ń mójútó ètò ààbò, Ali Abdullah Ayyoub lórílẹ̀-èdè náà. +Orile-ede mejeeji jo ni adehun pe won yoo jo fowosowopo mu atunse ba ile Syria, ti won ko si ni faye gba orile-ede miiran lati lowo si atunse ohun. Orílẹ̀-èdè méjèèjì jọ ní àdéhùn pé wọn yóò jọ fọwọ́sowọ́pọ̀ mú àtunṣe bá ilẹ̀ Syria, tí wọn kò sì ní fàyè gba orílẹ̀-èdè mìíràn láti lọ́wọ́ sí àtunṣe ọ̀hún. +"Hatami so pe,“Syria wa ni ikorita ti o se pataki bayii, nitori awon ohun ti orile-ede yii ti lakoja seyin lagbara pupo, bee si ni ojuna lati bere atunse ni O wa lowolowo,""Gege bi eka to n mojuto eto oro-aje ilu ati oro ayika ninu ajo isokan agbaye, won fi mule pe orile-ede Syria ti padanu oodunrun bilionu o le mejidinlaadoru- un owo dollar ($388bn) lataari oniruuru ijamba ati ogun ti o ti n waye lati odun 2011 seyin." "Hatami sọ pé,“Syria wà ní ìkoríta tí ó ṣe pàtàkì báyìí, nítorí àwọn ohun tí orílẹ̀-èdè yìí ti làkọjá ṣẹ́yìn lágbára púpọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ojúnà láti bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe ni Ó wà lọ́wọ́lọ́wọ́,""Gẹ́gẹ́ bi ẹ̀ka tó ń mójúto ètò ọrọ̀-ajé ìlú àti ọrọ̀ àyíká nínú àjọ ìṣokan àgbáyé, wọ́n fi múlẹ̀ pé orílẹ̀-èdè Syria ti pàdánù ọ́ọ̀dúnrún bílíọ́nù ó lé méjídínláàdọ́rù- ún owó dollar ($388bn) látààrí onírúurú ìjàm̀bá àti ogun tí ó tí ń wáyé láti ọdún 2011 sẹ́yìn." +Ninu osu ti o koja, Aare Assad salaye pe, lati se atunse si ile Syria lo je oun logun julo, leyin ti ogunlogo awon omo orile-ede Iran ti padanu emi won ti awon miiran si padanu ile ati awon ohun ini won sinu olokan-o-jokan ijamba naa. Nínú oṣù tí ó kọjá, Ààrẹ Assad ṣàlàyé pé, láti ṣe àtúnṣe sí ilẹ̀ Syria ló jẹ òun lógún jùlọ, lẹ́yìn tí ogúnlógó àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Iran ti pàdánù ẹ̀mí wọn ti àwọn mìíràn sì pàdánù ilé àti àwọn ohun ìní wọn sínú ọlọ́kan-ò-jọ̀kan ìjàm̀bá náà. +---Oko ofuurufu ti won jigbe ni Seattle-Tacoma ti ja l’Erekusu kan. ---Ọkọ̀ òfuurufú tí wọ́n jígbé ní Seattle-Tacoma ti já l’Érèkùsù kan. +Osise oloko ofuurufu kan to’ ji baalu kan gbe ni papako ofuurufu Seattle l’orile-ede Amerika ti lo fori sonpon ni Erekusu kan. Òṣìṣẹ́ ọlọ́kọ̀ òfuurufú kan tó’ jí bàálù kan gbé ní pápákọ̀ òfuurufú Seattle l’órílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti lọ forí ṣọ́npọ́n ní Èrèkùsù kan. +Awon alase ni baalu naa gbera lojo Eti laigba ase lati gbera kuro ni papako ofuurufu ni eyi t’o je ki ijoba ti papako Seattle-Tacoma pa. Àwọn aláṣe ní bàálù náà gbéra lọ́jọ́ Etì láìgba àṣẹ láti gbéra kúrò ní pápákọ̀ òfuurufú ní èyí t’ó jẹ́ kí ìjọba ti pápákọ̀ Seattle-Tacoma pa. +Awon oko ofuurufu ajagun meji F15 ni won yan lati tele ati lo wa baalu naa ki won to gbo bo se ja pelu ariwo nla. Àwọn ọkọ̀ òfuurufú ajagun méjì F15 ni wọ́n yàn láti tẹ̀lé àti lọ wá bàálù náà kí wọ́n tó gbọ́ bó ṣe já pẹ̀lú ariwo ńlá. +Oga olopaa agbegbe naa, Pearl Pasor ni ki i se awon agbesunmomi l’o ji i bikose oloko ofuurufu omo odun mokandinlogbon. Ọ̀ga ọlọ́pàá agbègbè náà, Pearl Pasor ní kì í ṣe àwọn agbẹ́sùnmómi l’ó jí i bíkòṣe ọlọ́kọ̀ òfuurufú ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ́n. +Aworan ojuiwo kan fihan pe won ti n ro okunrin naa k’o bale l’alaafia k’o to di pe oko ofuurufu naa ja. Àwòrán ojúìwò kan fihàn pé wọ́n ti ń rọ ọkùnrin náà k’ó balẹ̀ l’álàáfíà k’ó tó di pé ọkọ̀ òfuurufú náà já. +Iwe iroyin The Seattle Times sapejuwe okunrin naa gege bi eni ti ko nani nnkankan t’o ti fi opolopo aworan-olohun sori ayelujara nibi t’o ti n fi oko ofuurufu Q400 kan to je ti Alaska Airlines dara lorisiirisi. Ìwé ìròyìn The Seattle Times ṣàpèjúwe ọkùnrin náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò nání nǹkankan t’ó ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwòrán-olóhùn sórí ayélujára níbi t’ó ti ń fi ọkọ̀ òfuurufú Q400 kan tó jẹ́ ti Alaska Airlines dárà lóríṣiiríṣi. +Leah Morse, t’o ya aworan bi oko ofuurufu naa se n bale ni oun sakiyesi pe nnkankan n se oko naa loju ofuurufu k’o to wa bale nitosi ile oun pelu ariwo nla. Leah Morse, t’ó ya àwòrán bí ọkọ̀ òfuurufú náà ṣe ń balẹ̀ ni òun ṣàkíyèsí pé nǹkankan ń ṣe ọkọ̀ náà lójú òfuurufú k’ó tó wá balẹ̀ nítòsí ilé òun pẹ̀lú ariwo ńlá. +---Ijoba Naijiria yoo gbe awon onibara irinna oko ofuurufu Russia lo sile ejo. ---Ìjọba Nàìjíríà yóò gbé àwọn oníbàrá ìrinnà ọkọ̀ òfuurufú Russia lọ sílé ẹjọ́. +Ijoba apapo orile-ede Naijiria ti pinnu lati gbe awon onibara oko ofuurufu to ko awon ololufe lo si orile-ede Russia sugbon ti won kuna lati ko won ada si orile-ede Naijiria, ni eyi ti o je ki awon eniyan naa di alarinka leyin ife eye boolu 2018 to waye ni orile-ede Russia. Ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti pinnu láti gbé àwọn oníbàrá ọkọ̀ òfuurufú tó kó àwọn olólùfẹ́ lọ sí orílẹ̀-èdè Russia ṣùgbọ́n tí wọ́n kùnà láti kó wọn adà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ní èyí tí ó jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà di alárìnká lẹ́yìn ife ẹ̀yẹ bọ́ọ̀lù 2018 tó wáyé ní orílẹ̀-èdè Russia. +Asoju orile-ede Naijiria si orile-ede Russia ojogbon Steve Ugba l’o soro yii lori ero fidio ayelujara, ni eyi ti o fi ranse si agbenusoro ajo t’o n ri si oro ile okekere, Tope Elias-Fatile lojo Aiku, niluu Abuja. Aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sí orílẹ̀-èdè Russia ọ̀jọ̀gbọ́n Steve Ugba l’ó sọ̀rọ̀ yìí lórí ẹ̀rọ fídíò ayélujára, ní èyí tí ó fi ránṣẹ́ sí agbẹnusọ̀rọ̀ àjọ t’ó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèkèrè, Tope Elias-Fàtile lọ́jọ́ Àìkú, nílùú Àbújá. +Ugba je ki awon ololufe omo orile-ede Naijiria to wa ni Moscow, ni Russia mo, ipo ti ijoba wa, ki o to lo si orile-ede Naijiria. Ugba jẹ́ kí àwọn olólùfẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó wà ní Moscow, ní Russia mọ̀, ipò tí ìjọba wà, kí ó tó lọ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +O le ni aadojo (150) ololufe ere boolu ti won je omo orile-ede Naijiria ti awon onibara oko ofurufu kuna lati ko pada wa si orile-ede Naijiria, ni eyi ti awon eniyan naa lo si ile-ise to n soju orile-ede Naijiria ni Moscow lojo kejila osu keje, lati beere fun iranlowo lati odo ajo naa leyin ti ere boolu idaraya t’o waye lodun yii pari. Ó lé ní àádọ́jọ (150) olólùfẹ́ eré bọ́ọ̀lù tí wọn jẹ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí àwọn oníbàrá ọkọ̀ òfúrufú kùnà láti kó padà wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ní èyi tí àwọn ènìyàn náà lọ sí ilé-iṣẹ́ tó ń ṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní Moscow lọ́jọ́ kejìlá oṣù keje, láti bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ àjọ náà lẹ́yìn tí eré bọ́ọ̀lù ìdárayá t’ó wáyé lọ́dún yìí parí. +Lojo kerindinlogun ni Aare orile-ede Naijiria Muhammadu Buhari ti pase fun Minisita to n ri si ile okeere Geoffrey Onyeama ati akegbe re, t’o n ri si oro to je mo oko ofuurufu Hadi Sirika, lati ko gbogbo awon omo orile-ede Naijiria pada wa si ilu Abuja ni kiakia. Lọ́jọ́ kẹrìndínlógún ni Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Muhammadu Buhari ti pàṣẹ fún Mínísítà tó ń rí sí ilẹ̀ òkèèrè Geoffrey Onyeama àti akẹgbẹ́ rẹ̀, t’ó ń rí sí ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ọkọ̀ òfuurufú Hadi Sirika, láti kó gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà padà wá sí ìlú Àbújá ní kíákía. +Saaju ojo naa ni baalu Ethiopia ti ko awon eniyan marundinlogojo wa si ilu Abuja ni ogunjo osu keje. Ṣáájú ọjọ́ náà ni bàálù Ethiopia ti kó àwọn ènìyàn márùndínlọgọ́jọ wá sí ìlú Àbújá ní ogúnjọ́ oṣù keje. +Awon eniyan naa ko sai fi idunnu won han si Aare orile-ede Naijiria Muhammadu Buhari lati ri i pe awon eniyan naa pada wa sile. Àwọn ènìyàn náà kò sàì fi ìdùnnú wọn hàn sí Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Muhammadu Buhari láti rí i pé àwọn ènìyàn náà padà wá sílé. +Ugba, ni ijoba orile-ede yii ko ni je ki awon odaran naa lo ni alaafia, o wa ro awon ololufe ere idaraya to je omo orile-ede Naijiria lati fi iwe akosile won ranse si ile-ise won, lati le je ki ijoba mu awon odaran naa. Ugba, ní ìjọba orílẹ̀-èdè yìí kò ní jẹ́ kí àwọn ọ̀daràn náà lọ ní àlááfíà, ó wá rọ àwọn olólùfẹ́ eré ìdárayá tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti fi ìwé àkọsílẹ̀ wọn ránṣẹ́ sí ilé-iṣẹ́ wọn, láti lè jẹ́ kí ìjọba mú àwọn ọ̀daràn náà. +“E fun wa ni iwe akosile ti e ni nipa awon eniyan to lu yin ni jibiti, tabi ti won gbe e yin lowo lo, ki a le fiya to to je won ni orile-ede Naijiria. “Ẹ fún wa ní ìwé àkọsílẹ̀ tí ẹ ni nípa àwọn ènìyàn tó lù yín ní jìbìtì, tàbí tí wọ́n gbé e yín lówó lọ, kí a lè fìyà tó tọ́ jẹ wọn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +A o ni je ki won lo lai jiya. A ò ní jẹ́ kí wọn lọ láì jìyà. +Nitori naa, e fun wa ni iwe akosile ti e ni nipa won. Nítorí náà, ẹ fún wa ni ìwé àkọsílẹ̀ ti ẹ ni nípa wọn. +O tun so pe “a n duro de won ni orile-ede Naijiria, iru iwa ti e hu yii, fihan pe e je omoluabi, pe e tun ni ibowo fun ara yin ati orile-ede yin. Ó tún sọ pé “à ń dúró de wọ́n ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, irú ìwá tí ẹ hù yìí, fihàn pé ẹ jẹ́ ọmọlúàbí, pé ẹ tún ní ìbọ̀wọ̀ fún ara yín àti orílẹ̀-èdè yín. +“Ki i se iwa odaran ni pe, e wa si orile-ede Russia, ki o wa je iwa odaran lati pada sile. “Kì í ṣe ìwà ọ̀daràn ni pé, ẹ wá sí orílẹ̀-èdè Russia, kí ó wá jẹ́ ìwà ọ̀daràn láti padà sílé. +“Iwa odaran ni, fun eni ti o ta iwe irinna fun un yin, sugbon ti o kuna lati ko o yin pada wa sile, leyin ti o ti gba owo lati ko yin pada, nitori naa, ki i se ebi yin. “Ìwà ọ̀daràn ni, fún ẹni tí o ta ìwé ìrìnnà fún un yín, ṣ̀ugbọ́n tí ó kùnà láti kó o yín padà wá sílé, lẹ́yìn tí ó ti gba owó láti kó yín padà, nítorí náà, kì í ṣe ẹ̀bi yín. +O tun so pe “A o ri i pe a fiya je awon to hu iru iwa yii, labe ofin, to fi je pe lojo miiran, won ko ni hu iru iwa bee mo. Ó tún sọ̀ pé “A ó ri i pé a fìyà jẹ àwọn tó hu irú ìwà yìí, lábẹ òfin, tó fi jẹ pe lọ́jọ́ mìíràn, wọn kò ní hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ mo. +’’Ugba tun so pe orile-ede Naijiria gbosuba fun awon ololufe yii bi won se lo si orile-ede Russia lati lo ye awon Super Eagles si lorile-ede Russia. ’’Ugba tún sọ pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gbóṣùbà fún àwọn olólùfẹ́ yìí bí wọ́n ṣe lọ sí orílẹ̀-èdè Russia láti lo yẹ àwọn Super Eagles sí lorílẹ̀-èdè Russia. +O ni iwa ti won hu yii, ti je ki orile-ede Naijiria je ore pataki pelu orile-ede Russia. Ó ní ìwà tí wọ́n hù yìí, tí jẹ kí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ ọ̀rẹ́ pàtàkì pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Russia. +---Aare Trump yoo satunse si baalu ofuurufu ti aare. ---Ààrẹ Trump yóò ṣàtúnṣe sí bàálù òfuurufú ti ààrẹ. +Aare orile-ede Amerika, Donald Trump ti so pe ohun yoo satunse si baalu ofuurufu ti ile-ise aare nipa kikun un ni pupa, funfun ati buluu. Ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Donald Trump ti sọ pé òhun yóò ṣàtúnṣe sí bàálù òfuurufú ti ilé-iṣẹ́ ààrẹ nípa kíkùn ún ní pupa, funfun àti búlúù. +"Trump ni pe ""o dara ki baalu tuntun Boeing je kikun si oda pupa, funfun ati awo aro." "Trump ní pé ""ó dára kí bàálù tuntun Boeing jẹ́ kíkùn sí ọ̀dà pupa, funfun àti àwọ̀ aró." +Aare ana orile-ede Amerika, John F Kennedy ati iyawo re, ni won mu oda yii lodun 1960. Ààrẹ àná orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, John F Kennedy àti ìyàwó rẹ̀, ni wọ́n mú ọ̀dà yìí lọ́dún 1960. +Ipile tuntun amosa ipile tuntun yii yoo pari lodun 2021. Ìpílẹ̀ tuntun àmọ́ṣá ìpílẹ̀ tuntun yìí yóò parí lọ́dún 2021. +Trump soro yii ni Scotland lojo isinmi ose yii pe, baalu naa yoo tun wulo fun awon’’ aare lojo iwaju’’’nitori opolopo odun ti yoo lo. Trump sọ̀rọ̀ yìí ní Scotland lọ́jọ́ ìsinmi ọ̀sẹ̀ yìí pé, bàálù náà yóò tún wúlò fún àwọn’’ ààrẹ lọ́jọ́ iwájú’’’nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ti yóò lò. +Trump tun so pe “a o ni opolopo Aare, ti won yoo je anfaani yii. Trump tún sọ pé “a ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ààrẹ, tí wọn yóò jẹ ànfààní yìí. +"Atunse si baalu ofuurufu naa yoo dara pupo, yoo tun je eyi to dara julo ni agbaye""." "Àtúnṣe sí bàálù òfuurufú náà yóò dára púpọ̀, yóò tún jẹ́ èyí tó dára jùlọ ní àgbáyé""." +Ile-ise omo ogun ori ofuurufu orile-ede Amerika ni baalu meji. Ilé-iṣẹ́ ọmọ ogun orí òfuurufú orílẹ̀-èdè Amẹ́rikà ní bàálù méjì̀. +Lodun 1959 ni Aare Dwight D Eisenhowe lo baalu akoko, t’o awo pupa ati wura sugbon laye Aare Kennedy baalu naa tun lo awo aro ati funfun, titi di oni yii. Lọ́dún 1959 ni Ààrẹ Dwight D Eisẹnhowe lo bàálù àkọ́kọ́, t’ó àwọ̀ pupa àti wúrà ṣùgbọ́n láyé Ààrẹ Kennedy bàálù náà tún lo àwọ̀ aró àti funfun, títí di òní yìí. +Awon alatako ti n soro lori isamulo ero twitter re pe baalu orile-ede Russia, China ati France naa ni oda pupa, funfun ati awo aro, nitori naa ki Trump fi oda naa sile bo se wa. Àwọn alátakò tí ń sọ̀rọ̀ lórí ìṣàmúlò ẹ̀rọ twitter rẹ̀ pé bàálù orílẹ̀-èdè Russia, China àti France náà ní ọ̀dà pupa, funfun àti àwọ̀ aró, nítorí náà kí Trump fi ọ̀dà náà sílẹ̀ bó ṣe wà. +Ile-ise akoroyin ni orile-ede Amerika so pe Aare Trump ti n gbero lati se atunse si baalu naa. Ilé-iṣẹ́ akoròyìn ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé Ààrẹ Trump tí ń gbèrò láti ṣe àtúnṣe sí bàálù náà. +"Iroyin tun so pe aare Trump fe ki baalu naa tun da bii tuntun ""ko da bi ti Amerika, ko yi kuro ni eyi to da bi i ti oda Jackie Kennedy’’, ni eyi ti Raymond Loewy so pe o da bi oko oju omi." "Ìròyìn tún sọ pé ààrẹ̀ Trump fẹ́ kí bàálù náà tún dà bíi tuntun ""kó dà bí ti Amẹ́ríkà, kò yí kúrò ní èyí tó dà bí i ti ọ̀dà Jackie Kennedy’’, ní èyí tí Raymond Loewy sọ pé ó dà bí ọkọ̀ ojú omi." +Baalu ofuurufu naa ti lo ogbon odun, Aare George H W Bush, ni won koko fi gbe. Bàálù òfuurufú náà ti lo ọgbọ̀n ọdún, Ààrẹ George H W Bush, ni wọ́n kọ́kọ́ fi gbé. +Nigba ti aare Trump jawe olubori gege bi aare orile-ede Amerika, o soro lori isamulo twitter re pe, lati ra baalu ti yoo maa gbe aare yoo na won ni bilionu merin dola, ni eyi ti o fagile. Nígbà tí ààrẹ̀ Trump jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bi ààrẹ̀ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó sọ̀rọ̀ lórí ìṣàmúlò twitter rẹ̀ pé, láti ra bàálù tí yóò máa gbé ààrẹ̀ yóò na wọn ni bílíọ́nù mẹ́rin dọ́là, ní èyí tí ó fagilé. +---Aare Buhari de si Hague fun ipade agbaye ICC. ---Ààrẹ Buhari dé sí Hague fún ìpàdé àgbáyé ICC. +Ni irole ojo Aiku ni Aare orile-ede Naijiria Muhammadu Buhari de si orile-ede Netherlands saaju irinajo re lo si ile-ejo agbaye fun iwa odaran, ICC niluu Hague. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àìkú ni Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Muhammadu Buhari dé sí orílẹ̀-èdè Netherlands ṣáájú ìrìnàjò rẹ̀ lọ sí ilé-ẹjọ́ àgbáyé fún ìwà ọ̀daràn, ICC nílùú Hague. +Baalu Aare bale si Rotterdam ni papa ofurufu Hague ni deede aago meje koja iseju metalelogun osan, akoko orile-ede Naijiria. Bàálù Ààrẹ balẹ̀ sí Rotterdam ní pápá òfúrufú Hague ní déédé aago méje kọjá ìṣẹ́jú mẹ́tàlélógún ọ̀sán, àkókò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. +Aare ile-ejo agbaye ICC, adajo Chile Eboe-Osuji, ati igbakeji re fun ile-ejo naa, Marc Perrin de Brichambut ati Minisita fun oro ile okeere, Geoffrey Onyeama, ni won jo lo pade Aare ni papa ofurufu naa. Ààrẹ ilé-ẹjọ́ àgbáyé ICC, adájọ́ Chile Eboe-Osuji, àti igbákejì rẹ̀ fún ilé-ẹjọ́ náà, Marc Perrin de Brichambut àti Mínísítà fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè, Geoffrey Onyeama, ni wọn jọ lọ pàdé Ààrẹ ní pápá òfúrufú náà. +Lara awon to tun wa ni papa ofurufu naa ni Oji Ngofa, asoju orile-ede Naijiria fun orile-ede Netherlands,ogbeni Robert Petri to je asoju orile-ede Netherlands fun orile-ede Naijiria , ogagun Veenhuijzen,oluranlowo oba orile-ede Netherlands ati awon oga agba fun ile-ise to n ri si oro ile okeere lorile-ede Netherlands. Lára àwọn tó tún wà ní pápá òfúrufú náà ni Oji Ngofa, aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún orílẹ̀-èdè Netherlands,ọ̀gbẹ́ni Robert Petri tó jẹ́ aṣojú orílẹ̀-èdè Netherlands fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà , ọ̀gágun Veenhuijzen,olùrànlọ́wọ́ ọba orílẹ̀-èdè Netherlands àti àwọn ọ̀gá àgbà fún ilé-iṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè lórílẹ̀-èdè Netherlands. +Oluralowo Aare lori iroyin ati ipolongo, Femi Adesina so pe Aare yoo lo anfaani naa lati tun soro nibi ayeye ajodun ogun odun ti orile-ede Rome wa lara ile-ejo agbaye to n ri si iwa odaran. Olùràlọ́wọ́ Ààrẹ lórí ìròyìn àti ìpolongo, Fẹ́mi Adésínà sọ pé Ààrẹ yóò lo àǹfààní náà láti tún sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ àjọ̀dún ogún ọdún tí orílẹ̀-èdè Rome wà lára ilé-ẹjọ́ àgbáyé tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn. +Aare yoo tun maa lo anfaani naa lati ri arabinrin Fatou Bensouda t’o tun je agbejoro fun ajo ICC. Ààrẹ yóò tún máa lo àǹfààní náà láti rí arábìnrin Fatou Bensouda t’ó tún jẹ́ agbẹjọ́rò fún àjọ ICC. +Femi Adesina tun so pe “oun nikan ni Aare ti won pe fun ayeye ajodun ogun odun ati pe awon oga agba ile-ise lorile-ede Naijiria ri pipe yii gege bi ona lati fi dupe lori atileyin ti orile-ede Naijiria n se fun ajo naa. Fẹ́mi Adésínà tún sọ pé “òun nìkan ni Ààrẹ tí wọ́n pè fún ayẹyẹ àjọ̀dún ogún ọdún àti pé àwọn ọ̀gá àgbà ilé-iṣẹ́ lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà rí pípè yìí gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà láti fi dúpẹ́ lórí àtìlẹyìn tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń ṣe fún àjọ náà. +Ki Aare to de si Hague ni asoju orile-ede Naijiria ti ba awon akoroyin soro pe b’o tile je pe awon kan n tako ile-ejo agbaye to n ri si iwa odaran sibe Aare Buhari nigbagbo pe ise ti ile-ejo agbaye naa n se yoo dekun awon iwa odaran l’orile-ede agbaye. Kí Ààrẹ tó dé sí Hague ni aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ pé b’ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń tako ilé-ẹjọ́ àgbáyé tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn síbẹ̀ Ààrẹ Buhari nígbàgbọ́ pé iṣẹ́ tí ilé-ẹjọ́ àgbáyé náà ń ṣe yóò dẹ́kun àwọn ìwà ọ̀daràn l’órílẹ̀-èdè àgbáyé. +‘Lati bi ogun odun seyin ni orile-ede Naijiria ti n je igi leyin ogba fun ile-ejo agbaye, paapaa julo l’orile-ede Afirika. ‘Láti bi ogún ọdún ṣẹ́yìn ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ń jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún ilé-ẹj̀ọ àgbáyé, pàápàá jùlọ l’órílẹ̀-èdè Áfíríkà. +Nitori naa, irinajo Aare wa si ile-ejo agbaye je ona lati fi ife han si atileyin re. Nítorí náà, ìrìnàjò Ààrẹ wá sí ilé-ẹjọ́ àgbáyé jẹ́ ọ̀nà láti fi ìfẹ́ hàn sí àtìlẹ́yìn rẹ̀. +Asoju naa tun so pe ‘‘idaniloju wa pe irinajo Aare yoo tun fihan pe orile-ede Naijiria je alatileyin fun ipinnu Rome. Aṣojú náà tún sọ pé ‘‘ìdánilójú wà pé ìrìnàjò Ààrẹ yóò tún fihàn pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ alátìlẹyìn fún ìpinnu Rome. +---Aare Buhari daro iku asofin Longjan ---Ààrẹ Buhari dárò ikú aṣòfin Longjan +Aare Muhammadu Buhari ti ba ile igbimo asofin, ijoba ati awon eniyan ipinle Plateau daro lori iku asofin Ignatius Longjan to n soju fun ila Guusu ipinle Plateau. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti bá ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, ìjọba àti àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Plateau dárò lórí ikú aṣòfin Ignatius Longjan tó ń ṣojú fún ilà Gúúsù ìpínlẹ̀ Plateau. +Aare ba ebi, ore ati awon isongbe asofin naa ti o je igbakeji gomina lodun 2011-15, t’o tun je asoju orile ede Naijiria fun opolopo odun kedun. Ààrẹ bá ẹbí, ọ̀rẹ́ àti àwọn ìsọ̀ngbè aṣòfin náà tí ó jẹ́ igbákejì gómìnà lọ́dún 2011-15, t’ó tún jẹ́ aṣojú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kẹ́dùn. +Aare wa gbadura pe ki Olorun te oloogbe naa si afefe ire. Ààrẹ wá gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tẹ́ olóògbé náà sí afẹ́fẹ́ ire. +---Ile-ise olopaa ko ni kaare lati tubo maa gbogun ti iwa odaran. ---Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá kò ní kàárẹ̀ láti túbọ̀ máa gbógun ti ìwà ọ̀daràn. +Ile-ise olopaa l’orile ede Naijiria ti ni ohun ko ni kaare lati tubo maa gbogun ti iwa odaran l’orile ede yii. Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá l’órílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ní òhun kò ní kàárẹ̀ láti túbọ̀ máa gbógun ti ìwà ọ̀daràn l’órílẹ̀ èdè yìí. +Adari ile-ise olopaa lorile ede Naijiria, Mohammed Adamu lo soro yii lasiko to n se abewo si awon akinkanju olopaa to farapa nigba ti won n woya ija pelu awon odaran ninu igbo Kuduru to wa ni ijoba ibile Birnin Gwari, ni ipinle Kaduna. Adarí ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Mohammed Adamu ló sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń ṣe àbẹ̀wò sí àwọn akínkanjú ọlọ́pàá tó farapa nígbà tí wọn ń wọ̀yá ìjà pẹ̀lú àwọn ọ̀daràn nínú igbó Kuduru tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Birnin Gwari, ní ìpínlẹ̀ Kaduna. +Igbakeji adari ile–ise olopaa, Abdulmajid Ali to soju fun adari ile-ise olopaa orile ede yii ni adari ile-ise olopaa lo ni ki oun wa wo awon akinkanju olopaa naa, ti won farapa nibi isele to waye pelu awon odaran ohun. Igbákejì adarí ilé–iṣẹ́ ọlọ́pàá, Abdulmajid Ali tó ṣojú fún adarí ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá orílẹ̀ èdè yìí ni adarí ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ló ní kí òun wá wo àwọn akínkanjú ọlọ́pàá náà, tí wọn farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé pẹ̀lú àwọn ọ̀daràn ọ̀hún. +O ni inu oun dun pelu itoju ti awon olopaa naa n gba nile iwosan, o ni. “Awon dokita n toju awon to farapa naa, nitori naa ko si iberu nipa itoju ti won n gba“. Ó ní inú òun dún pẹ̀lú ìtọ́jú tí àwọn ọlọ́pàá náà ń gbà nílé ìwòsàn, ó ní. “Àwọn dókítà ń tọ́jú àwọn tó farapa náà, nítorí náà kò sí ìbẹ̀rù nípa ìtọ́jú tí wọn ń gbà“. +O wa fi da awon to farapa naa loju pe, won yoo gba itoju to peye. Ó wá fi dá àwọn tó farapa náà lójú pé, wọn yóò gba ìtọ́jú tó péye. +Igbakeji adari ile–ise olopaa naa ni o seni laaanu pe awon olopaa meji lo gbemii mi. Oruko awon olopaa ti won ku naa ni Muhammad Abubakar ati Sergeant Idris Igbákejì adarí ilé–iṣẹ́ ọlọ́pàá náà ní ó seni láàánú pé àwọn ọlọ́pàá méjì ló gbẹ́mìí mì. Orúkọ àwọn ọlọ́pàá tí wọn kú náà ní Muhammad Abubakar àti Sergeant Idris +---Ajo to n mojuto eto ilera ni agbaye ti ro orile ede Naijiria lati mojuto gbogbo enu ibode ati ibudo oko to wa lorile ede yii nipa gbigbogun ti iwa aarun ohun osin, coronavirus, paapaa julo ni awon ipinle mesan an to wa lorile ede yii. ---Àjọ tó ń mójútó ètò ìlera ní àgbáyé ti rọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti mójútó gbogbo ẹnu ibodè ati ibùdó ọkọ tó wà lórílẹ̀ èdè yìí nípa gbígbógun ti ìwà ààrùn ohun ọsin, coronavirus, pàápàá jùlọ ní àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́sàn án tó wà lórílẹ̀ èdè yìí. +Alakosoo eto akanse fun eto pajawiri ni eka ajo WHO, arabinrin, Dhamari Naidoo soro yii lasiko iforowanilenuwo pelu awon akoroyin niluu Abuja. Alákòsóo ètò àkànse fún ètò pàjáwìrì ní ẹka àjọ WHO, arábìnrin, Dhamari Naidoo sọ̀rọ̀ yìí lásìkò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn nílùú Àbújá. +O tesiwaju pe awon ipinle to wa ninu ewu lati ni aarun coronavirus lorile ede yii ni: Abuja, Eko, Kano, Cross River, Akwa Ibom, Port Harcourt, Enugu, Delta, ati Bayelsa. Ó tẹ̀síwájú pé àwọn ìpínlẹ̀ tó wà nínú ewu láti ní ààrun coronavirus lórílẹ̀ èdè yìí ni: Àbújá, Èkó, Kano, Cross River, Akwa Ibom, Port Harcourt, Enugu, Delta, ati Bayelsa. +O tun so pe ajo WHO ti seto iranwo ayewo ni awon ile iwosan to wa ni Gaduwa niluu Abuja ati LUTH to wa niluu Eko. Ó tún sọ pé àjọ WHO ti ṣètò ìrànwọ́ àyẹ̀wò ní àwọn ilé ìwòsàn tó wà ní Gaduwa nílùú Àbújá àti LUTH tó wà nílùú Èkó. +Arabinrin Naidoo tun so pe awon orile ede metala lo wa ninu ewu arun coronavirus, nitori bi opo eniyan se n yawo awon orile ede yii, Algeria, Angola, Cote d’Ivoire, Democratic Republic of Congo, Ethiopia, Ghana, Kenya, Mauritius, Nigeria, South Africa, Tanzania, Uganda ati Zambia. Arábìnrin Naidoo tún sọ pé àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́tàlá ló wà nínú ewu àrùn coronavirus, nítorí bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe ń yawọ àwọn orílẹ̀ èdè yìí, Algeria, Angola, Cote d’Ivoire, Democratic Republic of Congo, Ethiopia, Ghana, Kenya, Mauritius, Nigeria, South Africa, Tanzania, Uganda àti Zambia. +Arabinrin Charity Warigon to je alakooso eka to n mojuto eto iroyin ni ajo WHO wa ro awon akoroyin lati maa sewadii iroyin won ki won to gbee jade, paapaa julo nipa aarun coronavirus, nitori iroyin ti won ba gbe jade ni awon eniyan maa n gbekele. Arábìnrin Charity Warigon tó jẹ́ alákòóso ẹka tó ń mójútó ètò ìròyìn ni àjọ WHO wá rọ àwọn akọ̀ròyìn láti máa ṣèwádìí ìròyìn wọn kí wọn tó gbée jáde, pàápàá jùlọ nípa ààrùn coronavirus, nítorí ìròyìn tí wọ́n bá gbé jáde ni àwọn ènìyàn máa ń gbẹ́kẹ̀le. +---Orile ede Germany ti ni ohun setan lati fowosowopo pelu orile ede Naijiria lati mojuto isoro isikiri. ---Orílẹ̀ èdè Germany ti ní ohun ṣetán láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti mójútò ìṣoro ìṣikirí. +Minisita ipinle fun orile ede Germany ati komisona fun oro to je mo sisa kuro lorile ede, sise atipo ati ibagbepo, obabinrin Annette Widmann-Mauz, lo soro yii lasiko to se abewo si orile ede Naijiria. Mínísítà ìpínlẹ̀ fún orílẹ̀ èdè Germany àti kọmísọ́nà fún ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ sísá kúrò lórílẹ̀ èdè, ṣíṣe àtìpó àti ìbágbépọ̀, ọbabìnrin Annette Widmann-Mauz, ló sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ṣe àbẹ̀wò sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Minisita ipinle fun orile ede Germany ni “ Orile ede Naijiria ti n ko ipa pataki lati se atipo fun awon omo orile ede won to wa niluu Germany, idi niyi ti a se fe fowosowopo lati ba won se ise papo, mo si ni itara lati ri. Mínísítà ìpínlẹ̀ fún orílẹ̀ èdè Germany ní “ Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ń kó ipa pàtàkì láti ṣe àtìpò fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè wọn tó wà nílùú Germany, ìdí nìyí tí a ṣe fẹ́ fọwọ́sowọ́pọ̀ láti bá wọn ṣe iṣẹ́ papọ̀, mo sì ní ìtara láti rí. +Obabinrin tun salaye pe, won yoo gbe igbese ni kiakia lati lee wa ojutuu si eredi ohun to n fa ki awon eniyan maa sa kuro ni orile ede won. Ọbabìnrin tún ṣàlàyé pé, wọn yóò gbé ìgbésẹ̀ ní kíákíá láti leè wá ojútùú sí èrèdí ohun tó ń fá kí àwọn ènìyàn máa sá kúrò ní orílẹ̀ èdè wọn. +O tun tesiwaju pe “Lati lee gbe igbese nipa bi awon eniyan se n sa kuro lorile ede won, a nilo olubasepo to muna-doko, idi niyi ti a fi ni orile ede Naijiria to je alabaasisepo pelu wa”. Ó tún tẹ̀síwájú pé “Láti leè gbé ìgbésẹ̀ nípa bí àwọn ènìyàn ṣe ń sá kúrò lórílẹ̀ èdè wọn, a nílò olùbásepọ̀ tó múná-dóko, ìdí nìyí tí a fi ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó jẹ́ alábàásisẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa”. +Saaju eyi ni komisona to n mojuto, atipo, sisa kuro lorile ede ati awon ti ogun le kuro ni ibugbe won, Asofin Basheer Garba Mohammed naa so pe orile ede Naijiria n sise eto ilana nipa ti isinipokiri. Ṣáájú èyí ni kọmísọ́nà tó ń mójútó, àtìpó, sísá kúrò lórílẹ̀ èdè àti àwọn tí ogun lé kúrò ní ibùgbé wọn, Aṣòfin Basheer Garba Mohammed náà sọ pé orílè èdè Nàìjíríà ń ṣiṣẹ́ ètò ìlànà nípa ti ìṣínípòkiri. +Ile igbimo asofin n se ipade bonkele pelu adari awon olopaa Naijiria. Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ń ṣe ìpàdé bòǹkẹ́lẹ́ pẹ̀lú adarí àwọn ọlọ́pàá Nàìjíríà. +Ile igbimo asofin orile ede Naijiria ti wa ni ipade bonkele pelu adari awon olopaa orile ede yii, Mohammed Adamu lati wa soro nipa isoro to n dojuko eto aabo lorile ede yii. Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti wà ní ìpàdé bòǹkẹ́lẹ́ pẹ̀lú adarí àwọn ọlọ́pàá orílẹ̀ èdè yìí, Mohammed Adamu láti wa sọ̀rọ̀ nípa ìṣoro tó ń dojúkọ ètò ààbò lórílẹ̀ èdè yìí. +---Ile-ise aare ti ni igbese ti egbe awon onigbagbo Christian Association of Nigeria (CAN) gbe je eto gbogbo omo orile ede Naijiria lati fi ehonu han nipa erongba won lori esin, ilana ise ati awujo. ---Ilé-iṣẹ́ ààrẹ ti ní ìgbésẹ̀ tí ẹgbẹ́ àwọn onígbàgbọ́ Christian Association of Nigeria (CAN) gbe ́ jẹ́ ẹ̀tọ̀ gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti fi ẹ̀hónú hàn nípa èròǹgbà wọn lórí ẹ̀sìn, ìlànà iṣẹ́ àti àwùjọ. +Oluranwo aare Buhari lori iroyin ati ikede, Garba Shehu ni aare ba awon onigbagbo kedun, bee sini inu aare tun baje lori bi Boko Haram se pa pasito Lawan Andimi. Ọlùrànwọ́ ààrẹ Buhari lórí ìròyìn àti ìkéde, Garba Shehu ní ààrẹ bá àwọn onígbàgbọ́ kẹ́dùn, bẹ́ẹ̀ sìni inú ààrẹ tún bàjẹ́ lórí bí Boko Haram ṣe pa pásítọ̀ Lawan Andimi. +---Ijoba orile ede Amerika, ti gbosuba fun aare Buhari lori ipa ti o n ko lati gbogun ti iwa ibaje lorile ede Naijiria. ---Ìjọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, ti gbósùbà fún ààrẹ Buhari lórí ipa tí ó ń kó láti gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Ninu atejade kan ti Morgan Ortagus, ti o je agbenuso fun ile-ise otelemuye fun orile ede Amerika ko, leyin ti ijoba orile ede Amerika, Bailiwick of Jersey ati ijoba orile ede Naijiria towobo iwe adehun lati da milionu $308 owo ti oloogbe Sani Abacha ji ko pamo si orile Amerika pada fun orile ede Naijiria, orile ede Amerika tun seleri lati tubo maa satileyin fun orile ede Naijiria nipa gbigbogun ti iwa ibaje. Nínú àtẹ̀jáde kàn tí Morgan Ortagus, tí ó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé-isẹ́ ọ̀telẹ̀múyẹ́ fún orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà kọ̀, lẹ́yìn tí ìjọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, Bailiwick of Jersey àti ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tọwọ́bọ ìwé àdéhùn láti dá mílíọ́nù $308 owó ti olóògbé Sani Abacha jí kó pamọ́ sí orílẹ̀ Amẹ́ríkà padà fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, orílẹ èdè Amẹ́ríkà tún ṣèlérí láti túbọ̀ máa ṣàtìlẹyìn fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nípa gbígbógun ti ìwà ìbàjẹ́. +Oluranwo aare Buhari lori iroyin ati ikede, Garba Shehu lo soro yii lasaale ojo Isegun ninu iwe atejade kan. Olùrànwọ́ ààrẹ Buhari lórí ìròyìn àti ìkéde, Garba Shehu ló sọ̀rọ̀ yìí lásàálẹ́ ọjọ́ Ìsẹ́gun nínú ìwé àtẹ̀jáde kàn. +---Aare Muhammadu Buhari kedun iku aare orile ede Kenya teleri, Arap Moi. ---Ààrẹ Muhammadu Buhari kẹ́dùn ikú ààrẹ orílẹ̀ èdè Kenya tẹ́lẹ̀rí, Arap Moi. +Aare Muhammadu Buhari ti sapejuwe aare orile ede Kenya teleri, Daniel Arap Moi gege bi asiwaju rere , ti o fi ohun gbogbo ti o dara julo fun idagbasoke orile ede re. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti sàpéjúwe ààrẹ orílẹ̀ èdè Kenya tẹ́lẹ̀rí, Daniel Arap Moi gẹ́gẹ́ bí asíwájú rere , tí ó fi ohun gbogbo tí ó dára jùlọ fún ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè rẹ̀. +O ni Moi je okan pataki ninu awon to je ki idagbasoke ba ekun ila oorun Afirika. Ó ní Moi jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn tó jẹ́ kí ìdàgbàsókè bá ẹkùn ìlà oòrùn Áfíríkà. +Aare tun ba aare orile ede Kenya, Uhuru Kenyatta, ijoba ati awon eniyan orile ede Kenya kedun lori iku oloogbe naa, Aare Buhari ni: “Lati idile ti ko ri owo hori (o je oluko), oloogbe Arap Moi di oloselu, ki o to di aare orile ede naa. Ààrẹ tún bá ààrẹ orílẹ̀ èdè Kenya, Uhuru Kenyatta, ìjọba àti àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Kenya kẹ́dùn lórí ikú olóògbé náà, Ààrẹ Buhari ní: “Láti ìdílé tí kò rí ọwọ́ họrí (ó jẹ́ olùkọ́), olóògbé Arap Moi di olósèlú, kí ó tó di ààrẹ orílẹ̀ èdè náà. +Aare wa gbadura pe ki olorun te oloogbe naa si afefe ire. Ààrẹ wá gbàdúrà pé kí ọlọ́run tẹ́ olóògbé náà sí afẹ́fẹ́ ire. +---Minisita so wipe igbohun safefe ede Naijiria, okan ninu ohun to ni ominira julo. ---Mínísítà sọ wípé ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ èdè Nàíjíríà, ọ̀kan nínú ohun tó ní òmìnira jùlọ. +Ijoba orile ede Naijiria ti ni orile ede yii lo fi aaye gba ominira nipa oro siso ju fun awon eniyan ni agbaye. Ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà ti ní orílẹ̀ èdè yìí ló fi ààyè gba òmìnira nípa ọ̀rọ̀ sísọ jù fún àwọn ènìyàn ní àgbáyé. +Ijoba ni bo tile je pe orile ede Naijiria fun awon eniyan ni ominira lati lee so oro to ba wu won, pupo ninu won ni ko mo eto re nipa oro siso. Ìjọba ní bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fún àwọn ènìyàn ni òmìnira láti leè sọ ọ̀rọ̀ tó bá wù wọ́n, púpọ̀ nínú wọn ni kò mọ ẹ̀tọ́ rẹ nípa ọ̀rọ̀ sísọ. +Minisita fun iroyin ati asa lorile ede Naijiria, Lai Mohammed, lo soro yii lojo Aje nigba ti o n gba asoju orile ede Finland, Jyrki Pulkkinen, ati alaakoso to n mojuto oro ile okeere ni eka eto ogbon atinuda fun orile Finland, Jarmo Sareva, wa si ile-ise re fun ipolongo ominira oro siso. Mínísítà fún ìròyìn àti àṣà lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Lai Mohammed, ló sọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́ Ajé nígbà tí ó ń gba aṣojú orílẹ̀ èdè Finland, Jyrki Pulkkinen, àti aláákóso tó ń mójútó ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè ní ẹka ètò ọgbọ́n àtinúdá fún orílẹ̀ Finland, Jarmo Sareva, wá sí ilé-isẹ́ rẹ̀ fún ìpolongo òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. +Minisita tun so pe ajo to n mojuto eto iroyin ati asa yoo se ipade po pelu awon torookan losu yii lati se agbeyewo eto nipa lilo imo ero ayelujara, lona ti won ko fi ni te ominira nipa oro siso ati eto omoniyan mole. Mínísítà tún sọ pé àjọ tó ń mójútó ètò ìròyìn àti àsà yóò se ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn tọ́rọ̀ọ́kàn lósù yìí láti ṣe àgbéyẹ̀wò ẹ̀tọ́ nípa lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ ayélujára, lọ́nà tí wọn kò fi ní tẹ òmìnira nípa ọ̀rọ̀ sísọ àti ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn mọ́lẹ̀. +O ni inu ijoba orile ede Naijiria ko dun si bi awon kan se n lo imo ayelujara lati fi gbe awon iroyin eleje ati oro to lee da wahala sile jade lati fa ede aiyede. Ó ní inú ìjọba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kò dùn si bí àwọn kàn se ń lo ìmọ̀ ayélujára láti fi gbé àwọn ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ àti ọ̀rọ̀ tó leè dá wàhálà sílẹ̀ jáde láti fa èdè àìyedè. +---Gomina egbe oselu APC yoo fi atunse eto ofin ranse si ile igbimo asofin. ---Gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC yóò fi àtúnṣe ètò òfin ránsẹ́ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin. +Awon gomina egbe oselu APC, labe igbimo gomina to n mojuto eto itesiwaju fun awon gomina, Progressive Governors Forum, PGF ti n se agbeyewo ofin lati se atunse si eto ofin ti yoo mu igbaye-gbadun ati isejoba rere ba gbogbo ipinle lorile ede Naijiria, ni eyi ti won yoo fi ranse si ile igbimo asofin. Àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC, lábẹ́ igbimọ gómìnà tó ń mójútó ètò ìtẹ́síwájú fún àwọn gómìnà, Progressive Governors Forum, PGF ti ń ṣe àgbéyẹ̀wò òfin láti ṣe àtúnṣe sí ètò òfin tí yóò mú ìgbáyé-gbádùn àti ìṣèjọba rere bá gbogbo ìpínlẹ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ní èyí tí wọ́n yóò fi ránsẹ́ sí ilé ìgbìmọ̀ asòfin. +Philip Shuaibu to je asoju gomina ipinle Edo Godwin Obaseki lo soro yii lasiko to n ba awon akoroyin soro niluu Abuja, leyin ipade ti igbimo PGF se. Philip Shuaibu tó jẹ́ aṣojú gómìnà ìpínlẹ̀ Edo Godwin Obaseki ló sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nílùú Àbújá, lẹ́yìn ìpàdé tí ìgbìmọ̀ PGF ṣe. +O tun tesiwaju pe igbimo ohun yoo ye iwe akosile ti gomina ipinle Kaduna Nasir El-Rufai ko, lasiko ti o n dari igbimo to n sagbeyewo atunse ofin. Ó tún tẹ̀síwájú pé ìgbìmọ̀ ọ̀hún yóò yẹ ìwé àkọsílẹ̀ tí gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna Nasir El-Rufai kọ̀, lásìkò tí ó ń darí ìgbìmọ̀ tó ń ṣàgbéyẹ̀wò àtúnṣe òfin. +Ogbeni Shuaibu tun so pe igbimo naa n se ise papo pelu gbogbo awon gomina ti o wa ninu egbe oselu APC, awon igbimo asofin ati egbe oselu ohun lati lee se awon eto ati ilana ti yoo mu igbaye-gbadun ba gbogbo ipinle to wa lorile ede Naijiria. Ọ̀gbẹ́ni Shuaibu tún sọ pé ìgbìmọ̀ náà ń ṣe iṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn gómìnà tí ó wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, àwọn ìgbìmọ̀ aṣòfin àti ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún láti leè ṣe àwọn ètò àti ìlànà tí yóò mú ìgbáyé-gbádùn bá gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +Okan lara omo egbe ile igbimo asofin, Yahaya Abdullahi, to wa nibi ipade ohun, tun so pe igbimo teekoto naa yoo sagbeyewo iwe akosile ti El-Rufai ko, ni eyi ti ile igbimo asofin yoo fenuko le lori paapaa julo nipa eto igbaye-gbadun ati isejoba rere lorile ede Naijiria. Ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ ilé ìgbìmọ̀ asòfin, Yahaya Abdullahi, tó wà níbi ìpàdé ọ̀hún, tún sọ pé ìgbìmọ̀ tẹ̀ẹ́kótó náà yóò sàgbéyẹ̀wò ìwé àkọsílẹ̀ tí El-Rufai kọ, ní èyí tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin yóò fẹnukò lé lórí pàápàá júlọ nípa ètò ìgbáyé-gbádùn àti ìṣèjọba rere lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. +--- Anthony Joshua n jiroro lori ibi igbaradi saaju ifigagbaga pelu Jarrell Miller. --- Anthony Joshua ń jíròrò lórí ibi ìgbáradì ṣaájú ìfigagbága pẹ̀lú Jarrell Miller. +Ni bayii, elesee omo ile Biritiko, Anthony Joshua ti n se ipade lori gbagede igbaradi ti yoo lo ki o to lo koju elesee ile New York, Jarrell Miller ninu itakangbon fun ami-eye agbaaye. Ní báyìí, ẹlẹ́ṣẹ̀ẹ́ ọmọ ilẹ̀ Bìrìtìkó, Anthony Joshua ti ń ṣe ìpàdé lórí gbàgede ìgbáradì tí yóò lò kí ó tó lọ kojú ẹlẹ́ṣẹ̀ẹ́ ilẹ̀ New York, Jarrell Miller nínú ìtakàǹgbọ̀n fún àmì-ẹ̀yẹ àgbááyé. +Bi o tile je pe, Anthony Joshua ko figba kankan tura sile, leyin igbaradi olojo pipe fun ifigagbaga naa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, Anthony Joshua kò fìgbà kankan túra sílẹ̀, lẹ́yìn ìgbáradì ọlọ́jọ́ pípẹ́ fún ìfigagbága náà. +Iroyin fi idi re mule pe, Joshua n duro de aridaju ifigagbaga naa laarin oun ati Miller ni gbagede Madison Square, ninu osu kefa odun yii. Ìròyìn fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, Joshua ń dúró de àrídájú ìfigagbága náà láàrín òun àti Miller ní gbàgede Madison Square, nínú oṣù kẹfà ọdún yìí. +Bakan naa ni, akeegbe re ti o padanu, Eddie Hearn se ipade pelu Dillian Whyte lori boya ifigagbaga won yoo di atungbekale. Bákan náà ni, akẹẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó pàdánù, Eddie Hearn ṣe ìpàdé pẹ̀lú Dillian Whyte lórí bóyá ìfigagbága wọn yóò di àtúngbékalẹ̀. +--- Martial sun akoko re siwaju ninu iko Manchester United. --- Martial sún àkókò rẹ̀ síwájú nínú ikọ̀ Manchester United. +Atamatase omo orile-ede France, Anthony Martial ti o je agbaboolu iko Manchester United ti buwo lu iwe adehun isise olodun marun-un lati sun akoko re siwaju ninu iko Manchester United di odun 2024. Atamátàsé ọmọ orílẹ̀-èdè France, Anthony Martial tí ó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Manchester United ti buwọ́ lu ìwé àdéhùn ìṣiṣẹ́ ọlọ́dún márùn-ún láti sún àkókò rẹ̀ síwájú nínú ikọ̀ Manchester United di ọdún 2024. +Bi o ti le je pe, orisirisi aheso oro lo gba oju-oja kan pe, o seese ki agbaboolu naa o kuro ninu iko Manchester United. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, oríṣiríṣi àhesọ ọ̀rọ̀ ló gba ojú-ọjà kan pé, ó ṣeéṣe kí agbábọ́ọ̀lù náà ó kúrò nínú ikọ̀ Manchester United. +Ni bayii, Martial ti gba apapo boolu mewaa sawon ni saa yii, ti o si se iranwo ayo kan ninu ifesewonse marundinlogbon ni saa yii. Ní báyìí, Martial ti gbá àpapọ̀ bọ́ọ̀lù mẹ́wàá sáwọ̀n ní sáà yìí, tí ó sì ṣe ìrànwọ́ ayọ̀ kan nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ márùndínlọ́gbọ̀n ní sáà yìí. +Opolopo ninu awon agbaboolu ohun ni o gboriyin fun adele akonimoogba iko Manchester United, Ole Gunnar Solskjaer fun ise takuntakun ati ipa ti o ko lati igba ti o ti ropo akonimoogba iko naa tele, Jose Mourinho. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn agbábọ́ọ̀lù ọ̀hún ni ó gbóríyìn fún adelé akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Manchester United, Ole Gunnar Solskjaer fún iṣẹ́ takuntakun àti ipa tí ó kó láti ìgbà tí ó ti rọ́pò akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ náà tẹ́lẹ̀, Jose Mourinho. +Gege bi Martial se so, Mo dupe lowo Ole gidi gan ati awon akonimoogba yooku fun igbagbo won ninu mi, nitori pe won ranmi lowo pupo lati mu igberu ba bi mo se n kopa si. Gẹ́gẹ́ bí Martial ṣe sọ, Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ole gidi gan àti àwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá yòókù fún ìgbàgbọ́ wọn nínú mi, nítorí pé wọ́n rànmí lọ́wọ́ púpọ̀ láti mú ìgbèrú bá bí mo ṣe ń kópa sí. +A mo iko agbaboolu Manchester United seyin gege bi, iko ti o nifee lati maa gba ife eye lopolopo, o da mi loju pe, laipe a o tun gba ife eye. A mọ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Manchester United sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí, ikọ̀ tí ó nífẹ̀ẹ́ láti máa gba ife ẹ̀yẹ lọ́pọ̀lọpọ̀, ó dá mi lójú pé, láìpẹ́ a ó tún gba ife ẹ̀yẹ. +"""Anthony Martial dara po mo Manchester United lodun 2015 lati inu iko agbaboolu Monaco pelu milionu merindinlogoji £36 million ($47m), lati igba naa ni o ti n ri ara re gege bi okan lara agbaboolu odo ti o dara julo." """Anthony Martial dara pọ̀ mọ́ Manchester United lọ́dún 2015 láti inú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Monaco pẹ̀lú mílíọ́nù mẹ́rìndínlógójì £36 million ($47m), láti ìgbà náà ni ó ti ń rí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára agbábọ́ọ̀lù ọ̀dọ́ tí ó dára jùlọ." +Akonimoogba iko ohun, Solskjaer naa fi aidunnu re han leyin ti Martial tun buwo lu iwe adehun ninu iko naa. Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ ọ̀hún, Solskjaer náà fi àìdùnnú rẹ̀ hàn lẹ́yìn tí Martial tún buwọ́ lu ìwé àdéhùn nínú ikọ̀ náà. +"Anthony wa lara agbaboolu odo ti o dara julo fun iko naa, o si je agbaboolu ti akonimoogba yoowu yoo nifee lati ni ninu iko re, nitori pe, o rorun lati ba sisepo,""" "Anthony wà lára agbábọ́ọ̀lu ọ̀dọ́ tí ó dára jùlọ fún ikọ̀ náà, ó sì jẹ́ agbábọ́ọ̀lù tí akọ́nimọ̀ọ́gbá yòówù yóò nífẹ̀ẹ́ láti ní nínú ikọ̀ rẹ̀, nítorí pé, ó rọrùn láti bá ṣiṣẹ́pọ̀,""" +--- Sarri- Mi o di Hazard lowo to ba fe lo --- Sarri- Mi ò dí Hazard lọ́wọ́ tó bá fẹ́ lọ +Akonimoogba iko agbaboolu Chelsea, Maurizio Sarri ti je ki Eden Hazard mo pe oun ko da a duro, ti o ba pinnu lati maa lo. Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Chelsea, Maurizio Sarri ti jẹ́ kí Eden Hazard mọ̀ pé òun kò dá a dúró, tí ó bá pinnu láti máa lọ. +Sarri so pe looto oun fe ki Hazard o si wa ninu iko Chelsea, sugbon oun ko ni di i lowo ti o ba fe fi iko agbaboolu naa sile. Sarri sọ pé lòótọ́ òun fẹ́ kí Hazard ó ṣì wà nínú ikọ̀ Chelsea, ṣùgbọ́n òun kò ní dí i lọ́wọ́ tí ó bá fẹ́ fi ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù náà sílẹ̀. +A o ranti pe, iko agbaboolu Real Madrid ti n fe ki Hazard o dara po mo iko ohun ni orile-ede Spain. A ó rántí pé, ikọ̀ agbábọ́ọ̀lu Real Madrid ti ń fẹ́ ki Hazard ó dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ ọ̀hún ní orílẹ̀-èdè Spain. +Ti Hazard funra re ti so pe o wu oun lati dara po mo iko Real Madrid, bi iko ohun ba setan lati ra oun. Tí Hazard fúnra rẹ̀ ti sọ pe ó wu òun láti dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ Real Madrid, bí ikọ̀ ọ̀hún bá ṣetán láti ra òun. +Ni bayii, iko agbaboolu Chelsea fe ki Hazard towo bo iwe adehun tuntun ki adehun tile o to tan lodun to n bo. Ní báyìí, ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Chelsea fẹ́ kí Hazard tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn tuntun kí àdéhùn tilẹ̀ ó tó tán lọ́dún tó ń bọ̀. +Hazard dara po mo Chelsea lodun 2012, o si ti gba apapo ayo mewaa sawon fun iko Chelsea ninu idije premier league ti saa yii. Hazard dara pọ̀ mọ́ Chelsea lọ́dun 2012, ó sì ti gbá àpapọ̀ ayò mẹ́wàá sáwọ̀n fún ikọ̀ Chelsea nínú ìdíjé premier league ti sáà yìí. +--- Iko agbaboolu obinrin Dream Stars safihan akonimoogba tuntun. --- Ikọ̀ agbábòọ̀lù obìnrin Dream Stars ṣàfihàn akọ́nimọ̀ọ́gbá tuntun. +Iko agbaboolu obinrin Dream Stars ti ipinle Eko ti safihan akonimoogba agba tuntun, ogbeni Felix Nwosu, saaju idije saa 2018/2019 idije Liigi awon obinrin orile-ede Naijiiria. Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù obìnrin Dream Stars ti ìpínlẹ̀ Èkó ti ṣàfihàn akọ́nimọ̀ọ́gbá àgbà tuntun, ọ̀gbẹ́ni Felix Nwosu, ṣaájú ìdíje sáà 2018/2019 ìdíje Líìgì àwọn obìnrin orílẹ̀-èdè Nàìjííríà. +Iko ti o fi ilu eko se ibugbe ti o si sese gba igbega ohun nigbeyingbeyin ti gba ilumooka akonimoogba omo bibi ipinle Anambra yii. Ikọ̀ tí ó fi ìlú ẹ̀kọ́ ṣe ibùgbé tí ó sì ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ìgbéga ọ̀hún nìgbẹ̀yìngbéyín ti gba ìlúmọ̀ọ́ká akọ́nimọ̀ọ́gbá ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Anambra yìí. +Felix Nwosu je ojimi akonimoogba ti o ti sise pelu iko FC Talanta lorile-ede Kenya, Heegan FC ni Somali, FIN FA niluu Enugu, FIN Angels, Ambassador Child Youth Club /Angels niluu Enugu ri. Felix Nwosu jẹ́ òjìmì akọ́nimọ̀ọ́gbá tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ikọ̀ FC Talanta lórílẹ̀-èdè Kenya, Heegan FC ní Somali, FIN FA nílùú Enugu, FIN Angels, Ambassador Child Youth Club /Angels nílùú Enugu rí. +Ninu ifanikale fun ami eye, o je fifakale ati kikasi lati lowo iko Arsenal/ile ise WorldRemit gege bi okan lara awon akonimoogba odo ti o dangajia julo jake-jado ile Adulawo, o wa lara akonimoogba marundinlogbon akoko ninu apapo akonimoogba ti o le ni eedegberin Nínú ìfanikalẹ̀ fun àmì ẹ̀yẹ, ó jẹ́ fífàkalẹ̀ àti kíkàsí láti lọ́wọ́ ikọ̀ Arsenal/ilé iṣẹ́ WorldRemit gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn akọ́nímọ́ọ̀gbá ọ̀dọ́ tí ó dáńgájíá jùlọ jákè-jádò ilẹ̀ Adúláwọ̀, ó wà lára akọ́nimọ̀ọ́gbá márùndínlọ́gbọ̀n àkọ́kọ́ nínú àpapọ̀ akọ́nimọ̀ọ́gbá tí ó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin +Eni ti o je Alaga iko agbaboolu Dream Stars Ladies, Ogbeni AbdulRahmon Abolore so pe; “Iko naa ya si Nwosu tori agbongbe iriri ti o ni ati pe o da oun loju pe agbaboolu owo eyin iko Gor Mahia teleri ohun le se iranwo fun iko naa lati so erongba re di mimuse. Ẹni tí ó jẹ́ Alága ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Dream Stars Ladies, Ọ̀gbẹ́ni AbdulRahmon Àbọ̀lọrẹ sọ pé; “Ikọ̀ náà yà sí Nwosu torí àgbọ́ǹgbẹ ìrírí tí ó ní àti pé ó dá òun lójú pé agbábòọ̀lù ọwọ́ ẹ̀yin ikọ̀ Gor Mahia tẹ́lẹ̀rí ọ̀hún lè ṣe ìrànwọ́ fún ikọ̀ náà láti sọ èròńgbà rẹ̀ di mímúṣẹ. +“Afojusun wa ni lati kopa daradara pelu igbega wa yii si inu idije liigi, a ko si fe da okuta kan si laibi lule. “Àfojúsùn wa ni láti kópa dáradára pẹ̀lú ìgbéga wa yìí sí inú ìdíje líìgì, a kò sì fẹ́ da òkuta kan sí láìbì lulẹ̀. +--- Ko si idaniloju isawari Emiliano Sala to di awaari. --- Kò sí ìdánilójú ìṣàwárí Emiliano Sala tó di àwáàrí. +Oga agba ile-ise to n ri si isele pajawiri ati oko ofurufu ti o ba di awati sori erekusu, Ogbeni John Fitzgerald ti so pe, ko si ireti pe Sala yoo di sisawari mo. Ọ̀gá àgbà ilé-iṣẹ́ tó ń rí sí ìṣẹ̀lè pàjáwìrì àti ọkọ̀ òfurufú tí ó bá di àwáti sórí erékùsù, Ọ̀gbẹ́ni John Fitzgerald ti sọ pé, kò sí ìrètí pé Sala yóò di ṣíṣàwárí mọ́. +Emiliano Sala omo orile-ede Argentina, to je eni odun mejidinlogbon wa pelu awako ofurufu ninu oko baalu kan ti o di awati lanaa ojo aje (Monday). Emiliano Sala ọmọ orílẹ̀-èdè Argentina, tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n wà pẹ̀lú awakọ̀ òfurufú nínú ọkọ̀ bàálù kan tí ó di àwátì lánàá ọjọ́ ajé (Monday). +Siwaju si, iko adoola emi ti tesiwaju ninu wiwa oko ofurufu naa ati awon ero inu re lojoru (Wednesday). Ṣíwájú si, ikọ̀ adóòlà ẹ̀mí ti tẹ̀síwájú nínú wíwá ọkọ̀ òfúrufú náà àti àwọn èrò inú rẹ̀ lọ́jọ́rú (Wednesday). +Iroyin kan fi lede pe Sala fi atejise ero ayelujara whatsapp ranse si ore re kan ati awon molebi pe Eru n ba oun pelu bi oko ofurufu naa se n se loju ofurufu. Ìròyìn kán fi léde pé Sala fi àtẹ̀jíṣẹ́ ẹ̀rọ ayélujára whatsapp ránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan àti àwọn mọ̀lẹ́bí pé Ẹ̀rù ń ba òun pẹ̀lú bí ọkọ̀ òfúrufú náà ṣe ń ṣe lójú ofurufú. +"Gege bi ile-ise akoroyin l’orile-ede Argentina se so, Sala so fun awon molebi re bayii pe ""Mo wa ninu oko ofurufu kan to dabi eni pe o fe ni ijamba." "Gẹ́gẹ́ bí ilé-iṣẹ́ akọ̀ròyìn l’orílẹ̀-èdè Argentina ṣe sọ, Sala sọ fún àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ báyìí pé ""Mo wà nínú ọkọ̀ òfurufú kan tó dàbí ẹni pé ó fẹ́ ní ìjàm̀bá." +Wayii o ni nnkan bi aago mokanla aabo owuro, ile-ise olopaa ni Guernsey so pe, oko ofurufu meta ati baalu kekere kan wa loju ofurufu, bi won se n wa baalu Piper Malibu. Wàyíí o ní nǹkan bí aago mọ́kànlá ààbọ̀ òwúrọ̀, ile-iṣẹ́ ọlọ́pàá ni Guernsey sọ pé, ọkọ̀ òfúrufú mẹ́ta àti bàálù kékeré kan wà lójú òfurufú, bí wọ́n ṣe ń wá bàálù Piper Malibu. +Bakan naa ni awon olopaa so pe awon ti n sayewo awon itakuroso ori ero ibanisoro lati mo boya o le se iranwo Bákan náà ni àwọn ọlọ́pàá sọ pé àwọn ti ń ṣàyẹ̀wò àwọn ìtàkùrọ̀sọ orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ láti mọ̀ bóyá ó lè ṣe ìrànwọ́ +Sugbon titi di asiko yii, ko ti i si iroyin kankan nipa baalu to di awati ohun Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí, kò tí ì sí ìròyìn kankan nípa bàálù tó di àwáti ọ̀hún +Olu ilu orile-ede Welsh ni Sala n lo leyin to bowolu iwe adehun ise milionu meeedogun owo pounds pelu iko agbaboolu Bluebirds. Olú ìlú orílẹ̀-èdè Welsh ni Sala ń lọ lẹ́yìn tó bọwọ́lu ìwé àdéhùn iṣẹ́ mílíọ́nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún owó pounds pẹ̀lú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Bluebirds. +--- Petr Cech ti iko Arsenal setan ati feyinti nipari saa yii. --- Petr Cech ti ikọ̀ Arsenal ṣetán àti fẹ̀yìntì nípàrí sáà yìí. +Leyin ogun odun gege bi akosemose, Amule akoko iko agbaboolu Arsenal Petr Cech ti setan lati feyinti ni ipari saa 2018/2019 idije Premier League ile Geesi. Lẹ́yìn ogún ọdún gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, Amùlé àkọ́kọ́ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Arsenal Petr Cech ti ṣetán láti fẹ̀yìntì ní ìparí sáà 2018/2019 ìdíje Premier League ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. +Omo odun merindinlogoji ohun ti o dara po mo iko Arsenal ni osu kefa odun 2015 lati iko agbaboolu Chelsea kede eyi lori ikanni twitter re @petrcech ni ojo isegun. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlògòjì ọ̀hún tí ó dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ Arsenal ní oṣù kẹfà ọdùn 2015 láti ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Chelsea kéde èyí lóri ìkànnì twitter rẹ̀ @petrcech ní ọjọ́ ìṣégun. +“Eyi ni saa ogun mi gege bi akosemose agbaboolu, o si ti pe ogun odun ti mo towo bo iwe adehun mi akoko gege bi akosemose. “Èyí ni sáà ogún mi gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ agbábọ́ọ̀lù, ó sì ti pé ogún ọdún tí mo tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn mi àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. +--- Omeruo- maa nifee lati dara po mo iko agbaboolu CD Leganes fun adehun olojo pipe. --- Omeruo- máa nífẹ̀ẹ́ láti dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù CD Leganes fún àdéhùn ọlọ́jọ́ pípẹ́. +Agbaboolu owo eyin iko Super Eagles, Kenneth Omeruo ti so pe oun yoo gba siso adehun ayalo oun di adehun ojo pipe ninu iko agbaboolu CD Leganes ni towo-tese nitori iko agbaboolu idije La Liga ohun ri bi ile. Agbábọ́ọ̀lù ọwọ́ ẹ̀yìn ikọ̀ Super Eagles, Kenneth Omeruo ti sọ pé òun yóò gba sìsọ àdéhùn àyálò òun di àdéhùn ọjọ́ pípẹ́ nínú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù CD Leganes ní tọwọ́-tẹsẹ́ nítorí ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù ìdíje La Liga ọ̀hún rí bí ilé. +Omeruo wa ninu adehun alayaalo lati inu iko Chelsea di ipari saa yii, o si ti di ara ile ninu iko Leganes ohun ti o se dara gidi gan lati jinna si ifidiremi. Omeruo wà nínú àdéhùn aláyàálò láti inú ikọ̀ Chelsea di ìparí sáà yìí, ó sì ti di ará ilé nínú ikọ̀ Leganes ọ̀hún tí ó ṣe dára gidi gan láti jìnnà sí ìfìdírẹmi. +“Ni bayii, o da bi eni pe mo wa ni ile leyin titi kaakiri pelu orisiirisii adehun alayaalo ki n to de inu iko agbaboolu orile-ede Spain yii.” Agbaboolu owo eyin iko Super Eagles ohun lo so eyi di mimo fun awon oniroyin. “Ní báyìí, o dà bí ẹni pé mo wà ní ilé lẹ́yìn títì káàkiri pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àdéhùn aláyàálò kí n tó dé inú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè Spain yìí.” Agbábọ́ọ̀lù ọwọ́ ẹ̀yìn ikọ̀ Super Eagles ọ̀hún ló sọ èyí di mímọ̀ fún àwọn oníròyìn. +O da bi ala ti o wa si imuse fun mi gege bi a se mo pe idije La Liga je okan lara awon idije ti o tobi julo lagbaaye Ó dá bí àlá tí ó wá sí ìmúṣe fún mi gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé ìdíje La Liga jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìdíje tí ó tóbi jùlọ lágbàáyé +Mi o ni ro o leemeji lati towo bo iwe pelu iko yii, ti oore-ofe re ba yo. Mi ò ní rò ó lẹ́ẹ̀mejì láti tọwọ́ bọ ìwé pẹ̀lú ikọ̀ yìí, tí oore-ọ̀fẹ rẹ̀ bá yọ. +"""Iko agbaboolu ilu Madrid ohun yoo ni lati ya milionu marun-un owo Euros soto lati ra Omeruo omo odun meeedogbon fun adehun olojo pipe." """Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù ìlú Madrid ọ̀hún yóò ní láti ya mílíọ́nù márùn-ún owó Euros sọ́tọ̀ láti ra Omeruo ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n fún àdehùn ọlọ́jọ́ pípẹ́." +--- Ajo NFF yan papa isere Keshi fun ifesewonse Seychelles ati Egypt. --- Àjọ NFF yan pápá ìṣeré Keshi fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Seychelles àti Egypt. +Ajo to n moju to boolu afesegba lorile-ede Naijiiria (NFF) ni igbagbo wa pe won ti yan papa isere Keshi ni ilu Asaba, ipinle Delta lati gbalejo ifesewonse oloreesoree agbaaye laarin iko agbaboolu Super Eagles ati iko agbaboolu Pharaoh ti orile-ede Egypt ti o fi mo ifesewonse ipegede keyin fun idije ife eye ile Adulawo odun 2019 ti won yoo gba pelu orile-ede Seychelles. Àjọ tó ń mójú tó bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá lórílẹ̀-èdè Nàìjííríà (NFF) ni ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n ti yan pápá ìṣeré Keshi ní ìlú Asaba, ìpìnlẹ́ Delta láti gbàlejò ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ àgbááyé láàrin ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles àti ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Pharaoh ti orílẹ̀-èdè Egypt tí ó fi mọ́ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìpegedé kẹyìn fún ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ ọdún 2019 tí wọn yóò gbá pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Seychelles. +Agba oje kan ni Olu ile-ise ajo NFF niluu Abuja so o yanya pe, aayan lati gbalejo awon idije mejeeji ni ilu Asaba ti fe yori nitori pe ijoba ipinle Delta ti gba lati gbe ida aadorin ninu ogorun-un iye owo ti awon ifesewose ohun yoo na won. Àgbà ọ̀jẹ̀ kan ní Olú ilé-iṣẹ́ àjọ NFF nílùú Àbújá sọ ọ́ yanya pé, aáyan láti gbàlejò àwọn ìdíje méjéèjì ní ìlú Àsàbà ti fẹ́ yọrí nítorí pé ìjọba ìpínlẹ̀ Delta ti gbà láti gbé ìdá àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún iye owó tí àwọn ìfẹsẹ̀wọsẹ̀ ọ̀hún yóò ná wọn. +“A ti de abala ikeyin ijiroro wa, gbogbo eto si ti to pelu bi papa isere Asaba yoo se gbalejo awon ifesewonse naa ti gbogbo nnkan yoo si se yemu.” ni o wi. “A ti dé abala ìkẹyìn ìjíròrò wa, gbogbo ètó sì ti tò pẹ̀lú bí pápá ìṣeré Asaba yóò ṣe gbàlejò àwọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà tí gbogbo nǹkan yóò sì ṣe yémú.” ni ó wí. +"""Ifesewonse oloreesoree pelu Egypt yoo ni awon agbaboolu jankanjankan bi i Mohammed Salah ti iko Liverpool, Mohammed El-Shenawy ati Ahmed Hegazi." """Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lụ́ Egypt yóò ní àwọn agbábọ́ọ̀lù jàǹkànjàǹkàn bí i Mohammed Salah ti ikọ̀ Liverpool, Mohammed El-Shenawy àti Ahmed Hegazi." +Isejoba Gomina Ifeanyi Okowa ti je eyi ti o nifee irin-ajo igbafe ere idaraya, bakan naa ni abewo awon agbaboolu jankanjankan idije Premiership ile Geesi naa yoo mu igberu ba oro aje ilu Asaba ati awon ilu agbegbe re ni aarin ipinle naa. Ìsèjọba Gómínà Ifeanyi Okowa ti jẹ́ èyí tí ó nífẹ̀ẹ́ ìrìn-àjò ìgbafẹ́ eré ìdárayá, bákan náà ni àbẹ̀wò àwọn agbábọ́ọ̀lù jàǹkànjàǹkàn ìdíje Premiership ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà yóò mú ìgbèrú bá ọrọ̀ ajé ìlú Asaba àti àwọn ìlú agbègbè rẹ̀ ní àárín ìpínlẹ̀ náà. +--- Orile-ede Egypt ni aayo lati gbalejo idije AFCON ti odun 2019. --- Orílẹ̀-èdè Egypt ni ààyò láti gbàlejò ìdíje AFCON ti ọdún 2019. +Orile-ede Egypt, ile onigun abori sonso ni o seese ki o gbalejo idije ife eye ile Adulawo ti odun 2019, Ajo CAF ti fi lede pe awon orile-ede to ku ni ile naa le seri lo si orile-ede ti ki i fi ere boolu afesegba sere ohun ni odun to n bo. Orílẹ̀-ẹ̀dè Egypt, ilẹ̀ onígun aborí sóńsó ni ó ṣeéṣe kí ó gbàlejò ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ ti ọdún 2019, Àjọ CAF ti fi léde pé àwọn orílẹ̀-èdè tó ku ní ilẹ̀ náà lè sẹ́rí lọ sí orílẹ̀-èdè tí kì í fi eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ṣeré ọ̀hún ní ọdún tó ń bọ̀. +Ni igba keyin ti orile-ede Egypt gbalejo idije ife eye ile Adulawo, iko Super Eagle pari pelu ipo keta; pelu gbigba ami eye baba fun igba keta lera won ninu idije ohun meta ni telentele. Ní ìgbà kẹyìn tí orílẹ̀-èdè Egypt gbàlejò ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀, ikọ̀ Super Eagle parí pẹ̀lú ipò kẹta; pẹ̀lú gbígba àmì ẹ̀yẹ bàbà fún ìgbà kẹta léra wọn nínú ìdíje ọ̀hún mẹ́ta ní tèléǹtẹ̀lé. +Gege bi iroyin se so, Ajo CAF ti setan lati segbe ife orile-ede Egypt lati gbalejo idije AFCON odun 2019. Gẹ́gẹ́ bí ìròyin ṣe sọ, Àjọ CAF ti ṣetán láti sègbè ìfẹ́ orílẹ̀-èdè Egypt láti gbàlejò ìdíje AFCON ọdún 2019. +Aare igbimo to n moju to idije AFCON, Amaju Pinnick se e lalaye pe, awon orile-ede ti agbara won gbe atigbalejo idije naa nikan ni igbimo awon yoo wo se. Ààrẹ ìgbìmọ̀ tó ń mójú tó ìdíje AFCON, Amaju Pinnick ṣe é lálàyé pé, àwọn orílẹ̀-èdè tí agbára wọ́n gbé àtigbàlejò ìdíje náà nìkan ni ìgbìmọ̀ àwọn yóò wò ṣe. +Ajo CAF yoo kede orile-ede ti yoo gbalejo idije AFCON odun 2019 ohun ni ojo kesan-an osu kinni odun. Àjọ CAF yóò kéde orílẹ̀-èdè tí yóò gbàlejò ìdíje AFCON ọdún 2019 ọ̀hún ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kínní ọdún. +--- Mbappe gba ami-eye agbaboolu orile-ede France ti o dara julo. --- Mbappe gba àmì-ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè France tí ó dára jùlọ. +Agbaboolu owo iwaju iko Paris Saint-Germain, Kylian Mbappe ti gba ami-eye agbaboolu orile-ede France ti o dara julo fun igba akoko Agbábọ́ọ̀lù ọwọ́ iwájú ikọ̀ Paris Saint-Germain, Kylian Mbappe ti gba àmì-ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè France tí ó dára jùlọ fún ìgbà àkọ́kọ́ +Omo ogun odun ohun ti o kopa ribiribi fun orile-ede France lati gba ife-eye idije agbaaye lorile-ede Russia ni saa to koja gbadun meriiri odun 2018 yii. Ọmọ ogún ọdún ọ̀hún tí ó kópa ribiribi fún orílẹ̀-èdè France láti gba ife-ẹ̀yẹ ìdíje àgbàáyé lórílẹ̀-èdè Russia ní sáà tó kọjá gbádun mérìírí ọdun 2018 yìí. +Mbappe ran iko Les Bleus ohun lowo lati we yan kanhinkanhin pelu akitiyan adasise kara ti o fi ri awon he ninu ijawe olubori asekagba ami ayo merin si meji pelu iko Croatia. Mbappe ran ikọ̀ Les Bleus ọ̀hún lọ́wọ́ láti wẹ̀ yán kànhìnkànhìn pẹ̀lú àkitiyan àdáṣiṣẹ́ kára tí ó fi rí àwọ̀n he nínú ìjáwé olúborí àṣekágbá àmi ayò mẹ́rin sí méjì pẹ̀lú ikọ̀ Croatia. +Mbappe ti gba boolu merindinlogun sawon ninu ifesewonse mokandinlogun ti o ti gba fun iko agbaboolu PSG ni saa yii, pelu bi iko naa tun se n tesiwaju lati maa lepa ife eye nile ati leyin odi. Mbappe ti gbá bọ́ọ̀lù mẹ́rìndínlógún sáwọ̀n nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mọ́kàndínlógún tí ó ti gbá fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù PSG ní sáà yìí, pẹ̀lú bí ikọ̀ náà tún ṣe ń tẹ̀síwájú láti máa lépa ife ẹ̀yẹ nílé àti lẹ́yìn odi. +O pari pelu ipo kerin ninu abajade idibo ami eye agbaboolu ti o dara julo lagbaaye lodun 2018, pelu ipo giga yii gege bi omo kekere, eyi gbe e saaju Lionel Messi Agbaboolu ti o ti gba ami eye ohun leemarun-un otooto. Ó parí pẹ̀lú ipò kẹrin nínú àbájáde ìdìbò àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tí ó dára jùlọ lágbàáyé lọ́dún 2018, pẹ̀lú ipò gíga yìí gẹ́gẹ́ bí ọmọ kékeré, èyí gbé e ṣaájú Lionel Messi Agbábọ́ọ̀lù tí ó ti gba àmì ẹyẹ ọ̀hún lẹ́ẹ̀marùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. +Mbappe je fifun ni apata yii lati owo Ajo Ere Boolu ile France, leyin ti o ta Raphael Varane ati Antoine Griezmann yo. Mbappe jẹ́ fífún ní apata yìí láti ọ̀wọ́ Àjọ Eré Bọ́ọ̀lù ilẹ̀ France, lẹ́yìn tí ó ta Raphael Varane àti Antoine Griezmann yọ. +O jogun ami eye yii lowo agbaboolu owo aarin iko Chelsea, NGolo Kante, ti o moke julo lodun 2017. Ó jogún àmì ẹ̀yẹ yìí lọ́wọ́ agbábọ́ọ̀lù ọwọ́ àárín ikọ̀ Chelsea, NGolo Kante, tí ó mókè jùlọ lọ́dún 2017. +---Atamatase Omo Aare Weah yoo dara po mo iko agbaboolu Celtic pelu ayalo. ---Atamátàsé Ọmọ Ààrẹ Weah yóò dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Celtic pẹ̀lú àyálò. +Timothy Weah yoo kuro ninu iko asaaju idije boolu ile Faranse nni Paris St Germain (PSG), lati dara po mo Celtic iko agbaboolu ile Scotland. Timothy Weah yóò kúrò nínú ikọ̀ aṣáájú ìdíje bọ́ọ̀lù ilẹ̀ Faransé nnì Paris St Germain (PSG), láti dara pọ̀ mọ́ Celtic ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Scotland. +Weah so o di mimo lojo isegun (Tuesday). Weah sọ ọ́ di mímọ̀ lọ́jọ́ ìṣẹ́gun (Tuesday). +Gege ile-ise iroyin ile Biritiko se so, omo odun mejidinlogun ohun ti setan lati dara po mo iko asaaju idije boolu ile Scotland iyen Celtic. Gẹ́gẹ́ ilé-iṣẹ́ ìròyìn ilẹ̀ Bìrìtìkó ṣe sọ, ọmọ ọdún méjìdínlógún ọ̀hún ti ṣetán láti dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ aṣáájú ìdíje bọ́ọ̀lù ilẹ̀ Scotland ìyẹn Celtic. +Weah ti kopa fun iko agbaboolu PSG nigba meta pere ni saa yii, latari awon oloruko sanko bii Neymar, Kylian Mbappe ati Edinson Cavani ti o din oore-ofe atiwo iko akoko re ku. Weah ti kópa fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù PSG nígbà mẹ́ta pére ní sáà yìí, látàrí àwọn olórúkọ sàǹkò bíi Neymar, Kylian Mbappe àti Edinson Cavani tí ó dín oore-ọ̀fẹ́ àtiwọ ikọ̀ àkọ́kọ́ rẹ̀ kù. +Ninu atejise ti a ko lede Faranse lori ikanni Instagram re, Weah dupe lowo awon akeegbe re ninu iko PSG, awon akonimoogba ati awon ololufe iko naa fun anfaani ti won fun un lati je okan lara ebi naa. Nínú àtẹ̀jíṣẹ́ tí a kọ lédè Faransé lórí ìkànnì Instagram rẹ̀, Weah dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn àkẹẹgbẹ́ rẹ̀ nínú ikọ̀ PSG, àwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá àti àwọn olólùfé ikọ̀ náà fún àǹfààní tí wọ́n fún un láti jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀bí náà. +Weah je omobibi inu agbaboolu teleri fun orile-ede Liberia, iko agbaboolu PSG ati AC Milan, George Weah, ti o je Aare orile-ede Liberia bayii. Weah jẹ́ ọmọbíbí inú agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀rí fún orílẹ̀-èdè Liberia, ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù PSG àti AC Milan, George Weah, tí ó jẹ́ Ààrẹ̀ orílẹ̀-èdè Liberia báyìí. +--- Eyi ni atupale awon ifesewonse idije EPL ti o waye lopin ose. --- Èyí ni àtúpalẹ̀ àwọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìdíje EPL tí ó wáyé lópin ọ̀sẹ̀. +Iko agbaboolu Crytsal Palace fagba han Manchester City pelu ami ayo meta si meji ninu ifesewonse idije premier league ile Geesi ti o waye lopin ose. Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Crytsal Palace fàgbà han Manchester City pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sí méjì nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìdíje premier league ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí ó wáyé lópin ọ̀sẹ̀. +Bakan naa, iko agbaboolu Leicester City feyin Chelsea bele pelu ami ayo kan si odo. Bákan náà, ikọ̀ agbábọ̀ọ̀lu Leicester City fẹ̀yìn Chelsea bẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àmì ayò kan sí òdo. +Ninu inu awon ifesewonse akoko ti o waye saaju lojo abameta, iko agbaboolu Arsenal fagba han Burnley pelu ami ayo meta sookan Nínú inú àwọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó wáyé ṣaájú lọ́jọ́ àbámẹ́tà, ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Arsenal fàgbà han Burnley pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sóókan +Iko agbaboolu Southampton fagba han Huddersfield pelu ami ayo meta sookan ope pataki lowo ami ayo ti Michael Obafemi gba sawon. Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Southampton fàgbà han Huddersfield pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sóókan ọpẹ́ pàtàkì lọ́wọ́ àmì ayò tí Michael Ọbáfẹ́mi gbá sáwọ̀n. +Bakan naa Watford lu West Ham pelu ami ayo meji si odo Bournemouth na Brighton pelu ami ayo meji si odo Bákan náà Watford lu West Ham pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo Bournemouth na Brighton pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo +--- ATE AJO FIFA: Iko Super Eagles pari odun 2018 sipo kerinlelogoji. --- ÀTẸ ÀJỌ FIFA: Ikọ̀ Super Eagles parí ọdún 2018 sípò kẹrìnlélógójì. +Iko agbaboolu Super Eagles pari odun 2018 pelu didi ipo kerinlelogoji won mu sibe ninu ate ajo FIFA tuntun ti won gbe jade lojobo (Thursday). Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles parí ọdún 2018 pẹ̀lú dídi ipò kẹrìnlélógójì wọn mú síbẹ̀ nínú àtẹ àjọ FIFA tuntun tí wọ́n gbé jáde lọ́jọ́bọ (Thursday). +Iko agbaboolu yii ti o ti gba ife eye ile Adulawo leemeta otooto tun di ipo kerin won mu ni ile Adulawo sibe. Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù yìí tí ó ti gba ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ lẹ́ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀òtọ̀ tún di ipò kẹrin wọn mú ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ síbẹ̀. +Iko agbaboolu orile-ede Senegal dipo kinni won mu sibe pelu bi iko orile-ede Tunisia, Morocco, Naijiria ati DR Congo se paju iko marun-un akoko ni ile naa de. Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè Senegal dipò kínní wọn mú síbẹ̀ pẹ̀lú bí ikọ̀ orílẹ̀-èdè Tunisia, Morocco, Nàìjíríà àti DR Congo ṣe pajú ikọ̀ márùn-ún àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ náà dé. +Belgium ni o di ipo kinni mu sibe, France ipo keji sibe, Brazil ipo keta sibe Crotia wa ni ipo kerin, nigba ti England wa ni ipo karun-un lagbaaye. Belgium ni ó di ipò kínní mú síbẹ̀, France ipò kejì síbẹ̀, Brazil ipò kẹta síbẹ̀ Crotia wà ní ipo kẹrin, nígbà tí England wà ní ipò karùn-ún lágbàáyé. +Ipo ate ajo FIFA/Coca-Cola miiran yoo tun jade lojo keje, osu keji, odun 2019. Ipò àtẹ àjọ FIFA/Coca-Cola mìíràn yóò tún jáde lọ́jọ́ keje, oṣù kejì, ọdún 2019. +--- Mourinho ki mi kaabo pada sinu idije Premier League - Ranieri --- Mourinho kí mi káàbọ̀ padà sínú ìdíje Premier League - Ranieri +Claudio Ranieri so lojobo (Thursday) pe Jose Mourinho ni akonimoogba akoko ti o ki oun kaabo pada sinu idije Premier League nigba ti won yan oun gege bi akonimoogba iko Fulham losu to koja. Claudio Ranieri sọ lọ́jọ́bọ (Thursday) pé Jose Mourinho ni akọ́nimọ̀ọ́gbá àkọ́kọ́ tí ó kí òun káàbọ̀ padà sínú ìdíje Premier League nígbà tí wọ́n yan òun gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Fulham lóṣù tó kọjá. +Iko Fulham yoo teko leti lo si papa isere Old Trafford ni ojo Abameta (Saturday), nibi ti ireti wa pe iko Manchester United yoo ti jawe olubori ninu idije Premier League fun igba akoko ninu ifesewonse marun-un otooto, eyi ti yoo tun gbe awon akonimoogba mejeeji pade ara won lati igba ti Ranieri ti fi iko Leicester sile. Ikọ̀ Fulham yóò tẹkọ̀ létí lọ sí pápá ìṣeré Old Trafford ní ọjọ́ Àbámẹ́ta (Saturday), níbi tí ìrètí wà pé ikọ̀ Manchester United yóò ti jáwé olúborí nínú ìdíje Premier League fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìfẹsẹ̀wọnṣẹ̀ márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, èyí tí yóò tún gbé àwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá méjéèjì pàdé ara wọn láti ìgbà tí Ranieri ti fi ikọ̀ Leicester sílẹ̀. +Amo sa, akonimoogba iko Fulham ti so pe “Oun ni eni akoko to koko fi atejise ranse simi lati so pe ‘kaabo pada’ Àmọ́ ṣá, akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Fulham ti sọ pé “Òun ni ẹni àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sími láti sọ pé ‘káàbọ̀ padà’ +Ore mi daadaa lo je. Ọ̀rẹ́ mi dạ́adáa ló jẹ́. +Mo ti mo on lati ojo to ti pe, lati igba ti o wa sinu iko Chelsea lati orile-ede Italy, o n se daradara simi. Mo ti mọ̀ ọ́n láti ọjọ́ tó ti pẹ́, láti ìgbà tí ó wá sínú ikọ̀ Chelsea láti orílẹ̀-èdè Italy, o ń ṣe dáradára sími. +Akinkanju okunrin, akonimoogba ati Alakooso ni o je. Akínkanjú ọkùnrin, akọ́nimọ̀ọ́gbá àti Alákòóso ni ó jẹ́. +Iko agbaboolu Fulham ti o wa ni isale tabili kopa ti o wuni lori ninu omi ami ayo kookan pelu iko agbaboolu Leicester lojoruu (Wednesday), eyi fun Ranieri eni odun metadinlaaadorin ni ijawe olubori kan, omi kan ati ipadanu kan pelu ifesewonse meta ti o ti tuko. Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Fulham tí ó wà ní ìsàlẹ̀ tábìlì kópa tí ó wúni lórí nínú ọ̀mì àmì ayò kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Leicester lọ́jọ́rùú (Wednesday), èyí fún Ranieri ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin ní ìjáwé olúborí kan, ọ̀mì kan àti ìpàdánù kan pẹ̀lú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mẹ́ta tí ó ti tukọ̀. +--- Ile-ise Aare, Ajo NFF lo pade iko Super Falcons ni ilu Abuja. --- Ilé-iṣẹ́ Ààrẹ, Àjọ NFF lọ pàdé ikọ̀ Super Falcons ní ìlú Àbújá. +Olori osise Oba si Aare Alhaji Abba Kyari, lewaju igbimo awon eniyan jankan-jankan ati awon oga agba ninu ajo to n moju to boolu afesegba lorile-ede Naijiiria (NFF) ti o lo pade iko Super Falcons bi won se de si ilu Abuja nirole ojo Aiku (Sunday). Olórí òṣìṣẹ́ Ọba sí Ààrẹ Alhaji Abba Kyari, léwájú ìgbìmọ̀ àwọn ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn àti àwọn ọ̀gá àgbà nínú àjọ tó ń mójú tó bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá lórílẹ̀-èdè Nàìjííríà (NFF) tí ó lọ pàdé ikọ̀ Super Falcons bí wọ́n ṣe dé sí ìlú Àbújá nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Àìkù (Sunday). +Iko agbaboolu Super Falcons ti o ti gba ife eye awon Obinrin ile Adulawo ni eemesan-an otooto bale si papako ofurufu agbaaye Nnamdi Azikiwe ni aago merin ku iseju die. Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Falcons tí ó ti gba ife ẹ̀yẹ àwọn Obìnrin ilẹ̀ Adúláwọ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹsàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ balẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú àgbááyé Nnamdi Azikiwe ní aago mẹ́rin ku ìṣẹ́jú díẹ̀. +Lara awon omo egbe iko Super Falcons ti o wo ilu Abuja ni akowe apapo ajo NFF, Dokita Mohammed Sanusi, ti o fi mo awon osise ajo NFF miiran. Lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ikọ̀ Super Falcons tí ó wọ ìlú Àbújá ni akọ̀wé àpapọ̀ àjọ NFF, Dókítà Mohammed Sanusi, tí ó fi mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ àjọ NFF mìíràn. +Ni ojo Abameta (Saturday), ni papa isere Accra, iko agbaboolu Falcons gbo ewuro si iko Banyana Banyana ti orile-ede South Africa loju pelu ami ayo merin si meta ninu goli-wo-mi-n-gba-a-si-o leyin ogofa iseju lairawon he lati gba ife eye awon Obinrin ti o tobi ju nile Adulawo yii ni igba meta le ara won ti o si fi pe mesan-an ni apapo. Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta (Saturday), ní pápá ìṣeré Accra, ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Falcons gbo ewúro sí ikọ̀ Banyana Banyana ti orílẹ̀-èdè South Africa lójú pẹ̀lú àmì ayò mẹ́rin sí mẹ́ta nínú golí-wò-mi-n-gbá-a-sí-ọ lẹ́yìn ọgọ́fà ìṣẹ́jú láìráwọ̀n he láti gba ife ẹ̀yẹ àwọn Obìnrin tí ó tóbi jù nilẹ̀ Adúláwọ̀ yìí ní ìgbà mẹ́ta lé ara wọn tí ó sì fi pé mẹ́sàn-án ní àpapọ̀. +Ni oruko Aare, eni ti ko si niluu lowolowo bayii, a ki gbogbo yin kaabo pada, e si tun ku ise. Ní orúkọ Ààrẹ, ẹni tí kò sí nílùú lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, a kí gbogbo yín káàbọ̀ padà, ẹ sì tún kú iṣẹ́. +Koda, bi a se n kuro ni papako ofurufu, awon omo orile-ede Naijiiria jankan meji otooto pe won fun setore aadota millionu naira (N50m) ati milionu marundinlogbon naira (N25m) fun iko yii. Kódà, bí a ṣe ń kúrò ní pápákọ̀ ofurufú, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà jàǹkàn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pè wọ́n fún ṣètọrẹ àádọ́ta míllíọ́nù náírà (N50m) àti mílíọ́nù márùndínlọ́gbọ̀n náírà (N25m) fún ikọ̀ yìí. +E jowo, e sinmi daradara. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ sinmi dáradára. +A o kan si yin lori awon eto ti a ti la kale fun yin laipe A ó kàn si yín lórí àwọn ẹ̀tọ́ tí a ti là kalẹ̀ fun yín láìpẹ́ +Akowe apapo ajo NFF, Mohammed Sanusi so bayii pe, “Ni oruko awon adari ajo NFF, a mo riri atileyin lati odo ijoba ile Naijiiria, eyi ti o ran iko yii lowo lati saseyori ninu idije ife eye naa. Akọ̀wé àpapọ̀ àjọ NFF, Mohammed Sanusi sọ báyìí pé, “Ní orúkọ àwọn adarí àjọ NFF, a mọ rírì àtìlẹyìn láti ọ̀dọ̀ ìjọba ilẹ̀ Nàìjííríà, èyí tí ó ran ikọ̀ yìí lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí nínú ìdíje ifẹ ẹ̀yẹ náà. +Awon omobinrin yii ti wa seleri sisa gbogbo ipa won lati soju orile-ede naa daradara ninu idije ife eye agbaaye odun 2019. Àwọn ọmọbìnrin yìí ti wá ṣèlérí sísa gbogbo ipá wọn láti sojú orílẹ̀-èdè náà dáradára nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbááyé ọdún 2019. +--- Berhalter ti di kikede gege bi akonimoogba iko agbaboolu awon okunrin orile-ede US. --- Berhalter ti di kíkéde gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù àwọn ọkùnrin orílẹ̀-èdè US. +Akonimoogba iko Columbus Crew teleri Gregg Berhalter ni won ti kede gege bi akonimoogba tise kan fun iko agbaboolu awon okunrin orile-ede US ni ojo aiku (Sunday) Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Columbus Crew tẹ́lẹ̀rí Gregg Berhalter ni wọ́n ti kéde gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá tíṣé kan fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù àwọn ọkùnrin orílẹ̀-èdè US ní ọjọ́ àìkú (Sunday) +Berhalter eni odun marundinlaaadota ropo akonimoogba fidihee Dave Sarachan lati di eni ti o kere ju ti yoo tu iko naa lati akoko Steve Sampson lodun 1995. Berhalter ẹni ọdún márùndínláàádọ́ta rọ́pò akọ́nimọ̀ọ́gbá fìdíhẹ̀ẹ́ Dave Sarachan láti di ẹni tí ó kẹ́rẹ́ jù tí yóò tu ikọ̀ náà láti àkókò Steve Sampson lọ́dun 1995. +“Inu wa dun lopolopo lati yan Gregg gege bi gege bi akonimoogba iko agbaboolu awon okunrin orile-ede US” ninu oro Aare igbimo Ere Boolu ile naa Carlos Cordeiro. “Inú wa dùn lọ́pọ̀lọpọ̀ láti yàn Gregg gẹ́gẹ́ bí gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù àwọn ọkùnrin orílẹ̀-èdè US” nínú ọ̀rọ̀ Ààrẹ ìgbìmọ̀ Eré Bọ́òlù ilẹ̀ náà Carlos Cordeiro. +Gege bi agbaboolu iko teleri ti o ni opolopo iriri, ati ojimi akosemose akonimoogba, o da wa loju pe oun ni eni ti o to lati te wa siwaju. Gẹ́gẹ́ bí agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ tẹ́lẹ̀rí tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí, àti òjìmì akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá, ó dá wa lójú pé òun ni ẹni tí ó tọ́ láti tẹ̀ wá síwájú. +A n fojusona lati safihan re lojo isegun (Tuesday) niluu New York. À ń fojúsọ́nà láti ṣafihàn rẹ̀ lọ́jọ́ ìṣẹ́gun (Tuesday) nílùú New York. +Berhalter yoo di fifihan ninu ipade awon oniroyin kan ni agogo mejila osan ojo isegun (Tuesday) Berhalter yóò di fífihàn nínú ìpàdé àwọn oníròyìn kan ní agogo mẹ́jìlá ọ̀sán ọjọ́ ìṣẹ́gun (Tuesday) +Agbaboolu iko yii teleri, Berhalter wa ninu alakale iko naa fun ife eye agbaaye odun 2002 ati odun 2006. Agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ yìí tẹ́lẹ̀rí, Berhalter wà nínú àlakalẹ̀ ikọ̀ náà fún ife ẹ̀yẹ àgbááyé ọdún 2002 àti ọdún 2006. +--- Aare Buhari ki iko Super Falcons ku oriire gbigba ife eye ile Adulawo. --- Ààrẹ Buhari kí ikọ̀ Super Falcons kú oríire gbígba ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀. +Aare Muhammadu Buhari lale ana ki iko agbaboolu Super Falcons ti orile-ede Naijiiria ku oriire jijawe olubori pelu iko Banyana Banyana ile South Africa lojo abameta (Saturday) ninu asekagba idije boolu afesegba awon obinrin nile Afirika (AWCON) eekokanla iru re Ghana 2018. Ààrẹ Muhammadu Buhari lálẹ́ àna kí ikọ̀ agbábọ́ọ̀l�� Super Falcons ti orílẹ̀-èdè Nàìjííríà kú oríire jíjáwé olúborí pẹ̀lú ikọ̀ Banyana Banyana ilẹ̀ South Africa lọ́jọ́ àbámẹ́ta (Saturday) nínú àṣekágbá ìdíje bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá àwọn obìnrin nílẹ̀ Áfíríkà (AWCON) ẹ̀ẹ̀kọkànlá irú rẹ̀ Ghana 2018. +Aare fi idunnu re han pupo latari ise ifomoluabise ati ifarajin iko agbaboolu awon agba obinrin pelu bi akeegbe won lati orile-ede South Africa se gbona gidigidi. Ààrẹ fi ìdùnnú rẹ̀ hàn púpọ̀ látàrí iṣẹ́ ìfọmọlúàbíṣe àti ìfarajìn ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù àwọn àgbà obìnrin pẹ̀lú bí akẹẹgbẹ́ wọn láti orílẹ̀-èdè South Africa ṣe gbóná gidigidi. +O tenu mo o pe iko Super Falcons ti koko pegede lati soju orile-ede Naijiiria ninu idije Ife eye agbaaye awon Obinrin ti yoo waye ni orile-ede France ni odun to n bo, Aare sapejuwe ijawe olubori idije AWCON yii fun igba keta lera won ti o si fi pe mesan-an ni apapo gege bi “oyin inu akara naa” O tẹnu mọ́ ọ pé ikọ̀ Super Falcons ti kọ́kọ́ pegedé láti ṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjííríà nínú ìdíje Ife ẹ̀yẹ àgbááyé àwọn Obìnrin tí yóò wáyé ní orílẹ̀-èdè France ní ọdún tó ń bọ̀, Ààrẹ ṣàpèjúwe ìjáwé olúborí ìdíje AWCON yìí fún ìgbà kẹta léra wọn tí ó sì fi pé mẹ́sàn-án ní àpapọ̀ gẹ́gẹ́ bí “oyin inú àkàrà náà” +Nigba ti o n gboriyin fun iko obinrin orile-ede yii fun sisee mu yangan ati ijegaba lori ile Adulawo, o ro won lati lo sinu idije France 2019 pelu afojusun nla ati ipinnu lati yege ni ipele agbaaye. Nígbà tí ó ń gbóríyìn fún ikọ̀ obìnrin orílẹ̀-èdè yìí fún ṣíṣeé mú yangàn àti ìjẹgàba lórí ilẹ̀ Adúláwọ̀, ó rọ̀ wọ́n láti lọ sínú ìdíje France 2019 pẹ̀lú àfojúsùn ńlá àti ìpinnu láti yege ní ìpele àgbááyé. +Aare Buhari tun gboriyin fun awon iko akonimoogba, ajo to n moju to boolu afesegba lorile-ede Naijiiria (NFF), awon alatileyin ati gbogbo awon omo ilu ti won je ololufe ere boolu afesegba fun igbaradi to moyanlori ati atileyin won fun awon agbaboolu, o ro awon alenuloro lati mase wararo lori igbiyanju lati ri i pe awon iko ti o soju orile-ede naa ninu ere boolu afesegba n tesiwaju. Ewe, aare tun gbosuba kare fun awon akonimoogba won gbogbo, ajo NFF ati awon ololufe jakejado lagbaaye ku ise ribiribi eleyii ti o fara han ninu bi won se kopa si. Ààrẹ Bùhárí tún gbóríyìn fún àwọn ikọ̀ akọ́nimọ̀ọ́gbá, àjọ tó ń mójú tó bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá lórílẹ̀-èdè Nàìjííríà (NFF), àwọn alátìlẹyìn àti gbogbo àwọn ọmọ ìlú tí wọ́n jẹ́ olólùfẹ́ eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá fún ìgbáradì tó mọ́yánlórí àti àtìlẹyìn wọn fún àwọn agbábọ́ọ̀lù, ó rọ àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ láti máse wararo lórí ìgbìyànjú láti rí i pé àwọn ikọ̀ tí ó sojú orílẹ̀-èdè náà nínú eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ń tẹ̀síwájú. Ẹ̀wẹ̀, ààrẹ tún gbóṣùbà káre fún àwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn gbogbo, àjọ NFF àti àwọn olólùfẹ́ jákèjádò lágbàáyé kú iṣẹ́ ribiribi eléyìí ti ́ó fara hàn nínú bí wọ́n ṣe kópa sí. +“Emi ki i se iyemeji lori iyege awon omo orile-ede Naijiiria ti a ba fun won ni atileyin to ye” eyi ni o tenu mo nigba ti o n seleri ifarajin ijoba apapo fun idagbasoke ere idaraya gege bi ohun elo isokan. “Èmi kì í ṣe iyèméjí lórí ìyege àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà tí a bá fún wọn ní àtìlẹyìn tó yẹ” èyí ni ó tẹnu mọ́ nígbà tí ó ń ṣèlérí ìfarajìn ìjọba àpapọ̀ fún ìdàgbàsókè eré ìdárayá gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ìṣọ̀kan. +--- Rohr salaye ohun ti o n dun un ninu nipa owo iwaju iko Super Eagles. --- Rohr ṣàlàyé ohun tí ó ń dùn ún nínú nípa ọwọ́ iwájú ikọ̀ Super Eagles. +Bi orile-ede Naijiiria se n gbaradi fun awon ojuse won lodun to n bo leyin ti won ti pegede fun ife eye ile Adulawo ti odun 2019, Akonimoogba iko agba orile-ede Naijiiria Gernot ti fi idunnu re han lori awon agbaboolu ti o wa nile fun un lati gba owo iwaju. Bí orílẹ̀-èdè Nàìjííríà ṣe ń gbáradì fún àwọn ojúṣe wọn lọ́dún tó ń bọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti pegedé fún ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ ti ọdún 2019, Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ àgbà orílẹ̀-èdè Nàìjííríà Gernot ti fi ìdùnnú rẹ̀ hàn lórí àwọn agbábọ́ọ̀lù tí ó wà nílẹ̀ fún un láti gbá ọwọ́ iwájú. +Leyin omi ami ayo kookan pelu iko South Africa, iko Naijiiria yoo beere igbaradi fun idije AFCON to n bo ni inu osu keta nigba ti won yoo ma waako pelu iko Seychelles, ogangan pataki ninu iko ohun ti ko ko akonimoogba yii lominu ni awon agbaboolu ti o wa nile fun un lati gba owo iwaju. Lẹ́yìn ọ̀mì àmì ayò kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ikọ̀ South Africa, ikọ̀ Nàìjííríà yóò bẹẹrẹ ìgbáradì fún ìdíje AFCON tó ń bọ̀ ní inú oṣù kẹta nígbà tí wọn yóò ma wàákò pẹ̀lú ikọ̀ Seychelles, ọgangan pàtàkì nínú ikọ̀ ọ̀hún tí kò kọ akọ́nimọ̀ọ́gbá yìí lóminú ni àwọn agbábọ́ọ̀lù tí ó wà nílẹ̀ fún un láti gbá ọwọ́ iwájú. +Rohr tun tun un so pe Iko Naijiiria ni awon agbaboolu ti yoo mu ki iko naa o ta sansan ni owo iwaju. Rohr tún tún un sọ pé Ikọ̀ Nàìjííríà ní àwọn agbábọ́ọ̀lù tí yóò mú kí ikọ̀ náà ó ta sánsán ní ọwọ́ iwájú. +“A ni awon agbaboolu ayarabi asa legbee. Awon omokunrin tuntun wonyi n se daadaa. E ni Kalu, Simon Chukwueze, Victor Osimhen ati Collins to ri awon he ni ojo aiku (Sunday). Mo feran ifagagbaga naa. Bi apeere, Kalu le di eyin mu, o si le gba owo iwaju leyii ti o je oriire fun iko naa” ni akonimoogba ohun wi. “A ní àwọn agbábọ́ọ̀lù ayárabí àṣá lẹ́gbẹ̀ẹ́. Àwọn ọmọkùnrin tuntun wònyí ń ṣe dáadáa. Ẹ ní Kálu, Simon Chukwueze, Victor Osimhen àti Collins tó rí àwọn he ní ọjọ́ àìkú (Sunday). Mo fẹ́ràn ifagagbága náà. Bí àpẹẹrẹ, Kálu lè di ẹ̀yìn mú, ó sì le gbá ọwọ́ iwájú léyìí tí ó jẹ́ oríire fún ikọ̀ náà” ni akọ́nimọ̀ọ́gbá ọ̀hún wí. +--- Pinnick gboriyin fun ile ifowopamo Zenith fun ipegede AFCON odun 2019 --- Pinnick gbóríyìn fún ilé ìfowópamọ́ Zenith fún ìpegedé AFCON ọdún 2019 +Aare ajo NFF, Ogbeni Amaju Pinnick ti gboriyin fun ile ifowopamo Zenith fun ipegede si idije ife eye ile Adulawo (AFCON) odun 2019 to yoo waye ni orile-ede Cameroon Ààrẹ àjọ NFF, Ọ̀gbẹ́ni Amaju Pinnick ti gbóríyìn fún ilé ìfowópamọ́ Zenith fún ìpegedé sí ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ (AFCON) ọdún 2019 tó yóò wáyé ní orílẹ̀-èdè Cameroon +Lasiko ti o n se ififunni aso igbaboolu iko Super Eagle ti a ti bowo lu fun Oludari/Oga agba ile ifowopamo Zenith, iyen Ogbeni. Peter Amangbo gege bi idupe lati odo gbogbo awon agbaboolu fun atileyin ile ifowopamo naa lori ipegede won fun idije AFCON odun 2019, Pinnick dupe lowo ile ifowopamo naa fun atileyin gbogbo igba won lori idagbasoke ere boolu ati ere idaraya lapapo ni orile-ede naa. Lásìkò tí ó ń ṣe ìfifúnni aṣọ ìgbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Super Eagle tí a ti bọwó lù fún Olùdarí/Ọ̀gá àgbà ilé ìfowópamọ́ Zenith, ìyẹn Ọ̀gbẹ́ni. Peter Amangbo gẹ́gẹ́ bi ìdúpé láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn agbábọ́ọ̀lù fún àtìlẹyìn ilé ìfowópamọ́ náà lórí ìpegedé wọn fún ìdíje AFCON ọdún 2019, Pinnick dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé ìfowópamọ́ náà fún àtilẹ́yìn gbogbo ìgbà wọn lórí ìdàgbàsókè eré bọ́ọ̀lù àti eré ìdárayá lápapọ̀ ní orílẹ̀-èdè náà. +O tenu mo on pe oto ni ohun ti a o ba maa so bi ki i ba se iranlowo ati atileyin ile ifowopamo naa, ti o je pe laisi tabi sugbon o se pataki si ipegede iko agbaboolu Super Eagle fun idije AFCON odun 2019 lenu looloo yii. Ó tẹnu mọ́ ọn pé ọ̀tọ̀ ni ohun tí a ò bá máa sọ bí kì í bá ṣe ìrànlọ́wọ́ àti àtìlẹyìn ilé ìfowópamọ́ náà, tí ó jẹ́ pé láìsí tàbí ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì sí ìpegedé ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Eagle fún ìdíje AFCON ọdún 2019 lẹ́nu lọ́ọ́lóọ́ yìí. +Nigba ti o n fesi, Amangbo tun fi aridaju ifarajin ile ifowopamo naa mule lori atileyin fun gbogbo iko agbaboolu orile-ede, o si tun se ileri lati mu awon ileri tire se lojuna atimu ki awon iko agbaboolu ile Naijiiria o se e mu yangan lagbaaye. Nígbà tí ó ń fèsì, Amangbo tún fi àrídájú ìfarajìn ilé ìfowópamọ́ náà múlẹ̀ lórí àtìlẹyìn fún gbogbo ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè, ó sì tún ṣe ìlérí láti mú àwọn ìlérí tirẹ̀ ṣe lójúnà àtimú kí àwọn ikọ̀ agbábóọ̀lù ilẹ̀ Nàìjííríà ó ṣe é mú yangàn lágbàáyé. +--- Iko Super Falcons pegede si asekagba idije AWCON --- Ikọ̀ Super Falcons pegedé sí àṣekágbá ìdíje AWCON +Iko Super Falcons orile-ede Naijiiria ti pegede si asekagba idije ife eye awon obinrin ti o n lo lowo ni orile.-ede Ghana. Ikọ̀ Super Falcons orílẹ̀-èdè Nàìjííríà ti pegedé sí àṣekágbá ìdíje ife ẹ̀yẹ àwọn obìnrin tí ó ń lọ lọ́wọ́ ní orílè.-èdè Ghana. +Iko Super Falcons fagba han iko Cameroon pelu ami ayo merin si meji ninu Goli-wo-mi-n-gba-a-si-o leyin ogofa iseju ifigagbaga. Ikọ̀ Super Falcons fàgbà han ikọ̀ Cameroon pẹ̀lú àmì ayò mẹ́rin sí méjì nínú Golí-wò-mí-n-gbá-a-sí-ọ lẹ́yìn ọgọ́fà ìṣẹ́jú ìfigagbága. +Pelu esi yii, orile-ede Naijiiria ti pegede si asekagba idije AWCON odun 2019. Pẹ̀lú èsì yìí, orílẹ̀-èdè Nàìjííríà ti pegedé sí àṣekágbá ìdíje AWCON ọdún 2019. +--- Didier Drogba feyinti ninu ere boolu afesegba --- Didier Drogba fẹ̀yìntì nínú eré bọ́ọ̀lù ��fẹsẹ̀gbá +Agbaboolu owo iwaju iko Chelsea ati Ivory Coast tele ri Didier Drogba ti kede ifeyinti re gege bi agbaboolu. Agbábọ́ọ̀lù ọwọ́ iwájú ikọ̀ Chelsea àti Ivory Coast tẹ́lẹ̀ rí Didier Drogba ti kéde ìfẹ̀yìnti rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbábóọ̀lù. +Omo ogoji odun ohun gba ami-ayo merinlelogojo sawon ninu ifesewonse orinlelooodunrunlekan fun isi eemeji otooto ti o fi kopa fun iko agbaboolu Chelsea, eyi ti o ran won lowo lati gba Ife eye Premier League ile Geesi leemerin ati ife eye Champions League ni odun 2012, ti o fi mo ife eye FA ati ife Liigi meta. Ọmọ ogójì odun ọ̀hụ́n gbá àmì-ayò mẹ́rìnlẹ́lọ́gọ́jọ sáwọ̀n nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọ̀rìnlélọ́ọ̀ọ́dúnrúnlékan fún ìṣí ẹ̀ẹ̀méji ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó fi kópa fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Chelsea, èyí tí ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gba Ife ẹ̀yẹ Premier League ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lẹ́ẹ̀mẹrin àti ife ẹ̀yẹ Champions League ní ọdún 2012, tí ó fi mọ́ ife ẹ̀yẹ FA àti ife Líìgì mẹ́ta. +Drogba ti n gba boolu ni saa yii ni orile-ede United States pelu iko Phoenix Rising, iko onipele keji ti oun pelu wa lara awon ti o ni i. Ogbohuntarigi agbaboolu owo iwaju yii ni won ti lero pe yoo feyinti leyin ipadanu asekagba ife eye Liigi United Soccer sowo Louisville City ni ibeere osu yii. Drogba ti ń gbá bọ́ọ̀lù ní sáà yìí ní orílẹ̀-èdè United States pẹ̀lú ikọ̀ Phoenix Rising, ikọ̀ onípele kejì tí òun pẹ̀lú wà lára àwọn tí ó ni í. Ògbóhùntarìgì agbábọ́ọ̀lù ọwọ́ iwájú yìí ni wọ́n ti lérò pé yóò feyìntì lẹ́yìn ìpàdánù àṣekágbá ife ẹ̀yẹ Líìgì United Soccer sọ́wọ́ Louisville City ní ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ oṣù yìí. +Ti eri si pada jade ni irole ojoruu (Wednessday) pelu bi Drogba se gbe aworan igba kekere re si ori ikanni ayelujara re tohun ti oro idagbere. Tí èrí sì padà jáde ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́rùú (Wednessday) pẹ̀lú bí Drogba ṣe gbé àwòrán ìgbà kékeré rẹ̀ sí orí ìkànnì ayélujára rẹ̀ tòhun ti ọ̀rọ̀ ìdágbére. +--- Idije AWCON odun 2018: Iko Super Falcons lu iko Shepolopolo orile-ede Zambia pelu ami ayo merin si odo --- Ìdíje AWCON ọdún 2018: Ikọ̀ Super Falcons lu ikọ̀ Shepolopolo orílẹ̀-èdè Zambia pẹ̀lú àmì ayò mẹ́rin sí òdo +Iko Super Falcons orile-ede Naijiiria lu iko Shepolopolo orile-ede Zambia pelu ami ayo merin si odo ni ojoruu (Wednessday) ni Cape Coast ni orile-ede Ghana lati tesiwaju ninu idije ikokanla ife eye awon obinrin ile Adulawo. Ikọ̀ Super Falcons orílẹ̀-èdè Nàìjííríà lu ikọ̀ Shepolopolo orílẹ̀-èdè Zambia pẹ̀lú àmì ayò mẹ́rin sí òdo ní ọjọ́rùú (Wednessday) ní Cape Coast ní orílẹ̀-èdè Ghana láti tẹ̀síwájú nínú ìdíje ìkọkànlá ife ẹ̀yẹ àwọn obìnrin ilẹ̀ Adúláwọ̀. +Iko ti ife eye naa wa lowo re yii ti o koko padanu ifesewonse iside won lojo Aiku (Sunday) tun agbara mu wa pelu ijawe olubori to joju leyii ti o gbe won si oke tente tabili ipin won fun igba die naa. Ikọ̀ tí ife ẹ̀yẹ náà wà lọ́wọ́ rẹ̀ yìí tí ó kọ́kọ́ pàdánù ìfẹsẹ̀wọnṣẹ̀ ìṣíde wọn lójọ́ Àìkú (Sunday) tún agbára mú wá pẹ̀lú ìjáwé olúborí tó jọjú léyìí tí ó gbé wọn sí òkè téńté tábìlì ìpín wọn fún ìgbà díẹ̀ náà. +Desire Oparanozie gba ami ayo iside wole lati lewaju pelu ami ayo kan si odo ni saa akoko, nigbati Francesca Ordega fi ami ayo ikeji kun un ni iseju die ti abala keji bere. Desire Oparanozie gbá àmi ayò ìṣíde wọlé láti léwájú pẹ̀lú àmì ayò kan sí òdo ní sáà àkọ́kọ́, nígbàtí Francesca Ordega fi àmì ayò ìkejì kun un ní ìṣẹ́jú díẹ̀ tí abala kejì bẹ̀rẹ̀. +Oparanozie tun fi omiran kun un lati so o di ami ayo meta si odo, nigba ti Amarachi Okoronkwo ti won gbe wole to oyin si egbe akara pelu ami ayo re lati so o di merin si odo. Oparanozie tún fi òmíràn kún un láti sọ ọ́ di àmì ayò mẹ́ta sí òdo, nígbà tí Amarachi Okoronkwo tí wọ́n gbé wọlẹ́ tọ́ oyin sí ẹ̀gbẹ́ àkàrà pẹ̀lú àmì ayò rẹ̀ láti sọ ọ́ di mẹ́rin sí òdo. +Ijawe olubori yii ni o je ki Iko Naijiiria o gbon iko Zambia kuro bi ipo kini lori tabili saaju idije iko South Africa ati iko Equatorial Guinea ti yoo waye laipe lonii. Ìjáwé olúborí yìí ni ó jẹ́ kí Ikọ̀ Nàìjííríà ó gbọ́n ikọ̀ Zambia kúrò bí ipò kíní lórí tábìlì ṣaájú ìdíje ikọ̀ South Africa àti ikọ̀ Equatorial Guinea tí yóò wáyé láìpẹ́ lónìí. +Iko Falcons yoo wa maa ba iko Equatorial Guinea waako ninu idije ikeyin abala akoko ni ojo abameta (Saturday), nigba ti iko Shepolopolo yoo koju iko South Africa ni ojo yii kan naa. Ikọ̀ Falcons yóò wá máa bá ikọ̀ Equatorial Guinea wàákò nínú ìdíje ìkẹyìn àbala àkọ́kọ́ ní ọjọ́ àbámẹ́ta (Saturday), nígbà tí ikọ̀ Shepolopolo yóò kojú ikọ̀ South Africa ní ọjọ́ yìí kan náà. +--- Aare Buhari ki iko Super Eagles ku oriire ipegede sinu idije AFCON odun 2019 --- Ààrẹ Buhari kí ikọ̀ Super Eagles kú oríire ìpegedé sínú ìdíje AFCON ọdún 2019 +Aare Muhammadu Buhari ti ki iko Super Eagles orile-ede Naijiiria ku oriire ipegede sinu idije ife eye ile Adulawo odun 2019 ti yoo waye ni orile-ede Cameroon. Ààrẹ Muhammadu Buhari ti kí ikọ̀ Super Eagles orílẹ̀-èdè Nàìjííríà kú oríire ìpegedé sínú ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ ọdún 2019 tí yóò wáyé ní orílẹ̀-èdè Cameroon. +Oro re jade leyin omi ti won ta pelu iko Bafana Bafana orile-ede South Africa ni ilu Johannesburg ni ojo abameta (Saturday). Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde lẹ́yìn òmì tí wọ́n ta pẹ̀lú ikọ̀ Bafana Bafana orílẹ̀-èdè South Africa ní ìlú Johannesburg ní ọjọ́ àbámẹ́ta (Saturday). +Aare kun ogooro awon ololufe ere boolu omo orile-ede Naijiiria lati gbosuba fun iko naa fun isise pelu ipinu ati ifomoluabise won ninu ifigagbaga pelu ogbontarigi asorokolu iko yii, eyi ti o mu won pegede leyeosoka ti ifesewonse ikeyin won pelu iko Seychelles si je agbasere. Ààrẹ kùn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn olólùfẹ́ eré bọ́ọ̀lù ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà láti gbósùbà fún ikọ̀ náà fún ìṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìpinu àti ìfọmọlúàbíṣe wọn nínú ìfigagbága pẹ̀lú ògbóǹtarìgì aṣòrokọlù ikọ̀ yìí, èyí tí ó mú wọn pegedé lẹ́yẹòsọkà tí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìkẹyìn wọn pẹ̀lú ikọ̀ Seychelles sì jẹ́ àgbáṣeré. +Aare Buhari tun gboriyin fun awon iko akonimoogba, ajo to n moju to boolu afesegba lorile-ede Naijiiria (NFF), awon alatileyin paapaa julo awon omo orile-ede Naijiiria ti won n gbe ni orile-ede South Africa ti won tu jade lati wu awon agbaboolu naa lori, fun ise takuntakun yii. Ààrẹ Bùhárí tún gbóríyìn fún àwọn ikọ̀ akọ́nimọ̀ọ́gbá, àjọ tó ń mójú tó bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá lórílẹ̀-èdè Nàìjííríà (NFF), àwọn alátìlẹyìn pàápàá jùlọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà tí wọn ń gbé ní orílẹ̀-èdè South Africa tí wọ́n tú jáde láti wú àwọn agbábọ́ọ̀lù náà lórí, fún iṣẹ́ takuntakun yìí. +Aare Buhari fi atileyin gbogbo igba Ijoba Apapo da iko Super Eagle loju. Ààrẹ Bùhárí fi àtilẹ́yìn gbogbo ìgbà Ìjọba Àpapọ̀ dá ikọ̀ Super Eagle lójú. +--- Belgium duro sinsin ninu idije Liigi UEFA Nations. --- Belgium dúró ṣinṣin nínú ìdíje Líìgi UEFA Nations. +Michy Batshuayi fi ara re han gege bi eni ti o koja bee lati ropo Romelu Lukaku ti o fara pa ni ojobo (Thursday) nigba ti o gba ami ayo meji wole ninu ijawe olubori pelu ami ayo meji soodo iko won ati iko agbaboolu Iceland ninu idije Liigi UEFA Nations. Michy Batshuayi fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tì ó kọjá bẹ́ẹ̀ láti rọ́pò Romelu Lukaku tí ó fara pa ní ọjọ́bọ (Thursday) nígbà tí ó gbá àmì ayò méjì wọlé nínú ìjáwé olúborí pẹ̀lú àmì ayò méjì sóódo ikọ wọn àti ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Iceland nínú ìdíje Líìgi UEFA Nations. +Leyin Iseju marundinlaadorin ti won ti n dari so owo eyin iko Iceland, Balogun iko Eden Hazard sawari Thomas Meunier ni apa otun ori papa ti agbaboolu egbe iko Paris Saint-Germain ohun na a si Batshuayi lati gba boolu ayo naa wole. Lẹ́yìn Ìṣẹ́jú márùndínláàdọ́rin tí wọ́n ti ń dárí sọ ọwọ́ ẹ̀yìn ikọ̀ Iceland, Balógun ikọ̀ Eden Hazard ṣàwárí Thomas Meunier ní apá ọtún orí pápá tí agbábọ́ọ̀lù ẹ̀gbẹ́ ikọ̀ Paris Saint-Germain ọ̀hụ́n nà á sí Batshuayi láti gbá bọ́ọ̀lù ayò náà wọlé. +Ami ayo keji tile rorun fun agbaboolu ti o wa ninu iko Valencia pelu adehun ayalo yii pelu bi o se ta boolu sawon nigba ti ayo ti Hans Vanaken gba pada wa si odo re. Àmì ayò kejì tìlẹ̀ rọrùn fún agbábọ́ọ̀lù tí ó wà nínú ikọ̀ Valencia pẹ̀lú àdéhùn àyálò yìí pẹ̀lú bí ó ṣe ta bọ́ọ̀lù sáwọ̀n nígbà tí ayò tí Hans Vanaken gbá padà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. +Belgium ni ami mesan-an ninu idije meta ti won ti gba ninu ipin keji saaju iko Switzerland. Belgium ní àmì mẹ́sàn-án nínú ìdíje mẹ́ta tí wọ́n ti gbá nínú ìpín kejì ṣaájú ikọ̀ Switzerland. +Omi pelu iko Orile-ede Switzerland ti to lati mu iko Belgium wa lara awon iko merin akoko ni inu osu kefa. Iko Iceland padanu gbogbo ifesewonse mereerin won, won si ti fidiremi. Òmì pẹ̀lú ikọ̀ Orílẹ̀-èdè Switzerland ti tó láti mú ikọ̀ Belgium wà lára àwọn ikọ̀ mẹ́rin àkọ́kọ́ ní inú oṣù kẹfà. Ikọ̀ Iceland pàdánù gbogbo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọn, wọ́n sì ti fìdírẹmi. +--- idije Liigi UEFA Nations: Croatia fiya je Spain --- ìdíje Líìgì UEFA Nations: Croatia fìyà jẹ Spain +Iko Croatia bayii yoo fo to koso lo si ilu London nigba ti iko Spain ti di fifi seyin pelu ifojuwina ifidiremi labe akonimoogba tuntun Luis Enrique. Ikọ̀ Croatia báyìí yóò fò tọ kọ́sọ́ lọ sí ìlú London nígbà tí ikọ̀ Spain ti di fífi sẹ́yìn pẹ̀lú ìfojúwiná ìfìdírẹmi lábẹ́ akónimọ̀ọ́gbá tuntun Luis Enrique. +Spain padanu oore-ofe ati tesiwaju nini asekagba idije Liigi UEFA yii pelu bi won se padanu pelu ami ayo meta si meji sowo orile-ede Croatia ni ojobo (Thursday), eyi ti o waye pelu ami ayo iseju ketalelaaadorun-un ti Tin Jedvaj gba wole. Spain pàdánù oore-ọ̀fẹ́ àti tẹ̀síwájú níní àṣekágbá ìdíje Líìgì UEFA yìí pẹ̀lú bí wọ́n ṣe pàdánù pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sí méjì sọ́wó orílẹ̀-èdè Croatia ní ọjọ́bọ (Thursday), èyí tí ó wáyé pẹ̀lú àmì ayò ìṣẹ́jú kẹtàléláàádọ́rùn-ún tí Tin Jedvaj gbá wọlé. +Ami ayo owo ipari Jedvaj’s ni o si ilekun owo kerin sile gbayawu saaju ifesewonse keyin ti yoo waye ni aarin iko orile-ede England ati iko orile-ede Croatia ni ojo aiku (Sunday). Àmì ayò ọwọ́ ìparí Jedvaj’s ni ó sí ilẹ̀kùn ọ̀wọ́ kẹrin sílẹ̀ gbayawu ṣaájú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kẹyìn tí yóò wáyé ní àárín ikọ̀ orílẹ̀-èdè England àti ikọ̀ orílẹ̀-èdè Croatia ní ọjọ́ àìkú (Sunday). +Iko ti o ba jawe olubori yoo pegede, pelu bi o tun se seese ki iko Spain o tun pada pegede ti idije yii ti yoo waye ni papa isere Wembley ba pari si omi. Croatia ni o ye ki o bori ni Zagreb, nibi ti Jedvaj ti ri awon he leemeji – ami ayo re akoko ninu idije agbaaye – pelu ijawe olubori manigbagbe leyin ifagagbaga to gbona girigiri yii. Ikọ̀ tí ó bá jáwé olúborí yóò pegedé, pẹ̀lú bí ó tún ṣe ṣeéṣe kí ikọ̀ Spain ó tún padà pegedé tí ìdíje yìí tí yóò wáyé ní pápá ìṣeré Wembley bá parí sí ọ̀mì. Croatia ni ó yẹ kí ó borí ní Zagreb, níbi tí Jedvaj ti rí àwọn he lẹ́ẹ̀mejì – àmì ayò rẹ̀ àkọ́kọ́ nínú ìdíje àgbááyé – pẹ̀lú ìjáwé olúborí mánigbàgbé lẹ̀yìn ìfagagbága tó gbóná girigiri yìí. +Iko Croatia bayii yoo fo to koso lo si ilu London nigba ti iko Spain ti di fifi seyin pelu ifojuwina ifidiremi labe akonimoogba tuntun Luis Enrique, pelu ipadanu ti o yani lenu yii ti o je iru abajade kan naa ninu ifesewonse pelu orile-ede England ni ile won ni osu to koja. Ikọ̀ Croatia báyìí yóò fò tọ kọ́sọ́ lọ sí ìlú London nígbà tí ikọ̀ Spain ti di fífi sẹ́yìn pẹ̀lú ìfojúwiná ìfìdírẹmi lábẹ́ akónimọ̀ọ́gbá tuntun Luis Enrique, pẹ̀lú ìpadánù tí ó yani lẹ́nu yìí tí ó jẹ́ irú àbájáde kan náà nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè England ní ilé wọn ní oṣù tó kọjá. +Spain ti bo lowo ifidiremi, eyi ti a ko le fi ogun re gbari fun iko England tabi Croatia, ti won si le pari pelu ipo kinni tabi ipo ikeyin, eyi wa lowo abajade ale ojo aiku (Sunday). England yoo fidi remi ti won ba padanu tabi ti won ta omi. Croatia yoo bo rele ti won ba lu won tabi ta omi odo si odo. Spain ti bọ́ lọ́wọ́ ìfìdírẹmi, èyí tí a kò lè fi ògún rẹ̀ gbárí fún ikọ̀ England tàbí Croatia, tí wọ́n ṣì lè parí pẹ̀lú ipò kínní tàbí ipò ìkẹyìn, èyí wà lọ́wọ́ àbájáde alẹ́ ọjọ́ àìkú (Sunday). England yóò fìdí rẹmi tí wọ́n bá pàdánù tàbí tí wọ́n ta ọ̀mì. Croatia yóò bọ́ rẹ́lẹ̀ tí wọ́n bá lù wọ́n tàbí ta ọ̀mì òdo sí òdo. +--- Djokovic po Zverev mole ninu asekagba idije ATP --- Djokovic po Zverev mọ́lẹ̀ nínú àṣekágbá ìdìje ATP +Novak Djokovic akoko ninu awon Oniteniisi agbaaye se jade lona to lagbara lati feyin alaso ina omo orile-ede Germany nni Alexander Zverev bele ninu asekagba idije ATP lojoruu (Wednesday). Novak Djokovic àkọ́kọ́ nínú àwọn Onítẹníìsì àgbááyé ṣẹ́ jáde lọ́nà tó lágbára láti fẹ̀yìn alásọ iná ọmọ orílẹ̀-èdè Germany nnì Alexander Zverev bẹ́lẹ̀ nínú àṣekágbá ìdìje ATP lójọ́rùú (Wednesday). +Omo orile-ede Serbia yii, fi odun mewaa ju alatako re ti o fi oju re wina leyin alatako yii ti o ti koko gbiyanju ni abala akoko, gbogbo igbiyanju Zverev ni papa isere O2 Arena fori sanpon pelu bi Djokovic se bori pelu ami mefa si merin, mefa si okan. Ọmọ orílẹ̀-èdè Serbia yìí, fi ọdún mẹ́wàá ju alátakò rẹ̀ tí ó fi ojú rẹ̀ winá lẹ́yìn alátakò yìí tí ó ti kọ́kọ́ gbìyànjú ní abala àkọ́kọ́, gbogbo ìgbìyànjú Zverev ní pápá ìṣeré O2 Arena forí sánpọ́n pẹ̀lú bí Djokovic ṣe borí pẹ̀lú àmì méfà sí mẹ́rin, mẹ́fà sí ọ̀kan. +Ijawe olubori yii ni o je ki Eni ti o ti gba ami eye yii ni eemarun-un otooto lati to koso si ipele ti o kangun si asekagba. Ìjáwé olúborí yìí ni ó jẹ́ kí Ẹni tí ó ti gba àmì ẹyẹ yìí ní ẹ̀ẹ̀marùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti tọ kọ́sọ́ sí ìpele tí ó kángun sí àṣekágbá. +Djokovic, ti yoo pari odun yii gege bi eni-ipo kini lagbaaye fun igba karun-un ninu igbesi aye re leyin abala keji saa yii ti o gbona girigiri ni o siwaju owo Gustavo Kuerten. Djokovic, tí yóò parí ọdún yìí gẹ́gẹ́ bí ẹni-ipò kíní lágbàáyé fún ìgbà karùn-ún nínú ìgbésí ayé rẹ̀ lẹ́yìn abala kejì sáà yìí tí ó gbóná girigiri ni ó síwájú ọ̀wọ́ Gustavo Kuerten. +Eyi ni o mu omo orile-ede Serbia yii jawe olubori fun igba iketalelogbon ninu ifigagbaga marundinlogoji ti o ti gba seyin. Èyí ni ó mú ọmọ orílẹ̀-èdè Serbia yìí jáwé olúborí fún ìgbà ìkẹtàlélọ́gbọ̀n nínú ìfigagbága márùndínlógójì tí ó ti gbá sẹ́yìn. +--- IIfesewonse pelu Bafana: Musa, Balogun, ati awon ogun miiran gbaradi ni Asaba --- IÌfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹ̀lú Bafana: Musa, Balogun, àti àwọn ogún mìíràn gbáradì ní Asaba +Gernot Rohr ti ni agbaboolu mejilelogun ti o n gbaradi lowo ni papa isere Stephen Keshi ni ilu Asaba ninu awon agbaboolu ti o fiwe pe, pelu bi won se beere imurasile fun idije ipegede si ife eye ile Adulawo odun 2019 pelu iko Bafana Bafana ni papa isere FNB ni ilu Johannesburg. Gernot Rohr ti ní agbábọ́ọ̀lù mẹ́jìlélógún tí ó ń gbáradì lọ́wọ́ ní pápá ìṣeré Stephen Keshi ní ìlú Àsàbà nínú àwọn agbábọ́ọ̀lù tí ó fìwé pè, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ìmúrasílẹ̀ fún ìdíje ìpegedé sí ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ ọdún 2019 pẹ̀lú ikọ̀ Bafana Bafana ní pápá ìṣeré FNB ní ìlú Johannesburg. +Atamatase iko Bordeaux Samuel Kalu, ti won n reti ni ipago lonii nikan ni ko si ninu igbaradi naa. Àtàmátàsé ikọ̀ Bordeaux Samuel Kalu, tí wọn ń retí ní ìpàgọ́ lónìí nìkan ni kò sí nínú ìgbáradì náà. +Ninu won ni Balogun Ahmed Musa pelu awon asole Daniel Akpeyi, Theophilus Afelokhai ati Ikechukwu Ezenwa ati awon adieyinmu Olaoluwa Aina, Adeleye Aniyikaye, Semi Ajayi, Bryan Idowu, William Troost-Ekong, Leon Balogun, Kenneth Omeruo ati Jamilu Collins pelu gbara di. Nínú wọn ni Balogun Ahmed Musa pẹ̀lú àwọn aṣọ́lé Daniel Akpeyi, Theophilus Afelokhai àti Ikechukwu Ezenwa àti àwọn adiẹ̀yìnmú Olaoluwa Aina, Adeleye Aniyikaye, Semi Ajayi, Bryan Idowu, William Troost-Ekong, Leon Balogun, Kenneth Omeruo àti Jamilu Collins pèlú gbára dì. +Lara won tun ni awon agbaboolu owo aarin Oghenekaro Etebo, John Ogu ati Mikel Agu, ati awon owo iwaju Kelechi Iheanacho, Moses Simon, Victor Osimhen, Henry Onyekuru, Alex Iwobi, Isaac Success ati Samuel Chukwueze. Lára wọn tún ni àwọn agbábọ́ọ̀lù ọwọ́ àárín Oghenekaro Etebo, John Ogu àti Mikel Agu, àti àwọn ọwọ́ iwájú Kelechi Iheanacho, Moses Simon, Victor Osimhen, Henry Onyekuru, Alex Iwobi, Isaac Success àti Samuel Chukwueze. +Ninu ifesewonse akoko ipegede, South Africa jawe olubori pelu ami ayo meji si odo pelu ayo lati owo Tokelo Rantie ati Percy Tau ni inu papa isere Godswill Akpabio, pelu bi akonimoogba Gernot Rohr se lo awon agbaboolu orile-ede keekeeke ti won ko tii ni iriri. Nínú ífẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ ìpegedé, South Africa jáwé olúborí pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo pẹ̀lú ayò láti ọwọ́ Tokelo Rantie àti Percy Tau ní inú pápá ìṣeré Godswill Akpabio, pẹ̀lú bi akọ́nimọ̀ọ́gbá Gernot Rohr ṣe lo àwọn agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀-èdè kéékèèké tí wọn kò tíi ní ìrírí. +--- A ko beeru iko Naijiiria, Baxter tun un so. --- A kò bẹ̀ẹ̀rù ikọ̀ Nàìjííríà, Baxter tún un sọ. +Akonimoogba iko Bafana Bafana Stuart Baxter so o yanya pe oun ati iko oun o foya rara lati koju iko Super Eagle orile-ede Naijiiria lojo abameta (Saturday) ninu idije ipegede si ife eye ile Adulawo odun 2019 ti yoo waye ni papa isere FNB ni ilu Johannesburg. . Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Bafana Bafana Stuart Baxter sọ ọ́ yanya pé òun àti ikọ̀ òun ò fòyà rárá láti kojú ikọ̀ Super Eagle orílẹ̀-èdè Nàìjííríà lọ́jọ́ àbámẹ́ta (Saturday) nínú ìdíje ìpegedé sí ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ ọdún 2019 tí yóò wáyé ní pápá ìṣeré FNB ní ìlú Johannesburg. . +Baxter, ti o n lepa atibori fun igba keta nigba ti iko Bafana ba koju iko Super Eagles, lero ki iko ti o ti gba Ife eye ile Adulawo leemeta otooto yii ni ete igbesan lokan saaju ifigagbaga naa.. Baxter, tí ó ń lépa àtiborí fún ìgbà kẹta nígbà tí ikọ̀ Bafana bá kojú ikọ̀ Super Eagles, lérò kí ikọ̀ tí ó ti gba Ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ lẹ́ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yìí ní ète ìgbẹsan lọ́kàn ṣaájú ìfigagbága náà.. +Omo ile Biritiko yii ko iko South Africa bori iko Naijiiria pelu ami ayo meji si okan ni odun 2004 nini ifigagbaga fun Mandela ki o to di pe o fiya je iko Super Eagles pelu ami ayo meji si odo 2-0 ninu idije ipegede si ife eye ile Adulawo odun 2019 ni Uyo ninu osu kefa odun 2017 – idije akoko re ninu isi eekeji ninu iko naa. Ọmọ ilẹ̀ Bìrìtìkó yìí kó ikọ̀ South Africa borí ikọ̀ Nàìjííríà pẹ̀lú àmì ayò méjì sí ọ̀kan ní ọdún 2004 níní ìfigagbága fún Mandela kí ó tó di pé ó fìyà jẹ ikọ̀ Super Eagles pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo 2-0 nínú ìdíje ìpegedé sí ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ ọdún 2019 ní Uyo nínú oṣù kẹfà ọdún 2017 – ìdíje àkókọ́ rẹ̀ nínú ìṣí ẹ̀ẹ̀kejì nínú ikọ̀ náà. +-- Iko Flying Eagles yoo koju iko orile-ede Ghana, ati iko orile-ede Benin ninu idije WAFU -- Ikọ̀ Flying Eagles yóò kojú ikọ̀ orílẹ̀-èdè Ghana, àti ikọ̀ orílẹ̀-èdè Benin nínú ìdíje WAFU +Iko agbaboolu awon odo ti ojo ori won ko ju ogun odun lo yoo maa waako pelu akeegbe won lati orile-ede Ghana, Niger Republic ati Benin Republic ni ipin B idije komeseoyo ife eye WAFU awon odo ti ojo ori won ko ju ogun odun lo ti yoo waye ni Lome lorile-ede Togo, lati ojo kefa si ojo kerindinlogun osu kejila. Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn kò ju ogún ọdún lọ yóò máà wàákò pẹ̀lú akẹẹgbẹ́ wọn láti orílẹ̀-èdè Ghana, Niger Republic àti Benin Republic ní ìpín B ìdíje kòmẹsẹ̀óyọ ife ẹ̀yẹ́ WAFU àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn kò ju ogún ọdún lọ tí yóò wáyé ní Lome lórílẹ̀-èdè Togo, láti ọjọ́ kẹfà sí ọjọ́ kẹrìndínlọ́gún oṣù kejìlá. +Awon Alakooso eto ti to awon idije wonyi ni imurasile pataki de awon iko maraarun lati ekun kookan ti won ti pegede lati kopa ninu idije ife eye WAFU awon odo ti ojo ori won ko ju ogun odun lo ni orile-ede Tanzania lati Ojo keji si ojo ketadinlogun osu keji odun 2019. Àwọn Alákòóso ètò ti to àwọn ìdíje wọ̀nyí ní ìmurasílẹ̀ pàtàkì de àwọn ikọ̀ márààrún láti ẹkùn kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ti pegedé láti kópa nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ́ WAFU àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn kò ju ogún ọdún lọ ní orílẹ̀-èdè Tanzania láti Ọjọ́ kejì sí ọjó kẹtàdínlógún oṣù kejì ọdún 2019. +Iko Naijiiria ti o ti gba ife idije yii ni eemeje otooto yoo maa kopa ninu idije komeseoyo olojo mokanla yii pelu awon iko bii iko Senegal, Burkina Faso, Ghana ati iko Niger Republic ni Lome. Iko Burundi ati Angola ti won gbalejo idije yii yoo kun awon orile-ede marun yii. Ikọ Nàìjííríà tí ó ti gba ife idíje yìí ní ẹ̀ẹ̀meje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yóò máa kópa nínú ìdíje kòmẹsẹ̀oyọ̀ ọlọ́jọ́ mọ́kànlá yìí pẹ̀lú àwọn ikọ̀ bíi ikọ̀ Senegal, Burkina Faso, Ghana àti ikọ̀ Niger Republic ní Lome. Ikọ̀ Burundi àti Angola tí wọ́n gbàlejò ìdíje yìí yóò kún àwọn orílẹ̀-èdè márùn yìí. +Iko Flying Eagles waako pelu iko Young Squirrels ti orile-ede Benin ninu idije akoko won fun komeseoyo naa ni ojo keje osu kejila, ki won to kolu iko Junior Mena ti orile-ede Niger Republic ni ojo kesan-an osu kejila ati iko Black Satellites orile-ede Ghana ni ojo kejila osu kejila. Ikọ̀ Flying Eagles wàákò pẹ̀lú ikọ̀ Young Squirrels ti orílẹ̀-èdè Benin nínú ìdíje àkọkọ wọn fún kòmẹsẹ̀oyọ náà ní ọjọ́ keje oṣù kejìlá, kí wọ́n tó kọlu ikọ̀ Junior Mena ti orílẹ̀-èdè Niger Republic ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kejìlá àti ikọ̀ Black Satellites orílẹ̀-èdè Ghana ní ọjọ́ kejìlá oṣù kejìlá. +--- Iko orile-ede China dara po mo awon ti won n lepa atira Victor Moses --- Ikọ̀ orílẹ̀-èdè China dara pọ̀ mọ́ àwọn tí wọn ń lépa àtira Victor Moses +Ojo iwaju Victor Moses ninu iko Chelsea ko daju leyin ti akonimoogba won Maurizo Sarri yo oruko re kuro ninu iko re ti yoo maa koju Bate Borisov ninu idije Liigi Europa. Ọjọ́ iwájú Victor Moses nínú ikọ̀ Chelsea kò dájú lẹ́yìn tí akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn Maurizo Sarri yọ orúkọ rẹ̀ kúro nínú ikọ̀ rẹ̀ tí yóò máa kojú Bate Borisov nínú ìdíje Líìgì Europa. +Sarri so o kan Moses loju pe o le fi iko naa sile ninu osu kinni odun nigba ti ferese oju oja ba si sile. Lati igba yii ni omo orile-ede Naijiiria ko ti ri okankan ninu awon idije won gba. Sarri sọ ọ́ kan Moses lójú pé ó lè fi ikọ̀ náà sílẹ̀ nínú oṣù kínní ọdún nígbà tí fèrèsé ojú ọjà bá ṣí sílẹ̀. Láti ìgbà yìí ni ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà kò tí rí ọ̀kankan nínú àwọn ìdíje wọn gbá. +Iko Crystal Palace ati iko Wolverhampton Wanderers ti fi ife won han si isowosise re bee si ni iroyin ti o jade ni yajoyajo lati owo OwngoalNaijiiria.com so o di mimo pe Iko Liigi ile China Shanghai SIPG ti dara po lati maa lepa atira a. Ikọ̀ Crystal Palace àti ikọ̀ Wolverhampton Wanderers ti fi ìfẹ wọn hàn sí ìṣọwọ́ṣiṣẹ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni ìròyìn tí ó jáde ní yàjóyàjó láti ọwọ́ OwngoalNàìjííríà.com sọ ọ́ di mímọ̀ pé Ikọ̀ Líìgì ilẹ̀ China Shanghai SIPG ti dara pọ̀ láti máa lépa àtirà á. +--- Rohr mu Afelokhai gege bi aropo Uzoho --- Rohr mú Afelokhai gẹ́gẹ́ bí arọ́pò Uzoho +Akonimoogba iko Naijiiria Gernot Rohr ti fi kesi Asole iko Enyimba Theophilus Afelokhai gege bi aropo Uzoho fun idije ipegede sinu ife eye ile Adulawo pelu iko South Africa ati idije oloreesoree agbaaye pelu iko Uganda ninu osu yii. Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Nàìjííríà Gernot Rohr ti fi késí Asọ́lé ikọ̀ Enyimba Theophilus Afelokhai gẹ́gẹ́ bí arọ́pò Uzoho fun ìdíje ìpegedé sínú ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ pẹ̀lú ikọ̀ South Africa àti ìdíje ọlórẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ àgbááyé pẹ̀lú ikọ̀ Uganda nínú oṣù yìí. +Uzoho fi agidi kuro ninu alakale awon agbaboolu iko Super Eagles latari ese ti o se lopin ose to koja ti yoo fi wa letii papa na fun ose merin okere tan. Uzoho fi agídí kúro nínú àlàkalẹ̀ àwọn agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Super Eagles látàrí èṣe tí ó ṣe lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá tí yóò fi wà létíi pápá ná fún ọ̀ṣẹ̀ mẹ́rin ókéré tán. +Iko Naijiiria yoo koju iko South Africa ni Johannesburg lojo ketadinlogun osu kokanla ki o to di pe won o pade iko Uganda leyin ojo keta ni ilu Asaba. Ikọ̀ Nàìjííríà yóò kojú ikọ̀ South Africa ní Johannesburg lọ́jọ́ kẹtàdínlógún oṣù kọkànlá kí ó tó di pé wọn ó pàdé ikọ̀ Uganda lẹ́yìn ọjọ́ kẹta ní ìlú Asaba. +--- Iko Man City goke leyin ifakoyo nla --- Ikọ̀ Man City gòkè lẹ́yìn ìfakọyọ ńlá +Ogbonhuntarigi iko agbaboolu Manchester City ti gba ipo akoko won pada ninu idije Premier League ile Geesi ti o waye lale ana leyin ti won lu iko Southampton ni alubami, iko ti Pep Guardiola ko sodi yii jawe olubori pelu ami ayo mefa si okan ni ile won pelu bi Raheem Sterling se ri awon he leemeji ninu ifesewonse naa. Lapa ibomiira, Iko Chelsea di orogun ti o sunmo won julo leyin ti won fi ara bale fiyaje iko Crystal Palace pelu ami ayo meta si okan. Ògbónhùntarìgì ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Manchester City ti gba ipò àkọ́kọ́ wọn padà nínú ìdíje Premier League ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí ó wáyé lálẹ́ àná lẹ́yìn tí wọ́n lu ikọ̀ Southampton ní àlùbami, ikọ̀ tí Pep Guardiola kó sòdí yìí jáwé olúborí pẹ̀lú àmì ayò mẹ́fà sí ọ̀kan ní ilé wọn pẹ̀lú bí Raheem Sterling ṣe rí àwọn he lẹ́ẹ̀mejì nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà. Lápá ibòmìírà, Ikọ̀ Chelsea di orogún tí ó súnmọ́ wọn jùlọ lẹ́yìn tí wọ́n fi ara balẹ̀ fìyàjẹ ikọ̀ Crystal Palace pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sí ọ̀kan. +--- Idije Ipege AFCON: Bafana Bafana daruko iko ti yoo koju orile-ede Naijiiria --- Ìdìje Ìpege AFCON: Bafana Bafana dárúkọ ikọ̀ tí yóò kojú orílẹ̀-èdè Nàìjííríà +Akonimoogba iko Bafana Bafana Stuart Baxter ti pe agbaboolu owo aarin Thulani Serero ti iko SBV ni orile-ede Netherlands sinu iko re fun ifesewonse aigbodomabori idije ipegede sinu ife eye ile Adulawo (AFCON) odun 2019 won pelu iko orile-ede Naijiiria ni papa isere FNB Stadium ni ojo ketadinlogun osu kokanla. Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Bafana Bafana Stuart Baxter ti pe agbábọ́ọ̀lù ọwọ́ àárín Thulani Serero ti ikọ̀ SBV ní orílẹ̀-èdè Netherlands sínú ikọ̀ rẹ̀ fún ìfẹsẹ̀wọnṣẹ̀ àìgbọdọ̀máborí ìdíje ìpegedé sínú ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ (AFCON) ọdún 2019 wọn pẹ̀lú ikọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà ní pápá ìṣeré FNB Stadium ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kọkànlá. +--- Iko Naijiiria yoo pegede si idije ife eye ile Adulawo (AFCON) odun 2019 : Rohr --- Ikọ̀ Nàìjííríà yóò pegedé sí ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ (AFCON) ọdún 2019 : Rohr +Akonimoogba Gernot Rohr gbagbo pe iko re le bori tabi ki won ta omi ninu idije pelu orile-ede South Africa lati pegede sinu idije ife eye ile Adulawo (AFCON) odun 2019. Akọ́nimọ̀ọ́gbá Gernot Rohr gbàgbó pé ikọ̀ rẹ̀ lè borí tàbí kí wọ́n ta ọ̀mì nínú ìdíje pẹ̀lú orílẹ̀-èdè South Africa láti pegedé sínú ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ (AFCON) ọdún 2019. +Iko agbaboolu Super Eagles ti wa loke tente tabili pelu ami mesan-an ninu ipin E, won yoo si koju iko Bafana Bafana ni ojo ketadinlogun osu kokanla ni ilu Johannesburg lorile-ede South Africa Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles ti wà lókè téńté tábìlì pẹ̀lú àmì mẹ́sàn-án nínú ìpín E, wọn yóò sì kojú ikọ̀ Bafana Bafana ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kọkànlá ní ìlú Johannesburg lórílẹ̀-èdè South Africa +Omi tabi ijawe olubori ti to fun agba iko apa iwo oorun ile Adulawo yii lati ri aaye ninu idije ti orile-ede Cameroon yoo gbalejo re yii. Ọ̀mì tàbí ìjáwé olúborí ti tó fún àgbà ikọ̀ apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀ yìí láti rí ààyè nínú ìdíje tí orílẹ̀-èdè Cameroon yóò gbàlejò rẹ̀ yìí. +--- Iko orile-ede Naijiiria goke, ipo kerinlelogoji ni won wa bayii lori ate ipo FIFA --- Ikọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà gòkè, ipò kẹrìnlélógójì ni wọ́n wà báyìí lórí àtẹ ipò FIFA +Iko Super Eagles orile-ede Naijiiria ti te akaba merin goke sii si ipo kerinlelogoji lagbaaye ninu ate Cocacola FIFA ti osu kewaa. Ikọ̀ Super Eagles orílẹ̀-èdè Nàìjííríà ti tẹ àkàbà mẹ́rin gòkè síi sí ipò kẹrìnlélógójì lágbàáyé nínú àtẹ Cocacola FIFA tí osù kẹwàá. +Ni ori ate tabili ti won gbe jade lori ikanni igbimo apapo ere boolu lagbaaye ni ojobo (Thursday), orile-ede Naijiiria ni aami ami ojilelegbejedinmesan-an ju ami okoolegbejedinmarun-un ti won ni ninu osu kesan-an. Ní orí àtẹ tábìlì tí wọ́n gbé jáde lórí ìkànnì ìgbìmọ̀ àpapọ̀ eré bọ́ọ̀lù lágbàáyé ní ọjọ́bọ (Thursday), orílẹ̀-èdè Nàìjííríà ní ààmì àmì òjìlélégbèjedínmẹ́sàn-án ju àmì òkòólégbèjedínmárùn-ún tí wọ́n ní nínú oṣù kẹsàn-án. +Igbega yii ti wa gbe iko Naijiiria gege bi onipoketa ni ile Adulawo leyin iko orile-ede Tunisia ati iko Senegal. Ìgbéga yìí ti wá gbé ikọ̀ Nàìjííríà gẹ́gẹ́ bí onípòkẹta ní ilẹ Adúláwò lẹ́yìn ikọ̀ orílẹ̀-èdè Tunisia àti ikọ̀ Senegal. +O se pataki lati ranti pe ni akoko yen ni iko Naijiiria dana iya fun iko Lybia pelu ami ayo merin si odo ni ile won ati ami ayo meta si meji ni ajo ninu idije ipegede sinu ife eye ile Adulawo. Ó ṣe pàtàkì láti rántí pé ní àkókò yẹn ni ikọ̀ Nàìjííríà dáná ìyà fún ikọ̀ Lybia pẹ̀lú àmì ayò mẹ́rin sí òdo ní ilé wọn àti àmì ayò mẹ́ta sí méjì ní àjò nínú ìdíje ìpegedé sínú ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀. +Tunisia ni o wa ni ipo kejilelogun nigba ti Senegal wa ni ipo karundinlogbon. Tunisia ni ó wà ní ipò kejìlélógún nígbà tí Senegal wà ní ipò karùndínlógbọ̀n. +Iko Congo DR (wa ni ipo kerindinlaaadota ti Morocco je iketadilaaadota ti awon orile-ede ile Adulawo miiran si wa ninu aadota akoko. Ikọ̀ Congo DR (wà ní ipọ̀ kẹrìndínláàádọ́ta tí Morocco jẹ́ ìkẹtàdíláàádọ́ta tí àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ mìíràn sì wà nínú aádọ́ta àkọ́kọ́. +Kaakiri agbaaye, Belgium ni o wa ni ipo kinni bayii siwaju France ti o fi tintinni yesile pelu ami kan pere ninu ate Cocacola FIFA ti o jaje lonii. Iko Belgium ni ami Ojileleeedegbesandinmeje, ti France si ni ami Ojileleeedegbesandinmejo. Káàkiri àgbááyé, Belgium ni ó wà ní ipò kínní báyìí ṣíwájú France tí ó fi tíntinní yẹ̀sílẹ̀ pẹ̀lú àmì kan péré nínú àtẹ Cocacola FIFA tí ó jáje lónìí. Ikọ̀ Belgium ní àmì Òjìlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbèsándínméje, tí France sì ní àmì Òjìlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbèsándínmẹ́jọ. +Awon mejeeji di oke tente mu sibe leyin osu kan ti awon mejeeji ti n fi ijaweolubori ati omi panu, pelu bi iko Belgium se na iko Switzerland ko je ki iko yii kuro ni ipo kejo bee si ni lilu ti France lu Germany ninu idije Liiji UEFA Nations je ki won o jabo lenu akaso meji lo si ipo kerinla. Brazil dipo keta mu pelu ami otalelegbejolemesan-an, ti Croatia ipo kerin pelu ami ojilelegbejolemarun-un lori tabili, England ipo karun-un ami okoolelegbejo-din-okan nigba ti iko agbaboolu Argentina Leo Messi wa ni ipo kejila lori tabili. Àwọn méjèèjì di ọ̀kè téńté mú síbẹ̀ lẹ́yìn oṣù kan tí àwọn méjéèjì ti ń fi ìjáwéolúborí àti òmì panu, pẹ̀lú bí ikọ̀ Belgium ṣe na ikọ̀ Switzerland kò jẹ́ kí ikọ̀ yìí kúrò ní ipò kẹjọ bẹ́ẹ̀ sì ni lílù tí France lu Germany nínú ìdíje Líìjì UEFA Nations jẹ́ kí wọn ó jábọ́ lẹnu àkàsọ méjì lọ sí ipò kẹrìnlá. Brazil dipò kẹta mú pẹ̀lú àmì ọ̀tàlélẹ́gbèjọlémẹ́sàn-án, tí Croatia ipò kẹrin pẹ̀lú àmì òjìlélẹ́gbèjọlémárùn-ún lórí tábìlì, England ipò karùn-ún àmì okòólélẹ́gbẹ̀jọ-dín-ọ̀kan nígbà tí ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Argentina Leo Messi wà ní ipò kejìlá lórí tábìlì. +--- Pliskova yege sinu ipele to kangun si asekagba idije WTA --- Pliskova yege sínú ìpele tó kángun sí àṣekágbá ìdíje WTA +Omo orile-ede Czech Karolina Pliskova ti yege bo sinu ipele to kangun si asekagba ni ojobo (Thursday) leyin ti o o lu Petra Kvitova akinkanju ti o ti gba idije ohun ri ti o si yowo kilanko re kuro ninu asekagba idije WTA ti yoo waye ni ilu Singapore. Ọmọ orílẹ̀-èdè Czech Karolina Pliskova ti yege bọ́ sínú ìpele tó kángun sí àṣekágbá ní ọjọ́bọ (Thursday) lẹ́yìn tí ó ó lu Petra Kvitova akínkanjú tí ó ti gba ìdíje ọ̀hún rí tí ó sì yọwọ́ kílàńkó rẹ̀ kúrò nínú àṣekágbá ìdíje WTA tí yóò wáyé ní ìlú Singapore. +Pliskova di alayo akoko ti o koko pegede sinu asekagba eleni merin ohun leyin ti o bori pelu ami ayo mefa si meta, mefa si merin ni etalelogorin iseju. Pliskova di aláyò àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ pegedé sínú àṣekágbá ẹlẹ́ni mẹ́rin ọ̀hún lẹ́yìn tí ó borí pẹ̀lú àmì ayò mẹ́fà sí mẹ́ta, mẹ́fà sí mẹ́rin ní ẹ̀tàlélọ́gọ́rin ìṣẹ́jú. +Kvitova nilo lati lati jawe olubori kanle lati le tesiwaju ati maa fakoyo sugbon o ja fitafita ni lati le pari ifigagbaga ipele naa fun igba akoko lati odun 2015, abajade ifigagbaga yii da jinnijinni bo Caroline Wozniacki ti ami eye idije naa wa lowo re lowolowo, eni ti o nilo lati lu Elina Svitolina kanle lati le di ami eye yii mu sibe. Kvitova nílò láti láti jáwé olúborí kanlẹ̀ láti lè tẹ̀síwájú àti máa fakọyọ ṣùgbọ́n ó jà fitafita ni láti lè parí ìfigagbága ìpele náà fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ọdún 2015, àbájáde ìfigagbága yìí da jìnnìjìnnì bo Caroline Wozniacki tí àmì ẹyẹ ìdíje náà wà lọ́wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, ẹni tí ó nílò láti lu Elina Svitolina kanlẹ̀ láti lè di àmì ẹ̀yẹ yìí mú síbẹ̀. +Pliskova alayo akoko ninu idije naa nigbakanri wa aaye fun ara re ni ipele to kangun si asekagba fun igba keji lera won. Pliskova aláyò àkọ́kọ́ nínú ìdíje náà nígbàkanrí wá ààyè fún ara rẹ̀ ní ìpele tó kángun sí àṣekágbá fún ìgbà kejì léra wọn. +--- Messi di yiyo segbee fun ose meta latari ese apa. --- Messi di yíyọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́tà látàrí èṣe apá. +Balogun iko Barcelona yoo maa gbele woran fun ose meta gbako latari ese apa otun re ninu ijawe olubori idije La liga won lori iko Sevilla pelu ami ayo merin si meji ni ojo abameta (Saturday). Atejade iko won kan lo so eleyii di mimo. Balógun ikọ̀ Barcelona yóò máa gbélẹ̀ wòran fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko látàrí èṣe apá ọ̀tún rẹ̀ nínú ìjáwé olúborí ìdíje La liga wọn lórí ikọ̀ Sevilla pẹ̀lú àmì ayò mẹ́rin sí méjì ní ọjọ́ àbámẹ́ta (Saturday). Àtẹ̀jáde ikọ wọn kan ló sọ eléyìí di mímọ̀. +Ifarapa yii yo o kuro ninu iko ti yoo koju orogun Real Madrid ninu ifigagbaga ‘Clasico’ ti yoo waye ni ojo kejidinlogbon osu kewaa. Ifarapa yìí yọ ọ́ kúrò nínú ikọ̀ tí yóò kojú orogún Real Madrid nínú ìfigagbága ‘Clasico’ tí yóò wáyé ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá. +Ousmane Dembele ropo Messi ni iseju meeedogbon ti idije naa beere leyin ti Dokita ti ye e wo tan leti ila latari ikolu oun Franco Vazquez omo iko Sevilla. Ousmane Dembele rọ́pò Messi ní ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí ìdíje náà bẹ̀ẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí Dókítà ti yẹ̀ ẹ́ wò tán létí ìlà látàrí ìkọlù òun Franco Vazquez ọmọ ikọ̀ Sevilla. +Ni afikun si ifigagbaga ‘Clasico’ Agbaboolu ti o ri awon he julo fun iko Barca yii ko tun ni si lori papa lojoruu (Wednesday) ninu idije UEFA Champions League ni ile won pelu iko Inter Milan. Ní àfikún sí ìfigagbága ‘Clasico’ Agbábọ́ọ̀lù tí o rí àwọn he jùlọ fún ikọ̀ Barca yìí kò tún ní sí lórí pápá lọ́jọ́rùú (Wednesday) nínú ìdíje UEFA Champions League ní ilé wọn pẹ̀lú ikọ̀ Inter Milan. +--- Mikel Obi gbosunba fun iko Eagles --- Mikel Obi gbósùnbà fún ikọ̀ Eagles +Balogun iko Super Eagles Mikel Obi ti gbosuba fun iko naa leyin iko naa gbo ewuro si iko Libya loju pelu ami ayo merin si odo ni ojo abameta (Saturday) ninu idije ipegede sinu ife eye ile Adulawo (AFCON) odun 2019 won ni ilu Uyo. Mikel ti ko si ninu idije naa latari ifarapa fun iko naa ki iko naa fun ipinnu won bakan naa Odion Ighalo akoni ojo naa to ri awon he leemeta. Balógun ikọ̀ Super Eagles Mikel Obi ti gbósùbà fún ikọ̀ náà lẹ́yìn ikọ̀ náà gbo ewúro sí ikọ̀ Libya lójú pẹ̀lú àmì ayò mẹ́rin sí òdo ní ọjọ́ àbámẹ́ta (Saturday) nínú ìdíje ìpegedé sínú ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ (AFCON) ọdún 2019 wọn ní ìlú Uyo. Mikel tí kò sí nínú ìdíje náà látàrí ìfarapa fún ikọ̀ náà ki ikọ̀ náà fún ìpinnu wọn bákan náà Odion Ighalo akọni ọjọ́ náà tó rí àwọn he lẹ́ẹ̀mẹta. +--- idije ipegede (AFCON) odun 2019: Ipago iko Eagles di sisi lonii. --- ìdíje ìpegedé (AFCON) ọdún 2019: Ìpàgọ ikọ̀ Eagles di ṣíṣí lónìí. +Ipago iko Super Eagles yoo di sisi pada lonii pelu bi Gernot Rohr se n reti okere tan agbaboolu merindinlogun lati bale si olu ilu ipinle Akwa Ibom lati lee beere igbaradi saaju ifigagbaga pataki idije ipegede sinu (AFCON) odun 2019 ti won ni pelu iko Libya lojo abameta (Saturday). Ìpàgọ́ ikọ̀ Super Eagles yóò di ṣíṣí padà lónìí pẹ̀lú bí Gernot Rohr ṣe ń retí okéré tán agbábọ́ọ̀lù mẹ́rìndínlógún láti balẹ̀ sí olú ìlú ìpínlẹ̀ Akwa Ibom láti leè bẹ̀ẹ̀rẹ̀ igbáradì ṣaájú ìfigagbága pàtàkì ìdíje ìpegedé sínú (AFCON) ọdún 2019 tí wọ́n ní pẹ̀lú ikọ̀ Libya lọ́jọ́ àbámẹ́ta (Saturday). +Awon ibeji iko Leicester City lorile-ede England Kelechi Iheanacho ati Wilfred Ndidi, ti o fi mo adieyinmu fun iko Udinese, William Troost-Ekong ni igbagbo wa pe won o lewaju awon agbaboolu metala miiran wa sinu ago iko Super Eagles lonii, awon alakooso lo fi idi eyi mule. Atamatase iko Watford, Isaac Success ti de si ilu Eko lanaa igbagbo si wa pe yoo te oko ofurufu leti lo taara si Uyo ki ojo to kanri. Àwọn ìbejì ikọ̀ Leicester City lórílẹ̀-èdè England Kelechi Iheanacho àti Wilfred Ndidi, tí ó fi mọ́ adiẹ̀yìnmú fún ikọ̀ Udinese, William Troost-Ekong ni ìgbàgbọ́ wà pé wọn ó léwájú àwọn agbábọ́ọ̀lù mẹ́tàlá mìíràn wá sínú àgọ́ ikọ̀ Super Eagles lónìí, àwọn alákòóso ló fi ìdí èyí múlẹ̀. Atamátàsé ikọ̀ Watford, Isaac Success ti dé sí ìlú Èkó lánàá ìgbàgbọ́ sì wà pé yóò tẹ ọkọ̀ ofurufú létí lọ tààrà sí Uyo kí ọjọ́ tó kanrí. +Adieyinmu iko Hapoel Beer Sheva orile-ede Israel, ti o ran iko re lowo lati fi opin si oda ijawe olubori ninu Liigi ile Israeli lojo abameta (Saturday) pelu ijawe olubori ami ayo merin si okan nile won pelu iko Maccabi Petach Tikva fi idi re mule pe oun yoo wo ago lonii. Adiẹ̀yìnmú ikọ̀ Hapoel Beer Sheva orílẹ̀-èdè Israel, tí ó ran ikọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ láti fi òpin sí ọ̀dá ìjáwé olúborí nínú Líìgì ilẹ̀ Israeli lọ́jọ́ àbámẹ́ta (Saturday) pẹ̀lú ìjáwé olúborí àmì ayò mẹ́rin sí ọ̀kan nílé wọn pẹ̀lú ikọ̀ Maccabi Petach Tikva fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun yóò wọ àgọ́ lónìí. +Lara awon ti won tun n reti ni ago Super Eagles ni awon agbaboolu bii Kenneth Omeruo, Leon Balogun, William Troost-Ekong, Shehu Abdullahi, Oghenekaro Etebo, Ahmed Musa, Moses Simon, Henry Onyekuru, Semi Ajayi, Ikechukwu Ezenwa ati Ola Aina. Lára àwọn tí wọ́n tún ń retí ní àgọ́ Super Eagles ni àwọn agbábọ́ọ̀lù bíi Kenneth Omeruo, Leon Balogun, William Troost-Ekong, Shehu Abdullahi, Oghenekaro Etebo, Ahmed Musa, Moses Simon, Henry Onyekuru, Semi Ajayi, Ikechukwu Ezenwa àti Ola Aina. +--- Rafael Nadal duro loke tente sibe lori ate ATP --- Rafael Nadal dúró lókè téńtè síbẹ̀ lórí àtẹ ATP +Rafael Nadal omo orile-ede Spain ti tesiwaju lati dipo asaaju mu lori ate Egbe awon Alayo Teniisi Agbaaye (ATP) ti awon okunrin ti won gbe jade ni ojo aje (Monday) pelu egbokanlelogoji ami saaju akeegbe re omo orile-ede Switzerland. Rafael Nadal ọmọ orílẹ̀-èdè Spain ti tẹ̀síwájú láti dipò aṣaájú mú lórí àtẹ Egbé àwọn Aláyò Tẹníìsì Àgbááyé (ATP) ti àwọn ọkùnrin tí wọ́n gbé jáde ní ọjọ́ ajẹ́ (Monday) pẹ̀lú ẹgbọ̀kànlélógójì àmì ṣaájú akẹẹgbẹ́ rẹ̀ ọmọ orìlẹ̀-èdè Switzerland. +--- Musa gba ami-eye agbaboolu ose ti o dara julo nile Saudi. --- Musa gba àmì-ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù ọ̀sẹ̀ tí ó dára jùlọ nílẹ̀ Saudi. +Agbaboolu egbe iko Super Eagles, Ahmed Musa ti gba ami-eye agbaboolu ti o dara julo ni abala keta Liigi apapo ile Saudi, CompletesportsNaijiiria.com lo jabo eleyii. Agbábọ́ọ̀lù ẹ̀gbẹ́ ikọ̀ Super Eagles, Ahmed Musa ti gba àmì-ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tí ó dára jùlọ ní abala kẹta Líìgì apapọ̀ ilẹ̀ Saudi, CompletesportsNàìjííríà.com ló jábọ eléyìí. +Agbaboolu iko Leicester City ati CSKA Moscow teleri ohun, tun gba egberun mewa Riyal owo ile Saudi ti i se okemejidinlaaadodalelegbaarunlelarundinlaaadota owo naira fun ise takun-takun re, gege bi ikani iko agbaboolu naa se fi lede. Agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Leicester City àti CSKA Moscow tẹ́lẹ̀rí ọ̀hún, tún gba ẹgbẹ̀rún mẹ́wà Riyal owó ilẹ̀ Saudi tí í ṣe ọ̀kẹ́méjìdínláàádọ́dalélẹ́gbààrúnlélárúndínláàádọ́ta owó náírà fún iṣe takun-takun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìkànì ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù náa ṣe fi léde. +Musa ti o n ta sansan lowo tun je eni ti gbogbo eniyan ri ise re fun iko Super Eagles ninu idije ipegede sinu ife eye ile Adulawo (AFCON) odun 2019 won pelu iko orile-ede Seychelles eyi ti o pari pelu ami ayo meta si odo. Musa tí ó ń ta sánsán lọ́wọ́ tún jẹ́ ẹni tí gbogbo ènìyàn rí iṣẹ́ rẹ̀ fún ikọ̀ Super Eagles nínú ìdíje ìpegedé sínú ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ (AFCON) ọdún 2019 wọn pẹ̀lú ikọ̀ orílẹ̀-èdè Seychelles èyí tí ó parí pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sí òdo. +--- idije AFCON awon oje wewe: Ajo NFF yoo fun Eaglets ni imurasile to monyanlori. --- ìdíje AFCON àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́: Àjọ NFF yóò fún Eaglets ní ìmúrasílẹ̀ tó mọ́nyánlórí. +Leyin ti won ti pegede lati iha iwo oorun ile Adulawo sinu idije ipegede sinu ife eye ile Adulawo awon oje wewe. Aare Ajo to n moju boolu Afesegba lorile-ede Naijiiria (NFF), Amaju Pinnick so pe iko Golden Eaglets yoo di fifun ni imurasile to monyanlori, ki won o le gba ife eye idije naa ni orile-ede Tanzania lodun to n bo. Lẹ́yìn tí wọn ti pegédé láti ìhà ìwọ̀ oorùn ilẹ̀ Adúláwọ̀ sínú ìdíje ìpegedé sínú ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́. Ààrẹ Àjọ tó ń mójú bọ́ọ̀lù Afẹsẹ̀gbá lórílẹ̀-èdè Nàìjííríà (NFF), Amaju Pinnick sọ pé ikọ̀ Golden Eaglets yóò di fífún ní ìmúrasílẹ̀ tó mọ́nyánlórí, kí wọn ó lè gba ife ẹ̀yẹ ìdíje náà ní orílẹ̀-èdè Tanzania lọ́dún tó ń bọ̀. +Iko Eaglets lu iko Ghana pelu ami ayo meta si okan pelu lale ojo abameta (Saturday) lati pegede. Ikọ̀ Eaglets lu ikọ̀ Ghana pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sí ọ̀kan pẹ̀lú lálẹ́ ọjọ́ àbámẹ́ta (Saturday) láti pegedé. +Samson Tijani ni o gba ami eye agbaboolu to ta sansan ju lo nigba ti Olakunle Olusegun gba ti eni ti o ri awon he julo pelu ami ayo merin. Samson Tijani ni ó gba àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó ta sánsán jù lọ nígbà tí Olakunle Olusegun gba ti ẹni tí ó rí àwọn he jùlọ pẹ̀lú àmì ayò mẹ́rin. +“Awon ti a ni bayii je awon agbaboolu ti won je odo loooto ti won si ni ojo iwaju to dara. “Àwọn tí a ní báyìí jẹ́ àwọn agbábọ́ọ̀lù tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ lóòótọ́ tí wọ́n sì ní ọjọ́ iwájú tó dára. +Ni ti awa ninu ajo wa, a ti fenu ko lati maa se won bi iko Super Eagles lati ipele yii. Ní ti àwa nínú àjọ wa, a ti fẹnu kò láti máa ṣe wọ́n bí ikọ̀ Super Eagles láti ìpele yìí. +A fe ki won ni ironu ati opolo to suwon gege bi won se n dagba. Bi a se pese iko Eagles fun idije ife eye agbaaye ni Russia bee naa ni a o pese won sile fun idije ni Tanzania. A fẹ́ kí wọ́n ní ìrònú àti ọpọlọ tó suwọ̀n gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Bí a ṣe pèsè ikọ̀ Eagles fún ìdije ife ẹ̀yẹ àgbááyé ní Russia bẹ́ẹ̀ náà ni a ó pèsè wọn sílẹ̀ fún ìdíje ní Tanzania. +A n wo tayo Tanzania pelu. À ń wò tayọ Tanzania pẹ̀lú. +A n wo ojo iwaju, akoko yii si ni a ni lati beere si to awon omo naa sona. À ń wo ọjọ́ iwájú, àkókò yìí sì ni a ní láti bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí tọ́ àwọn ọmọ náà sọ́nà. +O so pe iko Eaglets yoo rin irin ajo igbafe kaakiri ilu Qatar ati ilu Jordan ki won o to lo sinu idije ni Tanzania. Ó sọ pé ikọ̀ Eaglets yóò rin ìrìn àjò ìgbafẹ́ káàkiri ìlú Qatar àti ìlú Jordan kí wọ́n ó tó lọ sínú ìdíje ní Tanzania. +--- Eaglets lu iko Niger, won yoo koju iko Starlets Ghana ni asekagba --- Eaglets lu ikọ̀ Niger, wọn yóò kojú ikọ̀ Starlets Ghana ní aṣekágbá +Iko Naijiiria ni o jawe olubori pelu ami ayo meji si okan lori iko Niger ti o gbalejo won lojoru (Wednessday) lati lo kolu iko Ghana ti yoo tun ina orogun odun metadinlaaadorin da. Ikọ̀ Nàìjííríà ni ó jáwé olúborí pẹ̀lú àmì ayò méjì sí ọ̀kan lórí ikọ̀ Niger tí ó gbàlejò wọn lọ́jọ́ru (Wednessday) láti lọ kọlu ikọ̀ Ghana tí yóò tún iná orogún ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin dá. +Ijawe olubori yii tumo si pe iko Golden Eaglets yoo koju iko Black Starlets ni Niamey lojo abameta (Saturday) fun atiri aaye ninu idije ife eye ile Adulawo ti awon odo ti ojo ori won o ju metadinlogun lo ti won seto lati waye lorile-ede Tanzania. Ìjáwé olúborí yìí túmọ̀ sí pè ikọ̀ Golden Eaglets yóò kojú ikọ̀ Black Starlets ní Niamey lọ́jọ́ àbáméta (Saturday) fún àtirí ààyè nínú ìdìje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn ò ju mẹ́tàdínlógún lọ tí wọ́n ṣètò láti wáyé lórílẹ̀-èdè Tanzania. +Iko Eaglets mu ara gidi won si sise won bi ise pelu bi won se lu iko Niger Republic ti o gbalejo won pelu ami ayo meji si odo ninu ifigagbaga yii ti o gbona girigiri ni papa isere General Seyni Kountche. Ikọ̀ Eaglets mú ara gidi wọ́n sì ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ pẹ̀lú bí wọ́n ṣe lu ikọ̀ Niger Republic tí ó gbàlejò wọn pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo nínú ìfigagbaga yìí tí ó gbóná girigiri ní pápá ìṣeré General Seyni Kountche. +Won gba ami ayo meji wole ninu ipadanu alami ayo meji si meta pelu iko Burkina Faso ninu ifigagbaga iside won ki won o to dana iya fun iko Cote d’Ivoire pelu ami ayo marun-un si okan ni ose to koja. Wọ́n gbá àmì ayò méjì wọlé nínú ìpadánù alámì ayò méjì sí mẹta pẹ̀lú ikọ̀ Burkina Faso nínú ìfigagbága ìṣíde wọn kí wọ́n ó tó dáná ìyà fún ikọ̀ Cote d’Ivoire pẹ̀lú àmì ayò márùn-ún sí ọ̀kan ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá. +--- Weah pada wa lona to ya gbogbo agbaaye lenu ninu idije pelu Naijiiria......leni odun mokanlelaaadota! --- Weah padà wá lọ́nà tó ya gbogbo àgbááyé lẹ́nu nínú ìdíje pẹ̀lú Nàìjííríà……lẹ́ni ọdún mọ́kànléláàádọ́ta! +Aare orile-ede Liberia ati agbaboolu to ta sansan julo lagbaaye nigba kan ri George Weah pada sinu ifigagbaga agbaaye lona ti o yani lenu pupo ni ilu Monrovia lojo isegun (Tuesday), o gba boolu ninu ipadanu alami ayo meji si okan sowo iko Naijiiria. Ààrẹ orílẹ̀-èdè Liberia àti àgbábọ́ọ̀lù tó ta sánsán jùlọ lágbàáyé nígbà kan rí George Weah padà sínú ìfigagbága àgbááyé lọ́nà tí ó yani lẹ́nu púpọ̀ ní ìlú Monrovia lọ́jọ́ ìṣẹ́gun (Tuesday), ó gbá bọ́ọ̀lù nínú ìpádánù alámì ayò méjì sí ọ̀kan sọ́wọ́ ikọ̀ Nàìjííríà. +Idije yii wa leyin ose die ti o se ayeye ojo ibi odun mejilelaaadota ti orile-ede Liberia si seto idije naa lati fi eyin Weah, gbajugbaja alaso igbaboolu nomba erinla ti. Ìdíje yìí wá lẹ́yìn ọ̀ṣẹ̀ díẹ̀ tí ó ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún méjìléláàádọ́ta tí orílẹ̀-èdè Liberia sì ṣètò ìdíje náà láti fi ẹ̀yin Weah, gbajúgbajà aláṣọ ìgbábọ́ọ̀lù nọ́ḿbà ẹ̀rìnlá tì. +Bakan naa, awon alatileyin wa ni ipo iyalenu nigba ti won ri atamatase yii ti o tun gbe aso ganrun siwaju iko orile-ede naa wo ori papa leyin odun merindinlogun ti o ti fara han gbeyin. Bákan náà, àwọn alátìlẹyìn wà ní ipò ìyàlẹ́nu nígbà tí wọ́n rí atamátàsé yìí tí ó tún gbé aṣọ gánrùn ṣíwájú ikọ̀ orílẹ̀-èdè náà wọ orí pápá lẹ́yìn ọdún mẹ́rìndínlógún tí ó ti fara hàn gbẹ̀yìn. +Iroyin fi lede pe Weah, ti o gba owo iwaju patapata ti o si pitu repete iru eyi ti o so oruko re di tooro fon kale kaakiri agbaaye gba iduro kini lati odo awon alatileyin nigba ti won ropo re ni iseju kokandinlogodorin. Ìròyìn fi léde pé Weah, tí ó gbá ọwọ́ iwájú pátápátá tí ó sì pitú rẹpẹtẹ irú èyí tí ó sọ orúkọ rẹ̀ di tọ́ọ́rọ́ fọ́n kálé káàkiri àgbááyé gba ìdúró kíni láti ọ̀dọ̀ àwọn alátìlẹyìn nígbà tí wọ́n rọ́pò rẹ̀ ní ìṣẹ́jú kọkàndínlọ́gọ́dọ́rin. +Ami ayo lati owo Henry Onyekuru ati Simeon Nwankwo ni o ran orile-ede Naijiiria lowo lati lewaju pelu ami ayo meji si odo ki o to di pe iko ti o wa nile yii da okan pada pelu goli-wo-mi-n-gba-a-si-o lati Kpah Sherman ni owo ipari ayo naa. Àmì ayò láti ọwọ́ Henry Onyekuru àti Simeon Nwankwo ni ó ran órílẹ̀-èdè Nàìjííríà lọ́wọ́ láti léwájú pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo kí ó tó di pé ikọ̀ tí ó wà nílé yìí dá ọ̀kan padà pẹ̀lú gólì-wò-mí-n-gbá-a-sí-ọ láti Kpah Sherman ní ọwọ́ ìparí ayò náà. +Weah gbadun igbesi aye re ni ile Europe ti o feree lo to odun mewaa abo eyi ti o mu u kopa fun awon iko bii Monaco, Paris Saint-Germain ati Marseille ni orile-ede France, AC Milan ni orile-ede Italy. Weah gbádùn ìgbésí ayé rẹ̀ ní ilè Europe tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lò tó ọdún mẹ́wàá àbọ̀ èyí tí ó mú u kópa fún àwọn ikọ̀ bíi Monaco, Paris Saint-Germain àti Marseille ní orílẹ̀-èdè France, AC Milan ní orílẹ̀-èdè Italy. +O tun kopa fun iko ile Geesi Manchester City ati Chelsea. Ó tún kópa fún ikọ̀ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Manchester City àti Chelsea. +Weah ni o di kikede gege bi agbaboolu ti o ta sansan julo lagbaaye lodun 1995 bakan naa ni o gba ami eye Ballon d’Or ni odun yii kan naa oun si ni omo ile Adulawo kan soso ti o si gba awon ami eye mejeeji yii. Weah ní ó di kíkéde gẹ́gẹ́ bí agbábọ́ọ̀lù tí ó ta sánsán jùlọ lágbàáyé lọ́dún 1995 bákan náà ni ó gba àmì ẹ̀yẹ Ballon d’Or ní ọdún yìí kan náà òun sì ni ọmọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ kan ṣoṣo tí ó ṣì gba àwọn àmì ẹ̀yẹ́ méjéèjì yìí. +--- Hiddink je yiyan gege bi akonimoogba iko Olympic orile-ede China --- Hiddink jẹ́ yíyàn gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ Olympic orílẹ̀-èdè China +Guus Hiddink ti di fifun ni ojuse lati ri i pe iko China pegede si asekagba idije Olympic odun 2020 leyin ti won fa iko odo ti ojo ori won ko ju mokanlelogun lo le akonimoogba iko Real Madrid ati iko orile-ede Netherlands teleri ohun lowo lojo aje (Monday). Guus Hiddink ti di fífún ní ojúṣe láti rí i pé ikọ̀ China pegedé sí àṣekágbá ìdíje Olympic ọdún 2020 lẹ́yìn tí wọ́n fa ikọ̀ ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn kò ju mọ́kànlélógún lọ lé akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Real Madrid àti ikọ̀ orílẹ̀-èdè Netherlands tẹ́lẹ̀rí ọ̀hún lọ́wọ́ lọ́jọ́ ajé (Monday). +Hiddink, eni okanlelaaladorin odun, ni akonimoogba nla ti o tuntun ju ti yoo koja si orile-ede China lati igba ti aare orile-ede naa, Xi Jinping, ti fi ife han lati so orile-ede naa di ile agbara ere boolu agbaaye. Hiddink, ẹni ọ̀kànléláàládọ́rin ọdún, ni akọ́nimọ̀ọ́gbá ńlá tí ó tuntun jù tí yóò kọjá sí orílẹ̀-èdè China láti ìgbà tí ààrẹ orílẹ̀-èdè náà, Xi Jinping, ti fi ìfẹ́ hàn láti sọ orílẹ̀-èdè náà di ilè agbára eré bọ́ọ̀lù àgbááyé. +Omo orile-ede Neitherland yii dara po mo akeegbere ti o ti gba ife eye ni ile Europe ri iyen Marcello Lippi lori ate isanwo ajo CFA, pelu bi akonimoogba ti o ko iko Italy gba ife eye agbaaye yii n tire se n pese iko agba ile naa sile lowolowo fun asekagba idije Ife ile Asia ti yoo waye ni United Arab Emirates ni inu osu kinni. Ọmọ orílẹ̀-èdè Neitherland yìí dara pọ̀ mọ́ akẹẹgbẹ́rẹ̀ tí ó ti gba ife ẹ̀yẹ ní ilẹ̀ Europe rí ìyẹn Marcello Lippi lórí àtẹ ìsanwó àjọ CFA, pẹ̀lú bí akọ́nimọ̀ọ́gbá tí ó kó ikọ̀ Italy gba ife ẹ̀yẹ àgbááyé yìí ń tirẹ̀ ṣe ń pèsè ikọ̀ àgbà ilẹ̀ náà sílẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ fún àṣekágbá ìdíje Ife ilẹ̀ Asia tí yóò wáyé ní United Arab Emirates ní inú oṣù kínní. +Awon akonimoogba nlanla bii Luiz Felipe Scolari, Fabio Capello, Manuel Pellegrini ati Andre Villas Boas pelu ti ni nnkan se pelu awon egbe agbaboolu ninu idije Chinese Super League. Àwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá ńláńlá bíi Luiz Felipe Scolari, Fabio Capello, Manuel Pellegrini àti Andre Villas Boas pẹ̀lú ti ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù nínú ìdíje Chinese Super League. +--- AWON AWORAN: Iko Super Eagles n ya oorun ile Seychelles’ --- ÀWỌN ÀWÒRÁN: Ikọ̀ Super Eagles ń yá òòrùn ilẹ̀ Seychelles’ +Iko Super Eagles ti setan lati koju iko Seychelles ninu idije kaka-keku-o –je-ese ti yoo waye ni ilu Victoria ni ojo abameta (Saturday). Ikọ̀ Super Eagles ti ṣetán láti kojú ikọ̀ Seychelles nínú ìdíje kàkà-kéku-ó –jẹ-èsé tí yóò wáyé ní ìlú Victoria ní ọjọ́ àbámẹ́ta (Saturday). +Pelu bi ile se kun fofo, iko Naijiiria ti n gbadun oorun aran yee ti o gba ori erekusu yii kan Pẹ̀lú bí ilé ṣe kún fọ́fọ́, ikọ̀ Nàìjííríà tí ń gbádùn oor̀un àràn yẹ́ẹ́ tí ó gba orí erékùsù yìí kan +--- LIIGI UEFA NATION: France ta omi odo si odo pelu Germany --- LÍÌGÌ UEFA NATION: France ta ọ̀mị̀ òdo sí òdo pẹ̀lú Germany +France ti ife eye agbaaye wa lowo re ko bode pade o si nilo lati dupe lowo asole keta won Alphonse Areola fun omi odo si odo ti won gba pelu Germany ninu ifesewonse idije Liigi UEFA Nations lole lojobo (Thursday), akoko iru e lati igba ti won ti gbe igba oro ife eye agbaaye soke. France tí ife ẹ̀yẹ́ àgbááyé wà lọ́wọ́ rẹ̀ kò bóde pàdé ó sì nílò láti dúpẹ́ lọ́wọ́ aṣọ́lé kẹta wọn Alphonse Areola fún ọ̀mị̀ òdo sí òdo tí wọ́n gbá pẹ̀lú Germany nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìdíje Líìgì UEFA Nations lọ́lẹ̀ lọ́jọ́bọ (Thursday), àkọ́kọ́ irú ẹ̀ láti ìgbà tí wọ́n ti gbé igbá oró ife ẹ̀yẹ agbááyé sókè. +Ni inu ojo lale ojo yii, iko Germany tun iyi won ra pada leyin ijakuro lati abala akoko ninu idije ife eye agbaaye ti o yani lenu gbaa ni orile-ede Russia, eyi ti o yara ju ninu idije naa lati bi ogorin odun seyin. Ní inú òjò lálẹ́ ọjọ́ yìí, ikọ̀ Germany tún iyì wọn rà padà lẹ́yìn ìjákúrò láti abala àkọ́kọ́ nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ́ àgbááyé tí ó yani lẹ́nu gbáà ní orílẹ̀-èdè Russia, èyí tí ó yára jù nínú ìdíje náà láti bí ọgọ́rin ọdún sẹ́yìn. +“O je idije ti o gbona girigiri pelu bi a se n fakoyo ju won lo ti awon naa si n fakoyo ju wa lo nigba miiran.,” ni Didier Deschamps akonimoogba iko France wi. “Ó jẹ́ ìdíje tí ó gbóná girigiri pẹ̀lú bí a ṣe ń fakọyọ jù wọ́n lọ tí àwọn náà sì ń fakọyọ jù wá lọ nígbà mìíràn.,” ni Didier Deschamps akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ France wí. +--- idije AFCON awon oje weewe: iko Eaglets foju sun ijawe olubori lori iko Burkina Faso --- ìdíje AFCON àwọn ọjẹ wẹ́ẹ́wẹ́: ikọ̀ Eaglets fojú sun ìjáwé olúbori lórí ikọ̀ Burkina Faso +Mohammed Sanusi, akowe apapo ajo ti o n moju to boolu afesegba lorile-ede Naijiiria (NFF), ni ojo aiku (Sunday) fi idaniloju re han pe iko Golden Eaglets yoo na iko Burkina Faso ni ola. Mohammed Sanusi, akọ̀wé àpapọ̀ àjọ tí ó ń mójú tó bọ́ọ̀lù afẹsẹ̀gbá lórílẹ̀-èdè Nàìjííríà (NFF), ní ọjọ́ àìkú (Sunday) fi ìdánilójú rẹ̀ hàn pé ikọ̀ Golden Eaglets yóò na ikọ̀ Burkina Faso ní ọ̀la. +Idije ipegede Ajo ti o mojuto boolu afesegba ni iha iwo oorun ile Adulawo (WAFU) ti awon odo ti ojo ori won o ju metadinlogun ipin B yoo beere ni orile-ede Niger Republic lojo aje (Monday) Ìdíje ìpegedé Àjọ tí ó mójútó bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀ (WAFU) ti àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn ò ju mẹ́tàdínlógún ìpín B yóò bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Niger Republic lọ́jọ́ ajé (Monday) +Sanusi so pe iko ti Manu Garba ko sodi yii danto, won si setan atibi iko yoowu ti o je alatako won ni iha iwo oorun ile Adulawo wo. Sanusi sọ pé ikọ̀ tí Manu Garba kó ṣòdí yìí dáńtọ́, wọ́n sì ṣetán àtibi ikọ̀ yóòwù tí ó jẹ́ alátakò wọn ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀ wó. +O ni awon ti setan lati da ogo ere boolu iko awon odo orile-ede Naijiiria ti ojo ori won o ju metadinlogun pada lagbaaye. Ó ní àwọn ti ṣetán láti dá ògo eré bọ́ọ̀lù ikọ̀ àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà tí ọjọ́ orí wọn ò ju mẹ́tàdínlógún padà lágbàáyé. +“A nilo lati kun fun adura, ni ti ogbon awon omo wa ni ogbon lori sugbon a nilo idasi Olorun,” eyi ni osise ijoba apapo yii wi. “A nílò láti kún fún àdúrà, ní ti ọgbọ́n àwọn ọmọ wa ní ọgbọ́n lórí ṣùgbọ́n a nílò ìdásí Ọlọ́run,” èyí ni òsìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ yìí wí. +Iko awon odo ti ojo ori won o ju metadinlogun ti orile-ede Naijiiria yoo koju iko meji latari yiyo iko Benin Republic danu. Ikọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn ò ju mẹ́tàdínlógún ti orílẹ̀-èdè Nàìjííríà yóò kojú ikọ̀ méjì látàrí yíyọ ikọ̀ Benin Republic dànù. +Mewaa ninu ogun awon agbaboolu iko Benin Republic ni won ko pegede pelu idanwo ayewo inu ara (MRI), eyi ti won fi yo iko naa danu bi eni yo jiga. Mẹ́wàá nínú ogún àwọn agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Benin Republic ni wọn kò pegedé pẹ̀lú ìdánwò àyẹ̀wò inú ara (MRI), èyí tí wọ́n fi yọ ikọ̀ náà dànù bí ẹni yọ jìgá. +Ni bayii iko Cote d’ Voire ati iko Burkina Faso nikan ni yo ku iko Naijiiria ku ninu ipin won. Ní báyìí ikọ̀ Cote d’ Voire àti ikọ̀ Burkina Faso nìkan ni yó ku ikọ̀ Nàìjííríà kù nínú ìpín wọn. +Iko Golden Eaglets bakan naa yoo maa waako lojo Aje (Monday) laago merin osan aago abele pelu iko Burkina Faso. Ikọ̀ Golden Eaglets bákan náà yóò máa wàákò lọ́jọ́ Ajé (Monday) láago mẹ́rin ọ̀sán aago abẹ́lé pẹ̀lú ikọ̀ Burkina Faso. +Idije ipegede (WAFU) yii je ipegede fun ife eye ile Adulawo (AFCON) awon odo ti ojo ori won o ju metadinlogun ti yoo waye ni orile-ede Tanzania eyi ti o tun je osuwon ipegede si idije ife eye agbaaye awon odo ti ojo ori won o ju metadinlogun eyi ti yoo waye ni orile-ede Peru lodun 2019. Ìdíje ìpegedé (WAFU) yìí jẹ́ ìpegedé fún ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Adúláwọ̀ (AFCON) àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn ò ju mẹ́tàdínlógún tí yóò wáyé ní orílẹ̀-èdè Tanzania èyí tí ó tún jẹ́ òsùwọ̀n ìpegedé sí ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbááyé àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn ò ju mẹ́tàdínlógún èyí tí yóò wáyé ní orílẹ̀-èdè Peru lọ́dún 2019. +--- Iko Naijiiria gbera lo si Idije Ajemayoteniisi agbaaye. --- Ikọ̀ Nàìjííríà gbéra lọ sí Idíje Ajẹmáyòtẹníísì àgbááyé. +Iko ti o soju Naijiiria nibi Idije Ajemayoteniisi kuro ni Eko lo si ibi idije Ajemayoteniisi agbaaye ni ilu Beijing. Ikọ̀ tí ó sojú Nàìjííríà níbi Idíjẹ Ajẹmáyòtẹníísì kúrò ní Èkó lọ sí ibi ìdíje Ajẹmáyòtẹníísì àgbááyé ní ìlú Beijing. +Iko yii ti o ni obinrin kan ati okunrin meta gbera kuro lorile-ede pelu oko ofurufu Ethiopian Ikọ̀ yìí tí ó ní obìnrin kan àti ọkùnrin mẹ́ta gbéra kúrò lórílẹ̀-èdè pẹ̀lú ọkọ̀ òfurufú Ethiopian +Obinrin kan soso yii ni Faith Obazuaye, nigba ti awon okunrin akeegbe re je Nasiru Bello, Tajudeen Agunbiade ati Olufemi Alabi. Obìnrin kan ṣoṣo yìí ni Faith Obazuaye, nígbà tí àwọn ọkùnrin akẹẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ Nasiru Bello, Tajudeen Agunbiade àti Olufemi Alabi. +Idije yii yoo beere ni ojo ketadinlogbon osu kejo yoo si pari ni ojo keta osu kesan-an. Ìdíje yìí yóò bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ yóò sì parí ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹsàn-án. +Bankole, nigba ti o n soro ki won to gbera, so pe awon alayo yii ti mura gidigidi fun ise ti o wa niwaju won. Bankole, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ kí wọ́n tó gbéra, so pé àwọn aláyò yìí ti múra gidigidi fún iṣẹ́ tí ó wà níwájú wọn. +“A nigbagbo ninu won ati ohun ti won le se, mo si ni igbagbo pe won yoo mu orile-ede wa yangan. Ki awon pelu fi ara bale gba gbogbo ayo naa pelu afojusun. “A nígbàgbọ́ nínú wọn àti ohun tí wọ́n lè ṣe, mo sì ní ìgbàgbọ́ pé wọn yóò mú orílẹ̀-èdè wa yangàn. Kí àwọn pẹ̀lú fi ara balẹ̀ gbá gbogbo ayò náà pẹ̀lú àfojúsùn. +Bankole, ti o je Komisanna Olopaa, bakan naa parowa si awon omo orile-ede Naijiiria ti won n gbe ni orile-ede China lati wa wu awon olufokansin wonyi lori. Bankole, tí ó jẹ́ Kọmíṣánnà Ọlọ́pàá, bákan náà pàrọwà sí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà tí wọ́n ń gbé ní orílẹ̀-èdè China láti wá wú àwọn olùfọkànsìn wọ̀nyí lórí. +--- Ma a rii pe mo duro pe ninu iko City – Kompany --- Mà á ríi pé mo dúró pé nínú ikọ̀ City – Kompany +Balogun iko Manchester City Vincent Kompany so pe abuda adamo oun lati maa se daadaa le mu ki oun o fa ojo oun gun ninu iko asaaju idije Premier League ile Geesi naa. Balógun ikọ̀ Manchester City Vincent Kompany sọ pé àbùdá àdámọ́ òun láti máa ṣe dáadáa le mú kí òun ó fa ọjọ́ òun gùn nínú ikọ̀ aṣaájú ìdíje Premier League ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà. +Omo odun mejilelogbon adieyinmu iko agbaboolu Belgium yii ti gbiyanju lopo lati jaja bo lowo orisiirisii ifarapa lati nnkan bi odun mewaa ti o ti wa ninu iko naa.. Ọmọ ọdún méjìlélọ́gbọ̀n adiẹ̀yìnmú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Belgium yìí ti gbìyànjú lọ́pọ̀ láti jàjà bọ́ lọ́wọ́ oríṣìíríṣìí ìfarapa láti nǹkan bí ọdún mẹ́wàá tí ó ti wà nínú ikọ̀ náà.. +“Mo woye pe ohun ti awon eniyan o tii fi taratara mo nipa mi ni pe yato si nini awon ifarapa, mo ri oore-ofe jije alabuda adamo ere sisa gba. “Mo wòye pé ohun tí àwọn ènìyàn ò tíì fi taratara mọ̀ nípa mi ni pé yàtọ̀ sí níní àwọn ìfarapa, mó rí oore-ọ̀fẹ́ jíjẹ́ alábùdá àdámọ́ eré sísá gbà. +“Nitori naa, ere si si wa lese mi,” Kompany, ti adehun re yoo tenu bepo ni saa to n bo lo so fun ikanni ayelujara iko agbaboolu naa. “Nítorí náà, eré ṣì ṣì wà lẹ́sẹ̀ mi,” Kompany, tí àdéhùn rẹ̀ yóò tẹnu bẹpo ní sáà tó ń bọ̀ ló sọ fún ìkànnì àyélujára ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù náà. +Kompany je gbigbe wole ninu ijawe olubori ami ayo meji si odo pelu iko Arsenal ninu idije akoko won, sugbon o beere pelu iko ti o fiya je iko Huddersfield Town pelu ami ayo mefa si okan ni opin ose to koja. Kompany jẹ́ gbígbé wọlé nínú ìjáwé olúborí àmì ayò méjì sí òdo pẹ̀lú ikọ̀ Arsenal nínú ìdíje àkọ́kọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó bẹ̀ẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ikọ̀ tí ó fìyà jẹ ikọ̀ Huddersfield Town pẹ̀lú àmì ayò mẹ́fà sí ọ̀kan ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá. +--- Ayo Hockey: Idije Liigi odun 2018 yoo beere lo abameta (Saturday) --- Ayò Hockey: Ìdíje Líìgì ọdún 2018 yóò bẹ̀ẹ̀rẹ̀ lọ́ àbámẹ́ta (Saturday) +Fatai Atanda, omo egbe igbimo imo ero ajo to n moju to idije Hocky lorile-ede Naijiiria (NHF), so ni ojobo (Thursday) pe Liigi ayo Hockey ti odun 2018 yoo beere ni ojo abameta (Saturday) ni papa isere ijoba apapo, Abuja. Fatai Atanda, ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ ìmọ̀ ẹ̀rọ àjọ tó ń mójú tó ìdíje Hocky lórílẹ̀-èdè Nàìjííríà (NHF), sọ ní ọjọ́bọ (Thursday) pé Líìgì ayò Hockey ti ọdún 2018 yóò bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ àbámẹ́ta (Saturday) ní pápá ìṣeré ìjọba àpapọ̀, Abuja. +Atanda so pe ipin merin ni won yoo pin idije naa si, o si so pe iko merindinlogun iko okunrin mejo ati obinrin mejo ni yoo kopa. Atanda sọ pé ìpín mẹ́rin ni wọn yóò pín ìdíje náà sí, ó sì sọ pé ikọ̀ mẹ́rìndínlógún ikọ̀ ọkùnrin mẹ́jọ àti obìnrin mẹ́jọ ni yóò kópa. +Lodun to koja, Kada Queens ilu Kaduna ni o gbe ife ti awon obinrin lo ile nigba ti Niger Flickers gba ti awon okunrin. Lọ́dún tó kọjá, Kada Queens ìlú Kaduna ni ó gbé ife ti àwọn obìnrin lọ ilé nígbà tí Niger Flickers gba ti àwọn ọkùnrin. +Idije yii wa ni ibamu pelu alakale ajo yii lati te ayo hockey siwaju lorile-ede Naijiiria, paapaa julo laarin awon odo lati le se alekun ise owo. Ìdíje yìí wà ní ìbámu pẹ̀lú àlàkalẹ̀ àjọ yìí láti tẹ ayò hockey síwájú lórílẹ̀-èdè Nàìjííríà, pàápàá jùlọ láàrin àwọn ọ̀dọ́ láti lè ṣe àlékún iṣẹ́ ọwọ́. +--- Iko Falconets le lu iko Spain – Garba Manu --- Ikọ̀ Falconets lè lu ikọ̀ Spain – Garba Manu +Akonimoogba iko Golden Eaglet Manu Garba so pe o da oun loju pe Iko Falconets ni agbara ati lu akeegbe won lati orile-ede Spain ninu ifigagbaga ipele keji si asekagba ife eye agbaaye awon odobinrin ti ojo ori won ko ju ogun odun lo ni ilu France. Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Golden Eaglet Manu Garba sọ pé ó dá òun lójú pé Ikọ̀ Falconets ní agbára àti lu akẹẹgbẹ́ wọn láti orílẹ̀-èdè Spain nínú ìfigagbága ìpele kejì sí àṣekágbá ife ẹ̀yẹ àgbááyé àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí ọjọ́ orí wọn kò ju ogún ọdún lọ ní ìlú France. +Garba, ti o fi aridaju yii han ni ilu Abuja, so pe iko Falconets ti se ise, won si ti pinnu lati le je ki ogo ife eye agbaaye yii je tiwon. Garba, tí ó fi àrídájú yìí hàn ní ìlú Abuja, sọ pé ikọ̀ Falconets ti ṣe iṣẹ́, wọ́n sì ti pinnu láti lè jẹ́ kí ògo ife ẹ̀yẹ àgbááyé yìí jẹ́ tiwọn. +“Iko Falconets ti sise takuntakun lati mura sile fun idije asekagba ife eye agbaaye awon odobinrin ti ojo ori won ko ju ogun odun lo. “Ikọ̀ Falconets ti ṣiṣẹ́ takuntakun láti múra sílẹ̀ fún ìdíje àṣekágbá ife ẹ̀yẹ àgbááyé àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí ọjọ́ orí wọn kò ju ogún ọdún lọ. +“ipele keji si asekagba je ipele ti a ti n jara eni bo, o si seese lati na iko Spain ti awon omobinrin wa ba le mu aleku ba isowowole lowo iwaju won, ni Garba wi. “ìpele kejì sí àṣekágbá jẹ̀ ìpele tí a ti ń jára ẹni bọ́, ó sì ṣeéṣe láti na ikọ̀ Spain tí àwọn ọmọbìnrin wa bá le mú àlékú bá ìṣọwọ́wọlé lọ́wọ́ iwájú wọn, ni Garba wí. +Akonimoogba yii fi atileyin orile-ede yii da iko Falconets loju, o so pe awon omo Naijiiria wa leyin won. Akọ́nimọ̀ọ́gbá yìí fi àtìlẹyìn orílẹ̀-èdè yìí dá ikọ̀ Falconets lójú, ó sọ pé àwọn ọmọ Nàìjííríà wà lẹ́yìn wọn. +O so pe iko yii pelu iranlowo Olorun ati ise takuntakun yoo pegede si ipele ti o kangun si asekagba. Ó sọ pé ikọ̀ yìí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run àti iṣẹ́ takuntakun yóò pegedé sí ipele tí ó kángun sí àṣekágbá. +Iko Falconets lojo aje (Monday) ta omi ami ayo kookan pelu iko orile-ede China lati pegede si ipele keji si asekagba. Ikọ̀ Falconets lọ́jọ́ ajé (Monday) ta ọmì àmì ayò kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ikọ̀ orílẹ̀-èdè China láti pegedé sí ìpele kejì sí àṣekágbá. +--- Ipe fun isonigbowo ti je fifi sita fun awon ere idaraya lorile-ede Naijiiria. --- Ìpè fún ìṣonígbọ̀wọ́ ti jẹ́ fífi síta fún àwọn eré ìdárayá lórílẹ̀-èdè Nàìjííríà. +Awon ile ise ati awon eniyan ti won lagbara lati nawo le ori ere-idaraya ni orile-ede Naijiiria ti je riro fun isonigbowo. Àwọn ilé iṣẹ́ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n lágbára láti náwó lé orí eré-ìdárayá ní orílẹ̀-èdè Nàìjííríà ti jẹ́ rírọ̀ fún ìṣonígbọ̀wọ́. +Ogbeni Bukola Olapade, okan ninu awon omo igbimo ti o n ri si awon idije ori papa ni ile Adulawo, eyi ti won n pe ni African Athelethics Championship ti odun 2018 ti o waye ni ilu Asaba, ipinle Delta state ni o so eyi lasiko ti o n ba awon oniroyin soro ni ilu Asaba, Ogbeni Olapade ni bayii wa lo ise rere ile-ise Rite foods limited gege bi apeere lori bi won se pese ohun jije ati ohun mimu fun awon oludije. Ọ̀gbẹ́ni Bukola Olapade, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tí ó ń rí sí àwọn ìdíje orí pápá ní ilẹ̀ Adúláwọ̀, èyí tí wọ́n ń pè ní African Athelethics Championship ti ọdún 2018 tí ó wáyé ní ilú Asaba, ìpínlẹ̀ Delta state ni ó sọ èyí lásìkò tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọrọ̀ ní ìlú Asaba, Ọ̀gbẹ́ni Olapade ní báyìí wá lo iṣẹ́ rere ilé-iṣẹ́ Rite foods limited gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ lórí bí wọ́n ṣe pèsè ohun jíjẹ àti ohun mímu fún àwọn olùdíje. +Nigba ti a fi isonigbowo lo won, lesekese ni won fi ife han si i, won si kopa dele ninu isonigbowo idije ori papa naa. Nígbà tí a fi ìṣonígbọ̀wọ́ lọ̀ wọ́n, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n fi ìfẹ́ hàn sí i, wọ́n sì kópa délẹ̀ nínú ìṣonígbọ̀wọ́ ìdíje orí pápá náà. +Ogbeni Olapade tun salaye siwaju si i pe nibi idije naa opo awon eniyan ti won wa nibi ayeye iside ni won pese ohun jije ati ohun mimu lati odo Rites foods fun, bee ni won pese elerindodo ati ipanu fun awon omo keekeeke nibi idije naa. Ọ̀gbẹ́ni Olapade tún ṣàlàyé síwájú sí i pé níbi ìdíje náà ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n wà níbi ayẹyẹ ìṣíde ní wọ́n pèsè ohun jíjẹ àti ohun mímu láti ọ̀dọ̀ Rites foods fún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n pèsè ẹlẹ́rìndòdò àti ìpanu fún àwọn ọmọ kéékèèké níbi ìdíje náà. +Olubewo agba fun ile-ise Rite Foods Ltd, Ogbeni Saleem Adegunwa fi idi re mule pe ile-ise naa n gbiyaju gbogbo ipa re lati satileyin ohun ti yoo gbe ogo Naijiiria jade. Olùbẹ̀wọ̀ àgbà fún ilé-iṣẹ́ Rite Foods Ltd, Ọ̀gbẹ́ni Saleem Adegunwa fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ilé-iṣẹ́ náà ń gbìyàjú gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣàtìlẹyìn ohun tí yóò gbé ògo Nàìjííríà jáde. +‘A nigbagbo pe awon eniyan wa le da awon ara oto pelu ebun won, atileyin wa orisirisi, isonigbowo, isatileyin pelu ilu, ati awon ohun miiran. ‘A nígbàgbọ́ pé àwọn ènìyàn wa lè dá àwọn àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú ẹ̀bùn wọn, àtìlẹ́yìn wa oríṣiríṣi, ìṣonígbọ̀wọ́, ìṣàtìlẹyìn pẹ̀lú ìlù, àti àwọn ohun mìíràn. +O so o di mimo. Ó sọ ọ́ di mímọ̀. +Ogbeni Adegunwa so pe ile-ise Rite foods ti na nnkan bi ogbon milionu naira (N30 million) lori ohun jije ati ohun mimu ti won pese fun awon alayo wonyi eyi ti o so pe awon se gege bi atileyin fun ere idaraya ni orile-ede Naijiiria ati ile Adulawo lapapo. Ọ̀gbẹ́ni Adegunwa sọ pé ilé-iṣẹ́ Rite foods ti ná nǹkan bí ọgbọ̀n mílíọ́nù náírà (N30 million) lórí ohun jíjẹ àti ohun mímu tí wọ́n pèsè fún àwọn aláyò wọ̀nyí ẹ̀yí tí ó sọ pé àwọn ṣe gẹ́gẹ́ bí àtìlẹyìn fún eré ìdárayá ní orílẹ̀-èdè Nàìjííríà àti ilẹ̀ Adúláwọ̀ lápapọ̀. +Olubewo agba fun ile-ise yii fi da wa loju pe, loooto ni idije yii n wa si opin ni oju aiku (Sunday), sugbon ile-ise Rite foods yoo tesiwaju akitiyan re lati maa satileyin idije naa. O so pe idi pataki atileyin ile-ise Rite Foods fun idije yii ni ilu Asaba lodun 2018 ni lati pese ohun jije fun awon ajawe olubori. Olùbẹ̀wọ̀ àgbà fún ilé-iṣẹ́ yìí fi dá wa lójú pé, lóòótọ́ ni ìdíje yìí ń wá sí òpin ní ọjụ́ àìkú (Sunday), ṣùgbọ́n ilé-iṣẹ́ Rite foods yóò tẹ̀síwájú akitiyan rẹ̀ láti máa ṣàtìlẹyìn ìdíje náà. Ó sọ pé ìdí pàtàkì àtìlẹyìn ilé-iṣẹ́ Rite Foods fún ìdíje yìí ni ìlú Àsaba lọ́dún 2018 ni láti pèsè ohun jíjẹ fún àwọn ajáwé olúborí. +O so pe awon ohun jije yii yoo so okun won dotun bi won tun se n dije si i. Ó sọ pé àwọn ohun jíjẹ yìí yóò sọ okun wọn dọ̀tun bí wọ́n tún ṣe ń díje sí i. +--- E se o – Ta Lou relishes ijawe olubori Asaba, o du pe lowo awon alatileyin --- E ṣé o – Ta Lou relishes ìjáwé olúborí Asaba, ó dú pé lọ́wọ́ àwọn alátilẹyìn +Latari ijawe olubori re ninu idije ologorun mita ni asekagba idije awon Agba Asare ori papa ile Adulawo odun 2018 ni ilu Asaba, Gbajugbaja elese ehoro omo ile Ivory coast Ta Lou Marie Josee‏ ti fi emi imoore re han fun atileyin nla lati odo awon ololufe ere idaraya lorile-ede. Látàrí ìjáwé olúborí rẹ̀ nínú ìdíje ọlọ́gọ́rùn mítà ní àṣekágbá ìdíje àwọn Àgbà Asáré orí pápá ilẹ̀ Adúláwọ̀ ọdún 2018 ní ìlú Asaba, Gbajúgbajà ẹlẹ́ṣẹ̀ ehoro ọmọ ilẹ̀ Ivory coast Ta Lou Marie Josée‏ ti fi ẹ̀mí ìmoore rẹ̀ hàn fún àtilẹ́yìn ńlá láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ eré ìdárayá lórílẹ̀-èdè. +Marie Josee Ta Lou lojobo (Thursday) gba ami eye wura idije naa pelu ere iseju aaya mokanla-le-iseju-ina-meeedogun 11.15 ti o fi na Janet Amponsah omo orile-ede Ghana ti o sa tire ni iseju aaya mejila-din- iseju-ina-mefa 11.54 seconds; nigba ti odomodebinrin omo Naijiiria Udo Joy-Gabriel pari tire pelu iseju aaya mejila-din- iseju-ina-meji Marie Josee Ta Lou lọ́jọ́bọ (Thursday) gba àmì ẹyẹ wúrà ìdíje náà pẹ̀lú eré ìṣẹ́jú àáyá mọ́kànlá-lé-ìṣẹ́jú-iná-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún 11.15 tí ó fi na Janet Amponsah ọmọ orílẹ̀-èdè Ghana tí ó sá tirẹ̀ ní ìṣẹ́jú àáyá méjìlá-dín- ìṣẹ́jú-iná-mẹ́fa 11.54 seconds; nígbà tí ọ̀dọ́mọdebìnrin ọmọ Nàìjííríà Udo Joy-Gabriel pári tirẹ̀ pẹ̀lú ìṣẹ́jú àáyá méjìlá-dín- ìṣẹ́jú-iná-méjì +Pelu bi o se ti gba ami eye idije ologorun mita sapo re, Ta Lou yoo gbiyaju lati mu igberu ba ikopa ipo re lagbaaye nipa kikopa daradara ninu idije IAAF ti yoo waye laipe yii. Pẹ̀lú bí ó se ti gba àmì ẹ̀yẹ ìdíje ọlọ́gọ́rùn mítà sápò rẹ̀, Ta Lou yóò gbìyàjú láti mú ìgbèrú bá ìkópa ipò rẹ̀ lágbàáyé nípa kíkópa dáradára nínú ìdíje IAAF tí yóò wáyé láìpẹ́ yìí. +--- Akanda eda onijo gba awon omo orile-ede Kenya niyanju. --- Àkàndá ẹ̀dá oníjó gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Kenya níyànjú. +Ajo Eleto Ilera Agbaaye ti so pe o le ni okanlelogorin milionu awon omo ile Adulawo ti o je Akanda, beeni opo ninu won si n foju wina irewesi okan ati ikoriira, leyii ti o n se akoba fun anfaani won lati kopa ninu eto eko, ise ati igbayegbadun. Àjọ Elétò Ilera Àgbááyé ti sọ pé ó lé ní ọ̀kànlélọ́gọ́rin mílíọ̀nù àwọn ọmọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí ó jẹ́ Àkàndá, bẹ́ẹ̀ni ọ̀pọ̀ nínú wọn sì ń fojú winá ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn àti ìkórìíra, léyìí tí ó ń ṣe àkóbá fún àǹfààní wọn láti kópa nínú ètò ẹ̀kọ́, iṣẹ́ àti ìgbáyégbádùn. +Fun eniyan lati jo loju ofurufu je okan lara awon ijo ti o wopo laaarin awon akanda lorile-ede Kenya. Fún ènìyàn láti jó lójú ofurufú jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ijó tí ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn àkàndá lórílẹ̀-ède Kenya. +Nicholas Ouma Odhiambo so pe iko yii fun ohun ni oore-ofe lati le kopa ninu idije ijo jijo naa Nicholas Ouma Odhiambo sọ pé ikọ̀ yìí fún òhun ní oore-ọ̀fẹ́ láti lè kópa nínú ìdíje ijó jíjó náà +--- Idi ti mo fi gba ise iko Juventus – Ronaldo --- Ìdí tí mo fi gba iṣẹ́ ikọ̀ Juventus – Ronaldo +Atamatase iko orile-ede Portugal Christiano Ronaldo so pe oun dara po mo ogbohuntarigi iko orile-ede Italy tori pe oun fe ran iko 'old lady' ohun lowo lati tubo maa gba ife eye si i paapaa julo ife eye UEFA Champions League. Atamátàsé ikọ̀ orílẹ̀-èdè Portugal Christiano Ronaldo sọ pé òun dara pọ̀ mọ́ ògbóhùntarìgì ikọ̀ orílẹ̀-èdè Italy torí pé òun fẹ́ ràn ikọ̀ 'old lady' ọ̀hún lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa gba ife ẹ̀yẹ sí i pàápàá jùlọ ìfẹ́ ẹ̀yẹ UEFA Champions League. +Nigba ti o n ba awon oniroyin soro leyin igba ti a si aso loju re, Ronaldo so pe oun fe ni ipa ninu idije Serie A. Nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìgbà tí a ṣí aṣọ lójú rẹ̀, Ronaldo sọ pé òun fẹ́ ní ipa nínú ìdíje Serie A. +"""Mo feran ifigagbaga, mo si mo pe eyi yoo le." """Mo fẹ́ràn ìfigagbága, mo sì mọ̀ pé èyí yóò le." +"""Idurokini ti mo gba ni Allianz nibi jo mi loju." """Ìdúrókíni tí mo gbà ní Allianz níbi jọ mí lójú." +Ronaldo seleri lati fi opin si oda ife European ti o ba iko Juventus. Ronaldo ṣèlérí láti fi òpin sí ọ̀dá ife European tí ó bá ikọ̀ Juventus. +Ronaldo dara po mo iko Juventus lati iko Real Madrid pelu adehun owo ti o le ogorun-un owo pounds. Ronaldo dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ Juventus láti ikọ̀ Real Madrid pẹ̀lú àdéhùn owó tí ó lé ọgọ́rùn-ún owó pounds. +Laaarin odun mesan-an Ronaldo gba ife eye UEFA Champions league merin ati ife La Liga meji. Láàárín ọdún mẹ́sàn-án Ronaldo gba ife ẹ̀yẹ UEFA Champions league mẹ́rin àti ife La Liga méjì. +--- VON gba ami eye idije Teniisi ori tabili Obinrin ti NUJ gbe kale. --- VON gba àmì ẹyẹ ìdíje Teníìsì orí tábìlì Obìnrin tí NUJ gbé kalẹ̀. +Kissit Golit ti Voice of Nigeria ti gbe igba oroke ninu idije Teniisi ori tabili Obinrin ti NUJ gbe kale eleekkeji iru re. Kissit Golit ti Voice of Nigeria tí gbé igbá orókè nínú ìdíje Teníìsì orí tábìlì Obìnrin tí NUJ gbé kalẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kkejì irú rẹ. +Idije olodoodun yii ti o ti wo eekeji iru re je gbigba ni ojo abameta (Saturday), Ojo kerinla, Osu keje odun 2018 ni gbongan ile asa ile China ni ilu Abuja. Ìdíje ọlọ́dọọdún yìí tí ó tí wọ ẹ̀ẹ̀kejì irú rẹ̀ jẹ́ gbígbá ní ọjọ́ àbámẹ́ta (Saturday), Ọjọ́ kẹrìnlá, Oṣù keje ọdún 2018 ní gbongan ilé àṣà ilẹ̀ China ní ìlú Abuja. +Ile asa ile China n se asepo pelu Egbe awon Oniroyin Naijiria (NUJ) eka ti olu ilu ile Naijiria. Ilé àṣà ilẹ̀ China ń ṣe àṣepọ̀ pẹ̀lú Ẹgbẹ́ àwọn Òníròyin Nàìjíríà (NUJ) ẹ̀ka ti olú ìlú ilẹ̀ Nàìjíríà. +Tokumbo Adesanya ni o gbaami eye idije Teniisi ori tabili Okunrin ti NUJ gbe kale, eleekeji ti eka si eka. Oun lo soju ajo oniroyin ile Naijiria lati na asoju ile-ise oro iroyin ti ami eye yii wa lowo re, Onosanya, Sangotola Tobi yii wa lara awon meta ti won soju Voice of Nigeria sugbon ko bode pade pelu bi won se yowo kilanko re ni ipele keji si asekagba. Tokumbo Adesanya ni ó gbaàmì ẹyẹ ìdíje Teníìsì orí tábìlì Ọkùnrin tí NUJ gbé kalẹ̀, ẹlẹ́ẹ̀kejì ti ẹ̀ka sí ẹ̀ka. Òun ló ṣojú àjọ oníròyìn ilẹ̀ Nàìjíríà láti na aṣojú ilé-iṣẹ́ ọ̀rọ̀ ìròyìn tí àmì ẹyẹ yìí wà lọ́wọ́ rẹ̀, Onosanya, Sangotola Tobi yìí wà lára àwọn mẹ́ta tí wọ́n ṣojú Voice of Nigeria ṣùgbọ́n kò bóde pàdé pẹ̀lú bí wọ́n ṣe yọwọ́ kílàńkó rẹ̀ ní ìpele kejì sí àsekágbá. +Lara awon ti o tun soju Voices of Nigeria ni Comfort Babatunde ti won ja kuro ni ipele akoko. Lára àwọn tí ó tún ṣojú Voices of Nigeria ni Comfort Babatunde tí wọ́n já kúrò ní ìpele àkọ́kọ́. +--- Irohin gbangba: Ronaldo dara po mo iko Juventus pelu adehun arunlelogorun-un milionu owo pounds. --- Ìròhìn gbangba: Ronaldo dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ Juventus pẹ̀lú àdéhùn àrùnlélọ́gọ́rùn-ún mílíọ́nu owó pounds. +Atamatase omo orile-ede portugal Cristiano Ronaldo ti kuro ni inu iko Real Madrid bo si inu akinkanju iko orile-ede Italy Juventus ti ilu Turin pelu arunlelogorun-un milionu owo pounds. Atamátàsé ọmọ orílẹ̀-èdè portugal Cristiano Ronaldo ti kúrò ní inú ikọ̀ Real Madrid bọ́ sí inú akínkanjú ikọ̀ orílẹ̀-èdè Italy Juventus ti ìlú Turin pẹ̀lú àrùnlélọ́gọ́rùn-ún mílíọ́nu owó pounds. +Ni ninu oro kan ti a fi lede lojo isegun (Tuesday), Real Madrid so pe awon ta Ronaldo si inu iko Juventus ni ibamu pelu ife omo etalelogbon odun ohun. Ní nínú ọ̀rọ̀ kan tí a fi léde lọ́jọ́ ìṣẹ́gun (Tuesday), Real Madrid sọ pé àwọn ta Ronaldo sí inú ikọ̀ Juventus ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ ọmọ ẹ̀tàlélọ́gbọ̀n ọdún ọ̀hún. +“Real Madrid fe fi emi imoore won han si agbaboolu ti o ti fi ara re han gege bi agbaboolu ti o dara julo lagbaaye ti o si ti nipa lori awon asiko ti o dara fun wa julo ninu itan boolu afesegba lagbaaye. “Real Madrid fẹ́ fi ẹ̀mí ìmoore wọn hàn sí agbábọ́ọ̀lù tí ó ti fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí agbábọ́òlù tí ó dára jùlọ lágbàáyé tí ó sì ti nípa lórí àwọn àsìkò tí ó dára fún wa jùlọ nínú ìtàn bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá lágbàáyé. +“Yato si awon ami eye yii, awon ife eye ti o gba ati awon ijawe olubori re lori papa laarin odun mesan-an yii, Cristiano Ronaldo ti je apeere ifarajin, isojuse, ebun ati ilosiwaju.” ninu oro naa. “Yàtọ̀ sí àwọn àmì ẹyẹ yìí, àwọn ife ẹ̀yẹ tí ó gbà àti àwọn ìjáwé ol��borí rẹ̀ lórí pápá láàrin ọdún mẹ́sàn-án yìí, Cristiano Ronaldo ti jẹ́ àpẹẹrẹ ìfarajìn, ìṣojúṣe, ẹ̀bùn àti ìlọsíwájú.” nínú ọ̀rọ̀ náà. +Ronaldo kuro ni olu ilu orile-ede Spaini yii leyin ti o ti di eni ti o ri awon he julo ninu itan iko Real Madrid pelu ami ayo otalenirinwodinmesan-an ninu ifesewonse ojilenirinwodin-meji. Ronaldo kúro ní olú ìlú orílẹ̀-èdè Spaini yìí lẹ́yìn tí ó ti di ẹni tí ó rí àwọn he jùlọ nínú ìtàn ikọ̀ Real Madrid pẹ̀lù àmì ayò ọ̀tàlénírinwódínmẹ́sàn-án nínú ifẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ òjìlénírinwódín-méjì. +Ni apapo o gba ife eye merindinlogun ninu won ni ife European merin, meta je lera won nigba ti ikerin je saa marun-un seyin. Ní àpapọ̀ ó gba ife ẹ̀yẹ mẹ́rìndínlógún nínú wọn ni ife European mẹ́rin, méta jẹ́ léra wọn nígbà tí ìkẹrin jẹ́ sáà márùn-ún sẹ́yìn. +--- Mahrez towo bo iwe adehun odun marun-un pelu iko Man City --- Mahrez tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn ọdún márùn-ún pẹ̀lú ikọ̀ Man City +Agbaboolu omo orile-ede Algeria Riyad Mahrez pari itokoso re losi iko asaaju idije Premier League, Manchester City lojo isegun (Tuesday), leyin osu meje ti o ti soreti nu latari pe iko City ko lati san owo ti iko Leicester n beere fun. Agbábọ́ọ̀lù ọmọ orílẹ̀-èdè Algeria Riyad Mahrez parí ìtọkọ́sọ́ rẹ̀ lọsí ikọ̀ aṣáájú ìdíje Premier League, Manchester City lọ́jọ́ ìṣẹ́gun (Tuesday), lẹ́yìn oṣù méje tí ó ti sọ̀rètí nù làtàrí pé ikọ̀ City kọ̀ láti san owó tí ikọ̀ Leicester ń bèèrè fún. +Ni asiko yii, iko Leicester so pe awon ta a ni iye owo ti o won inu iwe itan iko naa, ti awon iroyin kan si n ni I lero pe iko asaaju yii san ogota milionu owo pounds (Ogorin milionu din die Owo dola) leyii ti yoo so o di eyi ti o n wo inu iwe itan. Ní àsìkò yìí, ikọ̀ Leicester so pẹ́ àwọn tà á ní iye owó tí ó wọn inú ìwé ìtàn ikọ̀ náà, tí àwọn ìròyìn kan sì ń ní I lérò pé ikọ̀ aṣáájú yìí san ọgọ́ta mílíọ́nù owó pounds (Ọgọ́rin mílíọ́nù dín díẹ̀ Owó dọ́là) léyìí tí yóò sọ ọ́ di èyí tí ó ń wọ inú ìwé ìtàn. +Omo odun metadinlogbon yii ti o je eekan nigba ti iko Leicester gba ife Premier League lona iyanu lodun 2016 towo bo adehun odun marun-un. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n yìí tí ó jẹ́ èèkàn nígbà tí ikọ̀ Leicester gba ife Premier League lọ́nà ìyanu lọ́dún 2016 tọwọ́ bọ adéhùn ọdún márùn-ún. +“Inu mi dun lati dara po mo iko City, iko ti o n gba boolu to ta sansan labe Pep Guardiola. “Inú mi dùn láti dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ City, ikọ̀ tí ó ń gbá bọ́ọ̀lù tó ta sánsán lábẹ́ Pep Guardiola. +Wiwo won lokeere je oun ti o maa n wu mi.. Wíwò wọ́n lókèèrè jẹ́ oun tí ó máa ń wù mí.. +Pep je eni ti o fi ara si titi boolu siwaju, leyii ti o se regi pelu mi, bee si ni isowosise Citi ni saa to lo ko legbe” eyi ni Mahrez wi. Pep jẹ́ ẹni tí ó fi ara sí títi bọ́ọ̀lù síwájú, léyìí tí ó ṣe régí pẹ̀lú mi, bẹ́ẹ̀ sì ni ìṣọwọ́ṣiṣẹ́ Cítì ní sáà tó lọ kò lẹ́gbẹ́” èyí ni Mahrez wí. +---Spain yan Luis Enrique gege bi akonimoogba tuntun. ---Spain yan Luis Enrique gẹ́gẹ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá tuntun. +Ajo to n moju to boolu afesegba lorile-ede Spain ti so pe akonimoogba iko Barcelona teleri Luis Enrique ti di yiyan gege lati gba akoso iko orile-ede naa. Àjọ tó ń mójú tó bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá lórílẹ̀-èdè Spain ti sọ pé akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Barcelona tẹ̀lẹ̀rí Luis Enrique ti di yíyàn gẹ́gẹ́ láti gba àkóso ikọ̀ orílẹ̀-èdè náà. +O ropo Julen Lopetegui, ti won yo nise ni ife eye agbaaye ku ola leyin ti o gba ise ninu iko Real Madrid, nigba ti Fernando Hierro ti n tuko awon ifesewonse ni Russia fun igba die. Ó rọ́pọ̀ Julen Lopetegui, tí wọ́n yọ níṣẹ́ ní ife ẹyẹ àgbááyé ku ọ̀la lẹ́yìn tí ó gba iṣẹ́ nínú ikọ̀ Real Madrid, nígbà tí Fernando Hierro ti ń tukọ̀ àwọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ní Russia fún igbà díẹ̀. +Luis Enrique towo bo adehun odun meji. Luis Enrique tọwọ́ bọ àdéhùn ọdún méjì. +--- Ife eye agbaaye di sisafihan ni Moscow --- Ife ẹ̀yẹ àgbááyé di ṣíṣàfihàn ní Moscow +Ajo to n safihan nnkan isembaye ere idaraya FIFA yoo pate ife eye olujawe olubori odun 2018 fun odidi ojo aiku (Sunday) ni ilu Moscow. Àjọ tó ń ṣàfihan nǹkan ìṣèmbayé eré ìdárayá FIFA yóò pàtẹ ìfe ẹ̀yẹ olùjáwé olúborí ọdún 2018 fún odidi ọjọ́ àìkú (Sunday) ní ìlú Moscow. +Yoo je sisafihan pelu ife eye iru re, ife Jules Rimet, ti won koko fun eni ti o gba idije naa lodun 1930 nigba ti idije naa beere. Yóò jẹ́ ṣíṣàfihàn pẹ̀lú ife ẹ̀yẹ irú rẹ̀, ife Jules Rimet, tí wọ́n kọ́kọ́ fún ���ni tí ó gba ìdìje náà lọ́dún 1930 nígbà tí ìdíje náà bẹ̀ẹ̀rẹ̀. +Isafihan yii ti a mo si, “Awon Akotan”, yoo waye ni yara aworan ile-ise Hyundai Motorstudio ni agbegbe New ni ilu Moscow. Ìṣàfihàn yìí tí a mọ̀ sí, “Àwọn Akọ̀tàn”, yóò wáyé ní yàrá àwòrán ilé-iṣẹ́ Hyundai Motorstudio ní agbègbè New ní ìlú Moscow. +Isafihan yoo pari leyin ojo karun-un ifesewonse asekagba ife eye agbaaye odun 2018 lorile-ede Russia lojo keeedogun osu keje. Ìṣàfihàn yóò parí lẹ́yìn ọjọ́ karùn-ún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àsekágbá ife ẹ̀yẹ àgbááyé ọdún 2018 lórílẹ̀-èdè Russia lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje. +Ajo to n moju to boolu afesegba lagbaaye, FIFA, so ninu oro kan lojo abameta (Saturday) pe ofe ni iwole si ibi Isafihan yii, o fi kun un pe won gba awon oniroyin laaye lati wole, lati ya aworan ati lati ka aworan sile nibe. Àjọ tó ń mójú tó bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá lágbàáyé, FIFA, sọ nínú ọ̀rọ̀ kan lọ́jọ́ àbámẹ́ta (Saturday) pé ọ̀fẹ́ ni ìwọlé sí ibi Ìṣàfihàn yìí, ó fi kún un pé wọ́n gba àwọn oníróyìn láàyè láti wọlé, láti ya àwòrán àti láti ká àwòrán sílẹ̀ níbẹ̀. +“Ibi isafihan yii je imoriri ife ati ikobiarasi awon alatileyin kaakiri agbaaye ati ipa won lori rira iyi fun ife eye FIFA agbaaye. “Ibi ìṣàfihàn yìí jẹ́ ìmọrírì ìfẹ́ àti ìkọbiarasí àwọn alátìlẹyìn káàkiri àgbááyé àti ipa wọn lórí ríra iyì fún ife ẹ̀yẹ FIFA àgbááyé. +“Nibe, awon olubewo le ri atejise lati odo awon alatileyin awon orile-ede mejilelogbon ti won n figa gbaga ati afihan awon boolu ti won lo fun ifesewonse merinlelogota ife eye FIFA agbaaye odun 2018 lorile-ede Russia ti ile ise adidas pese. “Níbẹ̀, àwọn olùbẹ̀wò le rí àtẹ̀jíṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alátìlẹyìn àwọn orílẹ̀-èdè méjìlélọ́gbọ̀n tí wọn ń figa gbága àti àfihàn àwọn bọ́ọ̀lù tí wọn lò fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ife ẹ̀yẹ FIFA àgbááyé ọdùn 2018 lórílẹ̀-èdè Russia tí ilé iṣẹ́ adidas pèsè. +“Leyin ifesewonse kookan, boolu ti o ba beere ifesewonse naa yoo di fifikun ara awon afihan yii”,’’ ni oro ti Moritz Ansorge alakooso Ajo to n safihan nnkan isembaye ere idaraya FIFA se lalaye. “Lẹ́yìn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kọ̀ọ̀kan, bọ́ọ̀lù tí ó bá bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà yóò di fífikún ara àwọn àfihàn yìí”,’’ ní ọ̀rọ̀ tí Moritz Ansorge alákòóso Àjọ tó ń ṣàfihan nǹkan ìṣèmbayé eré ìdárayá FIFA ṣe lálàyé. +--- Tite gba adehun odun merin miiran. --- Tite gba àdéhùn ọdún mẹ́rin mìíràn. +Ajo to n moju to boolu afesegba lorile-ede Brazil (CBF) n fi adehun odun merin miiran lo akonimoogba agba iko naa Tite tohun tenu ijakuro ninu ife eye agbaaye leemarun-un otooto lati ipele keji si asekagba. Àjọ tó ń mójú tó bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá lórílẹ̀-èdè Brazil (CBF) ń fi àdéhùn ọdún mẹ́rin mìíràn lọ akọ́nimọ̀ọ́gbá àgbà ikọ̀ náà Tite tòhun tẹnu ìjakúrò nínú ife ẹ̀yẹ agbááyé lẹ́ẹ̀marùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti ìpele kejì sí àṣekágbá. +Gege bi Globo itakun ile Brazil se so, Isowosise akonimoogba agba yii te Ajo CBF lorun, won si n fi adehun miiran lo o. Gẹ́gẹ́ bí Globo ìtàkùn ilẹ̀ Brazil ṣe sọ, Ìṣọwọ́ṣiṣẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá àgbà yìí tẹ́ Àjọ CBF lọ́rùn, wọ́n sì ń fi àdéhùn mìíràn lọ̀ ọ́. +Eni odun metadinlogota gba akoso iko Brazil ni inu osu kefa odun 2016, o si ran iko naa lowo lati pegede si inu ife eye agbaaye FIFA odun 2018 pelu ipo kini lati inu awon orile-ede ile Guusu America. Ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta gba àkóso ikọ̀ Brazil ní inú oṣù kẹfà ọdún 2016, ó si ran ikọ̀ náà lọ́wọ́ láti pegedé sí inú ife ẹ̀yẹ àgbááyé FIFA ọdún 2018 pẹ̀lú ipò kíní láti inú àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Guusu America. +Labe akoso Tite, iko Brazil ti jawe olubori ni igba ogun, won ta omi merin won si padanu leemeji pere, ninu re ni ipadanu ojo eti (Friday) pelu iko Belgium. Lábẹ́ àkóso Tite, ikọ̀ Brazil ti jáwé olúborí ní ìgbà ogún, wọ́n ta ọ̀mì mẹ́rin wọ́n sì pàdánù lẹ́ẹ̀mejì péré, nínú rẹ̀ ni ìpàdánù ọjọ́ ẹtì (Friday) pẹ̀lú ikọ̀ Belgium.