Datasets:
line_id
stringlengths 4
4
| audio
audioduration (s) 7.56
906
| text
stringlengths 49
2.88k
| speaker_id
stringlengths 2
2
|
---|---|---|---|
01yy | a àga
b bàtà
d dùndún
e ehoro
е eşin
f filà
g garawa
gb gbágùúdá
h hanrun
i igi
j jígí
k kókóró
| légbélégbé
m mángòrò
n náírà
o ológbò
ọ òbọ
p pépéye
r ràkúnmí
s sálúbàtà
t
u
W
y
tata
tú
wárápá
yanmùyánmú | 01 |
|
02yy | b bàtà
d dùndú
f filà
g igi
gb gbogbo
k kó̟kó̟ró
l labalábá
m méjì
n nísisìnyí
p pátápátá
r rìkísí
s sálúbàtà
ş şibĺ
t tata
w wàrà
y yanmùyánmú | 02 |
|
03yy | an
en
in
ọn
un
'Ìbàdàn'
'iyen'
'erin'
'ìbon'
'fun' | 03 |
|
04yy | a
ajá
e
erin
е
--
i
O
u
บ
eye
imú
owó
o̟wó̟
*ooru | 04 |
|
06yy | Ę kááárò o, bàbá.
Kááárò o, Tádé. Şé o sùn dáadáa?
Béè ni, mo sùn dáadáa. Ę ṣé.
Ę káàbò o, Màmá
Kúulé O, Lolá. Şé àlàáfíà ni?
Alàáfíà ni.
Egbónon rẹ ńkó̟?
Won wà nílé.
Ó dáa o. Dìde.
Ẹ káàárò mà.
Ę kááárò o. Sé dáadáa ni o?
Dáadáa ni mà.
Şé e sùn dáadáa?
Bé̟è̟ ni mà.
Káásán o, Fúnmi.
Káásán o, Şadé. Şé dáadáa ni?
A dúpé. ìwọ náà ńkó̟?
A dúpé o.
Kí ni orúko̟ò̟ rẹ?
Orúko̟ò̟ mi ni Olúfémi.
Kí ni orúkọ bàbáà rè?
Orúkọ bábáà mi ni Kúnlé Akínlàjà.
Bá mi kí àwọn òbíì rẹ tí o bá délé,
Mo gbọ sà.
Ó dàbò o, Olúfémi.
Ó dàbọ sà.
Ę káásán o, Màmáa Fúnmi.
Ę káásán o, Màmáa Şadé. Gbogbo ilé
ńkó̟?
Dáadáa ni o. Bàbáa Fúnmi ńkó̟?
Wón wà. Ẹ şé o. Ó dàbò̟ o
Ó dàbò o.
Ẹ káalé mà.
Káalé o, Títí. Şé àlàáfíà ni?
A dúpé mà. Şé Şadé wà nílé?
Rárá o. Ó ti jáde.
Ó dáárò mà.
Ó dáárò o, Títí. Kílé o. | 06 |
|
07yy | Orúkọo mi ni Wálé. Mo jé̟ akékò̟ó ní Yunifásítì ti Texas ní Austin. Mo férán ilé-ìwéè mi
gan-an ni nítorí pé gbogbo ohun tí ó lè mú kí è̟kó̟ rọ ènìyàn lórùn ni ó wà níbè àgàgà nínú
kíláȧsìì mi.
Orişirişi nǹkan ni ó wà nínú kíláàsìì mi. Láraa wọn ni àga, tábìlì, àwòrán, kò̟ǹpútà, monito,
máòsì, kíĺboodù, ìwé atúmò̟-èdè, pé̟è̟nì, pé̟ńsùlù, rúlà, ìrésà, fídíò, síídiì, fáìlì, máàpù
àgbáyé, sóòkì, pátákó-ìkò̟wé àti béè béè lọ.
Léyìn èyí, a tún lè rí àwọn nǹkan mìíràn tí wọn mú kíláàsìì mi yàtò̟ sí kíláȧsì mìíràn ni
Yunifásítì bli ìlèkun aláràbarà, fèrèsé aláràbarà, iná ìlétírſìkì, àjà, apèrè̟-ìdalènùsí àti béè
béè lọ.
Mo férán ilé-ìwéè mi lọpọlọpọ. Mo sì máa ń fi í yangàn láàárín àwọn ò̟réè mi nítorí pé
náánní náànnì náánní, ohun a ní là á náánní bí ọmọ aṣégità se ń náánní èpo igi. | 07 |
|
08yy | Gbogbo yín, e mú ìwé ìṣiròo yín
jáde. Ę şí ìwé yín sí ojú-ìwé
karùnlélógbon. Títí, s̟e ìṣirò kìíní.
Aárùnúndínlógún àti eétàlá jé
eéjìdínló̟gbon.
Títí, o gba ìşirò rẹ şámúṣámú. Kémi,
şe ìşirò kọkànlá. Yọ ẹérin kúrò nínú
eétàlá.
Em em em, ó ku ẹésànán.
O káre, Kémi. Foláké, s̟e ìşirò tó
télé ìyẹn. Yọ ẹésànán kúrò nínú
eétàdínlógún.
: Ó kù ẹéjo.
Ó káre Folákę.
Èyin ọmọ, ẹ dáké ariwo. Òla ni ọjó ìdánwò. Ó yẹ kí á tún ìṣiròo wa wò. Lọlá, Kí ni ìşiròo
eéjì àti eéfà?
Ęéjo ni.
Ó káre Lolá. Títí, kí ni oókàndínlógún àti ogún?
Oókándínlógbon ni
Fémi, şé Títí gba ìṣiròo rè?
Rárá, oókándínlógójì ni àròpò̟ oókàndínlógún àti ogún.
O káre Fémi. Rèmí, yo aárùnúndínlógún kúrò nínú oókánléló̟gbon.
Eérìndínlógún ni.
Fúnmi, şé Rèmí gba ìṣiròo rè?
Béè ni, ó gba ìṣiròo rẻ.
Gbogbo yín, ẹ káre. | 08 |
|
09yy | Bàbá Olá, şé wà á bámi lọ sí oko ní ò̟sè̟ tí ó ń bò̟?
Rárá o, nítorí pé mo máa lọ sí ò̟dò̟ àbúròò mi obìnrin tí ara rè̟ kò yá. Tí mo bá
dé ibè, mà á ba lọ sí oko láti mú ișu, ilá, tòmátò, è̟gúsí, ata rodo, tàtàsé àti ègé
wá sílé. Tí mo bá dé láti oko, mà á ba se oúnjẹ. Léyìn náà, mà á ní láti bá a
foṣọ, lọta, kí n sì bá a gé igi. Mà á ba lọ gba oogùn ló̟dò̟o apòògùn. Mà á tójú
àbúròò mi dáradára. Mà á dúró tì í títí di alé. Mà á wá padà sí iléè mi.
Ó dára o. Má á sì lọ sí oko láti hú koríko. Tí mo bá șe tán, mà á padà wá sílé.
Bóyá ti ara àbúròò mi obìnrin bá yá tán a má a jọ lọ. Jé̟ kí á lọ ìsò̟o Màmáa Títí.
ìyẹn á dára púpò̟. | 09 |
|
10yy | Orúkọ mi ni Wálé. Mo jé̟ o̟mo̟ bíbí ìlú Ìbàdàn láti ìpínlè̟ Òyó̟ ní orílè̟-èdè Nàìjíríà. Tí ó bá di
ojó kesàn-án, oṣù kọkànlá ọdún tí ó ń bò̟ ni màá pé ọmọ ọdún mókándínlógbon.
Gégé bí ìtàn tí mo gbó̟, torí bí ọmọdé kò bá gbó̟ ìtàn, yóò gbó̟ àró̟bá torí pé àróbá ni bàbá
ìtàn. Mo gbó pé ojó ìṣégun ni ojó tí àwọn òbíì mi bí mi. Èyí máa ń jé̟ kí inúù mi dùn fún ọjó̟-
ìbíì mi tí ó bá bó sí ojó ìṣégun.
Nípa ti àwò̟, kín má puró, mo féràn àwò ṣùgbọn n kò fé̟ràn àwò̟ pupa àti yé̟lò rárá rárá.
Gbogbo ohun tí e̟nu ń jẹ pátá ni mo féràn. | 10 |
|
11yy | Fèyí, ṣé wà á wá kí mi ní òpin osè, ní
ojó àìkú?
Ní aago mélòó ni o fé kí n wá? ó máa
dára ní ò̟sán nítorí pé mo máa ń lọ sí
ìsìn o̟mo̟dé ní aago mésànán àbò
àárò. Léyìn náà, ní aago mewa, ìsìn
àgbà máa bèrè.
(Èmi náà), ní aago márùnún ìrolé, mo
ń lo sí ibi ojo ìbí ò̟réè mi kan.
Ojo ìbli ta ni?
Ojó ìbí Akin Ọmóyemí.
Rárá o, aago méta ni ojo ìbí Akin yen.
Tí o bá lọ ní aago márùnúun, wà á kàn
lọ gbá ile ni!
O ò se kúkú jé kí á pàdé ní ò̟dò̟ Akin.
Şé wà á so̟ fún àwọn òbli rẹ?
Nígbà wo ni o máa dé ò̟dò̟ Akin?
Bli aago méta àbò osán.
Ó dára, ó dìgbà kan ná. | 11 |
|
12yy | Yemí, Ọmọ ọdún mélòó ni é?
Ọmọ ọdún méjìdínlógún ni mí.
Ọmọ ọdún mélòó ni bàbáà rę?
Ọmọ ọdún métalélógójì ni wó̟n.
Ọmọ ọdún mélòó ni mȧmáà rę?
Ọmọ ogójì odún ni won.
Ọmọ ọdún mélòó ni àbúròo bàbáà rę?
Ọmọ ogbon odún ni won.
Ọmọ ọdún mélòó ni è̟gbó̟nòn rẹ?
Ọmọ ogún ọdún ni won.
Ọmọ ọdún mélòó ni àbúròò re?
Ọmọ ọdún mérìndínlógún ni. | 12 |
|
13yy | Bàbáà mi, mo ní òré kan.
ìyẹn dára o. Ta ni òréè re?
Orúkọ rẹ ni Láńre.
Ta ni bábáa Láńre ?
Ojogbón Òsúndáre ni bàbáa
Láńre | 13 |
|
14yy | Ębli mi ni ębí Adédiran
À n gbé ní ìlú Ìbàdàn ní àdúgbò ìyágànkú. Bàbá àti ìyáà mi bí ọmọ merin. Àkó̟bí wọn ń je
Adéolú. Ọmọ ọdún méjìlélógbon ni won. Apòògùn sì ni won pèlú. Won ní ìyàwó. Oruko
ìyàwóo won ni Gbémi. Wọn bí ọmọ méjìi, Doyin àti Yétúndé. Okùnrin ni Doyin. Doyin je
ọmọ ọdún mérin. Yétúndé sì jé̟ o̟mo̟ o̟dún méjì. Ọmọ kejì tí bàbáà àti màmáà mi bí ni
Bímpé. Bímpé jé ọmọ ogbon odún. Dókítà ni wó̟n, şùgbọn wọn kò ì tí ì fẻ ọkọ. Eni tí ó
tělé Bímpé ni Jídé. Ọmọ ọdún mérìndínló̟gbọn ni wó̟n. Agbejorò ni won. Won sèsè bí
ọmọ kan tí orúkọ rẻ ń jé̟ Rónké. Rónké jé̟ o̟mo̟ oṣù méta. Èmi ni àbígbéyìn nínú ẹbí
mi. Oruko̟ò̟ mi ni Àbíké. Mo jẹ ọmọ ọdún méjìlélógún. Mo wà ní Yunifásítì ti ìlú Ìbàdàn.
Mo ń ko nípa è̟kó̟ ìṣègùn. | 14 |
|
15yy | Ębí Akinwálé
Orúkọ mi ni Lolá. Orúkọ bàbáà mi ni Fémi. Orúkọ màmáà mi ni Ọláníkè̟é̟. Mo ní abúrò
meta. Orúkọ won ni Jídé, Báyò àti Bùnmi. Jídé àti Báyò ni àwọn abúrò mi ọkùnrin, Bunmi
sì ni àbúrò mi obìnrín. Jídé ni ọmọ kejì. Báyò ni ọmọ kẹta. Bunmi ni àbúrò mi àbígbéyìn. À
ń gbé ní ìlú Èkó. Mo férànan gbogbo àwọn ẹbí mi gan-an ni. | 15 |
|
16yy | Bàbáà mi tínínrín, wọn sì dúdú. Màmáà mi sanra, wó̟n sì pupa. Wón lewà. Kì í se pé
bàbáà mi búréwà o! Wón je ologbón, alááánú àti onírèlè. Wọn sì tún jé ènìyàn gíga.
Màmáà mi je oníwápělé. Won kì í se onígbéraga. Wọn kò ga bli bàbáà mi. Wọn kò sì kúrú
púpo. Won jé ènìyàn rere. Won sì jé̟ o̟mo̟lúwàbí ènìyàn. | 16 |
|
18yy | Eélòó ni tàtàsée yín, ìyá aláta?
Èwo nínúu won?
Àwọn tí ó wà ni àárín yen?
Náírá márùnún ni àwọn yen.
Háà! Wọn ti won jù. N kò lè san náírá márùnún o. Ę jé kín san náírà
méta àbò.
Rárá, kò gbà. (Màmáa Tádé ń lọ.) Ó dára o. Ę wá mú u ní náírá méta
àbò.
Ẹ gbà. Náírá márùnún nìyío.
Ò dára o. Ę gba náírà kan àti àádó̟ta kó̟bò̟. Ę padà wá o. | 18 |
|
19yy | Ę kááárò o, Màmáa Fúnmi
E kááárò o, Màmáa Şadé, a à jí bí?
A jíire o. Gbogbo ilé ńkó̟?
A dúpé o. Dáadáà ni won wà. Bàbáa Şadé ńkó̟? Şé àlàáfíà ni won
wà?
A dúpé o. Bàbáa Fúnmi náà ńkó̟ o?
Wọn wà o. Wọn mà ti lọ sí ìrìn àjò.
Dáadáa ni wọn yóò dé o. Mo mà fé ra ata rodo, ata s̟ò̟ǹbò̟, tòmáàtì,
àlùbosà, iyò àti epo pupa.
Èmi náà fẻ ra ẹja tútù àti s̟ò̟ǹbò̟ fún ọbè̟ eja aláta ni.
Mo máa ra è̟foo sọkọ yòkò̟tó̟ àti è̟gúsí. Mo ní láti ra èlùbó̟ fún àmàlà | 19 |
|
20yy | Háá Kúnlé, ki ni o wá se ní ọjà?
Màmáa mí ní kín wá ra eran náírà mé̟wàá, ìręsìi náírà márùnún ààbò̟, ata rodo náírà
kan, àlùbosà náírà kan, èfó̟ọ tètè̟ náírà méji. Wó̟n fún mi ní ogúnun náírà. Tí ìṣirò rẹ bá
péjú, eélòó ni ó yẹ kín mú padà lọ sí ilé?
Kúnlé, sé o mò̟ pé mo féràn ìṣirò! Wà á mú .....uhhhhh...... àádó̟ta kó̟bò̟ padà lọ sí ilé fún
màmáà rę. Tí o kò bá se béè, o ti wọ ìjò̟gbonọn màmáa rè̟ nìyẹn.
Ládi, èmi náà ti şirò iye tí ó yẹ ki n mú padà lọ sí ilé, O mọ ìṣirò gan-an ni o.
Màmáa tèmi náà ní kí ń ra ata tàtàsé ogóta kó̟bò̟, epo pupa náírá kan, àlùbósa ogórin
kó̟bò̟, è̟wà pupa náírà márùnún, gààrí náírà márùnún, nínúu náírà márùnúndínlógún. Èló
lo rò wípé ó yę kín mú padà lo sí ilé?
Náíra méjí ati ogóji kobo.
O gbà á. Ó dàbò̟ o.
Ó dàbò̟ o. | 20 |
|
21yy | Lángbé jíná o
Orokún orí ebè
Olóko ò gbowó
Àdàlú elédé o
Awùsá gbó keke bí obì
Ó gbó bí orógbó
Eléntú dé o.
Òré ìkété dé o
Ó tú sépo múyé,
Ó fàtàrí napo pé bé
Ómí é ń hó yeeyéè,
Yeeyéè ní ń hó o
Eyin omo àràbà méta Odòokun,
Ę wa mu ún
Yeeyéè ní ń hó o | 21 |
|
22yy | Oní moínmóín gbewá gbewá
Moínmoín epo
Só mepo
Şó mepo sìndin
Moínmóín epo
Şo fedé si pèlálùbó̟sà
Moínmoín epo
Oní dòdò oní moínmoin
Oní dòdò oní moínmoin
Nígbà tí ò tà ó gbé gbá kalè̟
Ę wá wò jà ní Láfíàji. | 22 |
|
23yy | Wálé, báwo ni nǹkan?
Dáadáa ni.
Àwọn ẹbli rę ńkó̟?
Dáadáa ni gbogbo won wà o. Màmáà mi ní kín máa kí ẹ.
Wọn mà sé o, won kú àìgbàgbé mi.
Àwọn òbli rę náà ńkó̟?
Won ti jade láti àárò̟, kò sì yẹ kí wó̟n pé dé mọ.
Ó ye kín dúró de won, nítorí pé ó pé tí mo ti rí wọn.
Kí ni kín fi ṣe é lálejò báyìí?
Èmi! Àlejò? Gbogbo ohun tí o bá ní nílé pátá ni kí o gbé wá, má á ję wó̟n.
Àmó, má gbé ògì wá o.
Kí ló dé?
N kì í mu ògì. N kò féràn ògì rárá.
Kò burú o, ìręsì àti èwà ni mo fé fún ẹ je o.
Ìresì kè! Şé kò sí iyán tàbí è̟bà ní?
Wálé! O ti féràn òkèlè jù. Ọmọ ọkà!
Şé ìwọ ti gbagbé òrò àwọn Yorùbá tí wọn sọ pé:
"Iyán l'oúnje, ọkà l'oògùn, Airí rárá là á j'èko, K'enu má dilè ni ti gúgúrú."
Ó dára, má á fún ẹ lébà.
Hèn-en-én! O sé jàre òré. | 23 |
|
24yy | Kí ni orúkọ ọjà tí wọn ń ná ní àdúgbò tí a
rìn kojá yen?
Ojȧa Sánńgo ni.
Sé ojà kan soso tí ó wà ní ìlú ìbàdàn
nìyẹn ni?
Rárá o!
Kí ni orúkọ àwọn ọjà tí ó kù àti àwọn ohun
tí a lè rí rà ní ibè?
Orişirişi ojà ló wà ní ìlú Ìbàdàn yìí. Nínúu
wọn ní a ti rí Qjàa Sánńgo, Ojàa Màpó,
Ojà Aléṣinloyé, Ojàa Dùgbé, àti Ojà
Orítamérin. Bí àpeere, a lè rí ohun èlò
enú ń ję rà ní ọjà Aléṣìnloyé bí ó ti lè̟ jé pé
ìsò àwọn álaṣọ ló pò̟ jù níbè̟. Àwọn èlò
oúnjẹ bli ata, tòmáàtì, epo pupa, irú, òróó,
àlùbosà, ilá, égúsí àti oúnjẹ bíi ìresì, è̟wà,
àgbàdo, eja, eran, gàrí, èlùbó̟, àti è̟fó̟. A
tún lè rí àwọn èso bli osàn, mángòrò,
ìbépe àti béè béè lọ ní àwọn ọjà wònyí.
Nínú àwọn ọjà tí mo dárúkọ wò̟nyí, a lè sọ
wípé Qjàa Sánńgo, Màpó, àti Aléṣinloyé
ni àwọn ojà tí wọn tobi jù ní ìlú Ìbàdàn.
Èyí mà dára o. Won yàto púpò sí àwọn
ojà tí a máa ń ná ní ilé-Ifè. | 24 |
|
25yy | Màmá, irú oúnjẹ wo ni ẹ ní?
Èbà, iyán, ọkà gidi àti fùfú.
Irú obè wo ló wà?
Obe ilá, égúsí, ewédú àti gbègìrì.
Irú eran wo ló wà?
Eran ògúnfe, màlúù àti ò̟yà.
Eja ń ko? Irú eja wo ló wà?
Eja sáwá, eja èpìà, eja aborí àti eja àrò.
Eélòó ni ìgbákọ àmàlà kan?
Ogúnun náírá.
Şé ó gba náírá márùnúndínlógún?
Rárá, kò gbà. Ogúnun náírà ni ìgbákọ.
Ẹ fún mi ní ìgbako merin.
Trú obè wo le fé? Obè̟ ilá, ewédú, gbègìrì, è̟gúsí àti è̟fó̟ rírò.
Ẹ fún mi ní àbùlà.
Erán ńkó̟?
Eélòó ni eran kò̟ò̟kan?
Náírá márùnún ni eran kò̟ò̟kan.
Ẹ fún mi ní eran méjì?
Şé omi le fé tàbí mínirà?
Trúu mínírà wo lẹ ní?
A ní fáńtà, kóòkì, sípíráìtì, séfúno̟ò̟pù, pẹpusí àti dókítò̟ pẹpè̟.
Eélòó ni kóòkìi yín?
Ogbonọn náírá ni.
Ẹ fún mi ní kóòkì kan. Eélòó ni owó mi jé̟?
Owóo yín je ogofàa náírà.
Ę gba owó.
Ẹ ṣé o. (Oníbàárà gba oúnjẹ, ó sì wọ inúu búkà lọ láti jẹ oúnjẹ rè̟.) | 25 |
|
26yy | Túndé, sé wàá wá sí ilé-ìwé lóla?
Rárá o, nítorí pé araà mi kò yá. Orí ń fó̟ mi. Gbogbo ara ń ro mí.
Şé o ní ibà ni?
Ó dàbée, sugbon n kò mò.
Şébí tí o bá ní ibà, wà á kàn lọ rí dókítà ní ilé-ìwòsàn ìjoba ni.
Njé o mo wípé n kò féràn láti máa lọ sí ilé-ìwòsàn? Mo bèrù abéré púpò̟.
Túndé, kì í ṣe gbogbo àìsàn ni ènìyàn ń gba abéré̟ sí. Tí ó bá je wípé ibà
lásán ni, o lè mu àgbo.
Háà, èèmi, àgbo kè! Ki ni yen korò bli ewúro.
Şebí kí àwọn òyìnbó tó dé, àgbo ni àwọn Yorùbá máa ń mu.
Àwọn Yorùbá şi ń mu àgbo títí dì ìsinyìí, şùgbọn èmi kó̟. Mà á kúkú lo gba
abéré yen ni!
Tí ojú, etí àti esè̟ bá ń dùn ó n ko?
Fún ojú, màá lọ rí dókítà ojú ni. Şebí dókítà kò níí fún mi ní abéré nínú ojú!
Túndé, o kì í se dókítà.
Bee ni, n kì í se dókítà. Nję o mo pé eyín ń dun èmi náà?
Háà! Wà á lo ri yoyinyoyín (dókítà eyín) nìyẹn. Wón á fún ẹ ní aber nínú
eyin.
Jo ó kúrò o jère. O dé nìyẹn. | 26 |
|
27yy | Bàwo ni, Felicia?
Háà! Marcus, dáadáa ni.
Kí ní o wá se ní láàbù?
Mo wá se ȧyewoo sámpùlù ni.
Hà! Hà! Şe è̟kó̟ nípa sáyéǹsì ni iwọ náà ñ kó̟ ni?
Beeni. Mo ń ko nípa sáyè̟nsì. Bàó̟ló̟jì ni è̟kó̟ò̟ mi dálé lórí nítorí pé mà á fé
di dókítá nígbà tí mo bá parí è̟kó̟ò̟ mi.
Ó dára bée. Abájọ tí o fi tera móṣé. Á á dára o!
Oo. O sé o Marcus. Kí ni ękóọ tìre dálé lórí?
Mo kan ń se işe kan tí ó jọmọ sáyéensì ni. Èkó̟ nípa ìmò̟-è̟rọ ni è̟kó̟ò̟ mi
dálé lórí. Mo féràn ìmò̟-è̟ro gan-an ni nítorí pé má á fé di enjiníà nígbà tí
mo bá parí è̟kó̟ò̟ mi.
Iṣé enjiníà náà dára púpò, ṣùgbón n kò lè ṣe é, nítorí pé mo férán isée
dókítà gan-an ni.
Kò burú. A jé wípé níwòyí ọdún márùnún, màá ti di ẹnjiníà. Ìwọ náà á ti di
dókítà. Ó dàbò̟ o.
Ó dàbò o, enjinía Marcus!!! | 27 |
|
28yy | ìmótótó ló lè ségun àrùn gbogbo
ìmótótó ló lè ségun àrùn gbogbo
ìmó̟tótó ilé, ìmó̟tótó ara, ìmótótó oúnjẹ
ìmótótó ló lè ségun àrùn gbogbo
ìmótótó ló lè ségun àrùn gbogbo
ìmótótó ló lè ségun àrùn gbogbo
ìmó̟tótó ilé, ìmó̟tótó ara, ìmótótó oúnjẹ
ìmótótó ló lè ségun àrùn gbogbo' | 28 |
|
29yy | We ki o mo
Gé èékánná re
Jęun tó dára lásìkò
Má jeun jù
We ki o mo
Gé èékánná re
Jęun tó dára lásìkò
Má jeun jù | 29 |
|
30yy | Ní ilẹẹ Nàìjíríà, àpátíméèntì ni àwọn Yorùbá máa ń pè ní fúláàtì. Tí àwọn ènìyàn kò bá tí ì
şetán láti kó̟ ilé, wọn máa ń rentì àpátíméèntì láti gbé. Àwọn alákowé ni wọn sáábà máa ń
gbé fúláàtì.
Àbúrò màmáà mi jẹ agbejó̟rò ní ìlú ìbàdàn. Wọn sì ré̟nti fúláàtì kan sí Bódìjà Tuntun.
Orúkọ won ni Loya Adébímpé. Fúláàtì wọn tóbi ganan ni. Ó ní pálò̟ ńlá méjì àti yàrá
ìbùsùn merin. Yàrá tí ó tòbi jù ni yàrá àbúrò màmáà mi àti ìyàwóo wọn. Yàrá yìí ní baluwè
àti ilé ìyàgbé tiré lóó̟tó̟. Balùwè àti ilé ìyàgbé kan tó kù wà fun àwọn ọmọ àti àwọn àlejò.
Ènìyàn kò lè şȧdédé wo̟ fúláàti àbúròo màmáà mi lái se pé ó jé ẹni mímò̟. Ìdí nìyí tí o fí je
pé ìta gbangba ni won ti máa ń gbàlejò. Tí ó bá se ènìyàn mímò̟ ni ó wá kí àwọn ìdílé
àbúròo mámáà mi, pálò̟ tí ó wà ní iwájú ni wọn máa jókòó sí láti bá wọn sòrò àti şeré.
Şùgbón tí ó bá ṣe àlejò pàtàkì ni, pálò̟ ńlá kejì ní wọn máa ti n gbàwọn lálejò. Pálò ñlá yìí
tóbi bli ààfin Oba. Wón sí tún şṣe é lós̟ò̟ó lóríṣiríṣi pèlú àwọn ohun mèremère bí i góólù.
Kódȧ kò yȧtò sí àafin. Ìdí nìyí tó fi jé̟ pé àwọn àlejò pàtàkì nìkan ni wó̟n máa ń gbà láàyè
láti jókòó nĺbè.
Ọmọ méjì péré ni àbúròo màmáà mi bí - Adébolá àtí Adébóyè. Okùnrin àti obìnrin ni won.
Adébolá ń lo yàrá kan. Adébóyè náà sì ní yàrá tire. Yàrá kan tókù ni yàrá àlejò. Fúláȧtì
àbúrò màmáà mi tóbi gan-an ni. Òpọlọpò̟ ènìyàn ni wọn máa ń sọ pé ó wu àwọn. Ìta
gbangbaa won téjú, ó sì láàyè tó pò̟. Ohun tó wù mí jùlo nípa fúláàti àbúrò màmáa mi nipé
won fi ọgbà yiká tó fi jépé àwọn ènìyàn tí wọn ń lọ níta kò le rí ohun tí ó ń lọ nínúu fúláàtì
àbúrò màmáà mi. | 30 |
|
31yy | llée wa jé ilé alájà méjì. Òpọlọpò̟ ojúlé ni ilé yìí ní. Àjà kìíní ní yàrá méjo̟, bé̟è̟ sì ni àjà kejì ní
yàrá méjo pèlú. Bàbáà mi fi gbogbo yàrá méjèèjo tí ó wà ní àjà kìíní rentì fún àwọn
ayálégbé. Àwọn ìdílé mérin otò̟ò̟tó̟ ni won gba àjà kìíní ní yàrá méji-méjì. Won fi yàrá kan şe
yàrá ìbùsunun wọn. llé ìdáná méjì, balúwè̟ méjì àti ilé ìyàgbé méjì ni ó wa ní àjà kìíní. Àwọn
ayalégbé sì pin wọn ní ìdílé méjì sí balúwè, ilée ìdáná àtí ilée ìyàgbé kò̟ò̟kan.
Yará mejo ni ó wà ní àjà kejì ṣugbọn èmi àti àwọn òbli mi pèlú awọn è̟gbọn àti àbúròò mí
nìkan ni à ń gbé ní àjà kejì. A ní pálò̟ ńlá kan tí a ti máa ń gba àlejò. A sì tún ní pálò̟ kékeré tí
awa ọmọ ti máa ń şeré, tí a sì ti máa ń wo telifíṣàn. Bàbáà mi ní yàráa ti wọn tí ó ti pálo ńlá.
Yará ìyáà mi sì tělé ti bàbáà mi. Ègbó̟nò̟n mi ọkùnrin tí ó wà ní Yunifásíti ti Obafemi
Awóló̟wó̟ ní ilé-Ifè̟ ní yàrá tiwọn lọtò̟, ó sì súnmó pálò ti àwa yòóku.
Yará àwọn ọmọ ọkùnrin méji yòókù àti ti awa obìnrin wà ní ìkangun ilé. Yàrá ìyáàgbà ni ó
tělé ti ìyáa mi. Gbogbo yàrá tí ó wà ní àjà keji ni àwọn ẹbli mi ń gbé tó bée gé tí ó fi ję wípé
kò sí àyè fún ayálégbé kankan láti gbé pèlúu wa. Yàrá ìdáná méjì, balúwè̟ méjì àtì ilé ìyàgbé
méjì ni ó wà ní àjà kejì bí ó ti wà ní àjà kìíní. ṣugbọn àwọn ẹbí mi nikan ni wọn ń lo gbogbo
àwọn yàrá wònyí. Eléyìí fún wa láàyè púpò̟ láti rí ibi kó erù sí. Kódà ìyáa mi ráȧyè sin nǹkan
osìnin wọn bli adie, ehoro àti tòlótòló. Bàbáà mi fi ọgbà yí ilée wa ká. Eléyìí sì fún àwa
o̟mo̟dé láńfààní láti şere sí ibi tí ó bá wùwà nínú o̟gbȧa wa. Ogbà ilée wa tóbi gan-an ni, ó sì
téjú púpo. | 31 |
|
32yy | Nínúu yàráà mi, mo ní ibùsùn, ìrò̟rí, àga, tábìlì ìkàwẻ, kó̟bó̟ò̟dù ìkáṣọsí, rédíò alágbèéká
kékeré kan, kápéèti (ení àtéèká) àti béè béè lọ.
Ní pálo, aga onítìmùtìmù merin ni wọn wà níbè, telifíṣàn ñlá kan, rédíò ñlá kan, aago ńlá
kan àti orişirişi àwòrán ara ògiri ni ó wa níbè pèlú. Sítóòfù onígáàsì àti sítóòfù
onikerosfinì wà nínúu ilé ìdáná. Bé̟ẹ náà sì ni firſìjì àti sfinkì. Ohún-èlò ìdáná oríşirişi bli
àwo, abo, ìkòkò, síbí, fó̟ò̟kì àti ò̟bẹ náà sì wà níbè. Ĕrọ omi, tó̟ò̟bù, sáwà, sfinkì, oṣẹ ìwè àti
táwèèlì wà nínúu balùwè. | 32 |
|
33yy | Nínú ilé-ìwee mi, oríşirişi nǹkan ni mo ní níbě bíi ìpara, ìparun, ìyarun, oṣẹ ìfoyín, ose ìwè,
oṣẹ ìfo̟wó̟, aṣo ìnura, omi tútù, omi gbígbóná, búró̟ò̟sì, kábíné̟è̟tì, kànhìnkànhìn, tíṣù, àti
àwọn nǹkan mìíràn.
Ní gélé tí mo ba ti wọ inú ilé-ìwèè̟ mi, búró̟ò̟sì mi ni mo kó̟kó̟ máa ń kì mó̟lè̟ tí má á fi ọṣẹ
ìfoyín sí i. Mo bèrè sí fọ ẹnu lọ nìyẹn. Léyìn òpò̟lò̟pò ìṣéjú, mà á bu omi yálà tútú tàbí
gbigbóná láti fi fọ ẹnuù mi mọ.
Àwọn Yorùbá ní ìgbàgbó̟ pé omi tútú máa ń jé̟ kí ara nà dáadáa, àmó̟ tí òtútù bá mú jù, omi
gbigbóná ni mo máa ń fi í wè̟ pè̟lú ọṣẹ àti kànhìnkànhìn ní àárò̟ kí gbogbo ìdò̟tí ara le bá
omi lọ. Mo máa fi ìpara àti ìparun ra ara àti irunùn mi. Tí mo ba ti wẻ tàn máa sì yarun pèlú.
Léyìn gbogbo èyí, háà! Oúnjẹ yá láti je nìyen! | 33 |
|
34yy | Tádé, njé o mò̟ pé kíláàsì márùnún ni mo ní ni simésítà yìí?
Háà! Hun ùn. Tirẹ mà dára à. Kíláàsì márùnún ni èmi náà ni, pè̟lú láàbù.
Mò ń se kákúló̟ò̟sì, físíìsì, è̟kó̟ èdèe Yorùbá, kémísírì àti sitatísííkì. Is̟é̟ náà
wò̟ mí lórùn nítorí pe ojoojúmó̟ ni mo máa ń lọ sí láàbù. Mo ń ṣe àyèwò
kan ló̟wó̟ nísinsìnyí fún ìdánwò. N kò sì mọ bí mo ti máa rí ké̟míkà tí màá
lò pè̟lú àyè̟wò náà láti fi rí èsì tỉ mò ñ retí nínú àyè̟wò náà.
Háà! Mo yìn é o. Is̟é̟ ńlá ni ò ń s̟e. Èmi kò ní láàbù, bé̟è̟ ni n kò sì ní is̟é̟
ojoojúmó̟. Nítorí náà kò yẹ kí n máa rojó̟. Kú isé̟ o, Tádé.
O o, O sé o. Wò ó, nís̟e ni mo ń retí kí simésítà yìí tán o jàre.
Má ṣè ìyonu Tádé, gbogbo rè̟ ti n tán lọ. Láìpé̟ ìwọ náà yóò di ẹnjíníà tó
mòye, tó ń gbówó rẹpętę.
Lóóótó ni o sọ Bùsólá, sùgbọn kíkékò̟ó̟ gboyè enjíníà kò rọrùn rárá.
Tádé, má sọ bé̟è̟ mó̟. Kò sí è̟kó̟ ìwé kankan tí ó rọrùn rárá. Șùgbọn tỉ
ènìyàn báá rójú, ènìyàn á jọrò̟ọ rẹ.
Otító̟ ni ọrọọ rẹ o, Bùsólá. Mo ti gbo ohun tí o sọ. Màá ró̟jú.
Ó dára béẹ. Jé kín kó̟ ẹ lórin tí bàbáa mi máa ń kọ láti gbàwá níyànjú kí a
ba à lè múra sí è̟kó̟o wa.
Bàtà rę á dún ko ko kà
Bàtà rę á dún ko ko kà
Bí o bá kȧwé rę, bàtà rẹ á dún ko ko kà
Bùsólá kàwé rẹ, bàtà rẹ á dún ko ko kà
Tádé kàwé rę, bàtà rẹ á dún ko ko kà
Bàtà rẹ á wó̟ ṣẹrẹrẹ nílè o
Bàtà rẹ á wó̟ ṣẹrẹrẹ nílè o
Bí o ò bá kàwé rẹ bàtà rẹ á wó̟ sẹrẹrẹ nílè̟.
Háà! Bùsólá, O ti fún mi ní agbára ò̟tun láti kàwé síi.
Ó dára o, alágbára ìwé. | 34 |
|
35yy | Òpolopo ilé-ìwé ló wà ní tòótò̟, àmọ ti ilé-ìwée mi yàto gan-an ni. llé-ìwée mi yȧtò sí àwọn ilé-
ìwé yòóku. Oro mi yìí kojá àpónlé, béè̟ kì í se àponlu. Àwọn Yorùbá ní bí a kò bá dé oko
baba elomíràn wò, a kò lè mọ èyí tí ó tóbi jù nínú oko baba eni àti baba elomíràn.
Èmi ti dé ilé-ìwé mìíràn, mo sì ti rí i dájú pé àjànàkú kojá mo ri nǹkan firí. Mo ti ri erin, mo sì
mò̟ pé erin ni. Şé ti àwọn olùkó̟ tí wọn gbámúṣé ni kí n sọ ni tàbí ti àwọn ilé aláràbarà tí wọn
wà ni kín wí?
Ká mú t'ègàn kúrò, ká tún fi t'ègàn kun, ilé-ìwé ni ilé-ìwéè mi. Yunifásítì ti Texas ní Austin
ni mò ń sọ. Gbogbo onà ni o lè gbà wọ ilé-ìwé mi yìí. Tí o bá wá gba iwájú ilé-ìfowopamosí
wolé, ki o kàn gbé ojú wo ò̟ọkàn, wà á rí ilé gogoro. Gígaa rè fé è lè kan orun. llé yìí ni
won n pè ní "UT Tower". Ibè gan-an ni gbogbo ètò àti àṣẹ ilé-ìwée mi ti ń wá. Ènìyàn kò
gbo̟dò̟ gbókè wòran rárá. Tí o bá gbìyànjú dé iwájú ilé yìí tàbí tí o ní àǹfààní láti wọ inúu
rè, wà á kí ajé kú ìkòlé. Ilé-ìwéè mi dára t'ègan lókù. Ìwo gbìyànjú kí o wá, ìròyìn kò tó
àfojúbà. | 35 |
|
36yy | Adéńrelé
dùndú
Bánké
gbangba
konko
gbàngbà
Déńdè
Bóláńlé
alángbá
àǹkárá
ànfààní | 36 |
|
37yy | Ìbàdàn
llú ébá odan, olú ìpínlè̟ Òyó
llú àwọn jagunjagun
llú Lágelú àtOlúyòlé
Ìlú ìbíkúnlé òun Ògúnmolá
Ogun kò kóbàdàn rí
Ìbàdàn ló kó gbogbo won yéye
ìlú tó gbę àlejò, tó gbe oníle
Ìbàdàn ló fè fè fè
To kojáa Móníyà lonà Òyó
Títí ó fi dé Ọmí Àdìó lónà Abéòkúta.
Onídùndú lonà Ifè àti Onígàǹbàrí lonà Ìjèbú
Ìbàdàn, ìlú ológunlógó òrùlé
Elérò ènìyàn bi eşu yako
Bé e débàdàn, ẹ bá mi kí wọn lójà Òjé
Lójàaba, Dùgbé àt' Aléṣinloyé oun Gbagi tuntun
Ní bi ti wọn ti n şe kátàkárà
Tówó ti ń wolé sápò ìṣòwò ní pereu
Olúbàdàn mo se o ní kábĺyèsí
Oba ìlú Ìbàdàn, mo gbósú bàǹbà
ìlú olóké púpò lèbá òdàn
Òké Adó, Òkèe Mapó, Òkè Ààrę
Òkée Séénì, Òkèe Bolà, Òkèe Bíókú
Òkė Eléyelé, Òkèèbàdan!
Òkèèbàdan dákun gbè mí o
Bí o ti gbe ara iwájú o
Eni to fapá se, fesè se nìbàdànán gbè
Nó şȧşekára ní těmi. | 37 |
|
38yy | Fáwọ̀jí Yorùbá (Yorùbá Vowels)
àlá
àrà
àwà
àsà
àdà
àló
àfọ̀
àdà
àgbára
àgà
Tone practice
àcà
àcá
àcā
Àjàlá je àpèjúwé Jidé
Àdé je ìyẹn Jáyé
ẹwẹ̀
ẹwẹ́
ẹrẹ̀
èdè
òde
ọdẹ̀
èdè
òṣé
gẹlẹ̀
èkó
Tone practice:
ẹní
ẹní
ẹnī
What is à to kìkì pro ọjẹ́
Dide dé èdè áńs.
ìwé
ìdẹ́
ìyàtọ̀
ìwé
ìlú
ìṣẹ́
ìyá
ìwé
ìdè
Tone practice:
ìní
ìní
ìnī
Orọ́ je tàbí kórí kẹlẹ.
Pélépélé kojẹ́ í tápárá.
ìjó
ìjẹ́
ibí
ọmọ
iṣu
ìdí
ilé
ibẹ̀
ìdẹ̀j
Tone practice
ìbí
ìbí
ìbī
Ìyàtọ̀ fẹ́ rí mógbọn tá yẹn tòní.
lọ́ lọ́ ní Jídé wá.
Bàbá dúdú ní orí ọjẹ gígọ.
ìwé
èdè
èké
àdúrà
òṣé
ẹbọ
ìdáná
ẹbọ̀
ọlàjú
Tone practice
òjé
ojé
ọjẹ́
òṣì
òṣé
Ọjẹ́ gbowó lẹwọ́ ọlọ́run í Ọwódù.
Olú dèédé sùn odò Mámúdù Tóbí.
ìwé
ẹ̀ṣẹ̀
á jẹ
à rí
ìdí
ẹjẹ́
ìdí
ìgbé
èdè
ìkókó
ìmọ́lẹ̀
ìlọjọ̀
NNPC
Tone practice
èsè
èsé
èsē
Ọgbọ́n wò rẹ́ rán tí yẹnju tábitọ́run.
Orí àná àtí ní ọrùn tí.
ìròyìn
ìsọ̀kàn
ìdàgbàsókè
tí
rí
wá
ní
jẹ
tí
Tone practice:
è
é
ē
Wo o kìní dúndú ńb'í Lágí.
Àwọn bàǹtẹ́ ńb'í ilé Ọlọ́run. | 38 |
|
39yy | Kôñsónáõtì Yorùbá (Yorùbá Consonants)
/b/
bàbá
bó
bèrè
Bísí
bàtà
bò
bé
bèrù
búburú
ìbínú
Tone practice
bí
bì
bi
bo
bo
bọ
Bísí bá bábá bộ bàtà.
Orin
Bá a bá léni
Bá a bá bánh
ìwòn là á bánií sòtá mọ
/d/
edá
ìdàmú
ìdále
òòde
òdėdė
dárijì
ìdáwó
dáwó
dánilójú
odė
ode
Tone practice
dé
dè
de
dẹ
edé
èdè
ode
odę
Adé dé adé oba ní Ayédé
Dàda tutù bí ẹyẹ àdàbà
/f/
Ifẹ
ìfé
aféfé
funfun
ìfàkì
féràn
efun
fún
filà
Fémi
Tone practice
fé
fè
fó̟
Fémi férànan filà funfun.
Aféfé fé ìyẹ funfun náà lọ.
Folá foso funfun fún Fémi.
/g/
ògá
ògo
ogún
ogun
Ògún
ogėdė
agogo
igi
àga
gé
Tone practice
gùn
gùn
gún
Proverb
Igi gogoro má gùn-ún mi lójú, òkèèrè la ti n wò ó.
Gbénga gé igi gíga.
Owe
Igi gogoro má gùn-ún mi lójú, òkèèrè la ti n wò ó.
/gb/
gbòngbò
àgbà
egbé
égbé
agbádá
àgbàdo
alángbá
agbòòrùn
ìgbàgbo
Tone practice
agbon
àgbọn
agbon
àgbàrá
agbára
Gbogbo àgbààgbà lo sí ojaa Gbági.
Gbogbo alángbá ń sá lángbáláńgbá nínú àgbàlá.
/h/
ihò
wàhálà
Wolé
hó
há
há
ahon
eléhàá
họ
ìhà
Tone practice
han
hàn
hán
há
ha
Híhanrun tí bàbáa Délé ń hanrun jé̟ wàhálà.
/j/
jó
àjò
ojà
iji
Ojó
òjò
oúnjẹ
ijù
ìjà
Tone practice
ėjė
éjé
ìjí jà ní ọjó̟ o̟jà ní ìjeje.
Jumokė judí ní ajo ijó.
/k/
oká
oríkì
kíákiá
eku
kèké
ọkùnrin
èrèké
èké
ekùn
Tone practice:
okò̟
ọkọ
oκό
ò̟kò̟
Kémi kí Kíké kááárò.
Kíké kí Kémi kááárò
Proverb
Kíkéré ni abéré ń kéré, kì í se mímì fún adie
/l/
lé
lè
le
lù
olá
Lékan
labalábá
Àlàbá
àlá
láti
Tone practice
lọ
lọ
là
lá
Lolá lá àlá lábà Àlàbá.
/m/
méjì
ìmò̟
omowé
ọmọ
amò̟
omobìnrin
ọmọkùnrin
mámá
omi
molémolé
Tone practice
mó̟
mò̟
Mo mu omi ní ilée màmàá Máyòwá.
Màmáà mi mu omil mi.
ní
níbí
/n/
nĺbo
nípon
níwájú
nísìnyí
níbeyen
nìkan
nù
náírà
Tone practice
ní
ni
ná
nà
Níyì ná náírá nílé ànaa rè.
Níran náwó nínȧákúnȧá.
/p/
àpá
ера
epo
аро
potopótò
pátápátá
pín
pátá
páálí
pàtàkì
Tone practice
apá
ȧpà
pón
pon
Pàkútée Péjú pa ẹyẹ àparò.
Paríolá pín èpà náà.
Pàdé pejò ní pápáa bó̟ò̟lù Àpápá
/r/
ara
rí
rà
rere
rérìnín
rárá
ronú
rojó
ròyìn
rántí
Tone practice
rò
rό
eré
èrè
erè
ère
Rírí tí Rèmí rí ò̟réè mi Rántí mú inuù Remí dùn.
Remí ra ìresì ní Rémo.
/s/
ìręsì
ìwòsí
sùúrù
esè
ìsìn
sò̟rò̟
Similólú
sinmi
àìsàn
àsè
Tone practice
sìn
sín
sin
ìsìn
èsín
èsín
Similólá sinmi lójó ìsinmi
Sanmí binú sí Sánní.
/ş/
Şòkòtò
eşin
işu
aṣọ
aláso
Şadé
Şolá
sòro
àṣà
àşá
Tone practice
ṣé
ṣè
àşà
àşá
Şadé subú níwájúu Şolá.
Şé Şolá ń ṣiṣé ní soobù Şeye?
/t/
atégùn
àtélewó
àti
ata
ote
ọtí
gbókìtì
télètélè
òtító
bàtà
Tone practice
Sángo Òtà
otá
to
tó
Títí ta atá ní títì.
Proverb
Atètè sùn làtètè jí.
Títí ta atá ní títì.
owe
Atètè sùn làtètè jí.
/w/
ìwé
ìwa
wéréwéré
weere
wàhálà
wó̟
wù
wà
wá
Wolé
Tone practice
ìwé
iwe
wọlé
Wėmimo
Wálé wọlée Wėmimo.
Wálé wolée Wolé.
Wálé wale mi.
/y/
iyanrìn
yȧto
yìnyín
yànmùyánmú
yojú
yìn
Yínká
Yemí
yoyĺnyoyin
éyìn
Tone practice
yo
yo
yará
yarí
Oyȧyà ìyáa Yemi máyé yẹ ẹ.
Ayé ye Yelé ní ìlú Qyo. | 39 |
summary
Textbook audio archive size: total 36M archive created: 8 July 2011
mp3 file size ======== ==== 01-yy_intro_alphabet.mp3 1.2M 02-yy_intro_consonants.mp3 757K 04-yy_intro_oral-vowels.mp3 319K 05-yy_intro_tones.mp3 620K 06-yy_ch01_l01_d01.mp3 1.6M 07-yy_ch02_l03_m01.mp3 1.1M 08-yy_ch02_l04_d01.mp3 1.5M 09-yy_ch03_l02_d01.mp3 856K 10-yy_ch03_l03_m01.mp3 635K 11-yy_ch04_l02_d01.mp3 726K 12-yy_ch04_l03_d02.mp3 492K 13-yy_ch05_l02_d01.mp3 199K 14-yy_ch05_l03_m01.mp3 1.3M 15-yy_ch05_l03_m02.mp3 556K 16-yy_ch05_l04_m03.mp3 456K 18-yy_ch06_l03_d01.mp3 502K 19-yy_ch06_l03_d02.mp3 743K 20-yy_ch06_l03_d03.mp3 1.1M 21-yy_ch06_l03_s01.mp3 201K 22-yy_ch06_l03_s02.mp3 313K 23-yy_ch07_l01_d01.mp3 1.2M 24-yy_ch07_l03_d02.mp3 1.3M 25-yy_ch07_l04_d03.mp3 1.2M 26-yy_ch08_l03_d01.mp3 1.3M 27-yy_ch09_l01_d01.mp3 1001K 28-yy_ch10_l02_s01.mp3 744K 29-yy_ch10_l02_s02.mp3 355K 30-yy_ch10_l03_m01.mp3 2.5M 31-yy_ch10_l04_m02.mp3 2.0M 32-yy_ch10_l04_m03.mp3 910K 33-yy_ch10_l04_m04.mp3 1.4M 34-yy_ch12_l02_d01.mp3 2.4M 35-yy_ch12_l03_m01.mp3 1.4M 36-yy_appx_syllabic-nasals.mp3 119K 37-yy_appx_poem.mp3 1.8M 38-yy_appx_vowels.mp3 4.1M 39-yy_appx_consonants.mp3 8.7M
Credit: Yorùbá Yé Mi: audio archive Creative Commons license Department of Middle Eastern Studeis The University of Texas at Austin
- Downloads last month
- 215